Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóẹ́lì àti Ìwé Ámósì
GBOGBO ohun tí Jóẹ́lì kàn sọ nípa ara rẹ̀ ni pé òun ní “Jóẹ́lì ọmọkùnrin Pétúélì.” (Jóẹ́lì 1:1) Nínú ìwé tá a fi orúkọ Jóẹ́lì pè nínú Bíbélì, ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ díẹ̀ ló sọ nípa àwọn nǹkan tó yàtọ̀ sí iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé kìkì àkókò tó fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ nìkan ni wọ́n lè fojú bù, pé ó jẹ́ nǹkan bí ọdún 820 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọdún mẹ́sàn-án lẹ́yìn tí Ùsáyà di ọba lórí ilẹ̀ Júdà. Kí nìdí tí Jóẹ́lì kò fi fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé iṣẹ́ tó ń jẹ́ ló fẹ́ gbé lárugẹ kì í ṣe ara rẹ̀.
Bákan náà, nígbà ayé Ùsáyà, Ọlọ́run yanṣẹ́ wòlíì fún Ámósì, tó ń gbé nílẹ̀ Júdà tó sì jẹ́ “olùṣọ́ agbo ẹran . . . àti olùrẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ igi síkámórè.” (Ámósì 7:14) Jóẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nílẹ̀ Júdà, àmọ́ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti àríwá Ísírẹ́lì ni Ọlọ́run rán Ámósì sí ní tiẹ̀. Èdè tó rọrùn tó sì jẹ́ ká rí bí nǹkan ṣe rí kedere ni Ámósì fi kọ ìwé náà. Nǹkan bí ọdún 804 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wòlíì yìí kọ ìwé rẹ̀ tán, ìyẹn lẹ́yìn tó padà sílẹ̀ Júdà.
“PÁGÀ FÚN ỌJỌ́ NÁÀ”—KÍ NÌDÍ?
Bí kòkòrò wùkúwùkú, eéṣú, àti aáyán ṣe bo ilẹ̀ náà lohun tí Jóẹ́lì rí nínú ìran. Bíbélì pe àwọn nǹkan wọ̀nyí ní “àwọn ènìyàn kan . . . tí ó pọ̀ níye, tí ó sì jẹ́ alágbára ńlá” ó sì tún pè wọ́n ní “àwọn ọkùnrin alágbára.” (Jóẹ́lì 1:4; 2:2-7) Jóẹ́lì kédàárò pé: “Págà fún ọjọ́ náà; nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé, yóò sì dé gẹ́gẹ́ bí ìfiṣèjẹ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí í ṣe Olódùmarè!” (Jóẹ́lì 1:15) Jèhófà gba àwọn olùgbé Síónì nímọ̀ràn pé: “Ẹ padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà yín.” Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà yóò “fi ìyọ́nú hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀,” yóò sì lé “ará àríwá” jìnnà rére, ìyẹn àwọn kòkòrò tó ya bò wọ́n. Àmọ́ ṣá o, kó tó di pé ọjọ́ ńlá Jèhófà dé, Jèhófà yóò “tú ẹ̀mí [rẹ̀] jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara” yóò sì “fúnni ní àwọn àmì àgbàyanu ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.”—Jóẹ́lì 2:12, 18-20, 28-31.
Jèhófà pe àwọn orílẹ̀-èdè náà pé kí wọ́n wá jagun, ó ní: “Ẹ fi àwọn abẹ ohun ìtúlẹ̀ yín rọ idà, kí ẹ sì fi àwọn ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn yín rọ aṣóró,” kí ẹ sì múra ogun. Ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n “gòkè wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jèhóṣáfátì,” níbi tí yóò ti dá wọn lẹ́jọ́ tí yóò sì pa wọ́n run. “Ṣùgbọ́n ní ti Júdà, a óò máa gbé e fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Jóẹ́lì 3:10, 12, 20.
dáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:15; 2:1, 11, 31; 3:14—Kí ni “ọjọ́ Jèhófà”? Ọjọ́ Jèhófà ni ìgbà tí Jèhófà yóò mú ìdájọ́ wá sórí àwọn ọ̀tá rẹ̀, ìyẹn yóò yọrí sí ìparun fún wọn àmọ́ yóò já sí ìgbàlà fáwọn olùjọsìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, irú ọjọ́ bẹ́ẹ̀ dé sórí Bábílónì ìgbàanì nígbà táwọn ará Mídíà àtàwọn ará Páṣíà ṣẹ́gun rẹ̀ lọ́dún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Aísáyà 13:1, 6) Ọjọ́ mìíràn tó jẹ́ “ọjọ́ Jèhófà” tún ti sún mọ́lé, nígbà tí yóò mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ lórí “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn gbogbo ìsìn èké ayé lápapọ̀.—Ìṣípayá 18:1-4, 21.
2:1-10, 28—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn kòkòrò tó ya bolẹ̀ yóò ṣe nímùúṣẹ? Kò sí àkọsílẹ̀ kankan nínú Bíbélì tó sọ pé àwọn kòkòrò ya bo ilẹ̀ Kénáánì lọ́pọ̀ yanturu bí èyí tí ìwé Jóẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nítorí náà, ohun tí Jóẹ́lì ṣàpèjúwe rẹ̀ yẹn ní láti jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í tú ẹ̀mí rẹ̀ jáde sára àwọn tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi ní ìjímìjí tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ọ̀rọ̀ tó dà bí iná lára àwọn aṣáájú ìsìn èké. (Ìṣe 2:1, 14-21; 5:27-33) Àǹfààní ńlá la ní bá a ṣe ń lọ́wọ́ sí irú iṣẹ́ kan náà yẹn lónìí.
2:32—Kí ni ‘kíképe orúkọ Jèhófà’ túmọ̀ sí? Kíképe orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí kéèyàn mọ orúkọ náà, kó bọ̀wọ̀ fún un gan-an, kó wá gbára lé ẹni tó ń jẹ́ orúkọ náà, kó sì tún fọkàn tán an.—Róòmù 10:13, 14.
3:14—Kí ni “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu”? Ó ń ṣàpẹẹrẹ ibì kan tí Ọlọ́run ti máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ. Nígbà ayé Jèhóṣáfátì Ọba Júdà, ẹni tórúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Jèhófà ni onídàájọ́,” Ọlọ́run gba ilẹ̀ Júdà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí i ká nípa mímú kí ọkàn àwọn ọmọ ogun wọn pòrúurùu. Ìdí nìyẹn tí wọ́n tún fi ń pe ibẹ̀ ní “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jèhóṣáfátì.” (Jóẹ́lì 3:2, 12) Lákòókò tiwa yìí, ó dúró fún ibì kan tí Ọlọ́run yóò ti tẹ àwọn orílẹ̀-èdè bí èso àjàrà nínú ìfúntí wáìnì.—Ìṣípayá 19:15.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:13, 14. Kéèyàn tó lè rí ìgbàlà, ohun pàtàkì téèyàn ni láti ṣe ni pé kó ronú pìwà dà tọkàntọkàn, kó sì gbà pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.
2:12, 13. Ojúlówó ìrònúpìwàdà gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó ti ọkàn èèyàn wá. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ká ‘fa ọkàn wa ya’ nínú lọ́hùn-ún kì í ṣe pé ká ‘fa aṣọ wa ya.’
2:28-32. Kìkì ẹni tó “bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́” ní “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà.” Ó mà yẹ ká kún fún ọpẹ́ gan-an o, pé Jèhófà tú ẹ̀mí rẹ̀ jáde sára onírúurú èèyàn débi pé tọmọdé tàgbà, tọkùnrin tobìnrin, ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, ìyẹn ni pé wọ́n ń polongo “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run”! (Ìṣe 2:11) Bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé, ǹjẹ́ kò yẹ ká túbọ̀ jára mọ́ “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run”?—2 Pétérù 3:10-12.
3:4-8, 19. Jóẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run máa dá àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Júdà ká lẹ́jọ́ nítorí ìyà tí wọ́n fi jẹ àwọn èèyàn tó jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ, Nebukadinésárì Ọba Bábílónì pa ìlú Tírè ti orí ilẹ̀ run. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Alẹkisáńdà Ńlá ṣẹ́gun ìlú Tírè ti orí omi, ẹgbẹẹgbẹ̀rún jagunjagun àtàwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn ibẹ̀ ló kú, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n àwọn olùgbé ibẹ̀ ni wọ́n sì tà sóko ẹrú. Irú nǹkan bí èyí náà ni Alẹkisáńdà àtàwọn tó jọba lẹ́yìn rẹ̀ ṣe fáwọn Filísínì. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹrin ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Édómù ti di ahoro. (Málákì 1:3) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó nímùúṣẹ wọ̀nyí túbọ̀ mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní pé Jèhófà jẹ́ Ẹni tó máa ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ túbọ̀ lágbára sí i. Wọ́n tún jẹ́ ká rí ọ̀nà tí Jèhófà máa gbà fìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ṣenúnibíni sáwọn olùjọsìn rẹ̀ lóde òní.
3:16-21. “Dájúdájú, ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò mì jìgìjìgì,” àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì gba ìdájọ́ mímúná látọ̀dọ̀ Jèhófà. “Ṣùgbọ́n Jèhófà yóò jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn ènìyàn rẹ̀,” yóò fún wọn ní ìyè nígbà tí ayé bá di Párádísè. Ǹjẹ́ kò yẹ ká fi gbogbo ọkàn wa sún mọ́ Ọlọ́run bí ọjọ́ tó máa mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí ayé búburú yìí ṣe ń sún mọ́lé?
“MÚRA SÍLẸ̀ LÁTI PÀDÉ ỌLỌ́RUN RẸ”
Ámósì ní iṣẹ́ kan tó fẹ́ jẹ́ fáwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká, ó tún fẹ́ jíṣẹ́ fún Júdà àti Ísírẹ́lì pẹ̀lú. Ìparun ń dúró de Síríà, Filísíà, Tírè, Édómù, àti Móábù nítorí ìwà ìkà tí wọ́n hù sáwọn èèyàn Ọlọ́run. Ìparun tún ń dúró de àwọn tó ń gbé ilẹ̀ Júdà “ní tìtorí kíkọ̀ tí wọ́n kọ òfin Jèhófà.” (Ámósì 2:4) Ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì wá ńkọ́? Lára ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ni pé ẹ̀mí ìwọra mú kí wọ́n fojú àwọn tálákà gbolẹ̀, wọ́n tún jẹ́ oníṣekúṣe, wọn ò sì bọ̀wọ̀ fáwọn wòlíì Ọlọ́run. Ámósì kìlọ̀ fún wọn pé Jèhófà yóò “béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ àwọn pẹpẹ Bẹ́tẹ́lì,” yóò sì “ṣá ilé ìgbà òtútù balẹ̀ ní àfikún sí ilé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.”—Ámósì 3:14, 15.
Pẹ̀lú gbogbo ohun tójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ abọ̀rìṣà wọ̀nyí ti rí, wọ́n kọ̀ láti ronú pìwà dà. Ámósì wá sọ fún wọn pé: “Múra sílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run rẹ.” (Ámósì 4:12) Ohun tí ọjọ́ Jèhófà yóò túmọ̀ sí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni pé wọ́n á “lọ sí ìgbèkùn ré kọjá Damásíkù,” ìyẹn ni pé, wọ́n á lọ sí Ásíríà. (Ámósì 5:27) Àlùfáà kan ní Bẹ́tẹ́lì ṣenúnibíni sí Ámósì, àmọ́ Ámósì ò bẹ̀rù rárá. Jèhófà sọ fún Ámósì pé: “Òpin ti dé bá àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì. Èmi kì yóò tún fàyè gbà wọ́n mọ́.” (Ámósì 8:2) Ṣìọ́ọ̀lù tàbí àwọn òkè ńláńlá kò lè dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. (Ámósì 9:2, 3) Síbẹ̀, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa mú wọn padà bọ̀ sípò. Jèhófà sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì kó òǹdè àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì jọ padà, ní ti tòótọ́, wọn yóò sì kọ́ àwọn ìlú ńlá tí ó ti di ahoro, wọn yóò sì máa gbé inú wọn, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì mu wáìnì wọn, wọn yóò sì ṣe ọgbà, wọn yóò sì jẹ èso wọn.”—Ámósì 9:14.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
4:1—Àwọn wo ni “abo màlúù Báṣánì” dúró fún? Òkè olórí pẹrẹsẹ ti Báṣánì, ìyẹn àgbègbè kan tó wà ní ìlà oòrùn Òkun Gálílì, jẹ́ ibì kan táwọn ẹranko pọ̀ sí gan-an títí kan àwọn abo màlúù pàápàá. Jíjẹ́ tí ibẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ ẹlẹ́tùlójú tí ewéko sì pọ̀ níbẹ̀ wà lára ohun tó mú káwọn ẹranko pọ̀ níbẹ̀. Ámósì wá fi àwọn obìnrin ará Samáríà tí wọ́n fẹ́ràn afẹ́ wé àwọn abo màlúù Báṣánì. Ó dájú pé ńṣe làwọn obìnrin wọ̀nyí ń fúngun mọ́ àwọn “ọ̀gá wọn,” ìyẹn àwọn ọkọ wọn pé kí wọ́n lu àwọn tálákà ní jìbìtì kí ọrọ̀ wọn lè túbọ̀ pọ̀ sí i.
4:6—Kí ni gbólóhùn náà “ìmọ́tónítóní eyín” túmọ̀ sí? Bíbélì lo ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “àìní oúnjẹ,” nípa bẹ́ẹ̀ gbólóhùn náà lè tọ́ka sí àkókò ìyàn nígbà tí eyín máa ń wà ní mímọ́ tónítóní nítorí pé kò sí oúnjẹ.
5:5—Ní ọ̀nà wo ni Ísírẹ́lì ‘kò fi ní wá Bẹ́tẹ́lì lọ’? Jèróbóámù gbé ìjọsìn ère ọmọ màlúù kalẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì. Àtìgbà yẹn ni ìlú yẹn ti di ojúkò ìjọsìn èké. Gílígálì àti Bíá-Ṣébà náà ti ní láti jẹ́ àwọn ibi ìjọsìn àwọn apẹ̀yìndà. Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àjálù tí Ámósì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, wọ́n ní láti jáwọ́ nínú rírin ìrìn àjò ìsìn lọ sáwọn ìlú wọ̀nyí kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá Jèhófà.
7:1—Kí ni “koríko ọba tí a gé” ń tọ́ka sí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé owó orí tí ọba sọ pé káwọn èèyàn san kó bàa lè rówó gbọ́ bùkátà àwọn darandaran àtàwọn ẹran rẹ̀ ló ń tọ́ka sí. Wọ́n ní láti san owó orí yìí “ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà tí irúgbìn àgbìnkẹ́yìn yọ.” Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn èèyàn náà tó lè kórè ohun ọ̀gbìn wọn. Àmọ́, kí wọ́n tó ṣèyẹn, àwọn eéṣú tó ń gbá yìn-ìn dé, wọ́n sì jẹ àwọn irúgbìn wọn àtàwọn ewébẹ̀ mìíràn pẹ̀lú.
8:1, 2—Kí ni “apẹ̀rẹ̀ èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kan” dúró fún? Ó fi hàn pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé. Ìgbà tí àkókò ìkórè bá ti fẹ́ parí ni wọ́n máa ń ṣa èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, ìyẹn nígbà tó bá kù díẹ̀ kí wọ́n kádìí iṣẹ́ ọ̀gbìn ti ọdún náà nílẹ̀. Nígbà tí Jèhófà mú kí Ámósì rí “apẹ̀rẹ̀ èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kan,” ohun tó túmọ̀ sí ni pé òpin ti sún mọ́lé fún Ísírẹ́lì. Nítorí náà, Ọlọ́run sọ fún Ámósì pé: “Òpin ti dé bá àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì. Èmi kì yóò tún fàyè gbà wọ́n mọ́.”
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:3, 6, 9, 11, 13; 2:1, 4, 6. Nítorí pé Jèhófà bínú sí Ísírẹ́lì, Júdà àtàwọn orílẹ̀-èdè mẹ́fà tó yí wọn ká ló mú kó sọ pé: “Èmi kì yóò yí i padà.” Kò sí béèyàn ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Jèhófà.—Ámósì 9:2-5.
2:12. A ò gbọ́dọ̀ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn míṣọ́nnárì, tàbí àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì nípa sísọ fún wọn pé kí wọ́n fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀ kí wọ́n wá máa gbé irú ìgbésí ayé tí gbogbo èèyàn ń gbé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa bá iṣẹ́ rere wọn lọ.
3:8. Bí ẹ̀rù ṣe máa ń ba èèyàn nígbà tó bá gbọ́ igbe kìnnìún lọ̀rọ̀ ṣe rí lára Ámósì tó fi rí i pé ó di dandan fóun láti wàásù nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé: “Lọ, sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn mi.” (Ámósì 7:15) Ó yẹ kí ìbẹ̀rù Ọlọ́run mú ká máa fi tọkàntara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.
3:13-15; 5:11. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, Ámósì tó jẹ́ darandaran “jẹ́rìí” fáwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ tí wọn ò sì ka ohunkóhun sí. Bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe lè mú kí ẹnì kan kúnjú ìwọ̀n láti kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run bó ti wù kí ìpínlẹ̀ tó ti máa ṣiṣẹ́ ìwàásù náà burú tó.
4:6-11; 5:4, 6, 14. Láìfi báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kùnà láti “padà sọ́dọ̀” Jèhófà pè, ó tún ń rọ̀ wọ́n pé: “Wá Jèhófà, kí o sì máa wà láàyè nìṣó.” Níwọ̀n ìgbà tí Jèhófà bá ṣì fàyè gba ètò búburú yìí láti máa bá a lọ, a gbọ́dọ̀ máa gba àwọn tó wà níbẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n wá sin Ọlọ́run.
5:18, 19. ‘Kí ọkàn èèyàn máa fà sí ọjọ́ Jèhófà’ láìmúra sílẹ̀ dè é jẹ́ ìwà òmùgọ̀. Ipò tí ẹni tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ wà dà bíi ti ọkùnrin kan tó ń sá fún kìnnìún tó wá lọ pàdé béárì, bó tún ṣe ń sá fún béárì ni ejò bù ú jẹ. Ọlọgbọ́n la jẹ́ tá a bá “wà lójúfò” tá a sì wà nípò tó fi hàn pé a ti múra sílẹ̀.—Lúùkù 21:36.
7:12-17. A ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù, a sì gbọ́dọ̀ nígboyà láti polongo iṣẹ́ Ọlọ́run.
9:7-10. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn baba ńlá olóòótọ́ ìgbàanì, tí wọ́n sì tún jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn èèyàn tí Ọlọ́run yàn láàyò tó sì dá nídè kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ wọ́n sì ṣe ohun tó burú lójú Ọlọ́run bíi tàwọn ọmọ Kúṣì. Wíwà nípò tó dára lójú Ọlọ́run tí kì í ṣe ojúsàájú kò sinmi lórí ìdílé téèyàn ti wá, àmọ́ ó sinmi lórí kéèyàn ‘bẹ̀rù rẹ̀ kó sì máa ṣiṣẹ́ òdodo.’—Ìṣe 10:34, 35.
Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe
Ọjọ́ tí Ọlọ́run máa mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí ayé Sátánì yìí ti sún mọ́lé. Ọlọ́run ti tú ẹ̀mí rẹ̀ dà sórí àwọn olùjọsìn rẹ̀ ó sì ti pèsè gbogbo ohun tí wọ́n nílò láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé ọjọ́ òun ń bọ̀. Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa sa gbogbo ipá wa láti máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá mọ Jèhófà, kí wọ́n sì ‘máa pe orúkọ rẹ̀’?—Jóẹ́lì 2:31, 32.
Ámósì gbani níyànjú pé: “Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere, kí ẹ sì fún ìdájọ́ òdodo láyè ní ẹnubodè.” (Ámósì 5:15) Bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé, ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni pé ká sún mọ́ Ọlọ́run ká má sì dara pọ̀ mọ́ ayé búburú yìí àtàwọn ẹgbẹ́ búburú inú rẹ̀. Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ tó bọ́ sásìkò gan-an la rí kọ́ látinú ìwé Jóẹ́lì àti ìwé Ámósì inú Bíbélì!—Hébérù 4:12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Jóẹ́lì sàsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé!”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Bíi ti Ámósì, àwa náà ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù, a sì gbọ́dọ̀ máa fìgboyà kéde iṣẹ́ Ọlọ́run