TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | ÉNỌ́KÙ
“Ó Ti Wu Ọlọ́run Dáadáa”
ÉNỌ́KÙ ti pẹ́ láyé gan-an, o ti lo ohun tí ó tó 365 ọdún láyé, èyí sì lè yà wá lẹ́nu, torí pé àwa èèyàn kì í lò tó ìdá mẹ́rin ọdún yẹn báyìí! Síbẹ̀, kì í ṣe pé ó ti darúgbó, torí pé àwọn èèyàn máa ń pẹ́ láyé jù bẹ́ẹ̀ lọ lásìkò yẹn. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ìyẹn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ọdún sẹ́yìn, àwọn èèyàn máa ń pẹ́ láyé gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Ádámù ti lé lẹ́ni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ọdún nígbà tí wọ́n bí Énọ́kù. Ádámù sì tún ló nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún sí i lẹ́yìn tí wọ́n bí Énọ́kù! Àwọn kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù tiẹ̀ tún pẹ́ láyé jù bẹ́ẹ̀ lọ. Torí náà, ó jọ pé ara Énọ́kù ṣì le koko nígbà tó wà lẹ́ni ọdún 365, torí pé ó ṣì lè lo ọ̀pọ̀ ọdún sí i láyé. Àmọ́, nǹkan kò rí bẹ́ẹ̀ fún un.
Ìdí ni pé ẹ̀mí Énọ́kù wà nínú ewu. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán-an ni, àmọ́ àwọn èèyàn gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ sódì. Ó ṣeé ṣe kí Énọ́kù máa sá lọ kọ́wọ́ àwọn èèyàn náà máa bàa tẹ̀ ẹ́. Torí pé inú ń bí àwọn èèyàn náà burúkú-burúkú, wọ́n sì kórìíra rẹ̀. Wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ tó jẹ́ fún wọn, wọ́n sì tún kórìíra Ọlọ́run tó rán an níṣẹ́. Àwọn èèyàn náà mọ̀ pé àwọn ò lè fọwọ́ kan Jèhófà Ọlọ́run Énọ́kù, àmọ́ wọ́n lè ṣe Énọ́kù bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú! Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí Énọ́kù ti máa rò ó pé bóyá lòun á fojú kan ìdílé òun mọ́. Ó ṣeé ṣe kó máa ronú nípa ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti Mètúsélà ọmọkùnrin rẹ̀, títí kan Lámékì tó jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ̀? (Jẹ́nẹ́sísì 5:21, 23, 25) Ṣé ibi tí Énọ́kù máa parí ìgbésí ayé rẹ̀ sí nìyí?
Bíbélì kò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa Énọ́kù. Kódà, ẹsẹ Bíbélì mẹ́ta péré ló sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 5:21-24; Hébérù 11:5; Júúdà 14, 15) Síbẹ̀, ìwọ̀nba tí Bíbélì sọ jẹ́ ká rí i pé Énọ́kù jẹ́ ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára. Ṣé ìwọ náà ní ìdílé tí ò ń bójú tó? Àbí o ti dojú kọ ìṣòro kan tó gba pé kó o ṣe ohun tó o mọ̀ pé ó tọ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ látinú àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Énọ́kù.
‘ÉNỌ́KÙ Ń RÌN PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN TÒÓTỌ́’
Ìwà burúkú pọ̀ gan-an nígbà ayé Énọ́kù. Ìran rẹ̀ ni ìran keje látọ̀dọ̀ Ádámù. Nígbà yẹn, àwọn èèyàn ṣì ní ìlera tó dára torí pé kò tíì pẹ́ tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pẹ́ láyé. Àmọ́, àwọn èèyàn kò bẹ̀rù Ọlọ́run, ìwàkíwà sì kún ọwọ́ wọn. Ìwà ìkà tún gbòde kan, torí pé àtìgbà tí Kéènì ti pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀ ni ìwà ìkà ti bẹ̀rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Kéènì tiẹ̀ máa ń fi ìwà ibi ọwọ́ rẹ̀ yangàn, kódà ó lẹ́mìí ìgbẹ̀san ju Kéènì lọ! Nígbà tó fi máa dórí ìran kẹta, ìwà ibi náà tún wá gba ọ̀nà míì yọ. Àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Jèhófà, àmọ́ kì í ṣe pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. Ńṣe ni wọ́n ń pe orúkọ Ọlọ́run lọ́nà òdì, wọ́n sì ń kẹ́gàn rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 4:8, 23-26.
Irú ìwà yìí ló gbòde kan lásìkò Énọ́kù. Bí Énọ́kù ṣe ń dàgbà, ó ní láti ṣe ìpinnu kan. Ṣé ó máa dara pọ̀ mọ́ àwọn tí kò ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́? Àbí ó máa jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, tó dá ọ̀run àti ayé? Ó ṣeé ṣe kí Énọ́kù ti gbọ́ nípa ìṣòtítọ́ Ébẹ́lì àti bí Kéènì ṣe pa á torí pé ó ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Énọ́kù náà sì pinnu láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ébẹ́lì. Jẹ́nẹ́sísì 5:22 sọ fún wa pé: “Énọ́kù ń bá a lọ ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́.” Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Énọ́kù jẹ́ olùfọkànsin Ọlọ́run, ó sì dá yàtọ̀ láàárín àwọn èèyàn ìgbà yẹn. Òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí Bíbélì ṣàpèjúwe lọ́nà yìí.
Ẹsẹ Bíbélì yẹn kan náà sọ pé Énọ́kù ń bá a nìṣó láti máa bá Jèhófà rìn lẹ́yìn tó bí Mètúsélà. Èyí fi hàn pé Énọ́kù ti ní ìdílé nígbà tó wà lẹ́ni ọdún márùnlélọ́gọ́ta [65]. Ó ní ìyàwó, àmọ́ Bíbélì kò sọ orúkọ rẹ̀, kò sì sọ iye “àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin” tó bí. Kí bàbá kan tó lè fi hàn pé òun bá Ọlọ́run rìn lásìkò tó fi ń tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, ó ní láti máa bójú tó ìdílé rẹ̀ lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́. Énọ́kù mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí òun jẹ́ olóòótọ́ sí ìyàwó òun. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ó sì dájú pé ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run. Kí ló wá yọrí sí?
Bíbélì kò sọ̀rọ̀ púpọ̀ lórí kókó yìí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì kò sọ nǹkan kan nípa ìgbàgbọ́ Mètúsélà tó jẹ́ ọmọ Énọ́kù. Òun ló pẹ́ jù láyé nínú àkọsílẹ̀ àwọn èèyàn inú Bíbélì. Ọdún tí Ìkún Omi bẹ̀rẹ̀ ni Mètúsélà kú. Àmọ́, ó bí ọmọ kan tó ń jẹ́ Lámékì. Lámékì ṣì bá Énọ́kù bàbá rẹ̀ àgbà láyé, kódà wọ́n jọ gbáyé fún nǹkan bi ọgọ́rùn-ún [100] ọdún. Bí Lámékì ṣe ń dàgbà, ó fi hàn pé òun nígbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ darí rẹ̀ láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa Nóà tí jẹ́ ọmọ Lámékì, àsọtẹ́lẹ̀ náà sì ṣe lẹ́yìn Ìkún Omi. Bíbélì fi hàn pé Nóà náà bá Ọlọ́run rìn bíi ti Énọ́kù baba ńlá rẹ̀. Àmọ́, Nóà kò bá Énọ́kù láyé. Síbẹ̀, àpẹẹrẹ rere ni Énọ́kù jẹ́ fún un. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀dọ̀ Lámékì ni Nóà ti gbọ́ nípa àpẹẹrẹ rere tí Énọ́kù fi lélẹ̀, ó sì lè jẹ́ ọ̀dọ̀ Mètúsélà bàbá rẹ̀ àgbà, tàbí kó jẹ́ ọ̀dọ̀ Járédì bàbá Énọ́kù, tó kú nígbà tí Nóà wà lẹ́ni 366 ọdún.—Jẹ́nẹ́sísì 5:25-29; 6:9; 9:1.
Ìyàtọ̀ gidi ló wà láàárín Énọ́kù àti Ádámù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Ádámù, ó ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara rẹ̀ di àpẹẹrẹ burúkú fún àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Àmọ́ ní ti Énọ́kù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni, ó bá Ọlọ́run rìn, ó sì fi àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ lélẹ̀ fáwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Ìgbà tí Énọ́kù wà lẹ́ni 308 ọdún ni Ádámù kú. Ṣé àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù tiẹ̀ ṣọ̀fọ̀ bàbá àgbà tó jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan yìí? A ò lè sọ. Àmọ́, ohun tó dájú ni pé, Énọ́kù “ń bá a nìṣó ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 5:24.
Tó o bá jẹ́ olórí ìdílé, o lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ìgbàgbọ́ tí Énọ́kù ní. Ó ṣe pàtàkì pé kó o máa pèsè oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé fún ìdílé rẹ, àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bó o ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run. (1 Tímótì 5:8) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan lo máa fi kọ́ wọn, àmọ́ ìwà rẹ tún ṣe pàtàkì. Tó o bá yàn láti bá Ọlọ́run rìn bíi ti Énọ́kù, tó o jẹ́ kí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣamọ̀nà rẹ, ìwọ náà á lè jẹ́ àwòkọ́ṣe rere fún ìdílé rẹ.
ÉNỌ́KÙ “SỌ TẸ́LẸ̀ PẸ̀LÚ NÍPA WỌN”
Ó ṣeé ṣe kí Énọ́kù máa rò pé òun nìkan lòun dá wà láàárín àwọn aláìgbàgbọ́ yẹn. Àmọ́, ṣé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ kíyè sí i? Bẹ́ẹ̀ ni. Lọ́jọ́ kan, Jèhófà bá Énọ́kù ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sọ̀rọ̀. Ọlọ́run sọ fún Énọ́kù pé kó lọ jíṣẹ́ kan fún àwọn èèyàn nígbà yẹn. Ó tipa bẹ́ẹ̀ sọ Énọ́kù di wòlíì àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ nípa iṣẹ́ tó jẹ́ fáwọn èèyàn. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà náà, Ọlọ́run mí sí Júúdà tó jẹ́ arákùnrin Jésù, láti ṣàkọsílẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí Énọ́kù sọ.a
Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Énọ́kù sọ? Àsọtẹ́lẹ̀ náà lọ báyìí: “Wò ó! Jèhófà wá pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́, láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn, àti láti dá gbogbo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi nípa gbogbo ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo ohun amúnigbọ̀nrìrì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ lòdì sí i.” (Júúdà 14, 15) Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé Énọ́kù sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí bíi pé ohun tó ń sọ ti ṣẹlẹ̀ kọjá. Ọ̀nà yìí ni wọ́n gbà sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì nínú Bíbélì. Ohun tí ìyẹn ń fi hàn ni pé: Wòlíì náà ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ, àfi bíi pé nǹkan náà ti ṣẹlẹ̀ kọjá!—Aísáyà 46:10.
Báwo ni Énọ́kù ṣe jíṣẹ́ yìí fún gbogbo àwọn èèyàn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló ń wàásù fún àwọn tó fẹ́ gbọ́. Wo bí ìkìlọ̀ náà ti lágbára tó, ó tẹnu mọ́ àwọn gbólóhùn bí “àìṣèfẹ́ Ọlọ́run” àti “aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” láti ké ègbé lé àwọn èèyàn náà àti ìwà wọn àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà hu ìwà ibi wọn. Àsọtẹ́lẹ̀ náà kìlọ̀ fáwọn èèyàn náà pé ìwàkíwà ló kúnnú ayé látìgbà tí Ọlọ́run ti lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì. Jèhófà sì máa wá pẹ̀lú àwọn “ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́,” ìyẹn àwọn ańgẹ́lì alágbára tó ti múra ogun, kó lè pa ayé ìgbà yẹn run. Énọ́kù sì dá nìkan kéde ìkìlọ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run yìí pẹ̀lú ìgboyà. Ó ṣeé ṣe kí orí Lámékì wú bó ṣe ń rí i tí bàbá àgbà yìí ń fi ìgboyà kéde ìkìlọ̀ Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ pé èyí ló mú kí ìgbàgbọ́ Lámékì náà lágbára.
Àpẹẹrẹ Énọ́kù lè mú ká ronú bóyá àwa náà kórìíra ohun tó ń lọ nínú ayé yìí bí Ọlọ́run ṣe kórìíra rẹ̀. Ìdájọ́ tí Énọ́kù fìgboyà kéde nígbà yẹn kan àwa náà lónìí. Bí Énọ́kù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Jèhófà fi Àkúnya omi pa àwọn èèyàn burúkú run nígbà ayé Nóà. Àmọ́, ńṣe ní ìparun yẹn ń ṣàpẹẹrẹ ìparun ńlá tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Mátíù 24:38, 39; 2 Pétérù 2:4-6) Bíi ti ìgbà yẹn, Ọlọ́run ti múra àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára sílẹ̀ láti mú ìdájọ́ wá sórí àwọn èèyàn burúkú lóde òní. Torí náà, ó yẹ kí gbogbo wa pátá fi ìkìlọ̀ Énọ́kù sọ́kàn, ká sì sọ ọ́ fáwọn míì. Èyí lè mú káwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa kẹ̀yìn sí wa tàbí kó dà bíi pé a dá wà. Àmọ́ ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé bí Jèhófà ṣe dúró ti Énọ́kù, ló ṣe máa dúró ti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lónìí!
‘A ṢÍ I NÍPÒ PA DÀ LÁTI MÁ ṢE RÍ IKÚ’
Báwo ni Énọ́kù ṣe kú? Ohun kan ni pé ikú rẹ̀ ṣeni ní kàyéfì ju ìgbésí ayé rẹ̀ lọ. Apá kan nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé: “Énọ́kù sì ń bá a nìṣó ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́. Lẹ́yìn náà, òun kò sì sí mọ́, nítorí tí Ọlọ́run mú un lọ.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:24) Lọ́nà wo ni Ọlọ́run gbà mú Énọ́kù lọ? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé, ó ní: “Nípa ìgbàgbọ́ ni a ṣí Énọ́kù nípò padà láti má ṣe rí ikú, a kò sì rí i níbi kankan nítorí tí Ọlọ́run ti ṣí i nípò padà; nítorí ṣáájú ìṣínípòpadà rẹ̀, ó ní ẹ̀rí náà pé ó ti wu Ọlọ́run dáadáa.” (Hébérù 11:5) Kí ní Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “a ṣí Énọ́kù nípò padà láti má ṣe rí ikú”? Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan sọ pé Ọlọ́run mú Énọ́kù lọ sí ọ̀run. Àmọ́ ìyẹn kò lè jóòótọ́. Torí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù Kristi ni ẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run jí dìde sí ọ̀run.—Jòhánù 3:13.
Ó dáa, báwo ni Ọlọ́run ṣe ṣí Énọ́kù nípò pa dà tó fi jẹ́ pé kò rí ikú”? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Jèhófà rọra mú kí Énọ́kù sùn kó sì gba ibẹ̀ kú láìjẹ ìrọra kankan. Àmọ́ kí Énọ́kù tó kú, Ọlọ́run jẹ́ kó yé e pé, ‘ó ti wu òun dáadáa.’ Báwo nìyẹn ṣe ṣẹlẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣáájú kí Énọ́kù tó kú, Ọlọ́run jẹ́ kó rí bí ayé ṣe máa rí lẹ́yìn tó bá di Párádísè. Énọ́kù sùn nínú oorun ikú lẹ́yìn tó rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba òun. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa Énọ́kù àtàwọn olóòótọ́ míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ó sọ pé: “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kú nínú ìgbàgbọ́.” (Hébérù 11:13) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn èèyàn burúkú yẹn wá òkú Énọ́kù, àmọ́ wọn ‘kò rí i níbi kankan.’ Jèhófà kò jẹ́ káwọn èèyànkéèyàn náà rí òkú Énọ́kù kí wọ́n má bàa fi òkú rẹ̀ gbé ìjọsìn èké lárugẹ.b
Bá a ṣe ń ronú lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ẹ jẹ́ ká fọkàn yàwòrán ọ̀nà tó ṣeé ṣe kí Énọ́kù gbà kú. Èyí kàn jẹ́ ọ̀kan nínú ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀. Fojú inú wo bí Énọ́kù ṣe ń sá lọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ ẹ́ tẹnu-tẹnu. Àwọn èèyàn burúkú ń lé e bọ̀, inú ń bí wọn gidigidi nítorí ìdájọ́ tí Énọ́kù kéde fún wọn. Énọ́kù wá ríbi kan sá pa mọ́ sí, síbẹ̀ ó mọ̀ pé bópẹ́ bóyá ọwọ́ á tẹ òun. Ó ń ronú nípa bí àwọn èèyàn burúkú yẹn ṣe máa pa òun nípakúpa. Bó ṣe ń sinmi, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run, Ọlọ́run sì jẹ́ kó ní ìtura ọkàn. Ọlọ́run wá fi ìran kan hàn án, ó sì dà bíi pé ńṣe ni Énọ́kù wà nínú ìran yẹn gan-an.
Ó ṣeé ṣe kó rí ilẹ̀ ayé tó yàtọ̀ pátápátá sí èyí tó wà. Gbogbo ibẹ̀ rẹwà bí ọgbà Édẹ́nì, àmọ́ kò sáwọn Kérúbù tó ń ṣọ́ ẹnubodè. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń ṣeré kiri, wọ́n sì ní ìlera tó dára. Àlàáfíà tó wà níbẹ̀ kọjá àfẹnusọ. Kò sẹ́ni tó kórìíra ọmọnìkejì tàbí ṣe ẹ̀tanú síra wọn. Èyí yàtọ̀ sí ayé tí Énọ́kù ń gbé. Ọkàn Énọ́kù balẹ̀ torí ó rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. Ó sì dá a lójú pé inú ayé tó rí rèǹtèrente yìí lòun máa gbé. Jèhófà jẹ́ kó ní ìtura ọkàn, ló bá rọra forí lélẹ̀, ó sì sùn nínú oorun ikú láìjẹ ìrora.
Énọ́kù ṣì ń sùn nínú oorun ikú títí dòní, síbẹ̀ Ọlọ́run kò gbàgbé rẹ̀ torí pé agbára ìrántí Ọlọ́run kò láàlà. Jésù tiẹ̀ ṣèlérí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí gbogbo àwọn tó wà nínú ìrántí Ọlọ́run máa gbọ́ ohùn Kristi, wọ́n á jí dìde látinú sàréè, wọ́n á sì bọ́ sínú ayé tuntun tó rẹwà, tí àlàáfíà á wà níbẹ̀ títí láé.—Jòhánù 5:28, 29.
Ṣé ìwọ náà máa fẹ́ wà níbẹ̀? Wo bínú wa ṣe máa dùn tó láti rí Énọ́kù. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan la máa kọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Á tiẹ̀ sọ fún wa bóyá bá a ṣe fọkàn yàwòrán ikú òun lọ̀rọ̀ ṣe rí. Àmọ́ nǹkan pàtàkì kan wà tá a gbọ́dọ̀ kọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ báyìí. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé èyí lẹ́yìn tó sọ̀rọ̀ nípa Énọ́kù, ó ní: ‘Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu Ọlọ́run dáadáa.’ (Hébérù 11:6) Ẹ ò ríi báyìí pé ó yẹ káwa náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Énọ́kù ká lè wu Ọlọ́run dáadáa!
a Àwọn ọ̀mọ̀wé kan jiyàn pé inú ìwé àpókírífà tí wọ́n pè ní Ìwé Énọ́kù ni Júúdà ti fa ọ̀rọ̀ yìí yọ. Àmọ́, a ò mọ àwọn tó ṣe ìwé àpókírífà, irọ́ pátápátá sì ni pé Énọ́kù fúnra rẹ̀ ló kọ ìwé ọ̀hún. Lóòótọ́, ìwé àpókírífà mẹ́nu ba àsọtẹ́lẹ̀ Énọ́kù lọ́nà tó péye, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú àwọn ìwé ìgbàanì kan tí kò sí mọ́ tàbí àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu ni wọ́n ti mú ọ̀rọ̀ náà. Ó lè jẹ́ pé inú ìwé ìgbàanì yẹn náà ni Júúdà ti rí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, ó sì lè jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Jésù ló ti gbọ́ ìtàn Énọ́kù, torí pé Jésù wà lọ́run, ó sì rí gbogbo bí Énọ́kù ṣe gbé ìgbésí ayé rẹ̀.
b Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run ò jẹ́ kọ́wọ́ àwọn èèyàn tẹ òkú Mósè àti ti Jésù, kí wọ́n má báa fi gbé ìsìn èké lárugẹ.—Diutarónómì 34:5, 6; Lúùkù 24:3-6; Júúdà 9.