ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 11-15
Jóòbù Gbà Pé Àjíǹde Máa Wà
Jóòbù sọ bó ṣe dá a lójú tó pé Ọlọ́run máa jí òun dìde
Jóòbù fi ọ̀rọ̀ igi ṣàpèjúwe bó ṣe dá òun lójú tó pé Ọlọ́run máa jí òun dìde, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé igi ólífì ló ní lọ́kàn
Gbòǹgbò igi ólífì máa ń ta gan-an, ó sì máa ń rinlẹ̀, ìyẹn máa ń jẹ́ kó tún lè sọjí bí wọ́n tiẹ̀ gé ìtì rẹ̀ lulẹ̀. Tí gbòǹgbò rẹ̀ kò bá ti kú, ó máa hù pa dà
Nígbà tí òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ lẹ́yìn tí ọ̀dá ti mú kí gbogbo nǹkan gbẹ táútáú, kùkùté igi ólífì tó ti gbẹ lè sọjí pa dà, á bẹ̀rẹ̀ sí í yọ “ẹ̀tun bí ọ̀gbìn tuntun”