Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JANUARY 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 1-2
“Jèhófà Dá Àwọn Nǹkan Sórí Ilẹ̀ Ayé”
it-1 527-528
Ìṣẹ̀dá
Nígbà tí Ọlọ́run sọ ní Ọjọ́ Kìíní pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ wà,” ìmọ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tàn díẹ̀díẹ̀ ní òfúrufú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orísun ìmọ́lẹ̀ náà ò tíì fara hàn kedere lórí ilẹ̀ ayé. Ó jọ pé ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ni èyí wáyé. Bí àpẹẹrẹ, atúmọ̀ èdè kan tó ń jẹ́ J. W. Watts sọ pé: “Díẹ̀díẹ̀, ìmọ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wà.” (Jẹ 1:3, A Distinctive Translation of Genesis) Ọlọ́run wá fìyàtọ̀ sáàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn, ó pe ìmọ́lẹ̀ ní Ọ̀sán, ó sì pe òkùnkùn ní Òru. Èyí jẹ́ ká rí i pé bí ayé ṣe ń yí, bẹ́ẹ̀ náà ló tún ń yípo oòrùn. Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé á máa rí ìmọ́lẹ̀ lọ́sàn-án àti òkùnkùn lóru.—Jẹ 1:3, 4.
Ní Ọjọ́ Kejì, Ọlọ́run mú kí ‘omi pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀,’ kí òfúrufú lè fara hàn. Omi díẹ̀ wà lórí ilẹ̀, Ọlọ́run sì mú kí alagbalúgbú omi wà lókè. Ọlọ́run wá mú kí òfúrufú wà láàárín ìwọ́jọpọ̀ omi méjèèjì, ó sì pe òfúrufú náà ní Ọ̀run. Àmọ́, ọ̀run tí ibí yìí ń tọ́ka sí kì í ṣe ìsálú ọ̀run níbi táwọn ìràwọ̀ wà, torí Bíbélì ò sọ pé omi tó wà lókè òfúrufú yìí bo àwọn ìràwọ̀ àtàwọn ohun míì tó wà ní ìsálú ọ̀run.—Jẹ 1:6-8; wo ÒFÚRUFÚ.
Ní Ọjọ́ Kẹta, Ọlọ́run tún lo agbára rẹ̀ láti mú kí omi tó wà ní ilẹ̀ wọ́ jọpọ̀, kí ilẹ̀ gbígbẹ lè fara hàn, Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ ní Ayé. Ọjọ́ yẹn kan náà ni Ọlọ́run mú káwọn nǹkan tíntìntín para pọ̀ káwọn ohun alààyè lè jáde, bíi koríko, ewéko àti igi eléso. Ọlọ́run ṣeé káwọn nǹkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí lè máa mú “irú tiwọn” jáde, ó sì dájú pé kì í ṣe nípa ẹfolúṣọ̀n tàbí èèṣì ni wọ́n fi wà.—Jẹ 1:9-13.
it-1 528 ¶5-8
Ìṣẹ̀dá
Ó gbàfiyèsí pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ Hébérù náà ba·raʼʹ, tó túmọ̀ sí “ṣẹ̀dá” ni wọ́n lò nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:16. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ Hébérù náà ʽa·sahʹ, tó túmọ̀ sí “ṣe” ni wọ́n lò. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ ti wà lára “ọ̀run” tí Jẹ́nẹ́sísì 1:1 mẹ́nu kàn, Ọlọ́run sì ti dá wọn tipẹ́tipẹ́ ṣáájú Ọjọ́ Kẹrin. Ní ọjọ́ kẹrin, Ọlọ́run ‘ṣe é’ lọ́nà tó fi jẹ́ pé ìmọ́lẹ̀ oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ á lè tàn dé ayé. Nígbà tí Bíbélì sọ pé, “Ọlọ́run wá fi wọ́n sí ojú ọ̀run kí wọ́n lè máa tàn sórí ayé,” ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé á ṣeé ṣe fún èèyàn láti rí ìmọ́lẹ̀ wọn láti orí ilẹ̀ ayé bíi pé ojú òfúrufú ni wọ́n wà. Bákan náà, àwọn orísun ìmọ́lẹ̀ yìí máa “jẹ́ àmì láti fi mọ àwọn àsìkò, ọjọ́ àti ọdún,” kó lè ṣe àwọn èèyàn láǹfààní.—Jẹ 1:14.
Ní Ọjọ́ Karùn-ún, Ọlọ́run dá àwọn ohun alààyè míì sórí ilẹ̀ ayé. Kì í ṣe ẹyọ kan tó mú onírúurú ohun alààyè míì jáde ni Ọlọ́run dá, kàkà bẹ́ẹ̀ ó dá wọn lónírúurú. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run sì dá àwọn ẹran ńlá inú òkun àti gbogbo ohun alààyè tó ń gbá yìn-ìn nínú omi ní irú tiwọn àti àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ní irú tiwọn.” Nígbà tí Ọlọ́run rí i pé gbogbo ẹ̀ dára, ó súre fún wọn pé ‘kí wọ́n pọ̀.’ Èyí sì rí bẹ́ẹ̀ torí Ọlọ́run tí dá wọn lọ́nà tí wọ́n á fi lè mú “irú tiwọn” jáde.—Jẹ 1:20-23.
Ní Ọjọ́ Kẹfà, “Ọlọ́run dá àwọn ẹran inú igbó ní irú tiwọn àti àwọn ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn àti àwọn ẹran tó ń rákò ní irú tiwọn.” Bíi táwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ yòókù, Ọlọ́run rí i pé ó dára.—Jẹ 1:24, 25.
Nígbà tí ọjọ́ kẹfà ìṣẹ̀dá náà ń lọ sópin, Ọlọ́run dá ohun alààyè kan tó yàtọ̀ sí gbogbo ohun míì tó ti dá. Ẹ̀dá yìí ní làákàyè ju àwọn ẹranko lọ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rẹlẹ̀ sáwọn áńgẹ́lì. Èèyàn ni ẹ̀dá náà, Ọlọ́run sì dá a ní àwòrán rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jẹ́nẹ́sísì 1:27 sọ nípa èèyàn pé “akọ àti abo [ni Ọlọ́run] dá wọn,” àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì 2:7-9 jẹ́ ká rí i pé erùpẹ̀ ni Jèhófà fi dá ọkùnrin náà, ó mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sí di alààyè. Ṣáájú ìgbà yẹn ni Ọlọ́run ti ṣètò Párádísè tó máa gbé àti oúnjẹ tó máa jẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé erùpẹ̀ ni Jèhófà fi dá ọkùnrin náà, ó gbàfiyèsí pé ọ̀kan lára egungun ìhà rẹ̀ ló fi dá obìnrin. (Jẹ 2:18-25) Bí Ọlọ́run ṣe dá obìnrin ló mú kó ṣeé ṣe fún èèyàn láti mú “irú tiwọn” jáde.—Jẹ 5:1, 2.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àǹfààní Tí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ń Ṣe fún Wa
Ìgbà tí ayé àti ìsálú ọ̀run ti wà
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fojú bù ú pé ayé yìí ti wà láti nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́rin ọdún sẹ́yìn. Wọ́n tún sọ pé ìsálú ọ̀run ti wà láti nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́tàlá sí bílíọ̀nù mẹ́rìnlá ọdún sẹ́yìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ ìgbà tí ayé àti ìsálú ọ̀run ti wà, síbẹ̀, kò sí ibi kankan tó ti sọ pé ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan sẹ́yìn ni Ọlọ́run dá ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ ni pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Bí Bíbélì kò ṣe sọ ìgbà kan pàtó tí Ọlọ́run dá ayé yìí ti mú kí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lo ìlànà ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì láti fojú bu ìgbà tí ayé yìí ti wà.
it-2 52
Jésù Kristi
Kì í ṣe Ẹlẹ́dàá pẹ̀lú Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù bá Bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́ nígbà ìṣẹ̀dá, ìyẹn ò sọ òun náà di Ẹlẹ́dàá. Àtọ̀dọ̀ Jèhófà nìkan ni agbára ìṣẹ̀dá ti wá, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ìyẹn agbára ìṣiṣẹ́ rẹ̀ ló sì lò. (Jẹ 1:2; Sm 33:6) Níwọ̀n ìgbà tó sì jẹ́ pé Jèhófà ni orísun ìyè, òun ló fún gbogbo ohun alààyè pátápátá yálà ní ọ̀run tàbí láyé ní ìwàláàyè. (Sm 36:9) Torí náà, dípò kí Jésù jẹ́ Ẹlẹ́dàá pẹ̀lú Bàbá rẹ̀, ṣe ló jẹ́ àgbà òṣìṣẹ́, ìyẹn ẹni tí Jèhófà lò láti dá àwọn nǹkan míì. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan, gbogbo Ìwé Mímọ́ látòkè délẹ̀ ló sì jẹ́rìí sí i.—Mt 19:4-6; wo ÌṢẸ̀DÁ.
Bíbélì Kíkà
JANUARY 13-19
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 3-5
“Àbájáde Irọ́ Àkọ́kọ́”
Ohun Tí Jèhófà Ní Lọ́kàn Máa Ṣẹ!
9 Sátánì Èṣù lo ejò láti mú kí Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà Baba rẹ̀ ọ̀run. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5; Ìṣí. 12:9) Sátánì sọ pé kò yẹ kí Jèhófà sọ fáwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn ò lè jẹ lára èso “gbogbo igi ọgbà”? Ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé: ‘A jẹ́ pé ẹ ò lè ṣe ohun tó wù yín nìyẹn.’ Ó wá gbé irọ́ ńlá kan kalẹ̀, pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.” Ó sì wá bó ṣe máa yí Éfà lọ́kàn pa dà kó lè rú òfin Ọlọ́run, ó ní: “Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là.” Sátánì dọ́gbọ́n sọ pé torí Jèhófà ò fẹ́ kí wọ́n rí ọ̀ọ́kán ló ṣe ní kí wọ́n má jẹ èso náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Sátánì gbé wọn gẹṣin aáyán pé wọn “yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”
A Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Tọkọtaya Ẹ̀dá Ènìyàn Àkọ́kọ́
Ṣé Éfà kò ríbi yẹ ẹ̀ṣẹ̀ yẹn sí ni? Kò sóhun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀! Ìwọ fira ẹ sípò rẹ̀ ná. Ńṣe ni nǹkan tí ejò náà sọ yí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run àti Ádámù ti sọ fún un tẹ́lẹ̀ pa dà. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ, ká ní àjèjì kan fi ẹ̀sùn àìṣòdodo kan ẹnì kàn tó o fẹ́ràn tó o sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹ̀? Kò yẹ kí Éfà hùwà bó ṣe hùwà yẹn rárá, ńṣe ló yẹ kó pa ejò yẹn tì, kó jájú mọ́ ọn, kó má tiẹ̀ tẹ́tí sí ohun tó fẹ́ sọ rárá. Ó ṣe tán, tá ni ejò tó fi máa wá gbé ìbéèrè dìde sí òdodo Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ tí ọkọ rẹ̀ sọ? Ká ní Éfà bọ̀wọ̀ fún ìlànà ipò orí ni, ó yẹ kó kọ́kọ́ béèrè ìmọ̀ràn kó tó di pé ó ṣe ìpinnu èyíkéyìí. Nǹkan tó yẹ kí àwa náà ṣe nìyẹn o, bí ẹnì kan bá gbé ìsọfúnni kan wá bá wa tó ta ko àwọn ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún wa. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ Adẹniwò yẹn ni Éfà gbà gbọ́, ó wù ú láti di onídàájọ́ ara rẹ̀ kó máa dá pinnu ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Bó ṣe ń ronú nípa ọ̀rọ̀ yẹn, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń wù ú. Àṣìṣe ńlá gbáà mà ló ṣe o nípa gbígba èròkérò láàyè, dípò kó yáa mú un kúrò lọ́kàn kíá tàbí kó jíròrò ọ̀ràn ọ̀hún pẹ̀lú olórí ìdílé rẹ̀!—1 Kọ́ríńtì 11:3; Jákọ́bù 1:14, 15.
Ádámù Fetí sí Ohùn Aya Rẹ̀
Láìpẹ́, Éfà mú kí Ádámù dara pọ̀ mọ́ òun nínú ẹ̀ṣẹ̀. Báwo la ṣe fẹ́ ṣàlàyé ọwọ́ dẹngbẹrẹ tí Ádámù fi mú ọ̀rọ̀ yìí? (Jẹ́nẹ́sísì 3:6, 17) Ádámù dojú kọ ìpinnu nípa ti ta ló yẹ kí òun ṣe. Ṣé yóò ṣègbọràn sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ tó fún un ní ohun gbogbo, títí kan olólùfẹ́ rẹ̀, Éfà? Ṣé Ádámù á wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run lórí ohun tó yẹ kó ṣe lórí ọ̀ràn yìí? Àbí ṣe ni ọkùnrin náà máa kúkú dara pọ̀ mọ́ aya rẹ̀? Ádámù mọ̀ pé ẹ̀tàn pátápátá ló wà nídìí ohun tí obìnrin náà ń retí àtirí nípa jíjẹ èso tí a kà léèwọ̀ náà. A mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “A kò tan Ádámù jẹ, ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn jẹ pátápátá, ó sì wá wà nínú ìrélànàkọjá.” (1 Tímótì 2:14) Nítorí náà, Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ yàn láti ṣàìka Jèhófà sí ni. Dájúdájú, ìbẹ̀rù Ádámù pé kóun máà wá dẹni tá a yà kúrò lọ́dọ̀ ìyàwó òun ju ìgbàgbọ́ rẹ̀ pé Ọlọ́run lè ṣe nǹkankan láti yanjú ìṣòro náà lọ.
Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin Tiẹ̀ Jẹ Ọlọ́run Lógún?
Ṣé Ọlọ́run gégùn-ún fún àwọn obìnrin ni?
Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù” ni Ọlọ́run gé “ègún” fún. (Ìṣípayá 12:9; Jẹ́nẹ́sísì 3:14) Nígbà tí Ọlọ́run sọ pé Ádámù yóò “jọba lé” ìyàwó rẹ̀ lórí, kì í ṣe pé ó ń fi hàn pé òun fọwọ́ sí bí àwọn ọkùnrin ṣe ń tẹ àwọn obìnrin lórí ba. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) Ṣe ló kàn ń sọ àkóbá tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ṣe fún tọkọtaya àkọ́kọ́ yẹn.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì—Apá Kìíní
3:17—Kí ni fífi tí Ọlọ́run fi ilẹ̀ gégùn-ún túmọ̀ sí, ègún yìí sì wà títí dìgbà wo? Fífi tí Ọlọ́run fi ilẹ̀ gégùn-ún túmọ̀ sí pé iṣẹ́ àṣekára lèèyàn yóò máa ṣe kó tó lè rí nǹkan kórè látinú rẹ̀. Àkóbá tí ilẹ̀ tá a fi gégùn-ún àti ẹ̀gún òun òṣùṣú rẹ̀ ṣe fún àtọmọdọ́mọ Ádámù pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Lámékì bàbá Nóà fi sọ̀rọ̀ débi “ìrora ọwọ́ wa tí ó jẹ́ àbáyọrí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fi gégùn-ún.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:29) Lẹ́yìn Ìkún Omi, Jèhófà súre fún Nóà àtàwọn ọmọ rẹ̀, ó sì sọ ète rẹ̀ pé kí wọ́n kún ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 9:1) Ó jọ pé Ọlọ́run tipa báyìí mú ègún rẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 13:10.
it-2 186
Ìrora Ìrọbí
Ìrora táwọn obìnrin máa ń ní tí wọ́n bá fẹ́ bímọ. Lẹ́yìn tí Éfà obìnrin àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run sọ pé lára ohun tó máa jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ náà ni pé á máa ní ìrora tó bá fẹ́ bímọ. Ká sọ pé ó ṣègbọràn ni, á máa gbádùn ìbùkún Jèhófà títí láé, kò sì ní ní ìrora kankan tó bá fẹ́ bímọ torí pé, “ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” (Owe 10:22) Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ báyìí, torí pé ó ti di aláìpé, á máa ní ìrora tó bá fẹ́ bímọ. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi sọ pé (Bíbélì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run fàyè gbà bíi pé òun gan-an ló ṣe é): “Èmi yóò mú kí ìrora rẹ pọ̀ gan-an tí o bá lóyún; inú ìrora ni wàá ti máa bímọ.”—Jẹ 3:16.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 192 ¶5
Lámékì
Ewì tí Lámékì kọ fáwọn ìyàwó rẹ̀ (Jẹ 4:23, 24) jẹ́ ká rí bí ìwà ipá ṣe gbòde kan nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Lámékì sọ pé: “Ẹ gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin ìyàwó Lámékì; Ẹ fetí sí mi: Mo pa ọkùnrin kan torí ó ṣe mí léṣe, àní ọ̀dọ́kùnrin kan, torí ó lù mí. Tí ẹni tó bá pa Kéènì bá máa jìyà ní ìlọ́po méje, ẹni tó bá pa Lámékì máa jìyà ní ìgbà àádọ́rin ó lé méje (77).” Ó jọ pé ṣe ni Lámékì ń dá ara ẹ̀ láre pé òun kì í ṣe apààyàn bíi ti Kéènì, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe lòun gbèjà ara òun. Lámékì sọ pé níbi tóun ti ń gbìyànjú láti gbèjà ara òun lòun ti pa ọkùnrin kan tó ṣe òun léṣe. Torí náà, ó kéwì yìí kó lè jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé òun ò jẹ̀bi àti pé kò yẹ kí ẹnikẹ́ni gbẹ̀san lára òun.
it-1 338 ¶2
Ìsọ̀rọ̀ Òdì
Nígbà ayé Énọ́ṣì, ìyẹn ṣáájú Ìkún-Omi, “àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Jèhófà.” Àmọ́ kò jọ pé ọ̀nà tó tọ́ ni wọ́n ń gbà lo orúkọ yẹn torí pé tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà yẹn ni Ébẹ́lì ti ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. (Jẹ 4:26; Heb 11:4) Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ṣe làwọn èèyàn ìgbà yẹn ń lo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí kò tọ́, tí wọ́n sì ń fi orúkọ Jèhófà pe èèyàn tàbí àwọn òrìṣà míì. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, á jẹ́ pé ṣe làwọn èèyàn yẹn ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run.—Wo ÉNỌ́ṢÌ.
Bíbélì Kíkà
JANUARY 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 6-8
“Ó Ṣe Bẹ́ẹ̀ Gẹ́lẹ́”
Jẹ́ Onígbọràn Kó O sì Nígbàgbọ́ Bíi Ti Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù
4 Àwọn ìṣòro tí Nóà kojú. Nígbà ayé Énọ́kù baba ńlá Nóà, ìwà àwọn èèyàn ti burú kọjá àfẹnusọ. Kódà, wọ́n ń sọ àwọn “ohun amúnigbọ̀nrìrì” lòdì sí Jèhófà. (Júúdà 14, 15) Ojoojúmọ́ ni ìwà ipá wọn ń peléke sí i. Kódà nígbà tó máa fi di ìgbà ayé Nóà, ‘ilẹ̀ ayé ti kún fún ìwà ipá.’ Àwọn áńgẹ́lì búburú kan para dà di èèyàn, wọ́n fẹ́ ìyàwó, wọ́n sì bí àwọn àdàmọ̀dì ọmọ tó jẹ́ oníwà ipá. (Jẹ́n. 6:2-4, 11, 12) Àmọ́ Nóà yàtọ̀ sí wọn ní tiẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Nóà rí ojú rere ní ojú Jèhófà. . . . Ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀. Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.”—Jẹ́n. 6:8, 9.
Ó “Bá Ọlọ́run Tòótọ́ Rìn”
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni iṣẹ́ náà gbà, ó ṣeé ṣe kó tó ogójì sí àádọ́ta ọdún kó tó parí. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ igi ńlá ni wọ́n máa ní láti gé lulẹ̀, wọ́n á wọ́ wọn lọ sí ibi tí wọ́n ti máa lò ó, wọ́n á là wọ́n, wọ́n á gé wọn sí ìwọ̀n tó yẹ, wọ́n á wá kàn wọ́n pa pọ̀. Áàkì náà yóò ní àjà mẹ́ta àti àwọn yàrá bíi mélòó kan, yóò sì ní ilẹ̀kùn kan ní ẹ̀gbẹ́. Ẹ̀rí fi hàn pé apá òkè ni àwọn fèrèsé áàkì náà máa wà, ó sì jọ pé orí rẹ̀ lókè máa dagun síhà méjèèjì láti àárín kó lè dami nù.—Jẹ́nẹ́sísì 6:14-16.
Ẹ Fi Ìfaradà Sá Eré Ìje Náà
13 Kí ló mú káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yìí fara dà á tí wọ́n fi kẹ́sẹ járí nínú eré ìje náà? Kíyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa Nóà. (Ka Hébérù 11:7.) Nóà ‘kò tíì rí àkúnya omi tó máa wá sórí ilẹ̀ ayé láti run gbogbo ẹran ara.’ (Jẹ́n. 6:17) Irú rẹ̀ kò tíì wáyé rí, kò sì tíì fìgbà kan ṣẹlẹ̀ rí. Síbẹ̀, Nóà kò ṣàì ka ọ̀rọ̀ náà sí kó wá máa rò pé irú rẹ̀ kò lè ṣeé ṣe tàbí pé kò tiẹ̀ jẹ́ wáyé. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó gbà gbọ́ pé ohunkóhun tí Jèhófà bá sọ, ni Jèhófà máa ṣe. Nóà kò wo ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe bí èyí tó ṣòro jù. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́n. 6:22) Bá a bá ronú lórí gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run sọ pé kí Nóà ṣe, a óò rí i pé kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá. Ọlọ́run ní kó kan ọkọ̀ áàkì, kí ó kó àwọn ẹran jọ, kí ó kó oúnjẹ tí àwọn ẹran àtàwọn èèyàn máa jẹ sínú ọkọ̀ náà, kó wàásù láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn, kó sì tún mú kí ìdílé rẹ̀ lókun nípa tẹ̀mí. “Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ Nóà àti ìfaradà rẹ̀ yọrí sí ìyè àti ìbùkún fún òun àti ìdílé rẹ̀.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì—Apá Kìíní
7:2—Kí ni wọ́n fi ń mọ àwọn ẹranko tó mọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí kò mọ́? Ẹ̀rí fi hàn pé kì í ṣe ọ̀ràn pé ẹran kan la lè jẹ, ọ̀kan la ò lè jẹ ni wọ́n fi ń mọ̀ wọ́n yàtọ̀. Bóyá ẹran náà ṣeé lò fún ẹbọ rírú nínú ìjọsìn tàbí kò ṣeé lò ni wọ́n fi ń mọ̀ wọ́n. Ṣáájú Ìkún Omi, ẹran kò sí lára oúnjẹ tọmọ èèyàn ń jẹ. Òfin Mósè ló dá ọ̀ràn pé oúnjẹ kan ló “mọ́” tí òmíràn sì jẹ́ “aláìmọ́” sílẹ̀, ìyẹn sì ti kásẹ̀ nílẹ̀ nígbà tá a mú Òfin yẹn kúrò. (Ìṣe 10:9-16; Éfésù 2:15) Ẹ̀rí fi hàn pé Nóà mọ ohun tó yẹ fún ẹbọ rírú nínú ìjọsìn Jèhófà. Gbàrà tó jáde kúrò nínú ọkọ̀ áàkì, ó “bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ pẹpẹ kan fún Jèhófà, ó sì mú díẹ̀ lára gbogbo ẹranko tí ó mọ́ àti lára gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń fò tí ó mọ́, ó sì rú ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ náà.”—Jẹ́nẹ́sísì 8:20.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì—Apá Kìíní
7:11—Ibo ni omi tó fa Ìkún Omi kárí ayé ti wá? Ní sáà iṣẹ́ ìṣẹ̀dá, tàbí “ọjọ́” ìṣẹ̀dá kejì, tí Ọlọ́run ṣe “òfuurufú” ti ayé, omi wà “lábẹ́ òfuurufú” yìí, omi sì wà “lókè òfuurufú” yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:6, 7) Omi tó wà “lábẹ́” òfuurufú yìí ni omi tó ti wà lórí ilẹ̀ ayé tẹ́lẹ̀. Omi tó wà “lókè” òfuurufú ni ọ̀rinrin tó lọ salalu tí Ọlọ́run so rọ̀ sójú sánmà, tó wá di “alagbalúgbú ibú omi.” Alagbalúgbú omi yìí ló ya lu ayé nígbà ọjọ́ Nóà.
Bíbélì Kíkà
JANUARY 27–FEBRUARY 2
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 9-11
“Èdè Kan Ni Gbogbo Ayé Ń Sọ”
it-1 239
Bábílónì Ńlá
Bábílónì Àtijọ́. Àwọn tó tẹ ìlú Bábílónì tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣínárì dó ló bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Ilé Gogoro Bábélì. (Jẹ 11:2-9) Ìdí tí wọ́n sì fi ń kọ́ ọ kì í ṣe láti gbé orúkọ Ọlọ́run ga, àmọ́ wọ́n ń kọ́ ọ láti ṣe orúkọ tó “lókìkí” fún ara wọn. Àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí àwọn ilé gogoro tó jẹ́ tẹ́ńpìlì òrìṣà ní àwókù ìlú Bábílónì àtijọ́ àti láwọn ibòmíì ní agbègbè Mesopotámíà, èyí sì jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé ìjọsìn èké ni wọ́n fẹ́ gbé lárugẹ ni Ilé Gogoro Bábélì tí wọ́n ń kọ́ nígbà yẹn. Bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe dáwọ́ iṣẹ́ ìkọ́lé náà dúró tún jẹ́ kó hàn gbangba pé ẹ̀sìn èké ni wọ́n fi ń gbé lárugẹ. Orúkọ tí wọ́n fún ìlú yẹn lédè Hébérù ni Bábélì tó túmọ̀ sí “Ìdàrúdàpọ̀,” àmọ́ orúkọ tí wọ́n fún un ní èdè Sumerian ni (Ka-dingir-ra) wọ́n sì ń pè ní (Bab-ilu) lédè Akkiadian. Ohun tí orúkọ méjèèjì yìí túmọ̀ sí ni “Ẹnubodè Ọlọ́run.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń gbé ìlú náà yí orúkọ rẹ̀ pa dà káwọn èèyàn má bàa fojú burúkú wò ó, síbẹ̀ orúkọ tí wọ́n fún un ṣì fi hàn pé ìbọ̀rìṣà ló gbilẹ̀ nílùú náà.
it-2 202 ¶2
Èdè
Àkọsílẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ká mọ̀ pé lẹ́yìn Ìkún Omi, àwọn kan kóra jọ láti kọ́ ilé kan tó ta ko ohun tí Jèhófà sọ fún Nóà àtàwọn ọmọ rẹ̀. (Jẹ 9:1) Dípò kí wọ́n tàn ká, kí wọ́n sì “kún ayé,” ṣe làwọn yìí pinnu láti kó gbogbo èèyàn jọ sójú kan, kí wọ́n sì tẹ ìlú kan dó ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣínárì tó wà ní agbègbè Mesopotámíà. Kò sí àní-àní pé ìjọsìn èké ni wọ́n fẹ́ máa gbé lárugẹ níbẹ̀, torí wọ́n pinnu láti kọ́ ilé gogoro kan tó jẹ́ tẹ́ńpìlì síbẹ̀.—Jẹ 11:2-4.
it-2 202 ¶3
Èdè
Jèhófà Ọlọ́run dá iṣẹ́ ìkọ́lé yìí dúró, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó da èdè wọn rú. Bí èdè wọn ṣe dàrú yìí mú kó ṣòro fún wọn láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kọ́ ilé náà, èyí sì mú kí wọ́n fọ́n káàkiri gbogbo ayé. Ó tún máa mú kó ṣòro fún wọn láti pawọ́ pọ̀ ṣe àwọn nǹkan burúkú lọ́jọ́ iwájú. Ìdí ni pé èrò wọn ò ní lè ṣọ̀kan, wọn ò ní lè ṣe ara wọn lóṣùṣù ọwọ̀, kí wọ́n sì lo ẹ̀bùn àti ìmọ̀ tí kálukú wọn ti kó jọ nípasẹ̀ ìwádìí àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí láti ṣe àwọn nǹkan tó ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run. (Fi wé Onw 7:29; Di 32:5.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè tó dàrú yìí mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti wà níṣọ̀kan, síbẹ̀ ó ṣe wá láǹfààní ní ti pé, kò jẹ́ káwọn èèyàn lè pawọ́ pọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ láabi tó ṣeé ṣe kó ti bá ayé yìí jẹ́ gan-an. (Jẹ 11:5-9; fi wé Ais 8:9, 10.) Tá a bá sì wo nǹkan burúkú táwọn èèyàn ń dán wò lákòókò yìí pẹ̀lú ìmọ̀ tí wọ́n ti kó jọ, àá túbọ̀ lóye ohun tó ṣeé ṣe kí Jèhófà rí tó fi da èdè àwọn èèyàn rú ní Bábélì. Ká sọ pé Jèhófà ò ṣe bẹ́ẹ̀ ni, ta ló mọ ohun táwọn èèyàn ò bá ti sọ ayé yìí dà.
it-2 472
Orílẹ̀-Èdè
Àtìgbà tí èdè àwọn èèyàn ti dàrú ni àwùjọ àwọn tó ń sọ èdè kan náà ti ní àṣà àti ẹ̀sìn tiwọn, kódà báwọn tó ń sọ onírúurú èdè ṣe ń ṣe nǹkan yàtọ̀ síra. (Le 18:3) Ní báyìí tí wọ́n ti jìnnà sí Ọlọ́run, kálukú wọn bẹ̀rẹ̀ sí í bọ àwọn òrìṣà tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ alágbára.—Di 12:30; 2Ọb 17:29, 33.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 1023 ¶4
Hámù
Ó ṣeé ṣe kí Kénáánì rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Nóà tó jẹ́ bàbá bàbá rẹ̀, àmọ́ kí Hámù tó jẹ́ bàbá ẹ̀ kọ̀ láti bá a wí. Ó sì lè jẹ́ torí ìwà burúkú Hámù tó ti ń kéèràn ran Kénáánì ọmọ rẹ̀, tí ìwàkiwà yìí sì tún máa fara hàn kedere lára àtọmọdọ́mọ Kénáánì ni Ọlọ́run fi mísí Nóà láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Ègún yìí kọ́kọ́ ṣẹ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn tí wọn ò sì pa run dẹrú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (àpẹẹrẹ kan làwọn ará Gíbéónì [Jos 9]). Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ègún yìí tún ṣẹ nígbà táwọn àtọmọdọ́mọ Kénáánì ọmọ Hámù bọ́ sábẹ́ àkóso Mídíà àti Páṣíà, Gíríìsì àti Róòmù tí gbogbo wọn jẹ́ àtọmọdọ́mọ Jáfẹ́tì.
it-2 503
Nímírọ́dù
Nímírọ́dù ló ń ṣàkóso ìlú Bábélì, Érékì, Ákádì, àti Kálínè, ti gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣínárì. (Jẹ 10:10) Torí náà ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló pàṣẹ fáwọn èèyàn láti kọ́ ilé gogoro Bábélì. Ọ̀rọ̀ yìí sì bá ohun táwọn òpìtàn Júù sọ mu. Bí àpẹẹrẹ, òpìtàn Júù kan tó ń jẹ́ Josephus sọ pé: “Díẹ̀díẹ̀ ni [Nímírọ́dù] sọ ara rẹ̀ di apàṣẹwàá, ó sì ń sọ pé ọ̀nà kan ṣoṣo táwọn èèyàn fi lè bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni kí òun máa darí wọn. Ó lérí pé òun máa gbẹ̀san àwọn baba ńlá wọn tó bá ìkún omi lọ tí Ọlọ́run bá tún gbìyànjú ẹ̀ láé láti fi omi pa àwọn èèyàn. Ó wá pinnu láti kọ́ ilé kan tó máa ga débi tí omi ò fi ní lè bò ó mọ́lẹ̀. Ó wu àwọn èèyàn náà láti tẹ̀ lẹ́ ohun tí [Nímírọ́dù] sọ torí wọ́n gbà pé ìyẹn máa ṣàǹfààní fún wọn ju kí wọ́n wà lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé náà . . . iṣẹ́ ilé náà sì yá ju bí ẹnikẹ́ni ṣẹ rò lọ.”—Jewish Antiquities, I, 114, 115 (iv, 2, 3).
Bíbélì Kíkà