ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 10
Tó O Bá Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Tó O sì Mọyì Rẹ̀, Wàá Ṣèrìbọmi
“Kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?”—ÌṢE 8:36.
ORIN 37 Máa Sin Jèhófà Tọkàntọkàn
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 8:27-31, 35-38, kí ló mú kí ìwẹ̀fà ará Etiópíà kan ṣèrìbọmi?
ṢÉ Ó wù ẹ́ pé kó o ṣèrìbọmi, kó o sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi? Ìfẹ́ tí ọ̀pọ̀ ní fún Jèhófà àti bí wọ́n ṣe mọyì rẹ̀ ti mú kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ yẹn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ ọbabìnrin àwọn ará Etiópíà.
2 Ọkùnrin yẹn kò fi nǹkan falẹ̀ rárá, gbàrà tó lóye ohun tó kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ ló ṣèrìbọmi. (Ka Ìṣe 8:27-31, 35-38.) Kí ló jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀? Kò sí àní-àní pé ó mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an, kódà ìwé Àìsáyà ló ń kà lọ́wọ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin bó ṣe ń pa dà sí ìlú rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù. Lẹ́yìn tí Fílípì bá a sọ̀rọ̀ nípa Jésù, inú ẹ̀ dùn, ó sì fi hàn pé òun mọyì ohun tí Jésù ṣe fún òun. Àmọ́ kí nìdí tó fi lọ sí Jerúsálẹ́mù? Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni. Báwo la ṣe mọ̀? Bíbélì ròyìn pé ó lọ jọ́sìn Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù. Ó dájú pé ọkùnrin yìí ti pa ìjọsìn àwọn ará ìlú rẹ̀ tì, ó sì ti dara pọ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo tó jẹ́ ti Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́. Ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà yìí kan náà ló mú kó ṣèrìbọmi tó sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi.—Mát. 28:19.
3. Kí ló lè mú kó ṣòro fún ẹnì kan láti ṣèrìbọmi? (Wo àpótí náà “Irú Èèyàn Wo Lo Jẹ́ Nínú Lọ́hùn-ún?”)
3 Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà lè mú kó wù ẹ́ láti ṣèrìbọmi. Àmọ́ tó ò bá ṣọ́ra, ìfẹ́ lè mú kó ṣòro fún ẹ láti ṣèrìbọmi. Lọ́nà wo? Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè máa bẹ̀rù pé wọ́n á kórìíra ẹ tó o bá ṣèrìbọmi. (Mát. 10:37) Táwọn ìwà kan tí Ọlọ́run ò fẹ́ bá sì ti mọ́ ẹ lára, ó lè nira fún ẹ láti jáwọ́. (Sm. 97:10) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe nínú ẹ̀sìn èké ti lè dùn mọ́ ẹ. Ó ṣeé ṣe kó o fẹ́ràn àwọn nǹkan tẹ́ ẹ máa ń ṣe nígbà ayẹyẹ wọ̀nyẹn, torí náà ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún ẹ láti jáwọ́ pátápátá nínú wọn. (1 Kọ́r. 10:20, 21) Ìbéèrè náà ni pé: “Ta lo fẹ́ràn jù tàbí kí lo fẹ́ràn jù?”
ẸNI TÓ YẸ KÓ O NÍFẸ̀Ẹ́ JÙ
4. Kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ kó o ṣèrìbọmi?
4 Káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́, ó ṣeé ṣe kó o fẹ́ràn àtimáa ka Bíbélì. Ó sì ṣeé ṣe kó o nífẹ̀ẹ́ Jésù náà. Ní báyìí tá a ti ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́, ó ṣeé ṣe kó o ti máa dara pọ̀ mọ́ wa. Ó dájú pé o mọyì àwọn nǹkan rere tó ò ń gbádùn. Ó dáa bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ tó o sì ń wá sípàdé, àmọ́ àwọn nǹkan yìí ò tó láti mú kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó o sì ṣèrìbọmi. Ohun tó ṣe pàtàkì jù táá mú kó o ṣèrìbọmi ni ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà Ọlọ́run. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ju ohunkóhun míì lọ, o ò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti jọ́sìn ẹ̀. Torí náà, ìfẹ́ fún Jèhófà lá mú kó o ṣèrìbọmi, òun náà lá sì mú kó o fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi.
5. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?
5 Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ fi gbogbo ọkàn wa, gbogbo ara wa, gbogbo èrò wa àti gbogbo okun wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Máàkù 12:30) Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kó o sì máa bọ̀wọ̀ fún un? Á dáa kó o ronú jinlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, ìyẹn á sì mú kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Jòh. 4:19) Kí làwọn nǹkan míì tí ìfẹ́ yìí máa mú kó o ṣe?b
6. Bó ṣe wà nínú Róòmù 1:20, sọ ọ̀nà kan tó o lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà.
6 O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tó o bá ń kíyè sí àwọn ohun tó dá. (Ka Róòmù 1:20; Ìfi. 4:11) Ronú nípa bí àwọn ewéko àtàwọn ẹranko ṣe ń gbé ọgbọ́n Jèhófà yọ. Fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹ̀yà ara rẹ, wàá sì rí i pé àgbàyanu niṣẹ́ Ọlọ́run. (Sm. 139:14) Máa ronú nípa agbára ńlá tí Jèhófà fi sínú oòrùn tó jẹ́ ẹyọ kan péré nínú ọ̀kẹ́ àìmọye ìràwọ̀.c (Àìsá. 40:26) Kò sí àní-àní pé tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ bẹ̀rù Jèhófà, wàá sì mọyì rẹ̀. Àmọ́, kéèyàn gbà pé Jèhófà jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti alágbára wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ohun táá mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Torí náà, tó o bá máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó tún ṣe pàtàkì kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀.
7. Kó o tó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn, kí ló yẹ kó dá ẹ lójú?
7 Ó yẹ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an. Ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé kò lè rí tìẹ rò ká má tíì sọ pé kó nífẹ̀ẹ́ rẹ? Tó bá ń ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀, máa rántí ohun tí Bíbélì sọ pé Jèhófà “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:26-28) Kódà “gbogbo ọkàn” ló ń wá, ó sì ṣèlérí fún ẹ bí ọ̀rọ̀ Dáfídì sí Sólómọ́nì pé “tí o bá wá a, á jẹ́ kí o rí òun.” (1 Kíró. 28:9) Òótọ́ kan ni pé Jèhófà ló mú kó ṣeé ṣe fún ẹ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé ‘mo ti fà ọ́ mọ́ra.’ (Jer. 31:3) Bó o ṣe túbọ̀ ń mọyì gbogbo ohun tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
8. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì ìfẹ́ Jèhófà?
8 Ọ̀nà kan tó o lè gbà fi hàn pé o mọyì ìfẹ́ Jèhófà ni pé kó o máa gbàdúrà sí i. Wàá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bó o ṣe ń sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún un tó o sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún gbogbo oore rẹ̀. Bákan náà, bó o ṣe ń kíyè sí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà rẹ, okùn ọ̀rẹ́ yín á máa lágbára sí i. (Sm. 116:1) Á túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ̀ ẹ́, ó sì lóye rẹ. Àmọ́ tó o bá fẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ lágbára, ó ṣe pàtàkì kó o mọ ojú tó fi ń wo nǹkan àti ìdí tó fi ń ṣe àwọn ohun tó ń ṣe. Ó tún ṣe pàtàkì kó o mọ ohun tó fẹ́ kó o ṣe. Ọ̀nà kan ṣoṣo tó o sì lè gbà mọ àwọn nǹkan yìí ni pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
9. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì Bíbélì?
9 Mọyì Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Inú Bíbélì nìkan lo ti lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà àtohun tó ní lọ́kàn fún ẹ. O lè fi hàn pé o mọyì Bíbélì tó o bá ń kà á lójoojúmọ́, tó ò ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ sílẹ̀, tó o sì ń fi ohun tó ò ń kọ́ sílò. (Sm. 119:97, 99; Jòh. 17:17) Ǹjẹ́ o ní ìṣètò láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́? Ṣé o máa ń tẹ̀ lé ìṣètò náà, ṣé o sì ń rí i dájú pé ọjọ́ kan ò lọ láìka Bíbélì?
10. Sọ ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa Bíbélì.
10 Ọ̀kan lára ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa Bíbélì ni pé àkọsílẹ̀ àwọn tọ́rọ̀ ṣojú ẹ̀ tí wọ́n sì mọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù wà nínú ẹ̀. Bíbélì nìkan ló sọ ohun tó péye nípa Jésù àtohun tó ṣe fún ẹ. Bó o ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe, wàá túbọ̀ mọyì rẹ̀, wàá sì fẹ́ di ọ̀rẹ́ rẹ̀.
11. Kí lá jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
11 Nífẹ̀ẹ́ Jésù kó o lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù gbé àwọn ànímọ́ Jèhófà yọ lọ́nà tó pé pérépéré. (Jòh. 14:9) Torí náà, bó o ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ lóye ẹni tí Jèhófà jẹ́, wàá sì mọyì rẹ̀. Ronú nípa bí Jésù ṣe fi àánú hàn sáwọn tí aráyé kò kà sí, ìyẹn àwọn tálákà, àwọn tó ń ṣàìsàn àtàwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Tún ronú nípa àwọn ìmọ̀ràn tí Jésù fún ẹ nínú ìwàásù rẹ̀ àti àǹfààní tó ò ń rí bó o ṣe ń fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílò láyé rẹ.—Mát. 5:1-11; 7:24-27.
12. Bó o ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, kí nìyẹn máa mú kó o ṣe?
12 Wàá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jésù bó o ṣe ń ronú nípa bó ṣe fẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kí Ọlọ́run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. (Mát. 20:28) Tó bá yé ẹ pé torí tìẹ ni Jésù ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, wàá ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, wàá sì bẹ Jèhófà pé kó dárí jì ẹ́. (Ìṣe 3:19, 20; 1 Jòh. 1:9) Bó o ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jésù àti Jèhófà, bẹ́ẹ̀ lá máa wù ẹ́ láti wà pẹ̀lú àwọn tó ti ṣe bẹ́ẹ̀.
13. Àwọn wo ni Jèhófà fi jíǹkí ẹ?
13 Nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà. Àwọn ẹbí rẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí àtàwọn tó ò ń bá ṣọ̀rẹ́ tẹ́lẹ̀ lè má lóye ìdí tó o fi pinnu pé Jèhófà ni wàá sìn. Wọ́n tiẹ̀ lè ta kò ẹ́. Àmọ́ Jèhófà máa fi àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ jíǹkí ẹ, wọ́n á sì mú ẹ bí ọmọ ìyá. Tó o bá ń sún mọ́ àwọn ará, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ ẹ, ọkàn ẹ á sì balẹ̀. (Máàkù 10:29, 30; Héb. 10:24, 25) Tó bá yá, ó ṣeé ṣe káwọn ará ilé rẹ náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì wá jọ́sìn Jèhófà.—1 Pét. 2:12.
14. Kí lo lè sọ nípa àwọn ìlànà Jèhófà bó ṣe wà nínú 1 Jòhánù 5:3?
14 Mọyì àwọn ìlànà Jèhófà, kó o sì máa fi wọ́n sílò. Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó tọ́ lójú ẹ lò ń ṣe. Àmọ́ ní báyìí tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́, o ti wá rí i pé àwọn ìlànà Jèhófà ló dáa jù. (Sm. 1:1-3; ka 1 Jòhánù 5:3.) Lára ìlànà bẹ́ẹ̀ làwọn ìmọ̀ràn tí Bíbélì gba àwọn ọkọ, àwọn aya, àwọn òbí àtàwọn ọmọ. (Éfé. 5:22–6:4) Bó o ṣe ń fi ìmọ̀ràn yẹn sílò, ǹjẹ́ o kíyè sí i pé ìdílé rẹ túbọ̀ ń láyọ̀? Bó o ṣe ń fi ìmọ̀ràn Jèhófà sílò pé kó o fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, ǹjẹ́ o kíyè sí i pé ìwà rẹ ń sunwọ̀n sí i? Ṣé o kíyè sí i pé o túbọ̀ ń láyọ̀? (Òwe 13:20; 1 Kọ́r. 15:33) Ó ṣeé ṣe kó o dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yìí.
15. Kí lo lè ṣe tí kò bá rọrùn fún ẹ láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò?
15 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè má rọrùn fún ẹ láti fàwọn ìlànà Bíbélì tó ò ń kọ́ sílò. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi ń lo ètò rẹ̀ láti pèsè àwọn ìtẹ̀jáde tó ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. (Héb. 5:13, 14) Tó o bá ń ka àwọn ìtẹ̀jáde yìí, tó o sì ń ronú lé e lórí, wàá rí àwọn ìmọ̀ràn pàtó tó o lè fi sílò, ìyẹn á sì mú kó o túbọ̀ sún mọ́ ètò Jèhófà.
16. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣètò àwa èèyàn rẹ̀?
16 Mọyì ètò Jèhófà kó o sì máa ti ètò náà lẹ́yìn. Jèhófà ti ṣètò àwa èèyàn rẹ̀ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan, ó sì fi Jésù Ọmọ rẹ̀ ṣe orí gbogbo ìjọ. (Éfé. 1:22; 5:23) Jésù wá yan àwùjọ kéréje àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró pé kí wọ́n máa múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ tó fẹ́ kó di ṣíṣe lásìkò wa yìí. Jésù pe àwùjọ yìí ní “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Ọwọ́ pàtàkì ni ẹrú yìí fi mú ojúṣe tí Jésù gbé fún wọn pé kí wọ́n máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún ẹ, kí wọ́n sì máa dáàbò bò ẹ́ nípa tẹ̀mí. (Mát. 24:45-47) Ọ̀kan lára ọ̀nà tí ẹrú olóòótọ́ gbà ń bójú tó ẹ ni bí wọ́n ṣe ń rí i dájú pé a yan àwọn alàgbà tó kúnjú ìwọ̀n láti máa tọ́ ẹ sọ́nà. (Àìsá. 32:1, 2; Héb. 13:17; 1 Pét. 5:2, 3) Inú àwọn alàgbà máa ń dùn láti fara wọn jìn nítorí ẹ, wọ́n ṣe tán láti tù ẹ́ nínú kí wọ́n sì mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Àmọ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí wọ́n ń ṣe fún ẹ ni bí wọ́n ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn míì nípa Jèhófà.—Éfé. 4:11-13.
17. Bó ṣe wà nínú Róòmù 10:10, 13, 14, kí nìdí tó fi yẹ kó o máa sọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn míì?
17 Ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n kọ́ àwọn míì nípa Jèhófà. (Mát. 28:19, 20) Ohun kan ni pé èèyàn lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọ́n ṣáà ní ká ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ bó o ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á yá ẹ lára láti sọ̀rọ̀ Jèhófà bíi ti àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù tó sọ pé: “A ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” (Ìṣe 4:20) Ṣàṣà nǹkan ló lè mú inú wa dùn bíi ká wàásù nípa Jèhófà fáwọn míì. Wo bí inú Fílípì ajíhìnrere ṣe máa dùn tó nígbà tó ran ìwẹ̀fà ará Etiópíà yẹn lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sì ṣèrìbọmi! Tó o bá fara wé Fílípì, tó o sì ń wàásù bí Jésù ṣe pa láṣẹ, ṣe lò ń fi hàn pé o fẹ́ di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóòótọ́. (Ka Róòmù 10:10, 13, 14.) Tó o bá ti tẹ̀ síwájú débi pé o ti lóye òtítọ́, o sì ti ń wàásù, ó yẹ kó o béèrè bíi ti ìwẹ̀fà ará Etiópíà yẹn pé: “Kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?”—Ìṣe 8:36.
18. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
18 Ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù tó o lè ṣe nígbèésí ayé ẹ ni pé kó o ṣèrìbọmi. Torí náà, á dáa kó o fara balẹ̀ ronú kó o tó gbé ìgbésẹ̀ yìí torí pé ìrìbọmi kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré. Kí ló yẹ kó o mọ̀ nípa ìrìbọmi? Kí ló yẹ kó o ṣe kó o tó ṣèrìbọmi àti lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
ORIN 2 Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ
a Àwọn kan tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ṣì ń ronú bóyá káwọn ṣèrìbọmi láti di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àbí káwọn má ṣe bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ bó ṣe ń ṣe ẹ́ nìyẹn, wàá rí àwọn nǹkan tó o lè ṣe nínú àpilẹ̀kọ yìí táá mú kó wù ẹ́ láti ṣèrìbọmi.
b Àwọn èèyàn yàtọ̀ síra, torí náà bí àwọn kan ṣe máa fi àwọn àbá inú àpilẹ̀kọ yìí sílò lè má tò tẹ̀ léra bó ṣe wà níbí.
c Tó o bá fẹ́ rí àwọn àpẹẹrẹ míì, wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí? lórí ìkànnì jw.org/yo.
d ÀWÒRÁN: Nígbà tí arábìnrin kan lọ sọ́jà, ó fún obìnrin tó ń rajà lọ́wọ́ ẹ̀ ní ìwé àṣàrò kúkúrú.