Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Olú Ọba Gbọ́ Ìhìn Rere
Lọ́dún 59 Sànmánì Kristẹni, Ọ̀gágun Julius àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan wọ ìlú Róòmù. Ó ti rẹ àwọn ọmọ ogun náà tẹnutẹnu. Ẹnu ibodè Porta Capena ni wọ́n gbà wọlé. Látorí Òkè Palatine, wọ́n lè rí ààfin Olú Ọba Nero, àtàwọn ẹ̀ṣọ́ olú ọba tí wọ́n fi idà há abẹ́ aṣọ wọn.a Àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà gba Gbàgede Róòmù kọjá, wọ́n sì gun orí Òkè Viminal. Wọ́n kọjá níbi ọgbà kan tó ní oríṣiríṣi ojúbọ òrìṣà àwọn ará Róòmù. Lẹ́yìn náà, wọ́n kọjá níbi pápá kan tó tẹ́jú, tí àwọn ọmọ ogun ti máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà. Kó tó dìgbà yẹn, áńgẹ́lì kan ti sọ fún un nígbà tí ìjì líle kan jà nínú ọkọ̀ òkun tó wọ̀ pé: “Ìwọ gbọ́dọ̀ dúró níwájú Késárì.” (Ìṣe 27:24) Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ti máa ronú pé ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì yẹn ti fẹ́ ní ìmúṣẹ. Bó ṣe ń wò yíká ìlú náà, ó ṣeé ṣe kó rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún un níbi Ilé Gogoro Antonia tó wà ní Jerúsálẹ́mù pé: “Jẹ́ onígboyà gidi gan-an! Nítorí pé bí o ti ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa àwọn nǹkan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú mi ní Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ tún gbọ́dọ̀ jẹ́rìí ní Róòmù.”—Ìṣe 23:10, 11.
Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù tẹsẹ̀ dúró díẹ̀ kó sì bojú wo àgọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ olú ọba. Bíríkì pupa ni wọ́n fi mọ odi gìrìwò yí àgọ́ náà ká, wọ́n sì mọ ilé ìṣọ́ sí i. Àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́ olú ọba méjìláb ló ń gbé níbẹ̀. Ibẹ̀ náà ni àwọn ọlọ́pàá àtàwọn agẹṣinjagun ń gbé. Ńṣe ni odi gìrìwò yìí ń rán wọn létí pé alágbára ni olú ọba Róòmù. Àwọn ẹ̀ṣọ́ olú ọba ló máa ń bójú tó àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wá láti àgbègbè mìíràn lórílẹ̀-èdè Róòmù. Torí náà, Ọ̀gágun Julius kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà gba ọ̀kan lára ẹnu bodè mẹ́rin tó wọ inú odi náà. Bó ṣe di pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà gúnlẹ̀ sí ìlú Róòmù nìyẹn, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tí wọ́n ti wà lẹ́nu ìrìn àjò.—Ìṣe 27:1-3, 43, 44.
PỌ́Ọ̀LÙ WÀÁSÙ “LÁÌSÍ ÌDÍLỌ́WỌ́”
Nígbà ìrìn àjò Pọ́ọ̀lù àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù, Ọlọ́run fi han Pọ́ọ̀lù nínú ìran pé ẹnì kankan kò ní kú nínú gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà. Ejò olóró kan tiẹ̀ ṣán Pọ́ọ̀lù, àmọ́ kò ṣe é ní jàǹbá kankan. Nígbà tí wọ́n dé erékùṣù Málítà, ó mú àwọn tó ń ṣàìsàn lára dá, lára àwọn tó ń gbé níbẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní ọlọ́run. Àwọn ẹ̀ṣọ́ olú ọba kan lè ti gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kí wọ́n sì máa sọ ọ́ láàárín ara wọn.
Pọ́ọ̀lù ti rí àwọn arákùnrin tí wọ́n ti Róòmù ‘wá pàdé rẹ̀ ní Ibi Ọjà Ápíọ́sì àti Ilé Èrò Mẹ́ta.’ (Ìṣe 28:15) Ó wu Pọ́ọ̀lù kó máa wàásù nìṣó ní ìlú Róòmù. Àmọ́, báwo ló ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ní báyìí tó ti di ẹlẹ́wọ̀n? (Róòmù 1:14, 15) Àwọn kan gbà pé ńṣe ni wọ́n kọ́kọ́ kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà lọ sọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àfàìmọ̀ ni kò ní jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Afranius Burrus ni wọ́n mú Pọ́ọ̀lù lọ. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ni igbá kejì olú ọba.c Àmọ́, ní báyìí o, ẹ̀ṣọ́ kan ṣoṣo ló ń ṣọ́ Pọ́ọ̀lù, dípò kó jẹ́ ọ̀pọ̀ ọmọ ogun. Wọ́n gbà kí Pọ́ọ̀lù ṣètò ibi tí yóò máa gbé, wọ́n sì tún gbà kí àwọn àlejò máa lọ kí i, kó sì máa wàásù fún wọn “láìsí ìdílọ́wọ́.”—Ìṣe 28:16, 30, 31.
PỌ́Ọ̀LÙ WÀÁSÙ FÚN “ẸNI KÉKERÉ ÀTI ẸNI ŃLÁ”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀gágun Burrus ti fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu Pọ́ọ̀lù nígbà tí wọ́n wà ní àgọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ olú ọba tàbí nígbà tí wọ́n wà ní ààfin kó tó di pé ó mú un lọ sọ́dọ̀ Nero. Pọ́ọ̀lù lo àǹfààní tó ní yìí dáadáa láti “jẹ́rìí fún àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá.” (Ìṣe 26:19-23) Ohun yòówù kí ọ̀gágun Burrus rò nípa Pọ́ọ̀lù, ohun tó dájú ni pé kò fi í sẹ́wọ̀n ní àgọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ olú ọba.d
Pọ́ọ̀lù pe “àwọn tí wọ́n jẹ́ sàràkí-sàràkí jọ lára àwọn Júù,” ó sì wàásù fún wọn. Ó tiẹ̀ tún jẹ́rìí fún àwọn ẹ̀ṣọ́ olú ọba pàápàá. Wọ́n gbọ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣé ń jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn Júù nípa Jésù àti Ìjọba Ọlọ́run “láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.”—Ìṣe 28:17, 23.
Ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń pààrọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ tó ń ṣọ́ ààfin olú ọba. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé oríṣiríṣi ọmọ ogun ló ń ṣọ́ Pọ́ọ̀lù náà lójoojúmọ́. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún un láti jẹ́rìí fún ọ̀pọ̀ nínú wọn. Gbogbo ìsọfúnni tí wọ́n ń bá a kọ sínú lẹ́tà ni àwọn ẹ̀ṣọ́ yìí ń gbọ́. Àwọn lẹ́tà yìí ló fi ránṣẹ́ sí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni àtàwọn ará ní Éfésù, Fílípì àti Kólósè. Lára àwọn ẹ̀ṣọ́ náà tún tẹ́tí sí lẹ́tà tó kọ sí Kristẹni kan tó ń jẹ́ Fílémónì. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n, ó ran ẹrú kan tó ń jẹ́ Ónẹ́símù lọ́wọ́. Ńṣe ni ẹrú yìí sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. Ní báyìí, ó ti wá dà bí ọmọ fún Pọ́ọ̀lù. Àmọ́, nígbà tó yá ó ní kó pa dà sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. (Fílém. 10) Kò sí àní-àní pé Pọ́ọ̀lù á ṣe ohun tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ogun tó ń ṣọ́ ọ jẹ ẹ́ lógún. (1 Kọ́r. 9: 22) Kódà, ó ṣeé ṣe kó fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹ̀ṣọ́ kan nípa ohun tí ìhámọ́ra ogun kọ̀ọ̀kan wà fún. Ó sì lè jẹ́ pé ohun tó rí kọ́ látinú ìjíròrò náà ló fi ṣe àpèjúwe nípa ìhámọ́ra.—Éfé. 6:13-17.
“SỌ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN LÁÌBẸ̀RÙ”
Yàtọ̀ sí pé àwọn ẹ̀ṣọ́ olú ọba ń ṣiṣẹ́ láàfin, wọ́n tún máa ń kàn sí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn míì jákèjádò ìlú Róòmù. Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe àwọn ẹ̀ṣọ́ olú ọba nìkan ló gbọ́ ìhìn rere, àwọn míì náà gbọ́, lára wọn sì di Kristẹni. (Fílí. 1:12, 13; 4:22) Pọ́ọ̀lù tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn ará tó wà ní Róòmù láti máa ‘fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù.’—Fílí. 1:14.
Bí Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́rìí ní Róòmù tún jẹ́ ìṣírí fún wa láti máa ‘wàásù ọ̀rọ̀ náà, ní àsìkò tí ó rọgbọ, àti ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú.’ (2 Tím. 4:2) Bí àpẹẹrẹ, ì báà jẹ́ ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó la wà, tàbí a wà ní ilé ìwòsàn, tàbí a wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wa, a lè wàásù fún àwọn tá a bá rí. Kódà, a lè wàásù fún àwọn tó ń tọ́jú wa tàbí àwọn tó wá ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá ń fi ìgboyà wàásù ní gbogbo ìgbà tá a bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé kò sí ohun tó máa mú kí ìhìn rere náà má tàn kálẹ̀.—2 Tím. 2:8, 9.
a Wo àpótí náà, “Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Olú Ọba Nígbà Ayé Nero.”
b Ó tó ẹgbẹ̀rún ọmọ ogun tó máa ń wà nínú àwùjọ ẹ̀ṣọ́ olú ọba kan ṣoṣo.
c Wo àpótí náà, “Ọ̀gágun Sextus Afranius Burrus.”