ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 21-27
Jóòbù Kò Fàyè Gba Èrò Òdì
Lóde òní, Sátánì máa ń pa oríṣiríṣi irọ́ mọ́ Ọlọ́run kó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Wo ìyàtọ̀ tó wà nínú àwọn irọ́ tí Sátánì ń pa mọ́ Jèhófà àti bí ọ̀rọ̀ wa ṣe rí lára Jèhófà gan-an nínú ìwé Jóòbù. Kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tó jẹ́ kó o gbà pé Jèhófà bìkítà nípa rẹ sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí.
ÀWỌN IRỌ́ TÍ SÁTÁNÌ Ń PA |
BÍ Ọ̀RỌ̀ WA ṢE RÍ LÁRA JÈHÓFÀ GAN-AN |
---|---|
Ọlọ́run rorò débi pé kò sóhun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe tó dára lójú rẹ̀. Kò sí ẹ̀dá kankan tó lè tẹ́ ẹ lọ́rùn (Job 4:18; 25:5) |
Jèhófà mọyì àwọn ìsapá wa (Job 36:5) |
Èèyàn ò wúlò fún Ọlọ́run (Job 22:2) |
Inú Jèhófà máa ń dùn sí iṣẹ́ ìsìn tá a fi tọkàntọkàn ṣe, ó sì ń bù kún wa (Job 33:26; 36:11) |
Jíjẹ́ tí o jẹ́ olódodo kò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run (Job 22:3) |
Ojú Jèhófà kì í kúrò lára olódodo (Job 36:7) |