Kí Ni Ọkàn?
Ohun tí Bíbélì sọ
Inú ọ̀rọ̀ èdè Hébérù kan tí wọ́n pè ní neʹphesh àti psy·kheʹ lédè Gíríìkì ní wọ́n ti túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” tó wà nínú Bíbélì. Ní èdè Hébérù, ọkàn túmọ̀ sí “ẹ̀dá tó ń mí,” ó sì túmọ̀ sí “ẹ̀dá alààyè” ní èdè Gíríìkì.”a Torí náà, ẹ̀dá alààyè lódindi ni ọkàn, kì í ṣe ohun kan tó wà nínú wa tí kì í kú tí ara bá ti kú. Jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe fi hàn pé èèyàn lódindi ni ọkàn:
Gbàrà tí Jèhófà Ọlọ́run dá Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, Bíbélì sọ pé “ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Kì í ṣe pé Ádámù gba ọkàn—kàkà bẹ́ẹ̀ òun fúnra rẹ̀ di alààyè ọkàn tàbí èèyàn.
Bíbélì sọ pé ọkàn máa ń ṣiṣẹ́, ó máa ń wá oúnjẹ, ó máa ń jẹun, ó máa ń pa òfin mọ́, tàbí fọwọ́ kan òkú. (Léfítíkù 5:2; 7:20; 23:30; Diutarónómì 12:20; Róòmù 13:1) Gbogbo ohun tá a mẹ́nu kàn yìí ni èèyàn lè ṣe.
Ṣé ọkàn máa ń kú?
Bẹ́ẹ̀ ni, ọkàn máa ń kú. Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì sọ pé ọkàn máa ń kú. Gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀wò:
‘Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀ òun ni yóò kú.’—Ìsíkíẹ́lì 18:4, 20.
Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, ìyà tó wà fún ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ni pé “ọkàn yẹn ni a óò ké kúrò.” (Ẹ́kísódù 12:15, 19; Léfítíkù 7:20, 21, 27; 19:8) Ẹni náà “ni a ó pa.”—Ẹ́kísódù 31:14, Bíbélì Mímọ́.
Lẹ́yìn tí ẹnì kan bá kú, àwọn ẹsẹ Bíbélì kan máa ń lo “òkú ọkàn” fún irú ẹni bẹ́ẹ̀. (Léfítíkù 21:11, Númérì 6:6) Lóòótọ́ àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan máa ń lo “òkú” tàbí “òkú èèyàn,” àmọ́ ohun tí èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ lò ni neʹphesh tàbí “ọkàn.”
“Ọkàn” lè túmọ̀ sí “ẹ̀mí”
Nígbà míì Bíbélì tún máa ń pe “ọkàn” ní “ẹ̀mí.” Bí àpẹẹrẹ, ìwé Jóòbù 33:22 (Bíbélì Mímọ́) lo ọ̀rọ̀ Hébérù náà “ọkàn” (neʹphesh) àti “ẹ̀mí” pa pọ̀. Torí náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn lè fi ọkàn rẹ̀ wewu tàbí kó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.—Ẹ́kísódù 4:19; Àwọn Onídàájọ́ 9:17; Fílípì 2:30.
Bí Bíbélì ṣe lo ọkàn ti jẹ́ ká lóye ohun tó túmọ̀ sí nígbà tí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sọ pé ó ń “jáde lọ” àbí “ó ti ń lọ.” (Jẹ́nẹ́sísì 35:18; Bíbélì Mímọ́) Ohun tí àkànlò èdè náà wulẹ̀ túmọ̀ sí ni pé ẹ̀mí ẹni náà ti fẹ́ bọ́. Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan tú ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 35:18 sí “ó mí èémí ìkẹyìn.”—Ìròhìn Ayọ̀.
Ibo ni ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn ti ṣẹ̀ wá?
Inú ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti rí ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ibi tí Bíbélì tọ́ka sí ni wọ́n ti lo ọkàn fún nǹkan tó ń mí, kò sì sí ìyàtọ̀ láàárín ọkàn àti ara. Torí náà, ìgbàgbọ́ nínú pé ìpínyà wà láàárín ọkàn àti ara wá látinú ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì.”
Ọlọ́run ò fẹ́ kí a máa da ìmọ̀ ọgbọ́n orí pọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì, irú bí àìleèkú ọkàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn.”—Kólósè 2:8.
a Wo ìwé The New Brown, Driver, and Briggs Hebrew and English Lexicon of the Old Testament, ojú ìwé 659, àti ìwé Lexicon in Veteris Testamenti Libros, ojú ìwé 627. Nínú ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì, ọ̀nà tó yàtọ̀ síra ni wọ́n gbà lo ọ̀rọ̀ náà neʹphesh àti psy·khe.ʹ Ohun tí Bíbélì bá sọ níbi tí àwọn ọ̀rọ̀ náà ti fara hàn ni wọ́n máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí. Ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì lo ọ̀rọ̀ bí “ọkàn”, “ẹ̀mí,” “èèyàn,” “ẹ̀dá” tàbí “ara.”