Ojú Ìwòye Bíbélì
“Eré Ìdárayá Àṣejù” Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí O Fara Rẹ Wewu?
“LÓDE ÒNÍ, Ọ̀PỌ̀ NÍNÚ WA NI KÌ Í TÚN ṢE ÒǸWÒRAN MỌ́, ṢÙGBỌ́N ÀWA FÚNRA WA TI Ń LO ÌHÙMỌ̀ TÍ A FI Ń BALẸ̀ LÁÌFARAPA, A Ń FI OKÙN FÒ BỌ́ SÍLẸ̀ LÁTORÍ ÀWỌN ÒKÈ ŃLÁ, A Ń FI ỌKỌ̀ ÒBÈLÈ DÁRÀ LÓJÚ ÒKUN TÍ Ń RU GÙDÙ, ÀWA ÀTI ÀWỌN ẸJA ÈKÙRÀ SÌ JỌ Ń WẸDÒ.”—ÌWÉ ÌRÒYÌN THE WILLOW GLEN RESIDENT.
GBÓLÓHÙN yìí fi ohun tó ń gbilẹ̀ nínú eré ìdárayá hàn. Bí àwọn eré ìdárayá bíi fífò bọ́ láti inú ọkọ̀ òfuurufú, gígun orí yìnyín, àwọn awakọ̀ òfuurufú tí ń fò bọ́ láti inú ọkọ̀ òfuurufú, àti fífòbọ́sílẹ̀ láti ibi gíga fíofíoa ṣe ń pọ̀ sí i ń fi hàn pé àwọn èèyàn fẹ́ràn fífi ara wọn wewu. Àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń yọ̀ tẹ̀rẹ́ lórí ìrì dídì, àwọn kẹ̀kẹ́ tí wọ́n fi ń gun òkè, àwọn ohun èlò onítáyà kéékèèké tí wọ́n fi ń wọ́ bọ́ látorí òkè, àti irin pẹlẹbẹ tí táyà rẹ̀ tò tẹ̀ léra wọn ni wọ́n tún máa ń lò láti fi gun òkè, láti fi bọ́ sílẹ̀ ní àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tó ga gan-an, àti láti fi fò bọ́ sílẹ̀ láti àwọn ibi tó ga jù lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Time ṣe sọ, bí “eré ìdárayá àṣejù”—àwọn eré ìdárayá tí àwọn tó ń ṣe é ti ń fi ẹ̀mí ara wọn wewu gidigidi—ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i ń fi hàn pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ló ń hára gàgà láti kópa nínú “ìgbòkègbodò tó léwu nínú, tó gba òye gidigidi, tó sì ń bani lẹ́rù, èyí sì ń mú kí àwọn tó ń ṣe eré ìdárayá ní òpin ọ̀sẹ̀ nìkan àti àwọn eléré ìdárayá amọṣẹ́dunjú máa ronú pé àwọn túbọ̀ ń dáńgájíá sí i.”
Ṣùgbọ́n, bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí i yìí tún ń mú ìnáwónára púpọ̀ dání. Àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i ló ń fara pa nígbà tí wọ́n bá ki àṣejù bọ àwọn eré ìdárayá tí kò léwu tẹ́lẹ̀. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, lọ́dún 1997, iye àwọn èèyàn tó ń lọ gbàtọ́jú níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn aláìsàn ní pàjáwìrì ní ilé ìwòsàn nítorí pé wọ́n ṣèṣe níbi tí wọ́n ti ń ṣe eré ìdárayá tó jẹ mọ́ wíwọ́ sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè fi iye tó ju ìpín mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lọ pọ̀ sí i, ti gígun orí yìnyín ju ìpín mọ́kànlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lọ, tí ti òkè gígùn sì ju ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún lọ. Ní ti àwọn eré ìdárayá mìíràn, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ túbọ̀ gbàfiyèsí, bí ó ti ṣe kedere pé iye àwọn tó ń kú nítorí eré ìdárayá àṣejù túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àwọn tó ń ṣalágbàwí eré ìdárayá wọ̀nyí mọ̀ pé ó léwu. Obìnrin kan tó kópa nínú eré ìyọ̀tẹ̀rẹ́ lórí yìnyín lọ́nà àṣejù wí pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ronú nípa ikú.” Ẹnì kan tó mọ bí wọ́n ṣe máa ń yọ̀ tẹ̀rẹ́ lórí ìrí dídì lámọ̀dunjú ṣàkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà nípa sísọ pé, bí “o kò bá fara pa, a jẹ́ pé o kò tíì ṣe eré ìdárayá dójú àmì nìyẹn.”
Lójú ìwòye kókó wọ̀nyí, báwo ló ṣe yẹ kí Kristẹni kan wo lílọ́wọ́ nínú irú ìgbòkègbodò wọ̀nyí? Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu bóyá ó yẹ ká lọ́wọ́ nínú eré ìdárayá àṣejù? Ṣíṣàyẹ̀wò èrò Ọlọ́run nípa ìjẹ́mímọ́ ìwàláàyè yóò jẹ́ ká lè dáhùn ìbéèrè wọ̀nyí.
Èrò Ọlọ́run Nípa Ìwàláàyè
Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà ni “orísun ìyè.” (Sáàmù 36:9) Yàtọ̀ sí pé ó dá ènìyàn, ó tún ń ṣàbójútó wa gidigidi nípa fífún wa ní ohun tí a nílò kí a lè gbádùn ìgbésí ayé. (Sáàmù 139:14; Ìṣe 14:16, 17; 17:24-28) Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu kí a sọ pé ó ń retí pé kí a tọ́jú ohun tí ó ti lo inú rere láti fi fún wa. Àwọn òfin àti ìlànà tó fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì jẹ́ ká mọ kókó yẹn.
Òfin Mósè béèrè pé kí ẹnì kan gbégbèésẹ̀ láti dáàbò bo ìwàláàyè àwọn ẹlòmíràn. Bí wọn kò bá ṣe èyí, tí ẹnì kan sì kú, ẹni tó yẹ kó dènà irú jàǹbá bẹ́ẹ̀ yóò jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó pàṣẹ fún ẹnì kan tó kọ́ ilé láti kọ́ ògiri tí kò ga tàbí kó fi irin yí etí òrùlé pẹrẹsẹ ilé rẹ̀ tuntun po. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹni náà yóò jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ bí ẹnì kan bá ṣubú láti ibẹ̀, tí ó sì kú. (Diutarónómì 22:8) Bí akọ màlúù kan bá kan ẹnì kan pa lójijì, kò sẹ́ni tó máa mú ẹni tó ni akọ màlúù náà. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí wọ́n bá mọ̀ pé akọ màlúù náà jẹ́ eléwu tí wọ́n ti kìlọ̀ fún ẹni tó ni í, ṣùgbọ́n tí kò de ẹran náà mọ́lẹ̀ bó ṣe yẹ, tí akọ màlúù náà sì kan ẹnì kan pa, a jẹ́ pé wọn óò ka ẹni tó ni akọ màlúù náà sí ajẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ nìyẹn, wọ́n sì lè pa á. (Ẹ́kísódù 21:28, 29) Níwọ̀n bí ìwàláàyè ti ṣeyebíye lójú Jèhófà, Òfin rẹ̀ fi ọ̀wọ̀ ńláǹlà hàn fún pípa ìwàláàyè mọ́ àti dídáàbò bò ó.
Àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóye pé ìlànà wọ̀nyí kan ọ̀ràn fífi ẹ̀mí ara ẹni wewu pẹ̀lú. Nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì kan, Dáfídì sọ pé òun fẹ́ láti “rí omi mu láti inú ìkùdu Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.” Abẹ́ Filísínì ni Bẹ́tílẹ́hẹ́mù wà lákòókò yẹn. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí Dáfídì sọ, mẹ́ta lára àwọn jagunjagun rẹ̀ gba àárín ibùdó àwọn Filísínì kọjá, wọ́n fa omi látinú ìkùdu ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, wọ́n sì gbé e wá fún Dáfídì. Kí ni Dáfídì ṣe? Kò mu omi náà, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló dà á sílẹ̀ẹ́lẹ̀. Ó wí pé: “Kò ṣeé ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ti Ọlọ́run mi, láti ṣe èyí! Ṣé ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni kí n mu ní fífi ọkàn wọn wewu? Nítorí ní fífi ọkàn wọn wewu ni wọ́n fi gbé e wá.” (1 Kíróníkà 11:17-19) Dáfídì ronú pé ká má ri pé kí ẹnì kan fẹ̀mí wewu nítorí àtitẹ́ òun lọ́rùn.
Nígbà kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ lójú ìran, Jésù pẹ̀lú ṣe ohun tó jọ èyí nígbà tí Èṣù dán an wò pé kí ó bẹ́ sílẹ̀ látorí òrùlé tẹ́ńpìlì kí ó sì wò ó bóyá àwọn áńgẹ́lì yóò dáàbò bò ó kí ó má fara pa. Jésù fèsì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run rẹ wò.” (Mátíù 4:5-7) Bẹ́ẹ̀ ni, Dáfídì àti Jésù mọ̀ pé Ọlọ́run kò fẹ́ kí èèyàn máa ṣe àwọn nǹkan tí kò pọndandan, tó lè fi ẹ̀mí sínú ewu.
Pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí lọ́kàn wa, a lè ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo la ṣe lè mọ ìgbà tí eré ìdárayá bá jẹ́ àṣejù tàbí tó léwu? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé irú eré ìtura tó wọ́pọ̀ pàápàá, tí kò sì léwu lè di èyí tí a ṣe láṣejù, báwo lá ṣe lè mọ ibi tó yẹ kí a ṣe é dé?’
Ṣé Ó Tó Ohun Tí Ó Yẹ Ká Tìtorí Rẹ̀ Fẹ̀mí Wewu?
Bí a bá fi òtítọ́ ọkàn díwọ̀n eré ìdárayá èyíkéyìí tí a fẹ́ ṣe, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ìdáhùn náà. Bí àpẹẹrẹ, a lè bi ara wa pé, ‘Báwo làwọn èèyàn ṣe máa ń ṣèṣe tó nígbà tí wọ́n bá ń ṣe eré ìdárayá yìí? Ṣé mo ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bí n kò ṣe ní ṣèṣe tàbí ṣé mo ní ohun èlò tí yóò dáàbò bò mi kí n má bàa fara pa? Kí ló máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ bí mo bá ṣubú, bí n kò bá fò bí ó ti yẹ, tàbí bí ohun èlò tó yẹ kó dáàbò bò mí kò bá ṣiṣẹ́? Ṣé màá kàn ṣèṣe díẹ̀ ni, tàbí ó ṣeé ṣe kí n fara pa gan-an tàbí kí n tilẹ̀ kú?’
Fífi ara ẹni wewu lọ́nà tí kò yẹ nítorí pé a fẹ́ ṣe eré ìtura lè ní ipa lórí àjọṣe oníyebíye tí Kristẹni tòótọ́ kan ní pẹ̀lú Jèhófà, ó sì tún lè mú ká ṣiyè méjì nípa ìtóótun rẹ̀ láti ní àwọn àkànṣe àǹfààní nínú ìjọ. (1 Tímótì 3:2, 8-10; 4:12; Títù 2:6-8) Ní kedere, àní nígbà tí àwọn Kristẹni bá ń ṣe eré ìdárayá, ó yẹ kí wọ́n ronú nípa ojú ìwòye tí Ẹlẹ́dàá náà ní nípa ìjẹ́mímọ́ ìwàláàyè.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ibi gíga tí a ń sọ níhìn-ín lè jẹ́ ilé, òpó gíga, afárá, àti ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́. Eré ìdárayá yìí, tí wọ́n máa ń fi ohun èlò amúnigúnlẹ̀ fò bọ́ látorí àwọn nǹkan tó dúró sójú kan bí ilé, afárá, àti ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ṣe ni wọ́n gbà pé ó léwu gidigidi tó fi jẹ́ pé Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọgbà Ìtura ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fòfin dè é.