Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ṣégbà kankan wà tí wọ́n fi òpó igi olórí ṣóńṣó yí Jerúsálẹ́mù ká, bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀?
Nígbà tí Jésù ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù, ó sọ pé: “Àwọn ọjọ́ yóò dé bá ọ, nígbà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ ká, wọn yóò sì ká ọ mọ́, wọn yóò sì wàhálà rẹ láti ìhà gbogbo.” (Lúùkù 19:43) Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni nígbà tí ọ̀gágun Titus pàṣẹ fáwọn ọmọ ogun Róòmù pé kí wọ́n mọ odi yí Jerúsálẹ́mù ká. Nǹkan mẹ́ta ni Titus ní lọ́kàn tó fi pàṣẹ pé káwọn ọmọ ogun ẹ̀ mọ odi yí Jerúsálẹ́mù ká, àkọ́kọ́ ni pé káwọn Júù má bàa lè sá lọ, ìkejì ni pé kí wọ́n lè juwọ́ sílẹ̀, ìdí kẹta sì ni pé kó lè febi pa wọ́n títí tá á fi ṣẹ́gun wọn.
Òpìtàn kan ní ọ̀rúndún kìíní tó ń jẹ́ Flavius Josephus sọ pé gbàrà tí wọ́n ti pinnu láti kọ́ odi náà ni wọ́n ti pín àwọn ọmọ ogun ìlú Róòmù sí àwùjọ ńláńlá àti kéékèèké tí wọ́n sì yan apá ibi tí wọ́n ti máa ṣiṣẹ́ fún wọn, àwọn ọmọ ogun yìí máa ń bára wọn díje lẹ́nu iṣẹ́ náà kí wọ́n lè mọ ẹni tó máa kọ́kọ́ parí apá ibi tí wọ́n yàn fún un. Gbogbo àwọn igi tó wà ní nǹkan bí kìlómítà mẹ́rìndínlógún [16] yípo ìlú náà làwọn ọmọ ogun yìí gé tí wọ́n sì fi ṣe odi tó gùn tó kìlómítà méje yí ìlú náà po, ìyẹn ò sì gbà wọ́n ju ọjọ́ mẹ́ta péré lọ! Torí itú táwọn ọmọ ogun yìí ti pa, òpìtàn Josephus sọ pé: “Kò síbì táwọn Júù lè sá gbà tọ́wọ́ ò ní tẹ̀ wọ́n.” Ní nǹkan bí oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ogun Róòmù ṣẹ́gun ìlú náà torí àwọn ará Jerúsálẹ́mù ò rí oúnjẹ jẹ mọ́, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í para wọn.
Ṣé Lóòótọ́ ni Hesekáyà Ọba ṣe ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tó wọ Jerúsálẹ́mù?
Hesekáyà ló ń jọba nígbà tí ilẹ̀ Júdà ń gbóná janjan torí ọ̀tá tó wà láàárín wọn àti ìjọba Ásíríà alágbára, ìyẹn sì jẹ́ nígbà tí ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni ń parí lọ. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Hesekáyà sapá gan-an láti dàábò bo Jerúsálẹ́mù, kó sì rí i dájú pé àwọn aráàlú ń rí omi lò nígbà ogun. Lára àwọn iṣẹ́ tó ṣe ni gbígbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tó gùn tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán-lé-mọ́kàndínláàádọ́ta [1,749] ẹsẹ bàtà kí omi odò lè máa ṣàn wọnú ìlú náà.—2 Àwọn Ọba 20:20; 2 Kíróníkà 32:1-7, 30.
Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún [19], àwọn awalẹ̀pìtàn rí ọ̀nà abẹ́lẹ̀ kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ èyí tí Hesekáyà gbẹ́. Wọ́n sì wá ń pe ọ̀nà yìí ní Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ Hesekáyà tàbí Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ Sílóámù. Wọ́n rí ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n kọ sára ògiri ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà tó sọ nípa àwọn nǹkan tí wọ́n hú jáde nígbà tí iṣẹ́ gbígbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà ń parí lọ. Ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ àwọn ọ̀rọ̀ sára ògiri ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà jẹ́ káwọn ọ̀mọ̀wé mọ̀ pé ìgbà ayé Hesekáyà ni wọ́n ti kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́, lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn àwọn awalẹ̀pìtàn kan ronú pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti gbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ yìí ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún ṣáájú ìgbà ayé Hesekáyà. Lọ́dún 2003, àgbájọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì kan gbé àbájáde ìwádìí wọn jáde láti fi sọ déètì pàtó tí wọ́n gbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà. Kí ni àbájáde ìwádìí wọn?
Dókítà Amos Frumkin tó wà ní Hebrew University of Jerusalem sọ pé: “Àyẹ̀wò kan tá a pè ní carbon-14 tá a ṣe lórí ọ̀kan lára èròjà tó wà lára nǹkan tí wọ́n fi rẹ́ Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ Sílóámù àti àyẹ̀wò tá a ṣe lórí àwọn òkúta kan tó kóra jọ tá a rí nínú ọ̀nà náà jẹ́ kó dájú pé ìgbà ayé Hesekáyà ni wọ́n ti gbẹ́ ọ̀nà ọ̀hún.” Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Nature fi kún un pé: “Àwọn ẹ̀rí mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn àyẹ̀wò fínnífínní lórí àwọn èròjà tó wà lára nǹkan tí wọ́n fi rẹ́ ògiri ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà, bí wọ́n ṣe kọ̀wé sára ògiri ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà àtàwọn ìtàn tó ti wà lákọọ́lẹ̀, gbogbo ẹ̀ jẹ́rìí sí i pé nǹkan bí ọdún 700 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ti gbẹ́ ọ̀nà náà, èyí sì tipa báyìí sọ Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ Sílóámù di èyí tó dájú jù lọ lára iṣẹ́ gbígbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀.”