Ẹ̀KỌ́ 61
Wọn Kò Tẹrí Ba
Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ tí Ọba Nebukadinésárì lá àlá nípa ère kan, ó fi góòlù ṣe ère ńlá kan. Ó gbé e sí ibì kan tí wọ́n ń pè ní Dúrà, ó sì pe àwọn èèyàn pàtàkì-pàtàkì tó wà ní ìlú náà, títí kan Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, pé kí wọ́n péjọ síwájú ère náà. Ọba wá pàṣẹ pé: ‘Tí ẹ bá ti gbọ́ ìró kàkàkí, háàpù àti fèrè, kí gbogbo yín forí balẹ̀ fún ère yìí! Ẹnikẹ́ni tí kò bá forí balẹ̀, a máa sọ ọ́ sínú iná.’ Ṣé àwọn Hébérù mẹ́ta yìí máa forí balẹ̀ fún ère náà, àbí Jèhófà nìkan ni wọ́n máa jọ́sìn?
Lẹ́yìn náà ọba pàṣẹ pé kí àwọn akọrin bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin. Ni gbogbo wọn bá forí balẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn ère náà. Àmọ́ Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kò forí balẹ̀. Àwọn kan rí wọn, wọ́n sì sọ fún ọba pé: ‘Àwọn Hébérù mẹ́ta yẹn kò forí balẹ̀ fún ère náà.’ Nebukadinésárì wá ránṣẹ́ pè wọ́n, ó ní: ‘Mo máa fún yín láyè lẹ́ẹ̀kan sí i láti jọ́sìn ère yìí. Tí ẹ bá kọ̀, mo máa sọ yín sínú iná. Kò sí ọlọ́run kankan tó lè gbà yín lọ́wọ́ mi.’ Wọ́n dá a lóhùn pé: ‘Má ṣe fún wa láyè kankan. Ọlọ́run wa lè gbà wá. Àmọ́, bí kò bá tiẹ̀ gbà wá, a ò ní jọ́sìn ère yìí.’
Ọ̀rọ̀ yìí bí Nebukadinésárì nínú gidigidi. Ló bá sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: ‘Ẹ mú kí iná náà gbóná sí i ní ìlọ́po méje!’ Ó wá pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé: ‘Ẹ de àwọn ọkùnrin yìí, kí ẹ sì jù wọ́n sínú iná náà!’ Iná yẹn gbóná débi pé nígbà tí àwọn ọmọ ogun náà sún mọ́ ọn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n kú. Àwọn Hébérù mẹ́ta náà ṣubú sínú iná. Àmọ́ nígbà tí Nebukadinésárì wo inú iná, ó rí i pé àwọn ọkùnrin mẹ́rin ló ń rìn nínú rẹ̀, dípò àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n jù síbẹ̀. Ẹ̀rù bà á, ló bá pe àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, ó sì bi wọ́n pé: ‘Ṣé kì í ṣe àwọn mẹ́ta la jù sínú iná ni? Àwọn mẹ́rin ni mo rí, ẹnì kẹrin sì dà bí áńgẹ́lì!’
Nebukadinésárì wá rìn sún mọ́ ibẹ̀, ó sì pè wọ́n, ó ní: ‘Ẹ jáde síta, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ!’ Ẹnu ya gbogbo wọn nígbà tí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò rìn jáde, nǹkan kan kò sì ṣe wọ́n. Ara wọn, irun wọn àti aṣọ wọn kò jóná, èéfín kò sì rùn lára wọn.
Nebukadinésárì wá sọ pé: ‘Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò tóbi lọ́ba. Ó rán áńgẹ́lì rẹ̀ láti wá gbà wọ́n. Kò sí ọlọ́run kankan tó dà bí Ọlọ́run wọn.’
Bíi ti àwọn Hébérù mẹ́ta yìí, ṣé ìwọ náà ti pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀?
“Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.” —Mátíù 4:10