“Máa Bá A Lọ ní Fífi Ara Rẹ . . . fún Kíkọ́ni”
“Ẹ Ń PÈ mí ní, ‘Olùkọ́,’ àti ‘Olúwa,’ ẹ sì sọ̀rọ̀ lọ́nà títọ́, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́.” (Jòh. 13:13) Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi ṣàlàyé ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ fún wọn. Ṣùgbọ́n, nígbà tó kù díẹ̀ kó gòkè re ọ̀run, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mát. 28:19, 20) Lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti jẹ́ olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó gba Tímótì, Kristẹni tó jẹ́ alàgbà náà níyànjú pé: “Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba, fún ìgbani-níyànjú, fún kíkọ́ni. . . . Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tím. 4:13-15.
Bíi ti ìgbà yẹn, apá pàtàkì ni kíkọ́ni jẹ́ lónìí, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá àti láwọn ìpàdé ìjọ. Báwo la ṣe lè máa bá a nìṣó láti máa fi ara wa fún kíkọ́ni, àwọn ọ̀nà wo lèyí sì máa gbà ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú, tàbí ká sunwọ̀n sí i gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
Fara Wé Olùkọ́ Ńlá Náà
Ọ̀nà tí Jésù ń gbà kọ́ni fa ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń tẹ́tí sí i mọ́ra. Kíyè sí bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe nípa lórí àwọn tó tẹ́tí sí i nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárétì. Lúùkù, òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà sọ pé: “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́rìí rẹ̀ ní rere, ẹnu sì ń yà wọ́n nítorí àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin tí ń jáde láti ẹnu rẹ̀.” (Lúùkù 4:22) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọ̀gá wọn nígbà tí wọ́n bá ń wàásù. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.” (1 Kọ́r. 11:1) Torí pé Pọ́ọ̀lù kọ́ni bí Jésù ti ṣe, ó di ọ̀jáfáfá nínú ‘kíkọ́ni ní gbangba àti láti ilé dé ilé.’—Ìṣe 20:20.
Kíkọ́ni “ní Ibi Ọjà”
Àpẹẹrẹ kan nípa bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń fi ìjáfáfá kọ́ni ní gbangba wà nínú ìwé Ìṣe orí 17. Níbẹ̀ la ti kà nípa ìbẹ̀wò tó ṣe sí ìlú Áténì, lórílẹ̀-èdè Gíríìsì. Kò sí ibi tí Pọ́ọ̀lù yíjú sí ní ìlú yẹn tí kò ti rí òrìṣà, ì báà jẹ́ ní òpópónà tàbí ní àwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí. Abájọ tí ọ̀rọ̀ náà fi da Pọ́ọ̀lù lọ́kàn rú gidigidi! Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kó má mọ ohun tó yẹ kó ṣe. Torí náà, ó “bẹ̀rẹ̀ sí fèrò-wérò nínú sínágọ́gù . . . àti ní ojoojúmọ́ ní ibi ọjà pẹ̀lú àwọn tí ó wà ní àrọ́wọ́tó.” (Ìṣe 17:16, 17) Àpẹẹrẹ àtàtà mà lèyí jẹ́ fún wa o! Bí a bá ń bá onírúurú èèyàn tó wá láti ibi tó yàtọ̀ síra sọ̀rọ̀, tí a kò tẹ́ńbẹ́lú wọn, àmọ́ tá à ń bá wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ìyẹn lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn kan lára wọn láti fetí sílẹ̀ kí wọ́n sì já ara wọn gbà kúrò nínú ìsìn èké.—Ìṣe 10:34, 35; Ìṣí. 18:4.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn tí Pọ́ọ̀lù bá pàdé níbi ọjà kò fẹ́ láti gbọ́rọ̀ rẹ̀. Àwọn kan lára wọn jẹ́ onímọ̀ èrò orí, èrò wọn sì ta ko òtítọ́ tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù rẹ̀. Nígbà tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ lọ́nà àríyànjiyàn, ó kúkú tẹ́tí sí ohun tí wọ́n ní láti sọ. Àwọn kan pè é ní “onírèégbè” (tó túmọ̀ lóréfèé sí, “ẹni tó ń ṣa èso jẹ”). Àwọn mìíràn sọ pé: “Ó dà bí pé ó jẹ́ akéde àwọn ọlọ́run àjúbàfún ti ilẹ̀ òkèèrè.”—Ìṣe 17:18.
Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ àlùfààṣá tí àwọn tí Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀ ń sọ sí i kò mú kó rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọ́n ní kí Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni, ó lo àǹfààní yẹn láti sọ àwíyé tó kún fún òye, èyí tó fi hàn bó ṣe jẹ́ ọ̀jáfáfá tó nínú kíkọ́ni. (Ìṣe 17:19-22; 1 Pét. 3:15) Ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò àsọyé rẹ̀ kínní-kínní ká sì kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti já fáfá sí i nínú kíkọ́ni.
Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Níbi Tí Èrò Yín Ti Jọra
Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Áténì, mo ṣàkíyèsí pé nínú ohun gbogbo, ó jọ pé ẹ kún fún ìbẹ̀rù àwọn ọlọ́run àjúbàfún ju àwọn mìíràn lọ. Fún àpẹẹrẹ, bí mo ti . . . ń fẹ̀sọ̀ kíyè sí àwọn ohun tí ẹ ń júbà fún, mo tún rí pẹpẹ kan, lórí èyí tí a kọ àkọlé náà ‘Sí Ọlọ́run Àìmọ̀.’ Nítorí náà, ohun tí ẹ ń fún ní ìfọkànsin Ọlọ́run láìmọ̀, èyí ni mo ń kéde fún yín.”—Ìṣe 17:22, 23.
Pọ́ọ̀lù kíyè sí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká rẹ̀ dáadáa. Látinú ohun tó ti fara balẹ̀ kíyè sí, ó mọ ohun tó pọ̀ nípa àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀. Àwa pẹ̀lú lè mọ ohun kan nípa ẹni tá a fẹ́ bá sọ̀rọ̀ bá a bá lákìíyèsí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ohun ìṣeré tó wà ní àyíká ilé kan tàbí àmì tó wà lára ilẹ̀kùn lè sọ púpọ̀ nípa ilé náà. Bó bá ṣeé ṣe fún wa láti mọ ipò tí onílé wà, a máa kíyè sára nípa ohun tá a máa sọ àti ọ̀nà tá a máa gbà sọ ọ́.—Kól. 4:6.
Pọ́ọ̀lù kò fi ìwàásù rẹ̀ tẹ́ńbẹ́lú àwọn ará Áténì. Àmọ́, ó rí i pé wọ́n ti gbé “ìfọkànsin Ọlọ́run” wọn gba ọ̀nà tí kò tọ́. Lọ́nà tó ṣe kedere, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè darí ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run òótọ́. (1 Kọ́r. 14:8) Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà pé ká máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere àti lọ́nà tó gbéni ró nígbà tá a bá ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run!
Máa Fọgbọ́n Sọ̀rọ̀ Má sì Ṣe Ojúsàájú
Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹni yìí ti jẹ́, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, kì í gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì àfọwọ́kọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn ṣe ìránṣẹ́ fún un bí ẹni pé ó ṣe aláìní nǹkan kan, nítorí òun fúnra rẹ̀ ni ó fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.”—Ìṣe 17:24, 25.
Nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, Pọ́ọ̀lù darí àfiyèsí sí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùfúnni-ní-Ìyè, nípa fífi ọgbọ́n pè é ní “Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Àǹfààní àgbàyanu ló jẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn olóòótọ́ ọkàn tí ẹ̀sìn wọn àti ibi tí wọ́n ti wá yàtọ̀ síra, kí wọ́n lè mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run ni orísun ìwàláàyè!—Sm. 36:9.
Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Láti ara ọkùnrin kan ni ó sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, . . . ó sì gbé àṣẹ kalẹ̀ nípa àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ àti àwọn ààlà ibùgbé tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn, fún wọn láti máa wá Ọlọ́run, bí wọ́n bá lè táràrà fún un, kí wọ́n sì rí i ní ti gidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:26, 27.
Ọ̀nà tá a gbà ń kọ́ni, lè jẹ́ káwọn míì mọ irú Ọlọ́run tá à ń sìn. Láìsí ojúsàájú, Jèhófà yọ̀ọ̀da fún àwọn èèyàn láti onírúurú orílẹ̀-èdè láti ‘táràrà fún òun, kí wọ́n sì rí òun ní ti gidi.’ Bákan náà, gbogbo ẹni tí àwa náà bá bá pàdé la máa ń bá sọ̀rọ̀. À ń gbìyànjú láti ran gbogbo àwọn tó bá gba Ẹlẹ́dàá gbọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè sún mọ́ ọn débi táá fi ṣeé ṣe fún wọn láti jogún ìbùkún ayérayé. (Ják. 4:8) Àmọ́, báwo la ṣe lè ran àwọn tí kò dá lójú pé Ọlọ́run wà lọ́wọ́? Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ló yẹ ká tẹ̀ lé. Kíyè sí ohun tó sọ bó ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ.
“Nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn kan lára àwọn akéwì láàárín yín ti wí pé, ‘Nítorí àwa pẹ̀lú jẹ́ àtọmọdọ́mọ rẹ̀.’ Nítorí náà, ní rírí i pé àwa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ọlọ́run, kò yẹ kí a lérò pé Olù-Wà Ọ̀run rí bí wúrà tàbí fàdákà tàbí òkúta.”—Ìṣe 17:28, 29.
Kí àwọn ará Áténì tí Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀ lè tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó tọ́ka sí ọ̀rọ̀ akéwì kan tí wọ́n mọ̀ dunjú tí wọ́n sì gba tiẹ̀. Àwa pẹ̀lú lè mú kí àwọn èèyàn lóye wa nípa bíbá wọn fèrò wérò lórí ohun tá a mọ̀ pé wọ́n máa gbà. Bí àpẹẹrẹ, àkàwé tí Pọ́ọ̀lù lò nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn Hébérù ṣì gbéṣẹ́ títí dòní olónìí. Ó sọ pé: “Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Héb. 3:4) Bá a bá jẹ́ kí àwọn onílé ronú lórí àkàwé tí kò ṣòro yìí, ó lè jẹ́ kí wọ́n gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ wa. Ohun míì tá a tún lè kíyè sí nínú àsọyé Pọ́ọ̀lù, tó mú kó máa kọ́ni lọ́nà tó já fáfá ni pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń súnni ṣe ohun tó tọ́.
Tẹnu Mọ́ Ọn Pé Àkókò Kánjúkánjú La Wà Yìí
Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Lóòótọ́, Ọlọ́run ti gbójú fo irúfẹ́ àwọn àkókò àìmọ̀ bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ nísinsìnyí, ó ń sọ fún aráyé pé kí gbogbo wọn níbi gbogbo ronú pìwà dà. Nítorí pé ó ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò.”—Ìṣe 17:30, 31.
Bí Ọlọ́run ṣe fi àyè gba ìwà ibi ti mú kí gbogbo wa láǹfààní láti fi irú ẹni tá a jẹ́ gan-an hàn án. Torí náà, ó ṣe kókó pé ká máa tẹnu mọ́ bí àkókò tá a wà yìí ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó, ká sì máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dájú ṣáká nípa ọ̀pọ̀ ìbùkún tá a máa gbádùn lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, èyí tó ti sún mọ́lé.—2 Tím. 3:1-5.
Ìṣesí Àwọn Èèyàn Máa Ń Yàtọ̀ Síra
“Tóò, nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa àjíǹde àwọn òkú, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹlẹ́yà, nígbà tí àwọn mìíràn wí pé: ‘Dájúdájú, àwa yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ nípa èyí àní ní ìgbà mìíràn.’ Nípa báyìí, Pọ́ọ̀lù jáde kúrò ní àárín wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan dara pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di onígbàgbọ́.”—Ìṣe 17:32-34.
Àwọn kan tètè máa ń gbọ́ ìwàásù wa; ó lè gba àkókò tó pọ̀ sí i kí ìfèròwérò wa tó yí àwọn míì lọ́kàn pa dà. Àmọ́, bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo ni àlàyé kedere àti èyí tó rọrùn tá a ṣe nípa òtítọ́ ràn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà, àní ká máa dúpẹ́ pé Ọlọ́run lò wá láti fa àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ Ọmọ rẹ!—Jòh. 6:44.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tá A Lè Rí Kọ́
Bá a ṣe ń ronú lórí àsọyé Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ nípa bó ṣe yẹ́ ká máa ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì fún àwọn ẹlòmíì. Bá a bá ní àǹfààní láti sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn nínú ìjọ, a lè sapá láti fara wé Pọ́ọ̀lù nípa fífi ọgbọ́n lo àwọn gbólóhùn tó máa ran àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ inú Bíbélì kí wọ́n sì gbà á gbọ́. A fẹ́ ṣàlàyé òtítọ́ fún wọn lọ́nà tó ṣe kedere, àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe bẹnu àtẹ́ lu ohun tí aláìgbàgbọ́ èyíkéyìí ti gbà pé ó jẹ́ òótọ́ tẹ́lẹ̀. Bákan náà, bá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, a fẹ́ sapá láti máa yí àwọn èèyàn lérò pa dà ká sì máa fi ọgbọ́n ṣe é. Bá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé lóòótọ́ là ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé ká máa ‘fi ara wa fún kíkọ́ni.’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Pọ́ọ̀lù máa ń kọ́ni lọ́nà tó ṣe kedere, tó rọrùn, tó sì mọ́gbọ́n dání
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
A lè fara wé Pọ́ọ̀lù bá a bá ń gba tàwọn tá à ń wàásù fún rò