Ìwọ Kò Gbọ́dọ̀ Gbàgbé Jèhófà
NÍGBÀ kan láyé àtijọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà létí Odò Jọ́dánì wọ́n fẹ́ sọdá. Jèhófà wá mú kí odò náà dúró kó má ṣàn mọ́, káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè rí orí ilẹ̀ gbígbẹ gbà kọjá. Bó ṣe di pé ogunlọ́gọ̀ ọmọ Ísírẹ́lì wọ́ tìrítìrí gba orí ilẹ̀ gbígbẹ kọjá lọ́wọ̀ọ̀wọ́, sí Ilẹ̀ Ìlérí nìyẹn. Àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìí ti fẹsẹ̀ rìn gba orí ilẹ̀ gbígbẹ kọjá láàárín agbami òkun rí, tí ara wọn kò sì tutù rárá. Àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nìyí, tó sì jẹ́ pé wọn ò ní ṣe é mọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tó la Odò Jọ́dánì kọjá lọ́jọ́ náà lá máa sọ lọ́kàn ara wọn, bíi tàwọn baba ńlá wọn tó sọdá Òkun Pupa ní ogójì ọdún sẹ́yìn, pé, ‘Mi ò ní gbàgbé ohun tí Jèhófà ṣe yìí láéláé.’—Jóṣ. 3:13-17.
Ṣùgbọ́n Jèhófà mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ‘gbàgbé àwọn iṣẹ́ òun kíákíá.’ (Sm. 106:13) Ìdí nìyẹn tó fi pàṣẹ pé kí Jóṣúà aṣáájú wọn gbé òkúta méjìlá ní ìsàlẹ̀ odò yẹn, kó sì kó wọn síbi tí wọ́n bá kọ́kọ́ pabùdó sí, kí wọ́n lè máa fi rántí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. Jóṣúà wá sọ fún wọn pé: “Àwọn òkúta wọ̀nyí . . . jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Jóṣ. 4:1-8) Àwọn òkúta ìrántí yìí yóò jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa rántí àwọn iṣẹ́ àrà Jèhófà, yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa fi ìṣòtítọ́ sìn ín nígbà gbogbo.
Ǹjẹ́ àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ nínú ìtàn yìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Àwa náà kò gbọ́dọ̀ gbàgbé Jèhófà, a sì gbọ́dọ̀ máa fi ìṣòtítọ́ sìn ín nìṣó. Àwọn ìkìlọ̀ míì tún wà tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kan àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ti òde òní náà. Ìwọ wo ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ yìí, ó ní: “Ṣọ́ra rẹ, kí o má bàa gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ, láti ṣàìpa àwọn àṣẹ rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ mọ́.” (Diu. 8:11) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé téèyàn bá gbàgbé Jèhófà, èèyàn lè dẹni tó mọ̀ọ́mọ̀ ń ṣàìgbọràn sí i. Irú èyí sì lè ṣẹlẹ̀ lóde òní náà. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni, ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe tẹ̀ lé “àpẹẹrẹ ọ̀nà àìgbọràn kan náà,” irú èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ní aginjù.—Héb. 4:8-11.
Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, táá jẹ́ ká túbọ̀ rí i pé a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ẹ̀kọ́ tá a máa rí kọ́ lára àwọn ọkùnrin olóòótọ́ méjì tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì yóò jẹ́ ká lè máa fi ìfaradà àti ìmọrírì sin Jèhófà.
Àwọn Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Rántí Jèhófà
Ní gbogbo ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi wà nílẹ̀ Íjíbítì, Jèhófà kò gbàgbé wọn. Ó “rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.” (Ẹ́kís. 2:23, 24) Ohun mánigbàgbé ló sì ṣe nígbà yẹn láti fi yọ wọ́n lóko ẹrú.
Jèhófà kọ́kọ́ fi ìyọnu mẹ́sàn-án kọ lu ilẹ̀ Íjíbítì. Àwọn àlùfáà pidánpidán Fáráò kò sì rí ohunkóhun ṣe láti dáwọ́ ìyọnu wọ̀nyẹn dúró. Síbẹ̀, Fáráò ṣorí kunkun, kò dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ kí wọ́n máa lọ. (Ẹ́kís. 7:14–10:29) Àmọ́ nígbà tí ìyọnu kẹwàá han agbéraga ọba náà léèmọ̀, kíá ló gba Ọlọ́run lọ́gàá, tó sì dá wọn sílẹ̀. (Ẹ́kís. 11:1-10; 12:12) Bí Mósè ṣe kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata jáde kúrò ní Íjíbítì nìyẹn. Àpapọ̀ iye wọn tó àádọ́jọ ọ̀kẹ́ [3,000,000]. (Ẹ́kís. 12:37, 38) Wọn ò tíì fi bẹ́ẹ̀ rìn jìnnà tí Fáráò fi tún dà á rò pé òun yóò dá wọn pa dà. Ó kó àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun àtàwọn agẹṣinjagun rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó lágbára jù láyé ìgbà yẹn, láti lọ fipá kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹrú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pa dà. Láàárín àkókò náà, Jèhófà sọ pé kí Mósè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí Píháhírótì, tó jẹ́ ilẹ̀ tóóró kan tó wà láàárín òkè ńlá àti Òkun Pupa, ìyẹn wá jẹ́ kó dà bíi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti há.—Ẹ́kís. 14:1-9.
Fáráò gbà pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti há pátápátá síbi tí wọ́n gbà, pé ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun òun sì máa tó bò wọ́n mọ́bẹ̀. Àmọ́ Jèhófà fi ọwọ̀n àwọsánmà àti ọwọ̀n iná pààlà sáàárín àwọn ọmọ ogun Íjíbítì àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọ́n má lè dé ọ̀dọ̀ wọn. Ọlọ́run wá pín Òkun Pupa níyà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ la ọ̀nà sí àárín òkun, tí omi òkun tó pín yà náà fi dà bí ògiri, ó sì ga tó òpó iná kan ààbọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń gba orí ilẹ̀ gbígbẹ kọjá lọ láàárín òkun. Nígbà táwọn ará Íjíbítì fi máa dé etíkun, ńṣe ni wọ́n ń wo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́ọ̀ọ́kán bí wọ́n ṣe ń lọ sí òdì kejì òkun.—Ẹ́kís. 13:21; 14:10-22.
Tó bá jẹ́ aṣáájú tó gbọ́n ni, ṣe ni ì bá rọra dẹ́yìn lẹ́yìn wọn, àmọ́ bíi ti Fáráò kọ́. Ó dá ara rẹ̀ lójú débi pé ó pàṣẹ pé kí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun òun àtàwọn agẹṣinjagun òun tẹ̀ lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ọ̀nà tó là láàárín òkun yẹn. Ni wọ́n bá gbá tẹ̀ lé wọn. Àmọ́ gbogbo eré àsápajúdé àwọn ará Íjíbítì yìí dópin kó tó di pé wọ́n lé àwọn ẹ̀ṣọ́ ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn bá. Wọ́n kàn dédé rí i pé àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àwọn ò lè rìn mọ́ ni! Jèhófà ti gbá àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn yọ.—Ẹ́kís. 14:23-25; 15:9.
Orí wàhálà kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn tí kò lè rìn mọ́ yìí làwọn ará Íjíbítì wà tí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi dé èbúté òdì kejì òkun níhà ìlà oòrùn. Mósè wá na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun Pupa. Jèhófà sì mú kí omi tó dúró bí ògiri lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì tí ọ̀nà fi là láàárín òkun, ya wálẹ̀. Bí alagbalúgbú omi ṣe ya bo Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́lẹ̀ bámúbámú nìyẹn, wọ́n sì kú sínú òkun. Kò sí ọ̀kan tó yè bọ́ lára àwọn ọ̀tá náà. Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe dòmìnira nìyẹn!—Ẹ́kís. 14:26-28; Sm. 136:13-15.
Ó pẹ́ gan-an kí jìnnìjìnnì ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tó kúrò lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní àyíká ibẹ̀. (Ẹ́kís. 15:14-16) Kódà, ní ogójì ọdún lẹ́yìn náà, Ráhábù ọmọ ìlú Jẹ́ríkò ṣì sọ fáwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì méjì pé: ‘Jìnnìjìnnì yín ti bá wa, nítorí a ti gbọ́ bí Jèhófà ti gbẹ omi Òkun Pupa táútáú kúrò níwájú yín nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Íjíbítì.’ (Jóṣ. 2:9, 10) Àní, àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà wọ̀nyẹn pàápàá kò gbàgbé bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ là. Dájúdájú, kò sídìí kankan rárá tó fi yẹ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbàgbé Jèhófà.
‘Ó Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Wọn bí Ọmọlójú Rẹ̀’
Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Òkun Pupa kọjá, wọ́n dé Aṣálẹ̀ Sínáì, tó jẹ́ “aginjù ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù.” Bí ogunlọ́gọ̀ èèyàn yẹn ṣe ń rìn lọ nínú “ìyàngbẹ ilẹ̀ tí kò ní omi kankan,” tí kò sì sí oúnjẹ kankan níbẹ̀ fún wọn láti jẹ, Jèhófà ń tọ́jú wọn. Nígbà tí Mósè ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ó ní: “[Jèhófà] rí [Ísírẹ́lì] ní ilẹ̀ aginjù, àti nínú aṣálẹ̀ tí ó ṣófo, tí ń hu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí yí i ká, láti tọ́jú rẹ̀, láti fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ bí ọmọlójú ojú rẹ̀.” (Diu. 8:15; 32:10) Báwo ni Ọlọ́run ṣe tọ́jú wọn?
Jèhófà fi ‘oúnjẹ fún wọn láti ọ̀run,’ wọ́n sì pè é ní mánà. Ọ̀nà ìyanu loúnjẹ yìí ń gbà wá tí wọ́n sì ń rí i “lórí ilẹ̀ aginjù.” (Ẹ́kís. 16:4, 14, 15, 35) Jèhófà tún mú kí omi ṣàn jáde wá fún wọn “láti inú akọ àpáta.” Ọlọ́run sì tún rí sí i pé, ní gbogbo ogójì ọdún tí wọ́n lò nínú aginjù, aṣọ àlàbora wọn kò gbó mọ́ wọn lára, bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wọn kò wú. (Diu. 8:4) Kí ni Jèhófà wá ń retí pé kí wọ́n máa ṣe láti fi hàn pé àwọn moore? Mósè sọ ọ́ fún wọn, ó ní: “Kí o ṣọ́ra rẹ, kí o sì ṣọ́ ọkàn rẹ gidigidi, kí o má bàa gbàgbé àwọn ohun tí ojú rẹ ti rí àti pé kí wọ́n má bàa lọ kúrò nínú ọkàn-àyà rẹ ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ.” (Diu. 4:9) Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mọrírì àwọn iṣẹ́ ará tí Jèhófà ṣe láti fi gbà wọ́n là, tí wọ́n sì ń rántí wọn, Jèhófà ni wọ́n á máa sìn títí ayé, wọn yóò sì máa sa gbogbo ipá wọn láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n kí ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe?
Wọ́n Gbàgbé, Wọ́n sì Di Aláìmoore
Mósè sọ pé: “Àpáta tí ó bí ọ ni ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàgbé, o sì bẹ̀rẹ̀ sí mú Ọlọ́run kúrò nínú ìrántí.” (Diu. 32:18) Kó pẹ́ tó fi di pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́kàn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àrà tí Jèhófà ṣe ní Òkun Pupa, àwọn ìpèsè rẹ̀ tí kò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà pa run sínú aginjù, àti gbogbo àwọn ohun rere yòókù tí Jèhófà ṣe. Wọ́n gbàgbé gbogbo èyí, wọ́n sì di ọlọ̀tẹ̀.
Nígbà kan, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fúngun mọ́ Mósè nítorí wọ́n ti rò pé kò sí báwọn ṣe lè rí omi mu. (Núm. 20:2-5) Wọ́n tún ń ráhùn lórí mánà tí wọ́n ń rí jẹ tí wọn ò fi kú, wọ́n ní: “Ọkàn wa . . . ti fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra oúnjẹ játijàti yìí.” (Núm. 21:5) Wọn ò fara mọ́ ìpinnu Ọlọ́run, wọ́n sì kọ Mósè ní aṣáájú, wọ́n ní: “Àwa ì bá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Íjíbítì, tàbí àwa ì bá kúkú ti kú ní aginjù yìí! . . . Ẹ jẹ́ kí a yan olórí sípò, kí a sì padà sí Íjíbítì!”—Núm. 14:2-4.
Báwo ni àìgbọràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rí lára Jèhófà? Nígbà tí onísáàmù kan ronú nípa gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ láyé ìgbà yẹn, ó ní: “Ẹ wo bí iye ìgbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù ti pọ̀ tó, wọn a máa mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́ ní aṣálẹ̀! Léraléra ni wọ́n sì ń dán Ọlọ́run wò, àní wọ́n ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì. Wọn kò rántí ọwọ́ rẹ̀, ní ọjọ́ tí ó tún wọn rà padà láti ọwọ́ elénìní, bí ó ṣe fi àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ sí Íjíbítì.” (Sm. 78:40-43) Ó dun Jèhófà gan-an bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbàgbé àwọn ohun tó ṣe.
Ọkùnrin Méjì Tí Kò Gbàgbé
Àmọ́ ṣá o, àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbàgbé Jèhófà. Jóṣúà àti Kálébù wà lára wọn. Wọ́n wà lára àwọn amí méjìlá tí Mósè rán láti Kadeṣi-báníà pé kí wọ́n lọ wo Ilẹ̀ Ìlérí wá. Mẹ́wàá lára wọn mú ìròyìn burúkú wá, àmọ́ Jóṣúà àti Kálébù sọ fáwọn èèyàn Ísírẹ́lì pé: “Ilẹ̀ náà tí a là kọjá láti ṣe amí rẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára gidigidi. Bí Jèhófà bá ní inú dídùn sí wa, dájúdájú, nígbà náà òun yóò mú wa wá sínú ilẹ̀ yìí, yóò sì fi í fún wa, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin. Kìkì kí ẹ má ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà.” Nígbà táwọn èèyàn náà gbọ́ ohun tí Jóṣúà àti Kálébù sọ, ńṣe ni wọ́n sọ pé àwọn á sọ wọ́n ní òkúta. Ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì ò mikàn, torí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.—Núm. 14:6-10.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Kálébù sọ fún Jóṣúà pé: “Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà rán mi jáde ní Kadeṣi-báníà láti ṣe amí ilẹ̀ náà, mo sì mú ọ̀rọ̀ padà wá fún un, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọkàn-àyà mi. Àwọn arákùnrin mi tí wọ́n gòkè lọ pẹ̀lú mi mú kí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn náà domi; ṣùgbọ́n ní tèmi, mo tọ Jèhófà Ọlọ́run mi lẹ́yìn ní kíkún.” (Jóṣ. 14:6-8) Torí pé Kálébù àti Jóṣúà gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, wọ́n fara da onírúurú ìnira. Wọ́n pinnu pé àwọn ò ní gbàgbé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé àwọn.
Kálébù àti Jóṣúà tún fẹ̀mí ìmoore hàn, wọ́n sọ ní gbangba pé Jèhófà mú ìlérí rẹ̀, láti mú àwọn èèyàn rẹ̀ wá sínú ilẹ̀ ọlọ́ràá, ṣẹ. Dájúdájú, ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò fi pa run. Jóṣúà sọ nínú ìwé rẹ̀ pé: “Jèhófà fún Ísírẹ́lì ní gbogbo ilẹ̀ tí ó búra láti fi fún àwọn baba ńlá wọn . . . Kò sí ìlérí kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí dáradára tí Jèhófà ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì; gbogbo rẹ̀ ni ó ṣẹ.” (Jóṣ. 21:43, 45) Báwo la ṣe lè lẹ́mìí ìmoore lóde òní, bíi ti Kálébù àti Jóṣúà?
Ẹ Jẹ́ Ká Máa Dúpẹ́
Nígbà kan, ọkùnrin kan tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run béèrè pé: “Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀?” (Sm. 116:12) Ọpẹ́ wa ò lópin lọ́dọ̀ Ọlọ́run o. Títí ayé la ó máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún bó ṣe ń bù kún wa nípa tara, tó ń darí wa nípa tẹ̀mí àti bó ṣe ṣí ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún wa. Àní sẹ́, a ò lè san oore Jèhófà tán. Síbẹ̀, gbogbo wa pátá ló lè máa ṣọpẹ́.
Ǹjẹ́ o ti gba ìtọ́ni Jèhófà kan rí, tó sì jẹ́ pé ìtọ́ni náà ni kò jẹ́ kó o kó sínú àwọn ìṣòro kan? Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run ṣe dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ọ́ ti jẹ́ kó o tún pa dà ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́? Àǹfààní àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe yìí máa ń wà títí lọ ni, bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe yẹ kó o máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ títí lọ. Ọmọbìnrin kan, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sandra ní àwọn ìṣòro ńlá kan, àmọ́ ìrànlọ́wọ́ Jèhófà mú kó borí wọn. Ọmọbìnrin yìí ní: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́, ọ̀nà tó sì gbà ràn mí lọ́wọ́ jọ mí lójú gan-an ni. Mo wá rídìí tí bàbá mi fi máa ń tẹnu mọ́ Òwe 3:5, 6 fún mi wàyí. Ó kà pé: ‘Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.’ Ó dá mi lójú pé, níwọ̀n bí Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ títí di báyìí, yóò máa ràn mí lọ́wọ́ nìṣó.”
Fi Hàn Pé O Rántí Jèhófà Nípa Lílo Ìfaradà
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ míì tó jẹ mọ́ rírántí Jèhófà, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.” (Ják. 1:4) Kí la máa ṣe táá fi hàn pé a ‘pé pérépéré, a sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà’? Ohun tá a máa ṣe ni pé ká ní àwọn ànímọ́ táá jẹ́ ká lè máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a bá wà nínú ìṣòro, táá sì jẹ́ ká lè pinnu pé a máa fara dà á títí dé òpin, láìbọ́hùn. Irú ìfaradà bẹ́ẹ̀ máa ń múnú ẹni dùn gan-an nígbà tí ìdánwò ìgbàgbọ́ náà bá wá sópin. Kò sì sí ìdànwó ìgbàgbọ́ tí kì í dópin.—1 Kọ́r. 10:13.
Ìránṣẹ́ Jèhófà kan tó ti ń sin Jèhófà bọ̀ tipẹ́tipẹ́, tó sì ní ọ̀pọ̀ àìlera tó le koko sọ ohun tó ń jẹ́ kó lè máa fara dà á nìṣó, ó ní: “Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni mo máa ń gbìyànjú láti fi sọ́kàn kì í ṣe ohun tí mo fẹ́. Láti lè pa ìwà títọ́ mi mọ́, mo ní láti gbájú mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run dípò ìfẹ́ ọkàn tèmi. Tí ìṣòro bá dé bá mi, n kì í sọ pé, ‘Jèhófà, báwo ni tèmi ṣe wá rí báyìí?’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni mò ń sin Ọlọ́run mi nìṣó, tí mo sì túbọ̀ ń sún mọ́ ọn, kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé òjijì ni ìṣòro dé.”
Lóde òní, àwa Kristẹni tòótọ́ ń jọ́sìn Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòh. 4:23, 24) Àwa Kristẹni tóòótọ́ lápapọ̀ kò ní gbàgbé Ọlọ́run bíi tàwọn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Àmọ́, pé èèyàn wà nínú ìjọ Kristẹni kò fi hàn pé òun fúnra rẹ̀ máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí dópin. Olúkúlùkù wa gbọ́dọ̀ máa fẹ̀mìí ìmoore àti ìfaradà bá iṣẹ́ Jèhófà nìṣó, bíi ti Kálébù àti Jóṣúà. Ó sì yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé Jèhófà kò ṣíwọ́ títọ́ tó ń tọ́ kálukú wa sọ́nà àti bó ṣe ń tọ́jú wa lákòókò òpin tó le koko yìí.
Bí àwọn òkúta ìrántí tí Jóṣúà tò kalẹ̀ ṣe jẹ́ ẹ̀rí, bẹ́ẹ̀ ni àkọsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà tí Ọlọ́run fi gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ náà ṣe mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run ò ní fi àwa èèyàn rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká nírú ẹ̀mí tí onísáàmù kan ní, tó fi sọ pé: “Èmi yóò rántí àwọn iṣẹ́ Jáà; nítorí ó dájú pé èmi yóò rántí ìṣe ìyanu rẹ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.”—Sm. 77:11, 12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Odindi orílẹ̀-èdè náà fẹsẹ̀ rìn la “ìyàngbẹ ilẹ̀” tó gbẹ táútáú kọjá
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Nígbà tí Ísírẹ́lì pabùdó sí Kadeṣi-báníà, Mósè rán amí lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú aginjù, ó yẹ kí wọ́n máa dúpẹ́ pé wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí tó jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Tá a bá gbájú mọ́ àwọn ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà, a ó lè fara da ìṣòro yòówù tá a bá ní