Kíróníkà Kìíní
29 Ọba Dáfídì sọ fún gbogbo ìjọ náà pé: “Sólómọ́nì ọmọ mi, ẹni tí Ọlọ́run yàn,+ jẹ́ ọ̀dọ́, kò ní ìrírí,*+ iṣẹ́ náà sì pọ̀, torí pé kì í ṣe tẹ́ńpìlì* èèyàn, àmọ́ ti Jèhófà Ọlọ́run ni.+ 2 Mo ti sa gbogbo ipá mi láti pèsè àwọn nǹkan sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run mi, mo ti pèsè wúrà fún iṣẹ́ ọnà wúrà, fàdákà fún iṣẹ́ ọnà fàdákà, bàbà fún iṣẹ́ ọnà bàbà, irin fún iṣẹ́ ọnà irin,+ àwọn igi fún iṣẹ́ ọnà igi,+ àwọn òkúta ónísì, àwọn òkúta tí wọ́n máa fi erùpẹ̀ tí a pò pọ̀ mọ, àwọn òkúta róbótó-róbótó lóríṣiríṣi àwọ̀, gbogbo oríṣiríṣi òkúta iyebíye àti òkúta alabásítà tó pọ̀ gan-an. 3 Bákan náà, nítorí ìfẹ́ tí mo ní fún ilé Ọlọ́run mi,+ mo fi wúrà àti fàdákà sílẹ̀ látinú àwọn ohun iyebíye mi+ fún ilé Ọlọ́run mi, láfikún sí gbogbo ohun tí mo ti fi sílẹ̀ fún ilé mímọ́ náà, 4 títí kan ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) tálẹ́ńtì* wúrà Ófírì+ àti ẹgbẹ̀rún méje (7,000) tálẹ́ńtì fàdákà tí a yọ́ mọ́, láti fi bo ògiri àwọn ilé náà, 5 wúrà fún iṣẹ́ ọnà wúrà àti fàdákà fún iṣẹ́ ọnà fàdákà àti fún gbogbo iṣẹ́ tí àwọn oníṣẹ́ ọnà máa ṣe. Ní báyìí, ta ló fẹ́ mú ẹ̀bùn wá fún Jèhófà lónìí?”+
6 Nítorí náà, àwọn olórí àwọn agbo ilé, àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ pẹ̀lú àwọn olórí tó ń bójú tó iṣẹ́ ọba+ jáde wá tinú-tinú. 7 Àwọn nǹkan tí wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́ nìyí: ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) tálẹ́ńtì wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) owó dáríkì,* ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ńtì fàdákà, ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) tálẹ́ńtì bàbà àti ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) tálẹ́ńtì irin. 8 Gbogbo àwọn tó ní òkúta iyebíye kó wọn wá sí ibi ìṣúra ilé Jèhófà lábẹ́ àbójútó Jéhíélì+ ọmọ Gẹ́ṣónì.+ 9 Inú àwọn èèyàn náà dùn pé wọ́n mú ọrẹ wá tinútinú, nítorí pé gbogbo ọkàn+ ni wọ́n fi mú ọrẹ náà wá fún Jèhófà, inú Ọba Dáfídì pẹ̀lú sì dùn gan-an.
10 Nígbà náà, Dáfídì yin Jèhófà lójú gbogbo ìjọ náà. Dáfídì sọ pé: “Ìyìn ni fún ọ, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì baba wa, títí láé àti láéláé.* 11 Jèhófà, tìrẹ ni títóbi+ àti agbára ńlá+ àti ẹwà àti ògo àti ọlá ńlá,*+ nítorí gbogbo ohun tó wà ní ọ̀run àti ní ayé jẹ́ tìrẹ.+ Jèhófà, tìrẹ ni ìjọba.+ Ìwọ ni Ẹni tó fi ara rẹ̀ ṣe olórí lórí ohun gbogbo. 12 Ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àti ògo ti wá,+ o sì ń ṣàkóso ohun gbogbo,+ ọwọ́ rẹ ni agbára+ àti títóbi+ wà, ọwọ́ rẹ ló lè sọni di ńlá,+ òun ló sì lè fúnni lágbára.+ 13 Ní báyìí, Ọlọ́run wa, a dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, a sì yin orúkọ rẹ ológo.
14 “Síbẹ̀, ta ni mí, ta sì ni àwọn èèyàn mi, tí a fi máa láǹfààní láti ṣe ọrẹ àtinúwá bí irú èyí? Nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, ohun tó ti ọwọ́ rẹ wá ni a sì fi fún ọ. 15 Nítorí àjèjì àti àlejò ni a jẹ́ níwájú rẹ, bí gbogbo àwọn baba ńlá wa ti jẹ́.+ Nítorí àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé da bí òjìji,+ kò sí ìrètí kankan. 16 Jèhófà Ọlọ́run wa, gbogbo ọrọ̀ yìí tí a ti kó jọ láti fi kọ́ ilé fún ìwọ àti orúkọ mímọ́ rẹ, ọwọ́ rẹ ni ó ti wá, tìrẹ sì ni gbogbo rẹ̀. 17 Ọlọ́run mi, mo mọ̀ dáadáa pé o máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn+ àti pé o fẹ́ràn ìwà títọ́.*+ Nínú òótọ́* ọkàn ni mo fínnú-fíndọ̀ pèsè gbogbo nǹkan yìí, ayọ̀ mi sì kún láti rí àwọn èèyàn rẹ tó wá síbí láti ṣe ọrẹ àtinúwá fún ọ. 18 Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ máa ní irú ẹ̀mí àti èrò yìí nínú ọkàn wọn títí láé, kí o sì darí ọkàn wọn sọ́dọ̀ rẹ.+ 19 Kí o fún Sólómọ́nì ọmọ mi ní ọkàn pípé,*+ kí ó lè máa pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́+ àti àwọn ìránnilétí rẹ pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ, kí ó lè ṣe gbogbo nǹkan yìí, kí ó sì kọ́ tẹ́ńpìlì* tí mo ti pèsè àwọn nǹkan sílẹ̀ fún.”+
20 Dáfídì wá sọ fún gbogbo ìjọ náà pé: “Ní báyìí, ẹ yin Jèhófà Ọlọ́run yín.” Gbogbo ìjọ náà sì yin Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, wọ́n tẹrí ba, wọ́n sì wólẹ̀ fún Jèhófà àti fún ọba. 21 Wọ́n ń rú àwọn ẹbọ sí Jèhófà, wọ́n sì ń rú àwọn ẹbọ sísun+ sí Jèhófà ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, ẹgbẹ̀rún (1,000) akọ ọmọ màlúù, ẹgbẹ̀rún (1,000) àgbò, ẹgbẹ̀rún (1,000) akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti àwọn ọrẹ ohun mímu+ wọn; àwọn ẹbọ tí wọ́n rú nítorí gbogbo Ísírẹ́lì pọ̀ gan-an.+ 22 Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu níwájú Jèhófà ní ọjọ́ yẹn tìdùnnútìdùnnú,+ wọ́n fi Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì jẹ ọba lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì fòróró yàn án níwájú Jèhófà láti jẹ́ aṣáájú,+ bákan náà wọ́n yan Sádókù láti jẹ́ àlùfáà.+ 23 Sólómọ́nì jókòó sórí ìtẹ́ Jèhófà+ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò Dáfídì bàbá rẹ̀, ó ṣàṣeyọrí, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń ṣègbọràn sí i. 24 Gbogbo àwọn ìjòyè,+ àwọn jagunjagun tó lákíkanjú+ àti gbogbo àwọn ọmọ Ọba Dáfídì+ fi ara wọn sábẹ́ Ọba Sólómọ́nì. 25 Jèhófà sọ Sólómọ́nì di ẹni ńlá tó ta yọ lójú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì fi iyì ọba dá a lọ́lá débi pé kò sí ọba kankan ní Ísírẹ́lì tó nírú iyì bẹ́ẹ̀ rí.+
26 Bí Dáfídì ọmọ Jésè ṣe jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì nìyẹn, 27 gbogbo ọdún* tó fi jọba lórí Ísírẹ́lì jẹ́ ogójì (40) ọdún. Ó fi ọdún méje jọba+ ní Hébúrónì, ó sì fi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) jọba+ ní Jerúsálẹ́mù. 28 Ó dàgbà, ó darúgbó+ kó tó kú, ẹ̀mí* rẹ̀ gùn dáadáa, ó ní ọrọ̀ àti ògo; Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+ 29 Ní ti ìtàn Ọba Dáfídì láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ó wà lákọsílẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì aríran àti ti wòlíì Nátánì+ àti ti Gádì+ olùríran 30 pẹ̀lú gbogbo ìjọba rẹ̀ àti agbára rẹ̀ àti àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i àti sí Ísírẹ́lì àti sí gbogbo ìjọba àwọn ilẹ̀ tó yí i ká nígbà ayé rẹ̀.