“Áńgẹ́lì Jèhófà Dó Yí Àwọn Tí ó Bẹ̀rù Rẹ̀ Ká”
Gẹ́gẹ́ bí Christabel Connell ṣe sọ ọ́
Àwọn ìbéèrè Christopher nípa Bíbélì tá à ń dáhùn ti gbà wá lọ́kàn débi tá ò fi mọ̀ pé ilẹ̀ ti ṣú gan-an, a ò sì mọ̀ pé Christopher ń gba ojú fèrèsé wo ìta. Nígbà tó wá yá, ó sọ fún wa pé: “Nísinsìnyí kò séwu mọ́, ẹ lè wá máa lọ.” Ló bá sìn wá lọ sídìí kẹ̀kẹ́ wa, ó sì dágbére fún wa pé ó dàárọ̀ o. Kí ló rí tẹ́lẹ̀ tó mú kó wá sọ pé kò séwu mọ́?
ORÚKỌ mi ni Christabel Earl, ìyẹn kí n tó lọ́kọ, ọdún 1927 ni wọ́n bí mi nílùú Sheffield, nílẹ̀ England. Ilé ẹ̀kọ́ ni mo wà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Nígbà tí wọ́n wá ju bọ́ǹbù sí ilé wa, wọ́n ní kí n lọ máa gbé lọ́dọ̀ ìyá ìyá mi títí màá fi jáde ilé ìwé. Àwọn onísìn Kátólíìkì ló ni ilé ẹ̀kọ́ tí mo lọ. Nílé ẹ̀kọ́ yìí, mo máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé tó wà níbẹ̀ pé kí ló fà á tí ìwà ibi àti ìwà ipá fi pọ̀ tó báyìí. Wọn ò fún mi ní ìdáhùn tó tẹ́ mi lọ́run, àwọn onísìn mìíràn tí mo sì bi ní ìbéèrè yìí náà ò lè dáhùn rẹ̀.
Lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, mo lọ kọ́ iṣẹ́ nọ́ọ̀sì. Mo sì lọ sí ìlú London láti lọ ṣiṣẹ́ ní ilé ìwòsàn kan tí wọ́n ń pè ní Paddington General Hospital, àmọ́ ìwà ipá tí mo rí nínú ìlú náà pọ̀ ju èyí tí mo ti rí tẹ́lẹ̀ lọ. Kété lẹ́yìn tí bọ̀ọ̀dá mi lọ sí Ogun Kòríà, mo rí àwọn kan tó wọ̀yá ìjà níwájú ilé ìwòsàn yẹn gan-an. Kò sì sẹ́ni tó là wọ́n títí tí wọ́n fi lu ara wọn débi tójú ọ̀kan lára wọn fi fọ́. Ní àkókò yẹn, èmi àti màmá mi tiẹ̀ lọ sí ìpàdé àwọn abókùúsọ̀rọ̀, síbẹ̀ náà, mi ò mọ ìdí tí ìwà ibi fi pọ̀ láyé.
Wọ́n Gbà Mí Níyànjú Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Lọ́jọ́ kan, John, bọ̀ọ̀dá mi àgbà tó ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà dé. Ó bi mí pé: “Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí gbogbo ohun búburú wọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀?” Mo dáhùn pé, “Rárá o.” Ló bá ṣí Bíbélì rẹ̀, ó ka Ìṣípayá 12:7-12. Mo wá rí i pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ló ṣokùnfà gbogbo ibi tó wà láyé. John gbà mí nímọ̀ràn pé kí n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ sígbà náà tí mo gbà pé kẹ́nì kan máa kọ́ mi. Àmọ́ nígbà yẹn, ìbẹ̀rù èèyàn ò jẹ́ kí n lè ṣèrìbọmi.—Òwe 29:25.
Àǹtí mi tó ń jẹ́ Dorothy náà ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Nígbà tóun àti àfẹ́sọ́nà rẹ̀ tó ń jẹ́ Bill Roberts pa dà dé láti àpéjọ àgbáyé tí wọ́n ṣe nílùú New York nílẹ̀ Amẹ́ríkà lọ́dún 1953, mo sọ fún wọn pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Bill bi mí pé: “Ǹjẹ́ o ka gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n yàn sínú ìwé tó o fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́? Ǹjẹ́ o fa ìlà sídìí àwọn ìdáhùn inú ìwé náà?” Nígbà tí mo ní rárá, ó sọ pé: “O ò tíì kẹ́kọ̀ọ́ kankan nìyẹn! Pa dà wá arábìnrin yẹn lọ, kó o tún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀!” Lákòókò yẹn, àwọn ẹ̀mí èṣù bẹ̀rẹ̀ sí í dà mí láàmú. Mo rántí pé mo bẹ Jèhófà pé kó dáàbò bò mí, kó sì gbà mí lọ́wọ́ wọn.
Mo Ṣe Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Nílẹ̀ Scotland àti Ireland
Mo ṣèrìbọmi ní January 16, ọdún 1954, iṣẹ́ nọ́ọ̀sì tí mò ń ṣe ní ilé ìwòsàn yẹn sì parí ní oṣù May. Mo wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní oṣù June. Ní oṣù mẹ́jọ lẹ́yìn náà, wọ́n rán mi lọ sí ìlú Grangemouth, nílẹ̀ Scotland, láti lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Níbẹ̀, mo rí i pé àwọn áńgẹ́lì Jèhófà ‘dó yí mi ká’ bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ ní àdádó tí wọ́n yàn mí sí.—Sm. 34:7.
Lọ́dún 1956, wọ́n gbé mi lọ sí ilẹ̀ Ireland. Wọ́n yan èmi àtàwọn arábìnrin méjì míì sí ìlú Galway. Lọ́jọ́ àkọ́kọ́, mo wàásù nílé àlùfáà Kátólíìkì kan. Láìpẹ́ ọlọ́pàá kan dé, ó sì mú èmi àti èkejì mi lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Ó gba orúkọ wa àti àdírẹ́sì wa, ó sì lọ sídìí tẹlifóònù lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àfìgbà tá a gbọ́ tó ń sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Fadá, mo mọ ibi tí wọ́n ń gbé gan-an.” Àṣé àlùfáà yẹn ló ní kó wá mú wa! Wọ́n fúngun mọ́ onílé wa pé kó lé wa jáde, nítorí náà ẹ̀ka ọ́fíìsì wa sọ pé ká kúrò ní àgbègbè náà. A fi ìṣẹ́jú mẹ́wàá pẹ́ dé ibùdókọ̀ ojú irin. Àmọ́, a ṣì bá ọkọ̀ ojú irin náà níbẹ̀, ọkùnrin kan sì dúró síbẹ̀ kó lè rí i dájú pé a wọnú ọkọ̀ náà. Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré la tíì lò nílùú Galway tí gbogbo èyí fi ṣẹlẹ̀ o!
Wọ́n ní ká lọ sí ìlú Limerick, tó jẹ́ ìlú míì tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti rinlẹ̀ gan-an. Gbogbo ìgbà làwọn jàǹdùkú èèyàn máa ń hó lé wa lórí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bẹ̀rù, wọn kì í jẹ́ ká wàásù nílé àwọn. Lọ́dún kan ṣáájú ìgbà yẹn, wọ́n lu arákùnrin kan lálùbolẹ̀ ní ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Cloonlara tó wà nítòsí ibẹ̀. Nítorí náà, inú wa dùn nígbà tá a bá Christopher pàdé, ìyẹn ẹni tí mo mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi. Ó ní ká pa dà wá dáhùn àwọn ìbéèrè tóun ní nínú Bíbélì. Nígbà tá a lọ sọ́dọ̀ Christopher, àlùfáà kan wọlé wá bá a, ó ní kó sọ fún wa pé ká máa lọ. Ó fún àlùfáà náà lésì pé: “Èmi ni mo pe àwọn obìnrin wọ̀nyí wá sínú ilé mi, wọ́n sì kan ilẹ̀kùn kí wọ́n tó wọlé. Àmọ́ mi ò pè ọ́, o ò sì kan ilẹ̀kùn kó o tó wọlé.” Ni àlùfáà náà bá bínú lọ.
A ò mọ̀ pé àlùfáà náà ti kó ọ̀pọ̀ géńdé ọkùnrin jọ pé kí wọ́n dúró dè wá níta ilé Christopher. Àmọ́ Christopher ti mọ̀ pé ńṣe ni wọ́n dènà dè wá, ló bá dọ́gbọ́n dá wa dúró gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣàlàyé níbẹ̀rẹ̀. Ó dá wa dúró títí gbogbo wọn fi tú ká. A wá gbọ́ nígbà tó yá pé kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà náà ni wọ́n lé Christopher àti ìdílé rẹ̀ kúrò ní àgbègbè yẹn, wọ́n sì kó lọ sí ilẹ̀ England.
Wọ́n Pè Mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
Mo ń múra láti lọ sí Àpéjọ Àgbáyé Ìfẹ́ Àtọ̀runwá lọ́dún 1958 ní ìlú New York nígbà tí wọ́n pè mí pé kí n wá sí Kíláàsì Kẹtàlélọ́gbọ̀n ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Kàkà kí n pa dà sílé lẹ́yìn àpéjọ náà, ńṣe ni mo lọ sìn ní ìlú Collingwood, ní ìpínlẹ̀ Ontario, nílẹ̀ Kánádà títí dìgbà tí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì á fi bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1959. Ṣùgbọ́n nígbà àpéjọ náà mo pàdé Arákùnrin Eric Connell. Ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́dún 1957, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú-ọ̀nà lọ́dún 1958. Lẹ́yìn àpéjọ náà, ojoojúmọ́ ló ń kọ̀wé sí mi ní gbogbo ìgbà tí mo fi wà ní Kánádà àti gbogbo ìgbà tí mo fi wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Mo máa ń ro ibi tọ́rọ̀ wa yìí máa já sí lẹ́yìn tí mo bá kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì.
Ohun mánigbàgbé kan ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì tí mo lọ jẹ́ nígbèésí ayé mi. Ìgbà kan náà ni èmi àti àǹtí mi Dorothy àti ọkọ rẹ̀ jọ lọ. Orílẹ̀-èdè Potogí ni wọ́n sì ní kí wọ́n ti lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi nígbà tí wọ́n yan èmi pa dà sí ilẹ̀ Ireland. Ó mà dùn mí gan-an o, pé wọn ò rán èmi àti àǹtí mi lọ síbì kan náà! Mo béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wa pé ṣé mo ṣe ohun kan tí kò dáa ni. Ó dáhùn pé, “Rárá o. Ìwọ àti Eileen Mahoney ṣáà ti gbà láti lọ sí ibikíbi tá a bá yàn yín sí láyé yìí,” èmi náà sì mọ̀ pé inú ayé yìí ni ilẹ̀ Ireland wà.
Mo Pa Dà sí Ilẹ̀ Ireland
Mo pa dà sí ilẹ̀ Ireland ní August, ọdún 1959, wọ́n sì ní kí n lọ sí ìjọ Dun Laoghaire. Láàárín àkókò yẹn Eric ti pa dà sí ilẹ̀ England, inú rẹ̀ sì dùn pé mo ti wà ní tòsí òun. Òun náà fẹ́ di míṣọ́nnárì. Ó rò ó pé níwọ̀n bí ilẹ̀ Ireland ti wà lára ibi tí wọ́n máa ń rán àwọn míṣọ́nnárì lọ nígbà yẹn, òun náà á lọ máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà níbẹ̀. Ó ṣí wá sí ìlú Dun Laoghaire, a sì ṣègbéyàwó lọ́dún 1961.
Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, Eric ọkọ mi ṣubú lórí alùpùpù, ó sì fara pa yánnayànna. Eegun agbárí rẹ̀ là, àwọn dókítà tó ń du ẹ̀mí rẹ̀ ò sì mọ̀ bóyá yóò yè é. Lẹ́yìn tó ti lo ọ̀sẹ̀ mẹ́ta nílé ìwòsàn, mo tọ́jú rẹ̀ nílé fún oṣù márùn-ún títí tí ara rẹ̀ fi yá. Síbẹ̀ mo rí i dájú pé mò ń sa gbogbo ipá mi nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
Lọ́dún 1965, wọ́n ní ká lọ sí ìjọ kan nílùú Sligo tó jẹ́ èbúté kan lápá ìwọ̀ oòrùn àríwá ilẹ̀ Ireland. Akéde mẹ́jọ ló wà nínú ìjọ náà. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, a lọ sí ìjọ kékeré míì nílùú Londonderry, tó wà lápá òkè àríwá lọ́hùn-ún. Lọ́jọ́ kan, a ń pa dà bọ̀ láti òde ẹ̀rí, la bá rí i pé wọ́n ti ta wáyà ẹlẹ́gùn-ún dí ojú ọ̀nà tó lọ sí ilé wa. Rògbòdìyàn àríwá ilẹ̀ Ireland ti bẹ́ sílẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ ń da ìlú rú, wọ́n ń sun àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Bí ìlú náà ṣe pín sí méjì nìyẹn, tí àgbègbè kan di tàwọn onísìn Kátólíìkì, àgbègbè kejì sì di tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì míì. Ó léwu gan-an láti kọjá láti àgbègbè kan sí àgbègbè kejì nínú ìlú náà.
Bí Ìgbésí Ayé Wa àti Iṣẹ́ Ìwàásù Wa Ṣe Rí Lákòókò Rògbòdìyàn
Síbẹ̀, ńṣe ni iṣẹ́ ìwàásù ń gbé wa káàkiri ilẹ̀ náà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ̀rí tún fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì yí wa ká. Nígbà tá a bá bá ara wa níbi tí rògbòdìyàn ti bẹ́ sílẹ̀, a máa ń tètè fibẹ̀ sílẹ̀, àmọ́ àá tún pa dà síbẹ̀ nígbà tí nǹkan bá rọlẹ̀. Nígbà kan tí wọ́n ń fa rògbòdìyàn nítòsí ilé wa, àwọn àjókù nǹkan láti ṣọ́ọ̀bù ọ̀dá tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé wa já bọ́ sójú fèrèsé wa. A ò lè sùn nítorí a ń bẹ̀rù pé ilé wa lè gbiná. Lẹ́yìn tá a kó lọ sílùú Belfast lọ́dún 1970, a gbọ́ pé bọ́ǹbù tí wọ́n fi epo pẹtiróòlù ṣe bú gbàù ní ṣọ́ọ̀bù ọ̀dà tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé tá à ń gbé tẹ́lẹ̀ yẹn, ó sì jó ṣọ́ọ̀bù yẹn àti ilé wa yẹn kanlẹ̀.
Ìgbà kan tún wà témi àti arábìnrin kan wà lóde ìwàásù, tá a rí páìpù kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lójú fèrèsé ilé kan, bẹ́ẹ̀ là ń bá tiwa lọ. Kò pẹ́ rárá tá a kọjá ibẹ̀ ni páìpù náà bú gbàù. Àwọn ará àdúgbò yẹn tí wọ́n jáde wá rò pé àwa la gbé bọ́ǹbù yẹn síbẹ̀! Ìgbà yẹn gan-an ni arábìnrin kan tó ń gbé ládùúgbò náà pè wá wọlé rẹ̀. Ìyẹn sì jẹ́ káwọn aládùúgbò rẹ̀ gbà pé àwa kọ́ la ṣe iṣẹ́ ibi náà.
Lọ́dún 1971, a lọ sọ́dọ̀ arábìnrin kan nílùú Londonderry tá a wà tẹ́lẹ̀. Nígbà tá a ṣàlàyé bí ojú ọ̀nà tá a gbà ṣe rí àti ibi tí wọ́n ti gbé nǹkan dábùú ọ̀nà tá a gbà kọjá, ló bá béèrè lọ́wọ́ wa pé, “Ṣé kò séèyàn ńbẹ̀ ni?” Ó yà á lẹ́nu gan-an nígbà tá a sọ pé, “Wọ́n wà ńbẹ̀, àmọ́ wọ́n kàn ń wò wá ni.” Kí ló dé tó fi béèrè ìbéèrè yìí? Ìdí ni pé ṣáájú ọjọ́ yẹn, àwọn jàǹdùkú èèyàn kan ti fipá gba ọkọ̀ lọ́wọ́ dókítà kan àti lọ́wọ́ ọlọ́pàá kan tí wọ́n sì dáná sun àwọn ọkọ̀ náà.
A kó lọ sílùú Cork lọ́dún 1972. Nígbà tó yá, a lọ sìn nílùú Naas, lẹ́yìn náà a tún lọ sìn nílùú Arklow. Níkẹyìn, wọ́n ní ka lọ sílùú Castlebar lọ́dún 1987, ibẹ̀ la sì wà títí dòní. Ibí yìí la ti ní àǹfààní ńlá láti lọ́wọ́ nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Àìsàn ńlá kan ṣe ọkọ mi lọ́dún 1999. Síbẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà àti ìtìlẹ́yìn ìjọ, mo forí tì í, mo sì tọ́jú rẹ̀ títí tára rẹ̀ fi yá.
Èmi àti ọkọ mi Eric ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà lẹ́ẹ̀mejì. Alàgbà ìjọ ni títí di báyìí. Àrùn oríkèé-ara-ríro ń yọ mí lẹ́nu, wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ abẹ fún mi ní ìgbáròkó àti orúnkún mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fojú winá àtakò ẹ̀sìn, mo ti fara da wàhálà tí ọ̀rọ̀ òṣèlú àti rògbòdìyàn láàárín ìlú dá sílẹ̀, àmọ́ ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tó ká mi lára jù ni pé ó di dandan fún mi pé kí n má wakọ̀ mọ́. Ìṣòro nìyẹn jẹ́ fún mi, torí pé mi ò lè lọ síbi tó bá wù mí mọ́. Àwọn ará ìjọ ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni, wọn ò fi mí sílẹ̀. Ọ̀pá ni mo fi ń rìn kiri báyìí, tí mo bá sì fẹ́ lọ síbi tó nasẹ̀ díẹ̀, kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta tó ń lo bátìrì ni mò ń gùn lọ.
Ó tó ọgọ́rùn-ún ọdún lápapọ̀ tí èmi àti ọkọ mi ti fi ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, méjìdínlọ́gọ́rùn-ún lára rẹ̀ la sì lò ní ilẹ̀ Ireland níbí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara wa ti ń dara àgbà, a ò ní in lọ́kàn pé ká dá iṣẹ́ ìsìn wa dúró. A ò retí pé kí iṣẹ́ ìyanu ṣẹlẹ̀ sí wa o, àmọ́ a nígbàgbọ́ pé àwọn áńgẹ́lì alágbára látọ̀dọ̀ Jèhófà ‘dó yí ká’ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ tí wọ́n sì ń fòtítọ́ sìn ín.