ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 6
Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹni Tó Ni Bíbélì
“Kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún ọ sínú ìwé kan.”—JER. 30:2.
ORIN 96 Ìṣúra Ni Ìwé Ọlọ́run
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí nìdí tó o fi mọyì Bíbélì?
A DÚPẸ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run pé ó fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀! Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tí Jèhófà sọ nínú Bíbélì máa ń jẹ́ ká fara da àwọn ìṣòro tá a ní lónìí. Ọlọ́run tún jẹ́ ká mọ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé inú Bíbélì ni Jèhófà ti jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ lára ìwà àti ìṣe ẹ̀. Bá a ṣe ń ronú nípa ìwà àti ìṣe Jèhófà, ó máa ń mórí wa wú gan-an, ó máa ń jẹ́ ká sún mọ́ ọn, ká sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀.—Sm. 25:14.
2. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà bá àwa èèyàn sọ̀rọ̀?
2 Jèhófà fẹ́ káwa èèyàn mọ òun. Nígbà àtijọ́, ó máa ń lo àlá, ìran àtàwọn áńgẹ́lì láti bá àwa èèyàn sọ̀rọ̀. (Nọ́ń. 12:6; Ìṣe 10:3, 4) Àmọ́ tí wọn ò bá kọ àlá, ìran àti iṣẹ́ táwọn áńgẹ́lì jẹ́ fáwọn èèyàn sínú Bíbélì, báwo la ṣe máa mọ̀ nípa ẹ̀? Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ pé káwọn èèyàn kọ àwọn ohun tó fẹ́ ká mọ̀ “sínú ìwé kan.” (Jer. 30:2) Nítorí pé “ọ̀nà Ọlọ́run tòótọ́” pé, ọkàn wa balẹ̀ pé ọ̀nà tó ń gbà bá wa sọ̀rọ̀ ló dáa jù lọ, ó sì ń ṣe wá láǹfààní.—Sm. 18:30.
3. Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo Bíbélì tí ò fi pa run? (Àìsáyà 40:8)
3 Ka Àìsáyà 40:8. Ọjọ́ pẹ́ tí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń tọ́ àwọn olóòótọ́ ọkùnrin àti obìnrin sọ́nà. Kí ló jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe? Ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì torí pé ó ti pẹ́ gan-an tí wọ́n ti kọ Ìwé Mímọ́, àwọn àkájọ ìwé àtàwọn ìwé awọ tí wọ́n kọ́kọ́ kọ ọ́ sí sì ti bà jẹ́. Àmọ́ Jèhófà jẹ́ káwọn èèyàn ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn èèyàn yẹn, wọ́n fara balẹ̀ dà á kọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀mọ̀wé kan ń sọ̀rọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó sọ pé: “A lè fi gbogbo ẹnu sọ pé kò sí ìwé àtijọ́ kankan tí wọ́n da ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ kọ lọ́nà tó péye bíi Bíbélì.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti kọ Bíbélì àti pé àwọn ohun tó lè tètè bà jẹ́ ni wọ́n kọ ọ́ sí, tó sì jẹ́ pé àwọn aláìpé ló dà á kọ, ó dá wa lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run là ń kà nínú Bíbélì lónìí torí pé Jèhófà ló ni ín.
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé” ti wá. (Jém. 1:17) Ọ̀kan lára ẹ̀bùn tó dáa jù lọ tí Jèhófà fún wa ni Bíbélì. Tẹ́nì kan bá fún wa lẹ́bùn, ẹ̀bùn náà fi hàn pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì tún mọ ohun tá a fẹ́. Bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tó fún wa ní Bíbélì ṣe rí náà nìyẹn. Tá a bá ń ka Bíbélì déédéé, àá túbọ̀ mọ̀ ọ́n. Á jẹ́ ká rí i pé Jèhófà mọ̀ wá dáadáa, ó sì mọ ohun tá a fẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ mẹ́ta lára àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní. Àwọn ni: Ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bí Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run.
BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ̀ PÉ ỌLỌ́GBỌ́N NI ỌLỌ́RUN
5. Sọ ọ̀nà kan tí Bíbélì gbà fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run.
5 Jèhófà mọ̀ pé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tóun ń fún wa máa ṣe wá láǹfààní, àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n náà sì pọ̀ nínú Bíbélì. Ìmọ̀ràn inú Bíbélì máa ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní, ó sì máa ń yí ìgbésí ayé wọn pa dà. Nígbà tí Mósè kọ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ inú Bíbélì, ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run pé: “Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí kò wúlò fún yín, àmọ́ òun ló máa mú kí ẹ wà láàyè.” (Diu. 32:47) Ìgbésí ayé àwọn tó ń ṣe ohun tí Bíbélì sọ máa ń dáa, wọ́n sì máa ń láyọ̀. (Sm. 1:2, 3) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ti wà tipẹ́, àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣì wúlò, ó sì ń mú kí ìgbésí ayé àwọn èèyàn dáa sí i. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá lọ sórí ìkànnì jw.org, wàá rí ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà.” Iye ìtàn ìgbésí ayé tó wà níbẹ̀ ju àádọ́ta (50) lọ, ìyẹn sì fi hàn pé iṣẹ́ kékeré kọ́ ni Bíbélì ń ṣe nígbèésí ayé ‘àwọn tó gbà á gbọ́’ lónìí.—1 Tẹs. 2:13.
6. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé kò sí ìwé tó dà bíi Bíbélì?
6 Kò sí ìwé tó dà bíi Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé olódùmarè ni Jèhófà Ọlọ́run tó ni ìwé náà, ó máa wà títí láé, ó sì gbọ́n ju ẹnikẹ́ni lọ. Tí ẹni tó ṣe ìwé kan bá kú, àwọn èèyàn ṣì máa ń ka ìwé náà, àmọ́ tó bá yá, ohun tó wà nínú ìwé náà kì í wúlò mọ́. Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ Bíbélì ò rí bẹ́ẹ̀. Kò sígbà táwọn ìlànà inú ẹ̀ kì í ṣe wá láǹfààní, gbogbo èèyàn tó ń gbé ayé ló sì ń ṣe láǹfààní. Bá a ṣe ń ka Ìwé Mímọ́ yìí tá a sì ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà, Ọlọ́run tó ni Bíbélì máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè fi ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé wa. (Sm. 119:27; Mál. 3:16; Héb. 4:12) Torí náà, Ọlọ́run tó ni Bíbélì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́!
7. Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run wà níṣọ̀kan nígbà àtijọ́?
7 Ọ̀nà míì tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Bíbélì gbà fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run ni bó ṣe ń jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run wà níṣọ̀kan. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n tẹ̀ dó sí. Iṣẹ́ apẹja làwọn kan ń ṣe, àwọn kan ń da màlúù, nígbà táwọn kan ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀. Torí pé ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé jìnnà síra, ìyẹn lè jẹ́ kó ṣòro fún wọn láti mọ bí nǹkan ṣe ń lọ fáwọn yòókù. Àmọ́ Jèhófà ṣètò pé kí wọ́n máa pé jọ látìgbàdégbà, kí wọ́n lè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì ṣàlàyé ẹ̀ fún wọn. (Diu. 31:10-13; Neh. 8:2, 8, 18) Ẹ wo bí inú ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣe máa dùn tó nígbà tó bá dé Jerúsálẹ́mù, tó sì rí àìmọye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiẹ̀ tí wọ́n wá láti ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, kí wọ́n lè jọ́sìn Jèhófà! Ètò tí Jèhófà ṣe yìí ló jẹ́ káwọn èèyàn ẹ̀ wà níṣọ̀kan. Nígbà tó yá, wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sì wà níbẹ̀. Olówó làwọn kan, àwọn kan ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, ibi tí wọ́n ti wá sì yàtọ̀ síra. Àmọ́ wọ́n jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ níṣọ̀kan torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni tó lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn tó ti di Kristẹni ṣáájú wọn máa ní láti ṣàlàyé ẹ̀ fún wọn, kí wọ́n sì máa pé jọ pẹ̀lú wọn déédéé.—Ìṣe 2:42; 8:30, 31.
8. Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ káwa èèyàn Jèhófà wà níṣọ̀kan lónìí?
8 Jèhófà Ọlọ́run wa tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ṣì ń lo Bíbélì láti kọ́ àwa èèyàn ẹ̀ ká lè wà níṣọ̀kan. Inú Bíbélì la ti ń rí gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó yẹ ká mọ̀ nípa Jèhófà. A máa ń pé jọ déédéé láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àtàwọn àpéjọ agbègbè wa. Láwọn ìpàdé yìí, wọ́n máa ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa, wọ́n máa ń ṣàlàyé ẹ̀, a sì jọ máa ń jíròrò ẹ̀. Torí náà, ipa kékeré kọ́ ni Bíbélì ń kó láti mú káwa èèyàn Jèhófà máa “sìn ín ní ìṣọ̀kan.”—Sef. 3:9.
9. Tá a bá fẹ́ lóye ohun tó wà nínú Bíbélì, ànímọ́ wo ló yẹ ká ní? (Lúùkù 10:21)
9 Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀rí míì tó fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni Jèhófà. Jèhófà jẹ́ kí àwọn tó kọ Bíbélì kọ ọ́ lọ́nà tó fi jẹ́ pé àwọn onírẹ̀lẹ̀ nìkan ló lè lóye ẹ̀. (Ka Lúùkù 10:21.) Ibi gbogbo láyé làwọn èèyàn ti máa ń ka Bíbélì. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Kò sí ìwé míì táwọn èèyàn kà tó Bíbélì, òun sì ni ìwé táwọn èèyàn máa ń fara balẹ̀ kà jù.” Àmọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ nìkan ló ń lóye ohun tó wà nínú ẹ̀ dáadáa, tí wọ́n sì ń ṣe ohun tó sọ.—2 Kọ́r. 3:15, 16.
10. Ọ̀nà míì wo ni Bíbélì gbà fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni Jèhófà?
10 Ohun míì tún wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni Jèhófà. Jèhófà máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti kọ́ gbogbo àwa èèyàn ẹ̀ lápapọ̀, ó sì tún máa ń lò ó láti tọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sọ́nà, kó sì tù wá nínú. Tá a bá ń ka Bíbélì, a máa ń rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. (Àìsá. 30:21) Ṣó o ti níṣòro kan rí, tó o wá ka ẹsẹ Bíbélì kan, tó sì dà bíi pé torí ẹ gan-an ni wọ́n ṣe kọ ọ́? Àmọ́, àìmọye èèyàn ló tún ń jàǹfààní Bíbélì. Kí ló jẹ́ kí àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì bóde mu, tó sì ń ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láǹfààní? Ohun tó mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé Ẹni tó gbọ́n jù lọ láyé àti lọ́run ló ni Bíbélì.—2 Tím. 3:16, 17.
BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ̀ PÉ ONÍDÀÁJỌ́ ÒDODO NI ỌLỌ́RUN
11. Báwo ni Ọlọ́run ṣe fi hàn pé òun kì í ṣe ojúsàájú nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?
11 Ìdájọ́ òdodo ni ànímọ́ míì tí Jèhófà ní. (Diu. 32:4) Tẹ́nì kan bá jẹ́ onídàájọ́ òdodo, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ojúsàájú. Irú ẹni tí Jèhófà sì jẹ́ nìyẹn. (Ìṣe 10:34, 35; Róòmù 2:11) Torí pé Jèhófà kì í ṣojúsàájú, ó jẹ́ kí wọ́n fi àwọn èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ nígbà àtijọ́ kọ Bíbélì. Èdè Hébérù ni wọ́n fi kọ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìwé mọ́kàndínlógójì (39) tó ṣáájú nínú Bíbélì, èdè yẹn sì yé àwọn èèyàn Ọlọ́run dáadáa nígbà yẹn. Àmọ́ nígbà tó fi máa di ìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, èdè Gíríìkì ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ. Torí náà, èdè yìí ni wọ́n fi kọ ìwé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) tó kẹ́yìn Bíbélì. Jèhófà jẹ́ kí wọ́n fi èdè tó yàtọ̀ síra kọ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Iye àwa tá à ń gbé ayé lónìí tó bílíọ̀nù mẹ́jọ, oríṣiríṣi èdè la sì ń sọ. Báwo làwọn èèyàn tí iye wọn pọ̀ tó yìí ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà?
12. Sọ ọ̀nà kan tí Dáníẹ́lì 12:4 gbà ṣẹ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.
12 Jèhófà ṣèlérí nípasẹ̀ wòlíì Dáníẹ́lì pé tó bá di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, “ìmọ̀ tòótọ́” tó wà nínú Bíbélì “máa pọ̀” gan-an. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ka Dáníẹ́lì 12:4.) Ọ̀nà kan tí ìmọ̀ tòótọ́ ń gbà pọ̀ gan-an ni bá a ṣe ń túmọ̀ Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, tá à ń tẹ̀ ẹ́, tá a sì ń pín in fáwọn èèyàn. Bíbélì ni ìwé tá a túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ, tá a sì pín kiri jù lọ láyé. Bíbélì táwọn ilé iṣẹ́ kan tẹ̀ jáde máa ń wọ́n gan-an. Iye èdè táwa èèyàn Jèhófà ti túmọ̀ Bíbélì sí, bóyá lápá kan tàbí lódindi ti ju igba ó lé ogójì (240) lọ, gbogbo èèyàn ló sì ní àǹfààní láti ní Bíbélì yìí láì jẹ́ pé wọ́n fowó rà á. Ìyẹn jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn níbi gbogbo láyé láti gbọ́ “ìhìn rere Ìjọba” Ọlọ́run kí òpin tó dé. (Mát. 24:14) Torí pé onídàájọ́ òdodo ni Ọlọ́run wa, ó fẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní láti ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí wọ́n lè wá mọ̀ ọ́n. Ẹ ò rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo wa gan-an.
BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ̀ PÉ ỌLỌ́RUN NÍFẸ̀Ẹ́ WA
13. Kí ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa? (Jòhánù 21:25)
13 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ ni ànímọ́ tó ta yọ jù lọ tí Ọlọ́run ní. (1 Jòh. 4:8) Ẹ jẹ́ ká ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà gbà kí wọ́n kọ sínú Bíbélì àtàwọn nǹkan tí ò jẹ́ kí wọ́n kọ síbẹ̀. Àwọn ohun tá a nílò gẹ́lẹ́, tó máa jẹ́ ká ní àjọse tó dáa pẹ̀lú ẹ̀, tó máa jẹ́ ká gbé ìgbé ayé aláyọ̀, táá sì jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun ni wọ́n kọ sínú Bíbélì. Àmọ́ torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, kò jẹ́ kí wọ́n kọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tá ò nílò sínú Bíbélì.—Ka Jòhánù 21:25.
14. Nǹkan míì wo ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?
14 Jèhófà tún fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa torí ó fi Bíbélì bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó buyì kún wa. Nínú Bíbélì, Jèhófà ò fún wa lófin jàǹrànjanran nípa ohun tó yẹ ká ṣe àtohun tí ò yẹ ká ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí wọ́n kọ ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ń múnú wa dùn àtàwọn ìmọ̀ràn tó wúlò sínú Bíbélì, ká lè fi ṣe ìpinnu tó tọ́. Àwọn nǹkan tí wọ́n kọ sínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí ló jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká sì máa ṣègbọràn sí i látọkàn wá.
15. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀? (b) Nínú àwòrán yẹn, ṣé o lè dárúkọ àwọn tí ọmọbìnrin yẹn, ọ̀dọ́kùnrin yẹn àti arábìnrin àgbàlagbà yẹn ń ronú nípa wọn? (Jẹ́n. 39:1, 10-12; 2 Ọba 5:1-3; Lúùkù 2:25-38)
15 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tí ìtàn wọn wà nínú Bíbélì yé wa dáadáa, torí èèyàn tó “mọ nǹkan lára bíi tiwa” ni wọ́n. (Jém. 5:17) Àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn èèyàn bíi tiwa lọ́wọ́, á túbọ̀ dá wa lójú pé “Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó sì jẹ́ aláàánú.”—Jém. 5:11.
16. Kí la máa ń kọ́ lára Jèhófà tá a bá kà nípa àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ nínú Bíbélì? (Àìsáyà 55:7)
16 Ohun míì tún wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Bíbélì fi dá wa lójú pé tá a bá ṣàṣìṣe, Ọlọ́run ò ní pa wá tì. Bí àpẹẹrẹ, léraléra làwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà, àmọ́ tí wọ́n bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà máa ń dárí jì wọ́n. (Ka Àìsáyà 55:7.) Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ náà mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn gan-an. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti gba àwọn tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run níyànjú pé kí wọ́n ‘dárí ji’ ọkùnrin kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, àmọ́ tó ronú pìwà dà, ó sì ní kí wọ́n “tù ú nínú.” (2 Kọ́r. 2:6, 7; 1 Kọ́r. 5:1-5) Inú wa mà dùn o pé Jèhófà kì í pa àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ tì tá a bá ṣẹ̀ ẹ́! Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń ràn wá lọ́wọ́, ó máa ń fìfẹ́ bá wa wí, ó sì máa ń jẹ́ ká pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun. Lónìí, ìlérí yìí kan náà ni Jèhófà ṣe fún àwọn tó bá ṣẹ̀ ẹ́, àmọ́ tí wọ́n ronú pìwà dà tọkàntọkàn.—Jém. 4:8-10.
MỌYÌ “Ẹ̀BÙN RERE” TÍ ỌLỌ́RUN FÚN WA
17. Kí nìdí tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi ṣàrà ọ̀tọ̀?
17 Jèhófà ti fún wa ní ẹ̀bùn kan tó dáa gan-an, ìyẹn Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kí nìdí tí Bíbélì fi ṣàrà ọ̀tọ̀? Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run, onídàájọ́ òdodo ni, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa. Ìwé yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká mọ òun, ká sì di ọ̀rẹ́ òun.
18. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì “ẹ̀bùn rere,” ìyẹn Bíbélì tí Jèhófà fún wa?
18 Ọwọ́ pàtàkì ló yẹ ká fi mú “ẹ̀bùn rere” tí Ọlọ́run fún wa yìí. (Jém. 1:17) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn yìí. Bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì Bíbélì ni pé ká gbàdúrà ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í kà á, ká sì ronú lórí ohun tá a kà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run tó ni Bíbélì máa bù kún wa, a sì máa ní “ìmọ̀ Ọlọ́run.”—Òwe 2:5.
ORIN 98 Ọlọ́run Ló Mí sí Ìwé Mímọ́
a Bíbélì ló jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè sún mọ́ Jèhófà. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ní ọgbọ́n, ó máa ń ṣèdájọ́ òdodo, ó sì jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́. Kí la lè kọ́ látinú Bíbélì nípa àwọn ànímọ́ mẹ́ta tí Ọlọ́run ní yìí? Ohun tá a bá kọ́ máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì máa jẹ́ ká rí i pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run ni Bíbélì.