Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 26. Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Ì báà jẹ́ ènìyàn, ẹranko, tàbí ohun ìní la fẹ́ fún Jèhófà, kí ló béèrè pé kí a fi fún òun? (Òwe 3:9)
2. Irú ohun èlò wo tí a fi ń ṣiṣẹ́ oko ni Jèhófà fi hàn nínú Òfin pé èèyàn lè lò lọ́nà àìtọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà? (Ẹ́kísódù 21:18)
3. Iṣẹ́ wo ni Dáfídì Ọba yàn fún àwọn àtìpó nígbà tí ó ń múra fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì? (1 Kíróníkà 22:2)
4. Nígbà tí wọ́n ń lọ sí Ẹ́máọ́sì ta ló sọ pé bóyá àtìpó tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ni Jésù nítorí pé ó dà bíi pé kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀? (Lúùkù 24:18)
5. Ta ni a máa ń dárúkọ rẹ̀ ṣìkejì nínú àwọn ọmọ Nóà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló kéré jù? (Jẹ́nẹ́sísì 5:32)
6. Àlùfáà wo tó wá láti ìlà ìdílé Áárónì la mọ̀ sí ògbógi adàwékọ àti olùkọ́ Òfin? (Nehemáyà 8:13)
7. Ní ìbámu pẹ̀lú Diutarónómì 21:20, 21, kí ni ọmọ aláìgbọràn kan yóò ṣe tí yóò mú kí wọ́n sọ ọ́ ní òkúta pa?
8. Àwọn nǹkan wo tó jẹ mọ́ ìjọsìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló ta kora nínú oṣù Búlì, tó jẹ́ oṣù kẹjọ lórí kàlẹ́ńdà mímọ́ àwọn Júù? (1 Àwọn Ọba 6:38; 12:26-33)
9. Nǹkan tó wọ́pọ̀ wo ló wá di àmì nǹkan kan tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, tó sì wà pẹ́ títí? (Númérì 18:19)
10. Kí ló mú kí ẹ̀gbọ́n ọmọkùnrin onínàákúnàá náà mọ̀ pé ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ń ṣẹlẹ̀ nílé? (Lúùkù 15:25)
11. Ibo ni áńgẹ́lì keje da àwokòtò rẹ̀, ti ìbínú Ọlọ́run jáde sí? (Ìṣípayá 16:17)
12. Ibo ni ààlà ìhà ìlà oòrùn ilẹ̀ ọba Páṣíà náà, Ahasuwérúsì Ọba? (Ẹ́sítérì 1:1)
13. Àwọn wo ni Jòhánù rí nínú ìran tí wọ́n jókòó sórí àwọn ìtẹ́ yí ká ìtẹ́ Jèhófà? (Ìṣípayá 4:4)
14. Kí ni Jésù pe àwọn Farisí tí wọ́n fẹ́ràn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́? (Mátíù 15:14)
15. Kí ni àwọn èèyàn ìgbàanì ń pe òkun Mẹditaréníà láti ìgbà Mósè wá? (Númérì 34:6)
16. Kí ni ìwẹ̀fà ará Etiópíà náà ń ṣe nígbà tí Fílípì wá bá a nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀? (Ìṣe 8:28)
17. Kí ni wọ́n máa ń ṣe láti fi hàn pé ẹrú kan tó jẹ́ Hébérù kò fẹ́ gba òmìnira lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀? (Ẹ́kísódù 21:6)
18. Ibo ni ará Samáríà rere náà gbé ọmọ Ísírẹ́lì tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú náà, tí ó rí lójú ọ̀nà lọ? (Lúùkù 10:34)
19. Ta ni ọba àkọ́kọ́ tó jẹ́ olódodo tó ṣàkóso ìjọba Júdà? (1 Àwọn Ọba 15:11)
20. Ta ni olórí oníṣọ̀nà àti kọ́lékọ́lé tó kọ́ àgọ́ ìjọsìn, ta sì ni igbá kejì rẹ̀? (Ẹ́kísódù 31:2-6)
21. Ipò wo ni Jésù wà sí ìjọ Kristẹni, tó ń ṣàlàyé ipò orí rẹ̀ àti ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ rẹ̀? (Éfésù 5:22, 23; Ìṣípayá 21:2)
22. Gbajúmọ̀ obìnrin wo ló gbọ́ ọ̀rọ̀ ìgbèjà Pọ́ọ̀lù ní Áréópágù ti Áténì, tó sì di onígbàgbọ́? (Ìṣe 17:33, 34)
23. Kí ni Fẹ́sítọ́ọ̀sì Gómìnà sọ tìtaratìtara pé “ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́” ń ṣe fún Pọ́ọ̀lù? (Ìṣe 26:24)
24. Ẹranko wo ni Jésù fi ọlá ńlá gùn wọ Jerúsálẹ́mù? (Jòhánù 12:14, 15)
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Àkọ́so
2. Ọkọ́
3. Gbígbẹ́ òkúta
4. Kíléópà
5. Hámù
6. Ẹ́sírà
7. Jíjẹ àjẹkì àti mímu ọtí para
8. Sólómọ́nì parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù; Jèróbóámù ṣe àdábọwọ́ ara rẹ̀, ó sì sọ ọ́ di oṣù àjọyọ̀ ní ìjọba àríwá láti yí àfiyèsí àwọn ènìyàn kúrò ní Jerúsálẹ́mù àti àjọyọ̀ tó máa ń wáyé níbẹ̀
9. Iyọ̀
10. “Ó gbọ́ ohùn orin àwọn òṣèré àti ijó”
11. “Sínú afẹ́fẹ́”
12. Íńdíà
13. Àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún
14. “Afọ́jú afinimọ̀nà”
15. Òkun Ńlá
16. Ó ń ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà
17. Wọ́n á fi òòlu lu etí rẹ̀
18. Ilé èrò kan
19. Ásà
20. Bẹ́sálẹ́lì, Òhólíábù
21. Ọkọ
22. Dámárì
23. Ó ti ń da orí rẹ̀ rú
24. Agódóńgbó