Jèhófà Ni “Olùṣí Àwọn Àṣírí Payá”
“Lóòótọ́, Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn ọba, ó sì jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá.”—DÁN. 2:47.
BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?
Kí ni Jèhófà ṣí payá fún wa nípa àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
Kí ni àwọn mẹ́fà àkọ́kọ́ lára orí ẹranko ẹhànnà náà dúró fún?
Báwo ni ẹranko ẹhànnà náà àti ère tí Nebukadinésárì rí ṣe jọra?
1, 2. Kí ni Jèhófà ṣí payá fún wa, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?
ÀWỌN ìjọba wo ni yóò máa ṣàkóso ayé nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá máa fòpin sí ìṣàkóso èèyàn? A mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí torí pé Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ “Olùṣí àwọn àṣírí payá” ti sọ ọ́ fún wa. Ó jẹ́ ká lè fi òye dá àwọn ìjọba wọ̀nyẹn mọ̀ nípasẹ̀ ohun tí wòlíì Dáníẹ́lì àti àpọ́sítélì Jòhánù ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀.
2 Jèhófà fi ọ̀wọ́ àwọn ẹranko kan han àwọn ọkùnrin yẹn nínú ìran. Ó tún sọ ìtúmọ̀ àlá kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ fún Dáníẹ́lì nípa ère arabarìbì kan tó jẹ́ ti wúrà, fàdákà, bàbà, irin àti amọ̀. Jèhófà mú kí wọ́n kọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sílẹ̀, kí wọ́n sì pá a mọ́ nínú Bíbélì fún àǹfààní wa. (Róòmù 15:4) Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ kí ìrètí tá a ní túbọ̀ dá wa lójú pé, Ìjọba òun máa fọ́ gbogbo ìjọba èèyàn túútúú láìpẹ́.—Dán. 2:44.
3. Kó tó lè ṣeé ṣe fún wa láti lóye àsọtẹ́lẹ̀ dáadáa, kí ló yẹ ká kọ́kọ́ mọ̀, kí sì nìdí?
3 Lápapọ̀, àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì àti Jòhánù jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan kan nípa ọba mẹ́jọ, tàbí ìṣàkóso àwọn èèyàn, ó sì tún jẹ́ ká mọ bí àwọn ọba náà ṣe máa fara hàn lọ́kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ ṣá o, ká tó lè lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn dáadáa, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ pàá tó wà nínú Bíbélì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ni ẹṣin ọ̀rọ̀ tó so Bíbélì pọ̀ lódindi. Lọ́nà kan, ńṣe ló dà bí okùn kan tí gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yòókù nínú Bíbélì rọ̀ mọ́.
IRÚ ỌMỌ EJÒ NÁÀ ÀTI ẸRANKO ẸHÀNNÀ
4. Àwọn wo ló para pọ̀ di irú ọmọ obìnrin náà, kí sì ni irú ọmọ yìí máa ṣe?
4 Láìpẹ́ lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà ṣèlérí pé “obìnrin” kan máa bí “irú ọmọ” kan.a (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:15.) Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, irú ọmọ yìí máa pa ejò náà, Sátánì, ní orí. Nígbà tó yá, Jèhófà ṣí i payá pé irú ọmọ náà máa wá láti ìlà ìdílé Ábúráhámù, láti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, pé ó máa jẹ́ ẹ̀yà Júdà àti pé ó máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba. (Jẹ́n. 22:15-18; 49:10; Sm. 89:3, 4; Lúùkù 1:30-33) Kristi Jésù ni apá àkọ́kọ́ lára irú ọmọ náà. (Gál. 3:16) Àwọn ẹni àmì òróró tó wà nínú ìjọ Kristẹni ni apá kejì lára irú ọmọ náà. (Gál. 3:26-29) Jésù àti àwọn ẹni àmì òróró yìí ló para pọ̀ di Ìjọba Ọlọ́run, Ìjọba yìí sì ni Ọlọ́run máa lò láti fọ́ Sátánì túútúú.—Lúùkù 12:32; Róòmù 16:20.
5, 6. (a) Agbára ńlá mélòó ni Dáníẹ́lì àti Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? (b) Kí ni àwọn orí ẹranko ẹhànnà tí ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ dúró fún?
5 Àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run sọ nínú ọgbà Édẹ́nì yẹn tún fi hàn pé Sátánì náà máa ní “irú ọmọ” tirẹ̀. Irú ọmọ Sátánì yìí máa bá irú ọmọ obìnrin náà ṣọ̀tá. Àwọn wo ló para pọ̀ di irú ọmọ ejò náà? Gbogbo àwọn tó kórìíra Ọlọ́run tí wọ́n sì ń ta ko àwọn èèyàn rẹ̀ bíi ti Sátánì ni. Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń ṣètò irú ọmọ rẹ̀ sí onírúurú ẹgbẹ́ òṣèlú, tàbí àwọn ìjọba. (Lúùkù 4:5, 6) Àmọ́, díẹ̀ lára àwọn ìjọba èèyàn ló tíì ní ipa tó lágbára gan-an lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run, ì báà jẹ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ tàbí ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Kí nìdí tí kókó yìí fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé ó jẹ́ ká mọ ìdí tó fi jẹ́ pé mẹ́jọ péré lára irú àwọn ìjọba alágbára bẹ́ẹ̀ ni Dáníẹ́lì àti Jòhánù rí nínú ìran.
6 Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni (S.K.) ń parí lọ, Jésù tó ti jíǹde fi ọ̀wọ́ àwọn ìran kíkàmàmà kan han àpọ́sítélì Jòhánù. (Ìṣí. 1:1) Nínú ọ̀kan lára àwọn ìran náà, Jòhánù rí Èṣù, tí wọ́n fi dírágónì ṣàpẹẹrẹ, tó dúró ní etíkun tó fẹ̀ lọ salalu. (Ka Ìṣípayá 13:1, 2.) Jòhánù tún rí ẹranko abàmì kan tó jáde wá láti inú òkun náà, tó sì gba agbára ńlá látọ̀dọ̀ Èṣù. Lẹ́yìn náà ni áńgẹ́lì kan wá fi han Jòhánù pé orí méje tí ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà ní, èyí tó jẹ́ ère ẹranko tí Ìṣípayá 13:1 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, dúró fún “ọba méje” tàbí àwọn ìjọba. (Ìṣí. 13:14, 15; 17:3, 9, 10) Ní àkókò tí Jòhánù ń kọ ìwé rẹ̀, márùn-ún lára àwọn ọba náà ti ṣubú, ọ̀kan ń ṣàkóso lọ́wọ́ nígbà yẹn, ọ̀kan tó kù “kò tíì dé.” Báwo la ṣe lè dá àwọn ìjọba, tàbí àwọn agbára ayé náà mọ̀? Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orí ẹranko tí ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. A tún máa rí bí ìwé Dáníẹ́lì ṣe fi kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ọ̀pọ̀ lára àwọn ìjọba yìí kún un, bẹ́ẹ̀ ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kí wọ́n tó fara hàn ni Dáníẹ́lì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn.
ORÍ MÉJÌ ÀKỌ́KỌ́ DÚRÓ FÚN ÍJÍBÍTÌ ÀTI ÁSÍRÍÀ
7. Kí ni àkọ́kọ́ lára orí ẹranko náà dúró fún, kí sì nìdí?
7 Àkọ́kọ́ lára orí ẹranko náà dúró fún orílẹ̀-èdè Íjíbítì. Kí nìdí? Ìdí ni pé Íjíbítì ni agbára ayé tó kọ́kọ́ mú àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ọ̀tá. Àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, ẹni tí Ọlọ́run ṣèlérí pé ipasẹ̀ rẹ̀ ni irú ọmọ obìnrin náà máa gbà wá, di púpọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, àwọn ará Íjíbítì wá ń pọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú. Sátánì gbìyànjú láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́ kí irú ọmọ náà tó dé. Lọ́nà wo? Ó mú kí Fáráò pa gbogbo ọmọ ọkùnrin tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí. Jèhófà mú kí ìsapá yìí forí ṣánpọ́n, ó sì dá àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ lóko ẹrú àwọn ará Íjíbítì. (Ẹ́kís. 1:15-20; 14:13) Ẹ̀yìn náà ló wá fìdí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kalẹ̀ sí Ilẹ̀ Ìlérí.
8. Kí ni èkejì lára orí ẹranko náà dúró fún, kí ló sì gbìyànjú láti ṣe?
8 Èkejì lára orí ẹranko náà dúró fún orílẹ̀-èdè Ásíríà. Ìjọba alágbára yìí náà gbìyànjú láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́. Òótọ́ ni pé Jèhófà lo orílẹ̀-èdè Ásíríà láti fìyà jẹ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì nítorí wọ́n di abọ̀rìṣà àti ọlọ̀tẹ̀. Àmọ́, orílẹ̀-èdè Ásíríà tún wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Sátánì ń wá bó ṣe máa pa ìlà ìdílé ọba tí Jésù máa gbà wá run. Ìgbéjàkò yìí kò sí lára ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe, ó sì dá àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sílẹ̀ lọ́nà ìyanu nípa pípa àwọn ọ̀tá náà run.—2 Ọba 19:32-35; Aísá. 10:5, 6, 12-15.
ORÍ KẸTA DÚRÓ FÚN BÁBÍLÓNÌ
9, 10. (a) Kí ni Jèhófà gba àwọn ará Bábílónì láyè láti ṣe? (b) Kí àsọtẹ́lẹ̀ tó lè ní ìmúṣẹ, kí ló ní láti ṣẹlẹ̀?
9 Ẹ̀kẹta lára orí ẹranko tí Jòhánù rí dúró fún ìjọba tí Bábílónì jẹ́ olú ìlú rẹ̀. Jèhófà fàyè gba àwọn ará Bábílónì láti pa Jerúsálẹ́mù run, kí wọ́n sì kó àwọn èèyàn rẹ̀ nígbèkùn. Àmọ́ kí Jèhófà tó jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ kan àbùkù lọ́nà yìí, ó ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti ya ọlọ̀tẹ̀ yẹn pé irú àgbákò yẹn máa dé bá wọn. (2 Ọba 20:16-18) Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé a máa mú ìlà àwọn ọba tí wọ́n ń jókòó sórí “ìtẹ́ Jèhófà” ní Jerúsálẹ́mù kúrò. (1 Kíró. 29:23) Àmọ́, Jèhófà tún ṣèlérí pé ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba, ẹni tó ní “ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin,” máa wá láti gba agbára ìjọba.—Ìsík. 21:25-27.
10 Àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn fi hàn pé àwọn Júù á ṣì máa jọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí Mèsáyà, tàbí Ẹni Àmì Òróró, tá a ṣèlérí náà bá dé. (Dán. 9:24-27) Àsọtẹ́lẹ̀ kan tí wọ́n ti sọ ṣáájú èyí, ìyẹn kí wọ́n tó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbèkùn lọ sí ìlú Bábílónì, sọ pé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n ti máa bí ẹni yìí. (Míkà 5:2) Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bá máa ní ìmúṣẹ, a jẹ́ pé a máa ní láti dá àwọn Júù sílẹ̀ nígbèkùn, wọ́n á pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, wọ́n á sì tún tẹ́ńpìlì kọ́. Àmọ́, kì í ṣe àṣà àwọn ará Bábílónì láti dá àwọn tí wọ́n bá kó nígbèkùn sílẹ̀. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì á ṣe borí ìdènà yẹn? Jèhófà ṣí ìdáhùn ìbéèrè yìí payá fún àwọn wòlíì rẹ̀.—Ámósì 3:7.
11. Àwọn ọ̀nà tó yàtọ̀ wo la gbà ṣàpẹẹrẹ Ilẹ̀ Ọba Bábílónì? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
11 Wòlíì Dáníẹ́lì wà lára àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí ìlú Bábílónì. (Dán. 1:1-6) Jèhófà lo Dáníẹ́lì láti ṣí àwọn ìjọba tó máa jẹ tẹ̀ lé agbára ayé Bábílónì payá. Jèhófà ṣí àwọn àṣírí yìí payá nípa lílo onírúurú nǹkan láti ṣàpẹẹrẹ àwọn ìjọba náà. Bí àpẹẹrẹ, ó mú kí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lá àlá nípa ère arabarìbì kan tó jẹ́ ti wúrà, fàdákà, bàbà, irin àti amọ̀. (Ka Dáníẹ́lì 2:1, 19, 31-38.) Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Dáníẹ́lì ṣí i payá pé orí ère náà tó jẹ́ wúrà dúró fún Ilẹ̀ Ọba Bábílónì.b Igẹ̀ àti apá ère náà tó jẹ́ fàdákà ṣàpẹẹrẹ agbára ayé tó máa tẹ̀ lé Bábílónì. Agbára ayé wo ni ìyẹn máa jẹ́, kí ló sì máa ṣe sáwọn èèyàn Ọlọ́run?
ORÍ KẸRIN DÚRÓ FÚN MÍDÍÀ ÒUN PÁṢÍÀ
12, 13. (a) Kí ni Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun Bábílónì? (b) Kì nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi ìkẹrin lára orí ẹranko ẹhànnà náà ṣàpẹẹrẹ Mídíà òun Páṣíà?
12 Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà ayé Dáníẹ́lì, Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà ṣí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan payá nípa agbára ayé tó máa ṣẹ́gun Bábílónì. Kì í ṣe ọ̀nà tí wọ́n máa gbà ṣẹ́gun ìlú Bábílónì nìkan ni Jèhófà sọ di mímọ̀, ó tún sọ orúkọ ẹni tó máa ṣẹ́gun ìlú náà. Ẹni tó máa ṣáájú ogun náà ni Kírúsì ará Páṣíà. (Aísá. 44:28–45:2) Dáníẹ́lì rí ìran méjì míì nípa Agbára Ayé Mídíà òun Páṣíà. Nínú ọ̀kan lára àwọn ìran náà, a fi ìjọba yìí wé béárì tá a gbé sókè ní ìhà kan. Wọ́n sì sọ fún un pé kí ó “jẹ ẹran púpọ̀.” (Dán. 7:5) Nínú ìran míì tó yàtọ̀ sí èyí, Dáníẹ́lì rí àgbò kan tó ní ìwo méjì èyí tó ṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè méjì tó para pọ̀ di agbára ayé yìí.—Dán. 8:3, 20.
13 Jèhófà lo Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà láti mú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ nígbà tó gba ìjọba lọ́wọ́ Bábílónì tó sì dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. (2 Kíró. 36:22, 23) Àmọ́, agbára ayé kan náà yìí tún fẹ́rẹ̀ẹ́ pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́. Ìwé Ẹ́sítérì nínú Bíbélì sọ nípa ìdìtẹ̀ kan tó wáyé. Ọkùnrin kan báyìí tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hámánì tó jẹ́ igbá kejì ọba Páṣíà ló sì dìtẹ̀ náà. Ó ṣètò pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù tó ń gbé ní Ilẹ̀ Ọba Páṣíà gbígbòòrò run, ó sì dá ọjọ́ kan pàtó tí ìpẹ̀yàrun náà máa wáyé. Ọpẹ́lọpẹ́ bí Jèhófà ṣe dá sí ọ̀rọ̀ náà ló yọ àwọn èèyàn rẹ̀, tó sì tún gbà wọ́n lọ́wọ́ irú ọmọ Sátánì tó ń ṣe kèéta sí wọn. (Ẹ́sít. 1:1-3; 3:8, 9; 8:3, 9-14) Ó bá a mu wẹ́kú bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi ìkẹrin lára orí ẹranko inú ìwé Ìṣípayá ṣàpẹẹrẹ Mídíà òun Páṣíà.
ORÍ KARÙN-ÚN DÚRÓ FÚN GÍRÍÌSÌ
14, 15. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wo ni Jèhófà ṣí payá nípa Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì ìgbàanì?
14 Ìkarùn-ún lára orí ẹranko ẹhànnà inú ìwé Ìṣípayá dúró fún ilẹ̀ Gíríìsì. Bí Dáníẹ́lì ṣe fi hàn nígbà tó ń sọ ìtumọ̀ àlá tí Nebukadinésárì lá, agbára ayé Gíríìsì yìí kan náà ni ikùn àti itan ère náà tó jẹ́ bàbà ṣàpẹẹrẹ. Dáníẹ́lì tún rí ìran méjì tó sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó gbàfiyèsí nípa bí ilẹ̀ ọba náà ṣe máa rí àti nípa alákòóso rẹ̀ tó lókìkí jù lọ.
15 Nínú ìran kan, Dáníẹ́lì rí ilẹ̀ Gíríìsì tá a fi àmọ̀tẹ́kùn tó ní ìyẹ́ apá mẹ́rin ṣàpẹẹrẹ, èyí tó fi hàn pé ó máa ṣẹ́gun lọ́nà yíyára kánkán. (Dán. 7:6) Nínú ìran míì, Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe bí òbúkọ kan tó ní ìwo ńlá kan ṣe yára kan àgbò kan tó ní ìwo méjì pa, ìyẹn Mídíà òun Páṣíà. Jèhófà sọ fún Dáníẹ́lì pé òbúkọ náà ṣàpẹẹrẹ ilẹ̀ Gíríìsì, ìwo ńlá tó wà lórí rẹ̀ sì dúró fún ọ̀kan lára àwọn ọba rẹ̀. Dáníẹ́lì sọ síwájú sí i pé ìwo ńlá tí òbúkọ náà ní máa ṣẹ́ àti pé ìwo kéékèèké mẹ́rin máa yọ dípò rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kí ilẹ̀ Gíríìsì tó di agbára ayé ni wọ́n ti kọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sílẹ̀, gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ náà ló ní ìmúṣẹ láìkù síbì kan. Alẹkisáńdà Ńlá, tó jẹ́ ọba tó lókìkí jù lọ nínú àwọn ọba tó jẹ ní ilẹ̀ Gíríìsì ìgbàanì, ló ṣáájú ogun tí wọ́n bá Mídíà òun Páṣíà jà. Àmọ́ kò pẹ́ tí ìwo yìí fi ṣẹ́, ọba alágbára yìí kú nígbà tí agbára rẹ̀ dé òtéńté, lẹ́ni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n [32] péré. Lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀gágun rẹ̀ mẹ́rin pín ìjọba rẹ̀ láàárín ara wọn.—Ka Dáníẹ́lì 8:20-22.
16. Kí ni Áńtíókọ́sì Kẹrin ṣe?
16 Lẹ́yìn tí ilẹ̀ Gíríìsì ti ṣẹ́gun Páṣíà, ó ṣàkóso lórí ilẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ní àkókò yìí àwọn Júù ti pa dà sí Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n sì ti tún tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́. Àyànfẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n ṣì jẹ́, tẹ́ńpìlì tí wọ́n tún kọ́ náà sì ni ojúkò ìjọsìn tòótọ́. Àmọ́ ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni (Ṣ.S.K.), ilẹ̀ Gíríìsì tó jẹ́ ìkarùn-ún lára orí ẹranko ẹhànnà náà, gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. Áńtíókọ́sì Kẹrin tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó gba ilẹ̀ ọba Alẹkisáńdà tí wọ́n pín, gbé ojúbọ òrìṣà sórí ilẹ̀ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣòfin pé pípa ni wọ́n máa pa ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí tó ń ṣe ẹ̀sìn àwọn Júù. Ẹ ò rí i pé ìkórìíra ńlá gbáà lèyí jẹ́ látọ̀dọ̀ irú ọmọ Sátánì! Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n fi gba agbára ayé lọ́wọ́ ilẹ̀ Gíríìsì. Kí ni ìkẹfà lára orí ẹranko ẹhànnà yìí dúró fún?
RÓÒMÙ TÍ ORÍ KẸFÀ DÚRÓ FÚN, ‘Ń BANI LẸ́RÙ, Ó SÌ Ń JÁNI LÁYÀ’
17. Ipa pàtàkì wo ni ìkẹfà lára orí ẹranko náà kó nínú ìmúṣẹ Jẹ́nẹ́sísì 3:15?
17 Róòmù ló ń ṣàkóso lọ́wọ́ nígbà tí Jòhánù rí ìran ẹranko ẹhànnà náà. (Ìṣí. 17:10) Róòmù tó jẹ́ ìkẹfà lára orí ẹranko yìí kó ipa pàtàkì nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Sátánì lo àwọn aláṣẹ ìlú Róòmù láti ṣe irú ọmọ obìnrin náà lọ́ṣẹ́ fúngbà díẹ̀, èyí tó já sí pé ó pa á “ní gìgísẹ̀.” Lọ́nà wo? Wọ́n gbẹ́jọ́ Jésù lórí àwọn ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn án pé ó dìtẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì dájọ́ ikú fún un. (Mát. 27:26) Àmọ́ kò pẹ́ tí ọgbẹ́ náà fi jinná torí pé Jèhófà jí Jésù dìde.
18. (a) Orílẹ̀-èdè tuntun wo ni Jèhófà yàn, kí sì nìdí? (b) Ọ̀nà wo ni irú ọmọ ejò náà ń gbà bá a nìṣó láti máa ṣe kèéta sí irú ọmọ obìnrin náà?
18 Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Róòmù lòdì sí Jésù, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè náà ló sì kọ Jésù sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pa Ísírẹ́lì nípa tara tí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀ tì. (Mát. 23:38; Ìṣe 2:22, 23) Ó wá yan orílẹ̀-èdè tuntun ìyẹn ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 3:26-29; 6:16) Ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni orílẹ̀-èdè náà, àwọn Júù àti àwọn Kèfèrí ló sì wà nínú rẹ̀. (Éfé. 2:11-18) Lẹ́yìn tí Jésù ti kú tó sì ti jíǹde, irú ọmọ ejò náà ń bá a nìṣó láti máa ṣe kèéta sí irú ọmọ obìnrin náà. Ó ju ìgbà kan lọ tí Róòmù gbìyànjú láti pa ìjọ Kristẹni tó jẹ́ apá kejì lára irú ọmọ náà rẹ́.c
19. (a) Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe agbára ayé kẹfà? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 14?
19 Nínú àlá tí Dáníẹ́lì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún Nebukadinésárì, ẹsẹ̀ ère náà tó jẹ́ irin ló ṣàpẹẹrẹ Róòmù. (Dán. 2:33) Dáníẹ́lì tún rí ìran míì tó ṣàpèjúwe Ilẹ̀ Ọba Róòmù lọ́nà tó ṣe wẹ́kú àti agbára ayé míì tó jáde wá látinú Róòmù. (Ka Dáníẹ́lì 7:7, 8.) Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn tó ń bá ìlú Róòmù ṣọ̀tá rí i bí ẹni “tí ń bani lẹ́rù, tí ń jáni láyà, tí ó sì lágbára lọ́nà kíkàmàmà.” Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ náà fi hàn pé “ìwo mẹ́wàá” máa tinú ilẹ̀ ọba yìí jáde wá, ọ̀kan lára wọn sì máa di olókìkí. Kí ni àwọn ìwo mẹ́wàá yìí dúró fún, kí la sì máa fi dá ìwo kékeré náà mọ̀? Ọ̀nà wo ni ìwo kékeré náà gbà bá àpèjúwe ère arabarìbì tí Nebukadinésárì rí mu? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó wà ní ojú ìwé 14.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Obìnrin yìí dúró fún ètò Jèhófà tó dà bí ìyàwó, àwọn áńgẹ́lì tó wà lókè ọ̀run ló sì para pọ̀ di ètò Ọlọ́run yìí.—Aísá. 54:1; Gál. 4:26; Ìṣí. 12:1, 2.
b Orí ère tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì àti ẹ̀kẹta lára orí ẹranko ẹhànnà tí ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ Bábílónì. Wo àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 12 sí 13.
c Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Róòmù pa ìlú Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, ìgbéjàkò yìí kò sí lára ìmúṣẹ Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Ní àkókò yẹn, Ísírẹ́lì nípa tara kì í ṣe orílẹ̀-èdè àyànfẹ́ Ọlọ́run mọ́.