Ọ̀nà Àwọn Ará Róòmù Ohun Tó Ń ránni Létí Iṣẹ́ Àwọn Onímọ̀ Ẹ̀rọ Ayé Àtijọ́
LÓJÚ tìrẹ, èwo ló ṣe pàtàkì jù nínú àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé àwọn ará Róòmù? Ṣé Gbọ̀ngàn Ìwòran tí àwókù rẹ̀ ṣì wà nílùú Róòmù títí dòní ni? Tá a bá ní ká wò ó, nínú gbogbo ohun táwọn ará Róòmù ṣe tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ tí ìtàn sì fi hàn pé ó nípa lórí ohun táwọn èèyàn ṣe jù, àwọn ojú ọ̀nà wọn ni.
Kì í ṣe àwọn ọmọ ogun nìkan ló ń gba ojú ọ̀nà àwọn ará Róòmù, kì í sì í ṣe ẹrù nìkan làwọn èèyàn ń kó gba ibẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Romolo A. Staccioli tó jẹ́ onímọ̀ nípa ọ̀nà ìgbàkọ̀wé àwọn ará ìgbàanì sọ pé àwọn tó máa ń gba àwọn ọ̀nà náà kọjá “máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa ohun tó ń lọ láwọn ibòmíì, nípa àwọn iṣẹ́ ọ̀nà tuntun, nípa èrò àwọn ọ̀mọ̀ràn àti nípa ẹ̀kọ́ àwọn ìsìn míì,” títí kan ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni.
Ohun àmúyangàn ni wọ́n ka àwọn ọ̀nà àwọn ará Róòmù sí láyé àtijọ́. Bí ọdún sì ṣe ń gorí ọdún, àwọn ará Róòmù ṣe ọ̀nà wọn káàkiri ilẹ̀ tó wá di ibi tí ọgbọ́n orílẹ̀-èdè wà lóde òní. Tá a bá wọn gbogbo ọ̀nà tí wọ́n ṣe lápapọ̀, yóò tó ọ̀kẹ́ mẹ́rin [80,000] kìlómítà.
Ọ̀nà pàtàkì tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe tá a lè pè ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ lóde òní ní Ọ̀nà Ápíà (ìyẹn Via Appia). Ọ̀nà yìí ni wọ́n gbà pé ó jẹ́ ọba ọ̀nà, òun ni wọ́n sì máa ń gbà láti ìlú Róòmù lọ sí ìlú Brundisium (tí wọ́n ń pè ní Brindisi báyìí), tó jẹ́ èbúté táwọn èèyàn ti ń wọkọ̀ lọ sí apá Ìlà Oòrùn ayé. Orúkọ aláṣẹ kan tó jẹ́ ará Róòmù, ìyẹn Appius Claudius Caecus, ni wọ́n fi sọ ojú ọ̀nà yìí. Òun ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 312 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Wọ́n tún ṣe ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní Via Salaria àtèyí tó ń jẹ́ Via Flaminia láti ìlú Róòmù lọ sí etí Òkun Adriatic lápá ìlà oòrùn. Ọ̀nà méjèèjì yìí sì dé àgbègbè Balkan, odò Rhine àti odò Danube pẹ̀lú. Ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní Via Aurelia bẹ̀rẹ̀ láti ìlú Róòmù lọ sí ilẹ̀ àwọn Gọ́ọ̀lù lápá àríwá ó sì dé ilẹ̀ Iberia pẹ̀lú, nígbà tí ọ̀nà tó ń jẹ́ Via Ostiensis lọ sí ìlú Ostia tó jẹ́ èbúté táwọn ará Róòmù sábà máa ń fẹ́ gbà tí wọ́n bá ń lọ sílẹ̀ Áfíríkà tàbí tí wọ́n bá ń bọ̀.
Àgbà Iṣẹ́ Táwọn Ará Róòmù Ṣe
Ipa kékeré kọ́ ni ojú ọ̀nà kó nínú ìdàgbàsókè ìlú Róòmù, àní ṣáájú káwọn èèyàn wọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ojú ọ̀nà tuntun pàápàá. Oríta kan táwọn ọ̀nà forí sọ láyé àtijọ́ ni ìlú Róòmù ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀. Ibẹ̀ nìkan ṣoṣo ni Odò Tiber ti ṣeé fẹsẹ̀ sọdá lápá ìsàlẹ̀. Àwọn ìwé ìtàn ayé àtijọ́ kan sọ pé ọ̀dọ̀ àwọn ará Kátééjì làwọn ará Róòmù ti kọ́ ọgbọ́n tí wọ́n fi ń tún àwọn ọ̀nà tí wọ́n bá rí ṣe. Ṣùgbọ́n ó jọ pé àwọn ará Etruria gan-an ló ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ọ̀nà ṣíṣe kí àwọn ará Róòmù tó bẹ̀rẹ̀. Èyí tó bà jẹ́ kù lára ọ̀nà àwọn ará Etruria ṣì wà títí dòní. Àwọn ipa ọ̀nà táwọn èèyàn máa ń gbà dáadáa ti wà kó tó dìgbà ayé àwọn ará Róòmù. Ó ṣeé ṣe káwọn tó ń daran máa gba ọ̀nà wọ̀nyẹn bí wọ́n ṣe ń kó ẹran ọ̀sìn wọn jẹ̀ láti ibì kan síbòmíràn. Àmọ́ ipa ọ̀nà wọ̀nyẹn ò fi bẹ́ẹ̀ dáa nítorí pé eruku ibẹ̀ máa ń pọ̀ gan-an nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ẹrẹ̀ sì máa ń wà níbẹ̀ nígbà òjò. Irú àwọn ipa ọ̀nà bẹ́ẹ̀ làwọn ará Róòmù sábà máa ń ṣe ọ̀nà tuntun sí.
Ńṣe làwọn ará Róòmù máa ń fara balẹ̀ ṣe ọ̀nà wọn kó lè lágbára, kó wúlò dáadáa, kó sì dùn ún wò. Wọ́n máa ń fẹ́ gbé ọ̀nà wọn gba ibi tó yá jù síbi tí wọ́n fẹ́ kí ọ̀nà yẹn dé. Ìdí nìyẹn tí ọ̀nà wọn fi sábà máa ń rí gbọnrangandan. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ojú ilẹ̀ ibi tí wọ́n fẹ́ gbé ọ̀nà gbà ló máa ń pinnu bí ọ̀nà náà á ṣe rí. Níbi tó bá jẹ́ òkè, àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ilẹ̀ Róòmù máa ń ṣe ọ̀nà wọn dé agbedeméjì òkè náà tó bá ṣeé ṣe fún wọn, wọ́n á wá gbé ọ̀nà náà gba ẹ̀gbẹ́ òkè náà, lápá ibi tí oòrùn máa ń tá sí. Èyí máa ń dín ìṣòro kù fáwọn tó bá gba ọ̀nà náà lásìkò tójú ọjọ́ ò bá fi bẹ́ẹ̀ dáa.
Àmọ́ báwo làwọn ará Róòmù tiẹ̀ ṣe ń ṣe ọ̀nà wọn? Ọ̀nà kan ṣoṣo kọ́ ni wọ́n ń gbà ṣe é, ṣùgbọ́n ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí rèé.
Wọ́n máa ń kọ́kọ́ wọn gbogbo ibi tí ọ̀nà yẹn máa gbà. Àwọn wọnlẹ̀-wọnlẹ̀ ayé ìgbà yẹn ló máa ń ṣe ìyẹn. Lẹ́yìn náà yóò wá kan iṣẹ́ ilẹ̀ gbígbẹ́ tó jẹ́ iṣẹ́ agbára. Àwọn ọmọ ogun, àwọn lébìrà tàbí àwọn ẹrú ló sábà máa ń ṣe èyí. Wọn yóò gbẹ́ kòtò gbọọrọ sí ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ibi tí wọ́n fẹ́ kí ọ̀nà náà wà. Àyè tó máa wà láàárín kòtò méjèèjì kì í dín sí nǹkan bí mítà méjì àbọ̀, àmọ́ mítà mẹ́rin ni ọ̀pọ̀ jù lọ rẹ̀ sábà máa ń jẹ́, ó sì lè fẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ níbi tó bá bọ́ sí kọ́nà. Tí wọ́n bá parí ọ̀nà kan tòun ti ọ̀nà táwọn ẹlẹ́sẹ̀ lè máa gbà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì, ó lè fẹ̀ tó mítà mẹ́wàá. Lẹ́yìn tí wọ́n bá gbẹ́ kòtò méjèèjì náà tán, wọn á wá wú ilẹ̀ tó wà láàárín àwọn kòtò náà jáde, kí gbogbo rẹ̀ lè pa pọ̀ di kòtò kan tó lọ gbọnrangandan. Tí wọ́n bá ti gbẹ́ ilẹ̀ ọ̀nà náà kan ibi tó le dáadáa, wọ́n á wá da oríṣi nǹkan mẹ́ta tàbí mẹ́rin lé e ní ìpele-ìpele. Wọ́n lè kọ́kọ́ da òkúta ńláńlá tàbí àfọ́kù òkúta sí i. Lẹ́yìn náà, wọ́n á da òkúta kéékèèké tàbí òkúta pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ sí i, wọ́n tiẹ̀ tún lè da kọnkéré sí i kó lè ṣù mọ́ra. Wọ́n á wá da òkúta wẹ́wẹ́ lé e lórí.
Òkúta wẹ́wẹ́ yìí ló máa ń wà lókè àwọn ọ̀nà kan táwọn ará Róòmù ṣe. Síbẹ̀, ọ̀nà tí wọ́n fi òkúta tẹ́ yìí gbayì gan-an lójú àwọn ará ìgbàanì. Àwọn òkúta fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀-fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ tí wọ́n bá rí láyìíká ni wọ́n sábà máa ń tò lé irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ lórí. Wọn yóò tò ó lọ́nà tí ọ̀nà yẹn á fi dagun díẹ̀ sí apá méjèèjì, kí omi òjò tó bá rọ̀ lè máa ṣàn sínú gọ́tà ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà náà. Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe àwọn ojú ọ̀nà wọn yìí ló jẹ́ kí wọ́n máa rí wọn lò pẹ́, débi pé òmíràn lára wọn ṣì wà títí dòní.
Àní lẹ́yìn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] ọdún tí wọ́n ṣe Ọ̀nà Ápíà, òpìtàn tó ń jẹ́ Procopius, ọmọ ìlú Bìsáńṣíọ̀mù, ṣì pè é ní “ọba ọ̀nà.” Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn òkúta fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ tó wà lójú ọ̀nà náà, ó ní: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òkúta wọ̀nyẹn ti wà látayébáyé, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ ẹṣin sì ń gba orí wọn kọjá lójoojúmọ́, bí wọ́n ṣe wà ni wọ́n ṣì ṣe wà. Ńṣe lojú wọn ń dán bíi tìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe àwọn ọ̀nà yẹn.”
Báwo ni wọ́n ṣe ń rí ojú ọ̀nà ṣe láwọn ibi tó ṣòro, irú bí ojú odò? Afárá ni wọ́n máa ń ṣe sírú ibẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn afárá náà ṣì wà tìtì dòní, èyí tó fi hàn pé orí àwọn ará Róòmù ìgbàanì pé gan-an tó bá dọ̀rọ̀ ọ̀nà ṣíṣe. Ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn má fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ wọ́n mọ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ṣíṣe, àmọ́ iṣẹ́ kékeré kọ́ ni wọ́n ṣe nídìí ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tá a bá wo bí òye wọn ṣe mọ àti irú irin iṣẹ́ tí wọ́n ń lò láyé ìgbà náà. Ìwé kan sọ pé: “Fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, kò sí iṣẹ́ àwọn tó dára tó iṣẹ́ táwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ilẹ̀ Róòmù ṣe.” Àpẹẹrẹ kan ni ti ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí wọ́n ṣe síbi àfonífojì Furlo lójú ọ̀nà tó ń jẹ́ Via Flaminia. Nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ọ̀nà yẹn nígbà yẹn lọ́hùn-ún lọ́dún 78 Sànmánì Kristẹni, àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ kọ́kọ́ fara balẹ̀ ṣe ètò bí wọ́n ṣe máa la ọ̀nà náà, wọ́n wá gbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ogójì mítà, tó fẹ̀ tó mítà márùn-ún tó sì ga tó mítà márùn-ún la inú apata kan kọjá. Iṣẹ́ ńlá gbáà nìyẹn tá a bá wo irú irin iṣẹ́ tí wọ́n ń lò láyé ìgbà náà. Ọ̀kan lára àwọn àgbà iṣẹ́ tọ́mọ èèyàn gbé ṣe nirú ojú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ jẹ́.
Ipa Táwọn Arìnrìn-Àjò Ń Kó Nínú Títan Èrò Àwọn Èèyàn Kálẹ̀
Àtàwọn ọmọ ogun àtàwọn oníṣòwò, àtàwọn oníwàásù àtàwọn arìnrìn-àjò afẹ́, àtàwọn òṣèré àtàwọn tó ń ja ìjà àjàkú akátá ní gbọ̀ngàn ìwòran, gbogbo wọn ló ń gba ọ̀nà wọ̀nyẹn. Àwọn tó ń fẹsẹ̀ rìn máa ń rìn tó kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ọgbọ̀n lójúmọ́. Àwọn òpó ibùsọ̀ wà láwọn ojú ọ̀nà yìí, àwọn tó ń rìnrìn àjò sì lè fìyẹn mọ bí àwọn ṣe rìn jìnnà tó tàbí bí ibi tí wọ́n ń lọ ṣe jìnnà sí wọn tó. Onírúurú òpó ibùsọ̀ ló wà nígbà yẹn àmọ́ òbírípo ni ìrísí wọn sábà máa ń jẹ́, wọ́n sì máa ń gbé wọn sí nǹkan bí ọgọ́rin lé légbèje [1,480] mítà síra, èyí tó jẹ́ gígùn ibùsọ̀ kan nílẹ̀ Róòmù. Àwọn ibi ìsinmi máa ń wà lójú ọ̀nà wọn, níbi táwọn tó ń rìnrìn àjò ti lè pààrọ̀ ẹṣin wọn, tàbí kí wọ́n ra oúnjẹ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ sùn mọ́jú nígbà míì. Díẹ̀ lára irú ibi ìsinmi bẹ́ẹ̀ di ìlú kékeré nígbà tó yá.
Nígbà díẹ̀ lẹ́yìn ìbí Kristi, Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì ṣe ètò pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tún àwọn ọ̀nà ṣe. Ó yan àwọn ọ̀gá tí wọ́n á máa bójú tó àtúnṣe ọ̀nà kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó rí sí i pé wọ́n ṣe òpó ibùsọ̀ oníwúrà [ìyẹn miliarium aureum] síbi Gbàgede Ìlú Róòmù. Ibi òpó ibùsọ̀ oníwúrà tí wọ́n fi idẹ kọ ọ̀rọ̀ sí lára yìí ni gbogbo ojú ọ̀nà táwọn ará Róòmù ṣe sí ilẹ̀ Ítálì parí sí. Ìdí nìyẹn táwọn kan fi máa ń pa á lówe pé: “Gbogbo ọ̀nà ló já sí ìlú Róòmù.” Ọ̀gọ́sítọ́sì tún rí sí i pé wọ́n gbé àwòrán àwọn ọ̀nà tó wà nílẹ̀ ọba Róòmù síbì kan táwọn èèyàn ti lè máa rí i. Ó dà bíi pé àwọn ọ̀nà wọ̀nyẹn dára tó fáwọn tó ń lò ó láyé ìgbà yẹn, wọ́n sì dé àwọn ibi pàtàkì-pàtàkì táwọn èèyàn máa ń lọ.
Àwọn arìnrìn-àjò kan láyé àtijọ́ tiẹ̀ máa ń ní ìwé ìsọfúnni nípa ìrìn àjò tí wọ́n máa ń tẹ̀ lé kí ìrìn àjò wọn lè túbọ̀ rọrùn. Irú ìwé bẹ́ẹ̀ máa ń ní ìsọfúnni nípa bí àwọn ibi tí wọ́n ti lè dúró lójú ọ̀nà ṣe jìnnà síra sí àti irú ohun tí wọ́n lè rí tí wọ́n bá débẹ̀. Àmọ́ owó gọbọi ni wọ́n ń ta àwọn ìwé wọ̀nyẹn, nítorí náà gbogbo èèyàn kọ́ ló máa ń ní wọn.
Síbẹ̀ àwọn Kristẹni ajíhìnrere ṣì rìnrìn àjò lọ sí ọ̀pọ̀ ibi tó jìnnà gan-an láyé ìgbà yẹn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn nígbà ayé rẹ̀ sábà máa ń wọkọ̀ òkun tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò lọ síhà ìlà oòrùn, torí afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ síhà ìlà oòrùn máa ń mú kí irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀ túbọ̀ rọrùn. (Ìṣe 14:25, 26; 20:3; 21:1-3) Ṣùgbọ́n nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, apá ìwọ̀ oòrùn lafẹ́fẹ́ máa ń fẹ́ sí lójú òkun Mẹditaréníà. Torí náà tí Pọ́ọ̀lù bá fẹ́ rìnrìn àjò lọ sápá ìwọ̀ oòrùn, ọ̀nà ilẹ̀ táwọn ará Róòmù ṣe ló sábà máa ń gbà. Báyìí ni Pọ́ọ̀lù ṣe rin ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ kejì àti ìkẹta. (Ìṣe 15:36-41; 16:6-8; 17:1, 10; 18:22, 23; 19:1)a Ní nǹkan bí ọdún 59 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù gba Ọ̀nà Ápíà lọ sílùú Róòmù, àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ sì wá pàdé rẹ̀ ní Api Fórúmù tàbí Ibi Ọjà Ápíọ́sì, èyí tó jẹ́ àádọ́rin ó lé mẹ́rin [74] kìlómítà sí ìlú Róòmù lápá gúúsù ìlà oòrùn. Àwọn míì dúró dè é níbi ìsinmi tí wọ́n ń pè ní Ilé Èrò Mẹ́ta, èyí tó jẹ́ kìlómítà mẹ́rìnlá péré sí ìlú Róòmù. (Ìṣe 28:13-15) Nígbà tó fi máa di nǹkan bí ọdún 60 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù sọ pé ìwàásù ìhìn rere ti dé “gbogbo ayé,” ìyẹn àwọn ibi tí wọ́n mọ̀ pé ayé dé nígbà náà. (Kólósè 1:6, 23) Ọ̀nà táwọn ará Róòmù ṣe wà lára ohun tó jẹ́ kí wọ́n lè wàásù dé gbogbo ibi tí wọ́n dé nígbà yẹn.
Dájúdájú, ojú ọ̀nà àwọn ará Róòmù jẹ́ ohun àmúyangàn tó ti wà látọjọ́ pípẹ́, wọ́n sì tún jẹ́ ohun tó mú kí ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run tètè tàn kálẹ̀.—Mátíù 24:14.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àwòrán ilẹ̀ tó wà lójú ewé 33 nínú ìwé Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Òpó ibùsọ̀ kan táwọn ará Róòmù ṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ojú ọ̀nà kan tó wà nílùú kan tó ń jẹ́ Ostia nílẹ̀ Ítálì láyé àtijọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn ibi tí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ayé àtijọ́ jẹ lára ojú ọ̀nà kan nílẹ̀ Austria
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Apá kan ọ̀nà àwọn ará Róòmù tó láwọn òpó ibùsọ̀ nílẹ̀ Jọ́dánì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ojú ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní Ọ̀nà Ápíà lẹ́yìn ìlú Róòmù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwókù àwọn ibojì kan níbi Ọ̀nà Ápíà lẹ́yìn ìlú Róòmù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ ní àfonífojì Furlo lójú ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní Via Flaminia, lágbègbè Marche
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Afárá Tìbéríù lójú ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní Via Emilia nílùú Rimini, nílẹ̀ Ítálì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Pọ́ọ̀lù pàdé àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ ní Api Fórúmù tàbí Ibi Ọjà Ápíọ́sì tí onírúurú ìgbòkègbodò ti ń wáyé
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]
Apá òsì, Ostia: ©danilo donadoni/Marka/age fotostock; apá ọ̀tún, ojú ọ̀nà tó láwọn òpó ibùsọ̀: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.