Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
Kí ló ran obìnrin kan tó máa ń ṣe fàyàwọ́ dáyámọ́ǹdì lọ́wọ́ tó sì tún máa ń jí ẹrù ọ̀gá ẹ̀ láti di òṣìṣẹ́ tó ṣeé fọkàn tán? Kí ló ran obìnrin kan tó ti fẹ́ para ẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́wọ́ láti rí ìdí tí Ọlọ́run fi dá òun sáyé? Báwo ni ọkùnrin kan tó máa ń mutí yó tó sì máa ń lòògùn nílòkulò ṣe bọ́ lọ́wọ́ àwọn àṣàkaṣà tó ti di bárakú fún un yìí? Gbọ́ ohun tí wọ́n fẹnu ara wọn sọ.
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ
ORÚKỌ: MARGARET DEBRUYN
ỌJỌ́ ORÍ: ỌDÚN MÁRÙNDÍNLÁÀÁDỌ́TA [45]
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: BOTSWANA
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ONÍFÀYÀWỌ́ ÀTI OLÈ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ọmọ orílẹ̀-èdè Jámánì ni bàbá mi, àmọ́ ó ti wá dọmọ ìlú South-West Africa (tí wọ́n ń pè ní Nàmíbíà báyìí). Ọmọ ìbílẹ̀ Mangologa, lórílẹ̀-èdè Botswana sì ni màmá tó bí mi lọ́mọ. Àmọ́ ìlú Gobabis, lórílẹ̀-èdè Nàmíbíà ni wọ́n bí mi sí.
Láàárín ọdún 1970 sí 1979, ìjọba orílẹ̀-èdè South Africa ló sábà máa ń pinnu ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàmíbíà, wọ́n sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi tìpá tìkúùkù mú káwọn ará Nàmíbíà nílé lóko bẹ̀rẹ̀ sí í ṣègbọràn sáwọn òfin kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tí wọ́n ń ṣe. Torí àwọn òbí mi kì í ṣe ẹ̀yà kan náà, wọ́n ní kí wọ́n fira wọn sílẹ̀. Torí náà, màmá mi kó àwa ọmọ lọ ságbègbè Ghansi, ní Botswana, ibẹ̀ la sì ń gbé.
Nígbà tó di ọdún 1979, mo kó lọ sílùú Lobatse ní Botswana, ọ̀dọ̀ àwọn alágbàtọ́ ni mo sì wà títí tí mo fi kàwé tán. Nígbà tó yá, mo ríṣẹ́ akọ̀wé sí ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń tún mọ́tò ṣe. Bí mo ṣe ń dàgbà, gbogbo ohun tí mo gbà gbọ́ ni pé Ọlọ́run kọ́ ló ń pèsè fáwa èèyàn, pé olúkúlùkù ló ní láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe, yálà rere tàbí búburú, láti fi bójú tó ìdílé ẹ̀.
Torí pé mo jẹ́ ọ̀gá níbi iṣẹ́, ó rọrùn fún mi láti máa jí àwọn ẹ̀yà ara ọkọ̀. Ìgbàkigbà tí ọkọ̀ ojú irin bá gba àárín ìlú kọjá lálẹ́, èmi àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ máa ń wọnú ẹ̀ láti jí ohunkóhun tọ́wọ́ wa bá ṣáà ti lè bà. Ìgbà tó yá mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe fàyàwọ́ dáyámọ́ǹdì, góòlù àti idẹ. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lòògùn nílòkulò, mo dọmọọ̀ta, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kó ọkùnrin.
Nígbà tó di ọdún 1993, ọwọ́ pálábá mi ségi, wọ́n ká mi mọ́ ibi tí mo ti ń jí nǹkan níbi iṣẹ́, wọ́n sì lé mi dà nù. Àwọn tá a jọ ń pera wa lọ́rẹ̀ẹ́ pa mí tì, torí ẹ̀rù ń bà wọ́n pé kí wọ́n má lọ mú àwọn náà. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn dùn mí gan-an, mo sì pinnu pé mi ò ní finú tán ẹnikẹ́ni mọ́.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Lọ́dún 1994, mo pàdé Tim àti Virginia, míṣọ́nnárì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn méjèèjì. Ibi iṣẹ́ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ni wọ́n ti wàásù fún mi, wọ́n sì máa ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà ìsinmi ọ̀sán. Nígbà tó yá, mo rí i pé mo lè finú tán wọn, torí náà mo gbà pé kí wọ́n máa wá kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé.
Kò pẹ́ kò jìnnà, mo rí i pé tí mo bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn mo ní láti ṣàwọn ìyípadà kan nígbèésí ayé mi. Bí àpẹẹrẹ, mo kẹ́kọ̀ọ́ látinú 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10 pé “kì í ṣe àwọn àgbèrè, . . . àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” Díẹ̀díẹ̀ ni mo jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú yìí. Mi ò jalè mọ́. Mi ò kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọọ̀ta tá a jọ ṣe kékeré wọ̀nyẹn mọ́. Nígbà tó sì yá, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo lé àwọn ọkùnrin tí mò ń kó kiri dà nù.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Mo máa ń sapá gidigidi láti má ṣe bínú sódì, mo sì máa ń rí i dájú pé mi ò jágbe mọ́ àwọn ọmọ mi tí wọ́n bá ṣàṣìṣe. (Éfésù 4:31) Mo máa ń gbìyànjú láti fi pẹ̀lẹ́tù bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ṣohun tó dùn mí. Ọ̀nà tí mo gbà ń báwọn sọ̀rọ̀ yìí tí ṣe wá láǹfààní gan-an, ó sì ti jẹ́ kí ìdílé wa wà níṣọ̀kan bí òṣùṣù ọwọ̀.
Àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ àtàwọn aládùúgbò wa pàápàá ti wá rí i pé àwọn lè fọkàn tán mi. Mo ti dẹni táwọn èèyàn lè gbẹ̀rí ẹ̀ jẹ́, mo ti di òṣìṣẹ́ tó ṣeé fọkàn tán, mo sì ti mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná. Ní báyìí, ó ti wá ṣeé ṣe fún mi láti máa gbọ́ bùkátà ara mi, bí mo ti ń lo àkókò tó pọ̀ láti kọ́ àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tọkàntọkàn ni mo fi gbà pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Òwe 10:22, tó sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ
ORÚKỌ: GLORIA ELIZARRARAS DE CHOPERENA
ỌJỌ́ ORÍ: ỌDÚN MẸ́TÀDÍNLÓGÓJÌ [37]
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: MẸ́SÍKÒ
OHUN TÍ MO ṢE: MO GBÌYÀNJÚ LÁTI PARA MI
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Àdúgbò àwọn olówó ni mo gbé dàgbà lágbègbè Naucalpan, ní olú ìlú orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Láti kékeré ni mo ti ya ọmọkọ́mọ, tí mo sì fẹ́ràn láti máa lọ sóde àríyá. Ọmọ ọdún méjìlá [12] ni mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í mutí lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá [14], mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn nílòkulò nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16]. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn ni mo sá ńlé. Àwọn ọmọ tó wá látinú ìdílé tí ò sí àlàáfíà ni mò ń bá ṣọ̀rẹ́, àwọ́n kan nínú wọn sá ńlé torí pé wọ́n lù wọ́n nílùkulù, àwọn míì sì sá ńlé nítorí pé wọ́n sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wọn. Ìgbésí ayé sú mi débi pé ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo gbìyànjú láti para mi.
Ìgbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìmúra bá àwọn èèyàn polówó ọjà wọn. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe yìí jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí í báwọn olóṣèlú, àwọn olórin, àwọn òṣèré àtàwọn eléré ìdárayá ṣe wọléwọ̀de. Ìgbà tó yá, mo ṣègbéyàwó mo sì bímọ, àmọ́ èmi ni mo máa ń ṣe gbogbo ìpinnu nínú ìdílé. Mi ò jáwọ́ nínú sìgá mímu, mò ń mutí mo sì ń ṣe fàájì dọ́ba. Ọ̀rọ̀ rírùn, ìsọkúsọ àtàwọn àwàdà tí ò dáa ló kún ẹnu mi. Mi ò sì ń pẹ́ bínú.
Ẹgbẹ́ ẹyẹ lẹyẹ ń wọ́ tọ̀ lọ̀rọ̀ èmi àtàwọn tí mò ń bá rìn. Lójú tiwọn, mi ò lálàṣí ohunkóhun. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ẹ̀ ńṣe layé ń sú mi, torí ìgbésí ayé mi ò nítumọ̀.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Ọdún 1998 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀kọ́ Bíbélì jẹ́ kí n mọ̀ pé ó nídìí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni láti sọ ayé yìí di Párádísè, kó jí àwọn òkú dìde àti pé ọjọ́ iwájú aláyọ̀ yìí ò yọ èmi náà sílẹ̀.
Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ọ̀nà téèyàn lè gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni pé kó máa ṣègbọràn sáwọn òfin rẹ̀. (1 Jòhánù 5:3) Èyí kọ́kọ́ ṣòro fún mi láti ṣe, torí pé mi ò gba ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ ẹnì kankan rí. Àmọ́ nígbà tó yá, mo rí i pé mi ò lè máa bá a nìṣó láti darí ìgbésí ayé mi. (Jeremáyà 10:23) Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ mi sọ́nà. Mo bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́ láti máa fàwọn ìlànà ẹ̀ ṣèwà hù nígbèésí ayé mi, kí n sì lè máa kọ́ àwọn ọmọ mi láti má ṣe fìwà jọ mí.
Kò rọrùn fún mi láti ṣàwọn ìyípadà tó yẹ kí n ṣe, àmọ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí í fìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Éfésù 4:22-24 ṣèwà hù, ó ní: “Kí ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé . . . kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” Mo mọ̀ pé tí mo bá fẹ́ gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, mo ní láti tọwọ́ àwọn ìwàkiwà bíi sìgá mímu bọlẹ̀, mo sì ní láti kọ́ béèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ gidi jáde lẹ́nu. Ó gbà mí tó nǹkan bí ọdún mẹ́ta kí n tó lè ṣàwọn ìyípadà tó yẹ, tí mo sì wá ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Yàtọ̀ síyẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bí ìyá àti ìyàwó nínú ilé. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í fìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Pétérù 3:1, 2 ṣèwà hù, ó ní: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà torí pé ní báyìí mo ti mọ̀ pé ó nídìí tó fi dá mi sáyé. Mo mọ̀ pé mo ti dáa léèyàn báyìí, ó sì ti ṣeé ṣe fún mi láti tọ́ àwọn ọmọ mi lọ́nà tó tọ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, lọ́kàn mi mo máa ń dára mi lẹ́bi torí àwọn ìwà burúkú tí mo ti hù tẹ́lẹ̀, àmọ́ mo mọ̀ pé Jèhófà mohun tó wà lọ́kàn mi. (1 Jòhánù 3:19, 20) Kò sí àní-àní pé, bí mo ṣe ń fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù ti dáàbò bò mí kúrò lọ́wọ́ ewu, ó sì ti jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀.
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ
ORÚKỌ: JAILSON CORREA DE OLIVEIRA
ỌJỌ́ ORÍ: ỌDÚN MẸ́TÀLÉLỌ́GBỌ̀N [33]
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: BRAZIL
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: Ọ̀MÙTÍ ÀTI AJÒÒGÙNYÓ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Bagé tó wà nítòsí ẹnubodè orílẹ̀-èdè Brazil àti Uruguay ni wọ́n bí mi sí. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] èèyàn ló ń gbé nílùú tó wà lórílẹ̀-èdè Brazil yìí. Iṣẹ́ àgbẹ̀ àti sísin màlúù sì niṣẹ́ wọn. Àdúgbò àwọn akúṣẹ̀ẹ́ táwọn ọmọọ̀ta pọ̀ sí ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, ṣàṣà sì lọmọdé tó wà ládùúgbò yìí tí kì í mutí tí kì í sì í lòògùn nílòkulò.
Nígbà tí mo kúrò níléèwé, mo bẹ̀rẹ̀ sí í mutí, mò ń mugbó, mo sì máa ń gbọ́ àwọn orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò. Mi ò gba Ọlọ́run gbọ́. Mo ronú pé bí ìyà ṣe wọ aráyé lẹ́wù, táyé ò sì rójú jẹ́ ẹ̀rí pé kò sí Ọlọ́run.
Mo máa ń fi gìtá kọrin, mo sì máa ń kọ ọ̀rọ̀ téèyàn lè sọ dorin, àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Ìṣípayá tó wà nínú Bíbélì ni mo sì sábà máa ń sọ dorin. Ẹgbẹ́ akọrin mi ò ríṣe bí mo ṣe fẹ́, torí náà mo bẹ̀rẹ̀ sí í lòògùn olóró kí n lè máa fijó dá bírà tí mo bá lọ kọrin. Mi ò bẹ̀rù pé lílo oògùn nílòkulò lè pa mí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ lára àwọn olórin tí mo gba tiwọn nìyẹn.
Ọwọ́ ìyá àgbà tó tọ́ mi dàgbà ni mo ti máa ń yáwó tí mo fi ń ra àwọn oògùn olóró tí mò ń lò. Tí wọ́n bá bi mí pé kí ni mo fẹ́ fowó ṣe, ńṣe ní mo máa ń parọ́ fún wọn. Nígbà tí mo tún máa wá ṣe é dójú ẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í tojú bọ ilé aláwo. Mo gbójú lé oògùn, torí mo rò pé ó lè jẹ́ kí n máa kọrin tó máa tà létí aráyé.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo sì ń lọ sáwọn ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìwà mi àti bí mo ṣe ń ronú bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Ìgbésí ayé bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí, mo sì fẹ́ máa láyọ̀. Ìyẹn ló mú kí n pinnu láti gé irun mi, torí mo ti dá a sílẹ̀ káwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìgbésí ayé mi ò tẹ́ mi lọ́rùn àti pé ọlọ̀tẹ̀ ni mí. Ìgbà tó yá, mo lóye pé tí mo bá fẹ́ kínú Ọlọ́run dùn sí mi, àfi kí n jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró àti sìgá mímu. Mo tún ní láti yan àwọn orin tó dáa tí màá máa gbọ́.
Lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n kọ sára ògiri. Ìwé Òwe 3:5, 6 ni, ohun tó sì wà níbẹ̀ rèé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” Nígbà tí mo ronú lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn, ó wá dá mi lójú pé tí mo bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa tún ìgbésí ayé mi ṣe.
Síbẹ̀, kò rọrùn fún mi láti fi ọ̀nà tí mo gbà ń gbé ìgbésí ayé mi tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, ńṣe ni jíjáwọ́ nínú ọtí mímu, sìgá mímu àti lílo oògùn olóró dà bí ìgbà téèyàn ní kí n lọ gé ọwọ́ mi dà nù. (Mátíù 18:8, 9) Kò rọrùn fún mi láti fàwọn àṣà yìí sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Mo mọ̀ pé mi ò lè ṣèyẹn. Torí náà, ẹ̀ẹ̀kan náà ni mo jáwọ́ nínú gbogbo àwọn ìwà burúkú wọ̀nyẹn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í sá fáwọn èèyàn tó lè mú kí n pa dà sẹ́sẹ àárọ̀, mi ò sì ń lọ síbi tí mo ti máa ráwọn tó ń fàwọn ìwà tó lè bayé èèyàn jẹ́ wọ̀nyẹn ṣayọ̀ mọ́.
Mo kọ́ láti máa jẹ́ káwọn àṣeyọrí tí mo bá ṣe lóòjọ́ máa wú mi lórí, mi kì í sì í ronú lórí àwọn ohun tó lè mú mi rẹ̀wẹ̀sì. Ó ń wù mí pé kí n mọ́ nípa tara, kí n níwà ọmọlúwàbí, kí n sì máa sin Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́. Mo gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti má ṣe pa dà máa ronú nípa àwọn ìwà tí mo ti fi sílẹ̀, àmọ́ kí n máa wo bí mo ṣe lè tẹ̀ síwájú, ó sì dá mi lójú pé ó gbọ́ àdúrà mi. Nígbà míì, mo máa ń pa dà hu àwọn ìwà tí mo ti fi sílẹ̀. Àmọ́, mi ò jáwọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo máa ń ṣe pẹ̀lú ẹni tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọtí àmujù tí mo ń mu lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan máa ń pa mí lọ́bọlọ̀.
Àwọn òtítọ́ tí mo kọ́ nínú Bíbélì nípa Ọlọ́run bọ́gbọ́n mu, bí àpẹẹrẹ mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, pé ó máa pa ìsìn èké run àti pé ó ń ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn kárí ayé. (Mátíù 7:21-23; 24:14; 1 Pétérù 5:6, 7) Kò séyìí tó ṣeé kó dà nù nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Paríparì ẹ̀, mo pinnu láti ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run, torí mo fẹ́ fi ìmoore hàn fún gbogbo nǹkan tó ti ṣe fún mi.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO RÍ: Mo ti rí i pé ayé mi ti nítumọ̀ báyìí. (Oníwàásù 12:13) Kàkà kí n sì máa gba nǹkan lọ́wọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí mi ṣáá, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti fún wọn ní nǹkan kan. Mo ṣàlàyé àwọn ohun rere tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì fún ìyá àgbà, àwọn náà sì ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà báyìí. Púpọ̀ lára àwọn mọ̀lẹ́bí mi àti ọ̀kan lára àwọn elégbè mi náà sì ti ṣe bẹ́ẹ̀.
Mo ti gbéyàwó báyìí, èmi àti ìyàwó mi sì ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wa láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo mọ̀ pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ni mo ní torí pé mo ti kọ́ láti ‘gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.’
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
“Ìgbésí ayé bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí, mo sì fẹ́ máa láyọ̀”