ORÍ 27
“Jẹ́rìí Kúnnákúnná”
Wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù, síbẹ̀ ó ń bá a lọ láti máa wàásù
Ó dá lórí Ìṣe 28:11-31
1. Kí ló fi Pọ́ọ̀lù, Lúùkù àti Àrísítákọ́sì lọ́kàn balẹ̀?
LỌ́DÚN 59 Sànmánì Kristẹni, ọkọ̀ akẹ́rù kan ń bọ̀ láti erékùṣù Málítà tó wà ní agbègbè Mẹditaréníà, ó sì ń lọ sí Ítálì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn oúnjẹ oníhóró ni wọ́n ń fi ọkọ̀ yìí kó. Ère kan wà ní téńté orí ọkọ̀ akẹ́rù náà tí wọ́n kọ “Àwọn Ọmọ Súúsì” sára ẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n táwọn ẹ̀ṣọ́ ń mú lọ sí Róòmù àtàwọn Kristẹni méjì míì, ìyẹn Lúùkù àti Àrísítákọ́sì náà wà nínú ọkọ̀ òkun yìí. (Ìṣe 27:2) Àwọn ajíhìnrere yìí ò dà bí àwọn èrò ọkọ̀ tó kù, tí wọ́n ń fi òrìṣà ìbejì náà Castor àti Pollux ṣe aláàbò wọn, ìyẹn àwọn ọmọ Súúsì tó jẹ́ òrìṣà Gíríìkì. (Ìṣe 28:11) Jèhófà ni Pọ́ọ̀lù, Lúùkù àti Àrísítákọ́sì ń sìn ní tiwọn. Ọkàn wọn sì balẹ̀, torí pé Jèhófà ló sọ fún Pọ́ọ̀lù pé ó máa jẹ́rìí sí òtítọ́ ní Róòmù àti pé ó máa dúró níwájú Késárì.—Ìṣe 23:11; 27:24.
2, 3. Ibo ni ọkọ̀ òkun tó gbé Pọ́ọ̀lù gbà, ta ló sì ń dáàbò bo Pọ́ọ̀lù láti ìbẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀?
2 Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, ọkọ̀ wọn gúnlẹ̀ sí Sírákúsì tó wà ní Sísílì. Ìlú yìí rẹwà gan-an, ó sì lókìkí bí ìlú Áténì àti Róòmù. Ọkọ̀ náà wá gbéra lọ sí Régíómù tó wà ní gúúsù ilẹ̀ Ítálì. Ẹ̀fúùfù tó ń fẹ́ gba apá gúúsù wá mú kí ìrìn ọkọ̀ náà yá ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, débi pé ó rin ìrìn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ogún (320) kìlómítà lọ sí Pútéólì, ìyẹn èbúté ìlú Ítálì (nítòsí ìlú Naples òde òní), ó sì débẹ̀ lọ́jọ́ kejì.—Ìṣe 28:12, 13.
3 Apá tó kẹ́yìn nìyí nínú ìrìn àjò Pọ́ọ̀lù sí ìlú Róòmù, níbi tó ti máa jẹ́jọ́ níwájú Olú Ọba Nérò. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà títí dé òpin rẹ̀, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù. (2 Kọ́r. 1:3) Bá a ṣe máa rí i, Ọlọ́run ò fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀, Pọ́ọ̀lù náà sì ń fìtara bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì ẹ̀ nìṣó.
Pọ́ọ̀lù “Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ó sì Mọ́kàn Le” (Ìṣe 28:14, 15)
4, 5. (a) Báwo làwọn ará ní Pútéólì ṣe lawọ́ sí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìrìn àjò, kí ló sì ṣeé ṣe kó fà á táwọn ẹ̀sọ́ fi fún un lómìnira tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? (b) Táwọn Kristẹni tó wà lẹ́wọ̀n bá ń hùwà rere, àǹfààní wo ló lè tibẹ̀ yọ?
4 Ní Pútéólì, Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ‘rí àwọn ará, àwọn ará náà sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n lo ọjọ́ méje lọ́dọ̀ àwọn.’ (Ìṣe 28:14) Àpẹẹrẹ rere làwọn ará yìí jẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ ká láájò àlejò, ká sì jẹ́ ọ̀làwọ́! Ó dájú pé àwọn ará yìí jèrè ìwà ọ̀làwọ́ wọn lọ́pọ̀lọpọ̀, torí pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ fún àwọn náà níṣìírí. Àmọ́, kí ló mú kí ẹlẹ́wọ̀n táwọn ẹ̀ṣọ́ ń ṣọ́ yìí ní òmìnira tó tóyẹn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé àpọ́sítélì yìí ti ṣe àwọn nǹkan tó mú káwọn ẹ̀ṣọ́ náà fọkàn tán an.
5 Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tàbí àgọ́ ìfìyàjẹni, wọ́n sábà máa ń fún wọn láwọn àǹfààní kan àti òmìnira tí wọn ò fún àwọn tó kù, torí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́, wọ́n sì ṣeé fọkàn tán. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Ròmáníà, ilé ẹjọ́ ní kí ọkùnrin kan tó jẹ́ adigunjalè lọ ṣẹ̀wọ̀n ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75). Àmọ́ nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tí ìwà ẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà lọ́nà tó kàmàmà. Bó ṣe di pé àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà bẹ̀rẹ̀ sí í rán an lọ sínú ìlú nìyẹn, kó lè lọ ra àwọn nǹkan tí wọ́n nílò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà láìfi ẹnikẹ́ni ṣọ́ ọ! Ẹ ò rí i pé ìwà rere wa máa ń fògo fún Jèhófà.—1 Pét. 2:12.
6, 7. Báwo làwọn ará tó wá láti Róòmù ṣe fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò?
6 Láti Pútéólì, ó jọ pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò fẹsẹ̀ rin ìrìn àádọ́ta (50) kìlómítà lọ sílùú Kápúà tó wà ní Ọ̀nà Ápíà, tó lọ já sí ìlú Róòmù. Òkúta pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ni wọ́n tò sójú ọ̀nà táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó yìí, ẹni tó bá sì gbabẹ̀ á rí àwọn abúlé tó rẹwà tó wà nílùú Ítálì. Téèyàn bá sì dé àwọn ibì kan lójú ọ̀nà yẹn, èèyàn á tún rí Òkun Mẹditaréníà. Ọ̀nà yìí kan náà ló já sí ibì kan tí wọ́n ń pè ní Pontine Marshes, ìyẹn ibi irà kan tó fi ọgọ́ta (60) kìlómítà jìn sí ìlú Róòmù àti Ibi Ọjà Ápíọ́sì. Lúùkù sọ pé nígbà táwọn ará tó wà ní Róòmù “gbọ́ ìròyìn nípa” wọn, àwọn kan wá wọn dé Ibi Ọjà, àwọn míì sì dúró ní Ilé Èrò Mẹ́ta, ìyẹn ibi ìsinmi kan tó fi àádọ́ta (50) kìlómítà jìn sí Róòmù. Ẹ ò rí i pé àwọn ará yẹn nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù gan-an!—Ìṣe 28:15.
7 Ibi Ọjà Ápíọ́sì kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún arìnrìn-àjò tó bá ti rẹ̀, tó sì nílò ìsinmi. Akéwì àti òǹkọ̀wé ará Róòmù náà, Horace sọ pé “àwọn awakọ̀ òkun àtàwọn oníwàkiwà tó ń bójú tó ilé èrò náà máa ń pọ̀” ní Ibi Ọjà yìí. Ó tún sọ pé “omi tó wà níbẹ̀ máa ń rùn.” Kódà, òun ò lè jẹun níbẹ̀ rárá! Àmọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ibi Ọjà náà ò tura, ibẹ̀ làwọn ará tó wá láti Róòmù dúró sí de Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò, kí wọ́n lè bá wọn rin apá tó kẹ́yìn nínú ìrìn àjò wọn. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n sì fi ń dúró dè wọ́n.
8. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tó “tajú kán rí” àwọn ará?
8 Ìwé Mímọ́ ròyìn pé: “Nígbà tí Pọ́ọ̀lù tajú kán rí [àwọn ará,] ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kàn le.” (Ìṣe 28:15) Bó ṣe tajú kán rí àwọn ẹni ọ̀wọ́n, tó ṣeé ṣe kóun àtàwọn kan lára wọn ti mọra tẹ́lẹ̀, ó mọ́kàn le ìyẹn sì tù ú nínú. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run? Ìdí ni pé ó mọ̀ pé ara èso ẹ̀mí Ọlọ́run ni irú ìfẹ́ tó dénú bẹ́ẹ̀ jẹ́. (Gál. 5:22) Bákan náà ló rí lónìí, ẹ̀mí mímọ́ ń mú káwa Kristẹni máa tu àwọn ará wa nínú, ká sì ṣe àwọn nǹkan tí ò rọrùn rárá láti fi hàn pé ìfẹ́ tó dénú la ní síra wa.—1 Tẹs. 5:11, 14.
9. Báwo làwa náà ṣe lè ṣe bíi tàwọn ará tó lọ pàdé Pọ́ọ̀lù?
9 Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀mí mímọ́ máa ń mú káwọn ará tí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́ ṣèrànwọ́ fáwọn alábòójútó àyíká, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún míì. Ọ̀pọ̀ lára àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún bẹ́ẹ̀ ti ṣe àwọn ìpinnu kan tí kò rọrùn rárá kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mo lè túbọ̀ máa kọ́wọ́ ti ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, bóyá kí n ṣèrànwọ́ fún un láwọn ọ̀nà kan tàbí fún òun àti ìyàwó ẹ̀ tó bá ti níyàwó? Ṣé mo lè ṣètò àkókò mi kí n lè bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí?’ Ọ̀pọ̀ àǹfààní lo máa rí tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo bínú àwọn ará ní Róòmù á ṣe dùn tó bí wọ́n ṣe ń gbọ́ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró lẹ́nu Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò.—Ìṣe 15:3, 4.
“Ibi Gbogbo Ni Wọ́n Ti Ń Sọ̀rọ̀ Rẹ̀ Láìdáa” (Ìṣe 28:16-22)
10. Báwo ni nǹkan ṣe rí fún Pọ́ọ̀lù nílùú Róòmù, kí ló sì ṣe nígbà tó débẹ̀?
10 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn èèyàn náà dé Róòmù, wọ́n “gba Pọ́ọ̀lù láyè kó máa gbé láyè ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ogun tó ń ṣọ́ ọ.” (Ìṣe 28:16) Tí wọ́n bá sé ẹnì kan mọ́lé, ṣe ni wọ́n máa ń fi ẹ̀wọ̀n so ọwọ́ ẹ̀ mọ́ ti ọmọ ogun tó ń ṣọ́ ọ, kó má bàa sá lọ. Ṣùgbọ́n, ẹ̀wọ̀n tó wà lọ́wọ́ Pọ́ọ̀lù ò ní kó má wàásù, torí pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni. Torí náà, lẹ́yìn tó ti fi ọjọ́ mẹ́ta sinmi lẹ́yìn ìrìn àjò yẹn, ó pe àwọn sàràkí-sàràkí jọ lára àwọn Júù tó wà ní Róòmù kó lè fara hàn wọ́n kó sì tún wàásù fún wọn.
11, 12. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń báwọn Júù tó wà ládùúgbò náà sọ̀rọ̀, kí ló sọ tó jẹ́ kó wù wọ́n láti gbọ́rọ̀ ẹ̀?
11 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ṣe ohunkóhun tó lòdì sí àwọn èèyàn tàbí sí àṣà àwọn baba ńlá wa, síbẹ̀ wọ́n fà mí lé ọwọ́ àwọn ará Róòmù ní ẹlẹ́wọ̀n láti Jerúsálẹ́mù. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò, wọ́n fẹ́ dá mi sílẹ̀, nítorí kò sí ìdí kankan tó fi yẹ kí wọ́n pa mí. Àmọ́ nígbà tí àwọn Júù fárí gá, ó di dandan fún mi láti ké gbàjarè sí Késárì, ṣùgbọ́n kì í ṣe torí pé mo ní ẹ̀sùn tí mo fẹ́ fi kan orílẹ̀-èdè mi.”—Ìṣe 28:17-19.
12 Pọ́ọ̀lù pe àwọn Júù tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ ní “ẹ̀yin ará” kí wọ́n lè mọ̀ pé Júù bíi tiwọn lòun náà, kí wọ́n sì lè mú ẹ̀tanú èyíkéyìí tí wọ́n bá ti ní kúrò. (1 Kọ́r. 9:20) Bákan náà, ó jẹ́ kó yé wọn pé òun ò wá síbẹ̀ láti fẹ̀sùn kan àwọn Júù bíi tiẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ torí kóun lè ké gbàjarè sí Késárì lòun ṣe wá. Àmọ́, ìgbà àkọ́kọ́ rèé táwọn Júù yẹn máa gbọ́ pé Pọ́ọ̀lù pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn síwájú Késárì. (Ìṣe 28:21) Kí nìdí táwọn Júù tó wà ní Jùdíà ò fi tíì sọ̀rọ̀ náà fáwọn Júù tó wà ní Róòmù? Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé: “Ó jọ pé ọkọ̀ òkun tí Pọ́ọ̀lù wọ̀ wá sí Ítálì wà lára àwọn tó kọ́kọ́ dé síbẹ̀ lẹ́yìn ìgbà òtútù. Torí náà, àwọn Júù tó ń ṣojú fáwọn aláṣẹ ìlú Jerúsálẹ́mù ò tíì dé Ítálì, wọn ò sì tíì fi lẹ́tà ránṣẹ́.”
13, 14. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ nígbà tó fẹ́ wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
13 Pọ́ọ̀lù wá sọ̀rọ̀ kan tó gbàfíyèsí kó lè wu àwọn Júù yẹn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ìdí nìyí tí mo fi ní kí n pè yín kí n lè bá yín sọ̀rọ̀, torí pé, nítorí ìrètí Ísírẹ́lì ni ẹ̀wọ̀n yìí ṣe yí mi ká.” (Ìṣe 28:20) Láìsí Mèsáyà náà àti Ìjọba ẹ̀ táwọn Kristẹni ń wàásù rẹ̀, kò lè sí ìrètí kankan fún Ísírẹ́lì. Àwọn àgbààgbà Júù fún Pọ́ọ̀lù lésì pé: “A rí i pé á dáa ká gbọ́rọ̀ lẹ́nu rẹ, ká lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ, torí a mọ̀ lóòótọ́ pé, tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀ya ìsìn yìí, ibi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa.”—Ìṣe 28:22.
14 Nígbàkigbà tá a bá láǹfààní láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, ká máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tàbí ìbéèrè tó máa mú kó wu àwọn èèyàn láti gbọ́rọ̀ wa kí wọ́n sì ronú jinlẹ̀. A lè rí àwọn àbá tó dáa nínú àwọn ìtẹ̀jáde bíi Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni àti Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni. Tó o bá ń lo àwọn àbá tó wà níbẹ̀, wàá túbọ̀ máa kọ́ni lọ́nà tó dáa sí i.
Àpẹẹrẹ Tó Dáa Nípa Bá A Ṣe Lè “Jẹ́rìí Kúnnákúnná” (Ìṣe 28:23-29)
15. Ohun mẹ́rin wo ló fara hàn kedere nínú ìwàásù Pọ́ọ̀lù?
15 Lọ́jọ́ tí wọ́n fi àdéhùn sí, àwọn Júù wá síbi tí Pọ́ọ̀lù ń gbé. Kódà, “àwọn tó wá pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ.” Pọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí fún wọn. “Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, ó ṣàlàyé ọ̀ràn náà fún wọn bí ó ṣe ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run, kó lè yí èrò tí wọ́n ní nípa Jésù pa dà nípasẹ̀ Òfin Mósè àti ìwé àwọn Wòlíì.” (Ìṣe 28:23) Ohun mẹ́rin kan fara hàn kedere nínú ìwàásù Pọ́ọ̀lù. Àkọ́kọ́, Ìjọba Ọlọ́run ni ìwàásù ẹ̀ dá lé. Ìkejì, ó sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń yíni lérò pa dà, ìyẹn sì jẹ́ kí ìwàásù ẹ̀ wọ àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn. Ìkẹta, ó bá wọn fèrò wérò látinú Ìwé Mímọ́. Ìkẹrin, bó ṣe wàásù “láti àárọ̀ ṣúlẹ̀” fi hàn pé kò mọ tara ẹ̀ nìkan, àmọ́ ó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń wàásù fún jẹ ẹ́ lógún. Àpẹẹrẹ rere lèyí mà jẹ́ fún wa o! Kí nìyẹn wá yọrí sí? Lúùkù sọ pé: “Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í gba ohun tó sọ gbọ́; àmọ́ àwọn míì ò gbà á gbọ́. Tóò, nígbà tí èrò wọn ò ṣọ̀kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ibẹ̀ sílẹ̀.”—Ìṣe 28:24, 25a.
16-18. Kí nìdí tí kò fi ya Pọ́ọ̀lù lẹ́nu pé àwọn Júù kan nílùú Róòmù ò gba ọ̀rọ̀ ẹ̀, kí ni kò sì yẹ káwa náà ṣe táwọn èèyàn ò bá fetí sí ìwàásù wa?
16 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ò ya Pọ́ọ̀lù lẹ́nu, torí pé ìgbà àkọ́kọ́ tírú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ kọ́ nìyẹn, ó sì bá àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mu. (Ìṣe 13:42-47; 18:5, 6; 19:8, 9) Torí náà, Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn tọ́kàn wọn ti yigbì, tí wọ́n ń fi ibẹ̀ sílẹ̀ náà pé: “Ẹ̀mí mímọ́ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe wẹ́kú nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà fún àwọn baba ńlá yín, pé, ‘Lọ sọ fún àwọn èèyàn yìí pé: “Ó dájú pé ẹ ó gbọ́, àmọ́ kò ní yé yín rárá; ó dájú pé ẹ ó wò, àmọ́ ẹ ò ní rí nǹkan kan. Nítorí ọkàn àwọn èèyàn yìí ti yigbì.” ’ ” (Ìṣe 28:25b-27) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a tú sí “yigbì” túmọ̀ sí kí ọkàn èèyàn “le gbagidi” débi pé ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ò ní le wọ ibẹ̀. (Ìṣe 28:27) Ẹ ò rí i pé nǹkan ńlá ni wọ́n pàdánù!
17 Níparí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, ó sọ fáwọn Júù tí kò fetí sí ìhìn rere náà pé bí wọn ò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́, “àwọn orílẹ̀-èdè . . . á fetí sí i.” (Ìṣe 28:28; Sm. 67:2; Àìsá. 11:10) Ẹnu Pọ́ọ̀lù sì gbà á láti sọ bẹ́ẹ̀ torí pé ó ti fojú ara ẹ̀ rí bí ọ̀pọ̀ àwọn Kèfèrí ṣe gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tí wọ́n sì yí pa dà!—Ìṣe 13:48; 14:27.
18 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹ má ṣe jẹ́ kínú bí wa táwọn èèyàn ò bá fetí sí ìhìn rere. Ó ṣe tán, a ti mọ̀ pé díẹ̀ làwọn tó máa rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè. (Mát. 7:13, 14) Táwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere bá sì dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn tòótọ́, ẹ jẹ́ ká máa yọ̀, ká sì gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀.—Lúùkù 15:7.
“Ó Ń Wàásù Ìjọba Ọlọ́run” (Ìṣe 28:30, 31)
19. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo àkókò tí wọ́n fi sé e mọ́lé lọ́nà tó dáa?
19 Ọ̀rọ̀ tí Lúùkù fi parí ìtàn tó ń sọ bọ̀ tuni lára gan-an, ó sọ pé: “[Pọ́ọ̀lù] lo odindi ọdún méjì ní ilé tí òun fúnra rẹ̀ gbà, ó sì máa ń gba gbogbo àwọn tó bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tọwọ́tẹsẹ̀, ó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún wọn, ó sì ń kọ́ wọn nípa Jésù Kristi Olúwa ní fàlàlà, láìsí ìdíwọ́.” (Ìṣe 28:30, 31) Àbẹ́ ò rí i pé Pọ́ọ̀lù kó àwọn èèyàn mọ́ra, ó nígbàgbọ́, ó sì nítara! Àpẹẹrẹ tó dáa lèyí jẹ́ fún wa.
20, 21. Sọ díẹ̀ lára àwọn tí Pọ́ọ̀lù ràn lọ́wọ́ nígbà tó wà nílùú Róòmù.
20 Ọ̀kan lára àwọn tí Pọ́ọ̀lù tẹ́wọ́ gbà ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ónísímù, ẹrú kan tó sá wá láti Kólósè. Pọ́ọ̀lù kọ́ Ónísímù lẹ́kọ̀ọ́ tó fi di Kristẹni, Ónísímù sì wá di “arákùnrin . . . olóòótọ́ àti olùfẹ́” fún Pọ́ọ̀lù. Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ Ónísímù gan-an, kódà ó pè é ní “ọmọ mi, tí mo di bàbá rẹ̀.” (Kól. 4:9; Fílém. 10-12) Ó dájú pé bí Ónísímù ṣe di Kristẹni tó sì jẹ́ olóòótọ́ máa gbé Pọ́ọ̀lù ró gan-an!a
21 Àwọn míì náà tún jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ rere tí Pọ́ọ̀lù fi lé lẹ̀. Ó kọ̀wé sáwọn ará Fílípì pé: “Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti mú kí ìhìn rere tẹ̀ síwájú, tó fi jẹ́ pé gbogbo èèyàn mọ̀ nípa àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi nítorí Kristi láàárín gbogbo Ẹ̀ṣọ́ Ọba àti gbogbo àwọn yòókù. Púpọ̀ lára àwọn ará nínú Olúwa ti ní ìgboyà nítorí àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi, wọ́n sì túbọ̀ ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù.”—Fílí. 1:12-14.
22. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo àkókò tí wọ́n fi sé e mọ́lé nílùú Róòmù?
22 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sé Pọ́ọ̀lù mọ́lé nígbà tó wà nílùú Róòmù, ó lo àkókò yẹn láti kọ àwọn lẹ́tà sáwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn lẹ́tà yẹn sì ṣe wọ́n láǹfààní gan-an. Àwọn lẹ́tà yẹn ló wá di apá kan Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì báyìí.b Bí àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú lẹ́tà yẹn ṣe wúlò nígbà yẹn náà ló wúlò lóníì, ó ń ṣe wá láǹfààní torí pé Ọlọ́run ló mí sí i.—2 Tim. 3:16, 17.
23, 24. Báwo làwọn Kristẹni ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lónìí tí wọ́n bá jù wọ́n sẹ́wọ̀n láìtọ́?
23 Ìwé Ìṣe ò sọ ìgbà tí wọ́n dá Pọ́ọ̀lù sílẹ̀, àmọ́ nígbà tí wọ́n fi máa dá a sílẹ̀, ó ti lo nǹkan bí ọdún mẹ́rin látìmọ́lé. Ó lo ọdún méjì ní Kesaríà, ó sì lo ọdún méjì ní Róòmù.c (Ìṣe 23:35; 24:27) Àmọ́, ayọ̀ rẹ̀ ò dín kù, ó ṣì ń bá a lọ láti ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ni wọ́n ti jù sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, àmọ́ ayọ̀ wọn ò dín kù, wọn ò sì dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Adolfo. Wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Sípéènì torí pé ó kọ̀ láti bá wọn dá sí ogun. Aláṣẹ kan sọ fún un pé: “Ọ̀rọ̀ ẹ yà wá lẹ́nu gan-an, torí bá a ṣe ń fayé ni ẹ́ lára tó, bẹ́ẹ̀ lò ń rẹ́rìn-ín músẹ́, tó o sì ń sọ ọ̀rọ̀ tó dáa lẹ́nu.”
24 Nígbà tó yá, wọ́n fọkàn tán Adolfo débi pé wọn ò kì í tilẹ̀kùn yàrá ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi í sí mọ́. Nígbà míì, àwọn sójà máa ń lọ sọ́dọ̀ ẹ̀ kí wọ́n lè mọ púpọ̀ sí i nípa Bíbélì. Ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣọ́ ọ tiẹ̀ máa ń lọ ka Bíbélì nínú yàrá ẹ̀wọ̀n Adolfo, Adolfo á wá máa bá a wo ìta bóyá àwọn èèyàn ń bọ̀ kí wọ́n má bàa rí i. Bó ṣe di pé ẹlẹ́wọ̀n ń ṣọ́ ẹni tó ń ṣọ́ ọ nìyẹn o! Torí náà, ẹ jẹ́ kí àpẹẹrẹ àwọn Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ yìí mú ká ‘túbọ̀ máa fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù,’ kódà nígbà tí kò bá rọrùn rárá.
25, 26. Àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu wo ni Pọ́ọ̀lù rí tó ṣẹ, báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì ṣe ń ṣẹ lónìí?
25 Ìwé Ìṣe sọ ìtàn tó mórí ẹni wú nípa àwọn Kristẹni tí wọ́n sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere. Apá tó gbẹ̀yìn ìwé Ìṣe sì jẹ́ ká rí bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń “wàásù Ìjọba Ọlọ́run” fún gbogbo àwọn tó wá kí i nígbà tí wọ́n sé e mọ́lé. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn jẹ́ fún wa! Ní orí kìíní, a kà nípa àṣẹ tí Jésù pa fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Kò tíì pé ọgbọ̀n (30) ọdún tí Jésù pàṣẹ yẹn, tí Bíbélì fi sọ pé wọ́n ti “wàásù láàárín gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.”d (Kól. 1:23) Èyí jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀mí Ọlọ́run lágbára gan-an!—Sek. 4:6.
26 Bákan náà lónìí, ẹ̀mí Ọlọ́run ń ran àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn “àgùntàn mìíràn” lọ́wọ́, kí wọ́n lè máa bá a nìṣó láti máa “jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run” ní igba ó lé ogójì (240) ilẹ̀! (Jòh. 10:16; Ìṣe 28:23) Ṣéwọ náà ń sa gbogbo ipá rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
a Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí Ónísímù wà lọ́dọ̀ òun ní Róòmù, àmọ́ tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, á tẹ ẹ̀tọ́ Fílémónì lójú torí òun ni ọ̀gá Ónísímù, á sì tún ta ko òfin àwọn ará Róòmù. Torí náà, Ónísímù pa dà sọ́dọ̀ Fílémónì, ó sì mú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù fi rán an sí Fílémónì dání. Nínú lẹ́tà yẹn, Pọ́ọ̀lù rọ Fílémónì pé kó gba Ónísímù pa dà tọwọ́tẹsẹ̀ torí pé ó ti di Kristẹni.—Fílém. 13-19.
b Wo àpótí náà, “Lẹ́tà Márùn-ún Tí Pọ́ọ̀lù Kọ Nígbà Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Fi Sẹ́wọ̀n ní Róòmù.”
c Wo àpótí náà, “Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù Lẹ́yìn Ọdún 61 Sànmánì Kristẹni.”
d Wo àpótí náà, “A Ti Wàásù Ìhìn Rere Náà ‘Láàárín Gbogbo Ẹ̀dá Tó Wà Lábẹ́ Ọ̀run.’ ”