Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì—Apá Kìíní
“JẸ́NẸ́SÍSÌ” túmọ̀ sí “ìpilẹ̀ṣẹ̀” tàbí “ìbí.” Ohun tó sì yẹ ká pe ìwé yìí náà nìyẹn, ìwé tó sọ ìtàn bí ayé àtọ̀run ṣe wáyé, bí a ṣe ṣètò ilẹ̀ ayé kó lè ṣeé gbé fún ọmọ èèyàn àti bó ṣe di pé ọmọ èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí gbé ayé. Aginjù Sínáì ni Mósè ti kọ ìwé yìí, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa ló kọ ọ́ parí.
Ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ fún wa nípa ipò tí ayé wà ṣáájú Ìkún Omi, ohun tó ṣẹlẹ̀ ní kété lẹ́yìn Ìkún Omi àti àjọṣe Jèhófà Ọlọ́run pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù àti Jósẹ́fù. Àpilẹ̀kọ yìí yóò dá lórí àwọn kókó pàtàkì látinú Jẹ́nẹ́sísì 1:1–11:9, yóò sì parí sí ìgbà tí àjọṣe Jèhófà àti Ábúráhámù baba ńlá bẹ̀rẹ̀.
AYÉ TÓ WÀ ṢÁÁJÚ ÌKÚN OMI
Gbólóhùn náà, “ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì mú òye wa padà sí ọ̀kẹ́ lọ́nà ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún sẹ́yìn. Ìwé yìí ṣàpèjúwe iṣẹ́ ìṣẹ̀dá gẹ́lẹ́ bó ṣe máa rí lójú ọmọ ènìyàn ká ní pé onítọ̀hún wà nínú ayé tó ń wo bí gbogbo rẹ̀ ṣe ń ṣẹlẹ̀ láàárín “ọjọ́” mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ti ìṣẹ̀dá, ìyẹn àwọn sáà tá a ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìṣẹ̀dá. Apá ìparí ọjọ́ kẹ́fà ni Ọlọ́run dá ènìyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ èèyàn pàdánù Párádísè nítorí àìgbọràn, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọjọ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dára. Àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ pàá nínú Bíbélì sọ nípa “irú-ọmọ” kan tí yóò ṣàtúnṣe gbogbo wàhálà tí ẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀, tí yóò sì pa Sátánì ní orí.
Gbogbo èèyàn tó ń bẹ láyé láàárín ọ̀rúndún mẹ́rìndínlógún lẹ́yìn ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ni Sátánì mú kẹ̀yìn sí Ọlọ́run àyàfi àwọn olóòótọ́ bíi mélòó kan bíi Ébẹ́lì, Énọ́kù àti Nóà. Bí àpẹẹrẹ, Kéènì pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀ olódodo. Bẹ́ẹ̀ ló di pé àwọn èèyàn “bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ Jèhófà” lọ́nà àìmọ́. Lámékì kọ orin ewì kan nípa pípa tó pa ọ̀dọ́mọkùnrin kan, ó lòun gbẹ̀mí ẹ̀ láti lè dáàbò bo ara òun, èyí tó fi irú ìwà táwọn èèyàn ń hù láyé ìgbà náà hàn. Ayé túbọ̀ wá burú sí i bí àwọn áńgẹ́lì ọmọ Ọlọ́run tó ya aláìgbọràn ṣe ń fẹ́ àwọn obìnrin tí wọ́n wá ń bí àwọn jàgídíjàgan òmìrán tá à ń pè ní Néfílímù. Síbẹ̀, Nóà olóòótọ́ kan ọkọ̀ áàkì, ó fi ìgboyà kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa Àkúnya Omi tó ń bọ̀, òun àti ìdílé rẹ̀ sì la Àkúnya Omi náà já.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
1:16—Báwo ni Ọlọ́run ṣe mú kí ìmọ́lẹ̀ wà lọ́jọ́ kìíní nígbà tó jẹ́ pé ọjọ́ kẹrin ló tó ṣe àwọn ohun atànmọ́lẹ̀? Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “ṣe” ní ẹsẹ kẹrìndínlógún yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n lò nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní, ẹsẹ kìíní, ìkọkànlélógún àti ìkẹtàdínlọ́gbọ̀n tá a tú sí “dá.” Ọlọ́run ti dá “ọ̀run” àtàwọn ohun atànmọ́lẹ̀ inú rẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí “ọjọ́ kìíní” tó tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pàápàá. Ṣùgbọ́n ìmọ́lẹ̀ wọn kò dé orí ilẹ̀ ayé. “Ìmọ́lẹ̀ wá wà” lọ́jọ́ kìíní nítorí pé fìrífìrí ìmọ́lẹ̀ ń gba inú ìkuukùu tó jẹ́ abala-abala kọjá, tí a sì wá ń rí i lórí ilẹ̀ ayé wàyí. Bí ayé tó ń yí bírí ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní ọ̀sán àti òru nìyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1-3, 5) Àmọ́ a ò tíì lè rí àwọn orísun ìmọ́lẹ̀ yẹn nínú ayé. Ṣùgbọ́n, ní sáà kẹrin iṣẹ́ ìṣẹ̀dá, àyípadà pàtàkì dé. Ọlọ́run mú kí oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ máa “tàn sórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:17) “Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí ṣe” wọ́n ní ti pé à ń rí wọn láti orí ilẹ̀ ayé wàyí.
3:8—Ǹjẹ́ Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ bá Ádámù sọ̀rọ̀ ní tààràtà? Bíbélì fi hàn pé láwọn ìgbà tí Ọlọ́run bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, áńgẹ́lì ló sábà máa ń lò láti fi bá wọn sọ̀rọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 16:7-11; 18:1-3, 22-26; 19:1; Àwọn Onídàájọ́ 2:1-4; 6:11-16, 22; 13:15-22) Ẹni tó jẹ́ olórí agbọ̀rọ̀sọ Ọlọ́run ni Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo tá a pè ní “Ọ̀rọ̀.” (Jòhánù 1:1) Ó ṣeé ṣe pé “Ọ̀rọ̀” yìí ni Ọlọ́run gbẹnu rẹ̀ bá Ádámù àti Éfà sọ̀rọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; 2:16; 3:8-13.
3:17—Kí ni fífi tí Ọlọ́run fi ilẹ̀ gégùn-ún túmọ̀ sí, ègún yìí sì wà títí dìgbà wo? Fífi tí Ọlọ́run fi ilẹ̀ gégùn-ún túmọ̀ sí pé iṣẹ́ àṣekára lèèyàn yóò máa ṣe kó tó lè rí nǹkan kórè látinú rẹ̀. Àkóbá tí ilẹ̀ tá a fi gégùn-ún àti ẹ̀gún òun òṣùṣú rẹ̀ ṣe fún àtọmọdọ́mọ Ádámù pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Lámékì bàbá Nóà fi sọ̀rọ̀ débi “ìrora ọwọ́ wa tí ó jẹ́ àbáyọrí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fi gégùn-ún.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:29) Lẹ́yìn Ìkún Omi, Jèhófà súre fún Nóà àtàwọn ọmọ rẹ̀, ó sì sọ ète rẹ̀ pé kí wọ́n kún ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 9:1) Ó jọ pé Ọlọ́run tipa báyìí mú ègún rẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 13:10.
4:15—Báwo ni Jèhófà ṣe “ṣe àmì kan nítorí Kéènì”? Bíbélì ti èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ kò sọ pé Ọlọ́run ṣe àmì tàbí pé ó fi àmì kankan sí Kéènì lára rárá. Ó jọ pé òfin ìkàléèwọ̀ kan táwọn èèyàn mọ̀ tí wọ́n sì ń pa mọ́ ni àmì yìí, èyí tó jẹ́ pé a ṣe torí kí wọ́n má bàa pa Kéènì láti gbẹ̀san.
4:17—Ibo ni Kéènì ti rí aya fẹ́? Ádámù “bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:4) Nítorí náà, ọ̀kan lára àwọn àbúrò Kéènì tàbí ọmọ àbúrò rẹ̀ ló fi ṣaya. Nígbà tó yá, Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò kò gbọ́dọ̀ fẹ́ra wọn mọ́.—Léfítíkù 18:9.
5:24—Lọ́nà wo ni Ọlọ́run gbà ‘mú Énọ́kù lọ’? Ó jọ pé ẹ̀mí Énọ́kù wà nínú ewu, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ò jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ rí i fìyà jẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “A ṣí Énọ́kù nípò padà láti má ṣe rí ikú.” (Hébérù 11:5) Èyí ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run mú un lọ sí ọ̀run kó máa gbé níbẹ̀ o. Nítorí Jésù lẹni àkọ́kọ́ tó gòkè re ọ̀run. (Jòhánù 3:13; Hébérù 6:19, 20) Ṣíṣí tá a “ṣí Énọ́kù nípò padà kí ó má ṣe rí ikú” lè túmọ̀ sí pé Ọlọ́run mú kó wà lójú ìran alásọtẹ́lẹ̀, ó sì mú kí ó kú látojú ìran yìí. Nírú ipò bẹ́ẹ̀, Énọ́kù kò jìyà, kò sì “rí ikú” látọwọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
6:6—Lọ́nà wo la fi lè sọ pé Jèhófà “kẹ́dùn” pé òun dá ènìyàn? Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tá a tú sí “kẹ́dùn” níhìn-ín jẹ mọ́ yíyí ìṣe ẹni tàbí ohun téèyàn gbèrò láti ṣe padà. Ẹni pípé ni Jèhófà, nítorí náà kò ṣàṣìṣe bó ṣe dá èèyàn. Ṣùgbọ́n ó kanlẹ̀ yí èrò ọkàn rẹ̀ padà nípa ìran búburú tó wà láyé ṣáájú Ìkún Omi. Ọlọ́run yí ìṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá èèyàn padà, ó wá dẹni tó ń pa wọ́n nítorí pé inú rẹ̀ kò dùn sí ìwà burúkú wọn. Dídá tó dá àwọn kan sí fi hàn pé àwọn tó ya ẹni ibi yìí ló fà á tó fi ń kẹ́dùn.—2 Pétérù 2:5, 9.
7:2—Kí ni wọ́n fi ń mọ àwọn ẹranko tó mọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí kò mọ́? Ẹ̀rí fi hàn pé kì í ṣe ọ̀ràn pé ẹran kan la lè jẹ, ọ̀kan la ò lè jẹ ni wọ́n fi ń mọ̀ wọ́n yàtọ̀. Bóyá ẹran náà ṣeé lò fún ẹbọ rírú nínú ìjọsìn tàbí kò ṣeé lò ni wọ́n fi ń mọ̀ wọ́n. Ṣáájú Ìkún Omi, ẹran kò sí lára oúnjẹ tọmọ èèyàn ń jẹ. Òfin Mósè ló dá ọ̀ràn pé oúnjẹ kan ló “mọ́” tí òmíràn sì jẹ́ “aláìmọ́” sílẹ̀, ìyẹn sì ti kásẹ̀ nílẹ̀ nígbà tá a mú Òfin yẹn kúrò. (Ìṣe 10:9-16; Éfésù 2:15) Ẹ̀rí fi hàn pé Nóà mọ ohun tó yẹ fún ẹbọ rírú nínú ìjọsìn Jèhófà. Gbàrà tó jáde kúrò nínú ọkọ̀ áàkì, ó “bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ pẹpẹ kan fún Jèhófà, ó sì mú díẹ̀ lára gbogbo ẹranko tí ó mọ́ àti lára gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń fò tí ó mọ́, ó sì rú ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ náà.”—Jẹ́nẹ́sísì 8:20.
7:11—Ibo ni omi tó fa Ìkún Omi kárí ayé ti wá? Ní sáà iṣẹ́ ìṣẹ̀dá, tàbí “ọjọ́” ìṣẹ̀dá kejì, tí Ọlọ́run ṣe “òfuurufú” ti ayé, omi wà “lábẹ́ òfuurufú” yìí, omi sì wà “lókè òfuurufú” yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:6, 7) Omi tó wà “lábẹ́” òfuurufú yìí ni omi tó ti wà lórí ilẹ̀ ayé tẹ́lẹ̀. Omi tó wà “lókè” òfuurufú ni ọ̀rinrin tó lọ salalu tí Ọlọ́run so rọ̀ sójú sánmà, tó wá di “alagbalúgbú ibú omi.” Alagbalúgbú omi yìí ló ya lu ayé nígbà ọjọ́ Nóà.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
1:26. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwòrán Ọlọ́run ni a dá ènìyàn, ẹ̀dá ènìyàn lè gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ. Láìsí àní-àní, ó yẹ ká sapá láti ní àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, àánú, inú rere, ìwà rere àti sùúrù, ká fìwà jọ Ọlọ́run tó dá wa.
2:22-24. Ọlọ́run ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀. Ìdè ìgbéyàwó jẹ́ ìdè tó ń wà títí gbére, ó jẹ́ ohun ọ̀wọ̀, ọkọ sì ni olórí ìdílé.
3:1-5, 16-23. Bá a bá fẹ́ jẹ́ aláyọ̀, a gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù Jèhófà ní ìgbésí ayé wa nítorí pé òun ni ọba aláṣẹ.
3:18, 19; 5:5; 6:7; 7:23. Ọ̀rọ̀ Jèhófà kò lè ṣaláìṣẹ.
4:3-7. Inú Jèhófà dùn sí ẹbọ Ébẹ́lì nítorí pé ó jẹ́ olódodo, ẹni ìgbàgbọ́. (Hébérù 11:4) Àmọ́ ní ti Kéènì, ìwà rẹ̀ fi hàn pé ó jẹ́ aláìnígbàgbọ́. Iṣẹ́ tirẹ̀ burú, ó jẹ́ òjòwú, ẹlẹ́mìí ìkórìíra àti apànìyàn. (1 Jòhánù 3:12) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó jọ pé kò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ ronú nípa ẹbọ tó ń rú, ó kàn sáà rú ẹbọ lásán ni láìfọkàn sí i. Nígbà náà, ǹjẹ́ kò yẹ kí àwọn ẹbọ ìyìn wa sí Jèhófà jẹ́ èyí tá à ń ṣe tọkàntọkàn, kí ìwà àti ìṣe wa sì jẹ́ èyí tó tọ́ àtèyí tó yẹ?
6:22. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí Nóà tó kan ọkọ̀ áàkì tán, ohun tí Ọlọ́run ní kí Nóà ṣe náà ló ṣe gẹ́lẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run dá ẹ̀mí Nóà àti ìdílé rẹ̀ sí nígbà Àkúnya Omi yẹn. Jèhófà ń tipa àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá wa sọ̀rọ̀, ó sì ń tipa ètò àjọ rẹ̀ fún wa nítọ̀ọ́ni. Nítorí náà, fún ire ara wa, ó yẹ ká máa fetí sílẹ̀ ká sì máa ṣègbọràn.
7:21-24. Jèhófà kì í pa olódodo run pọ̀ mọ́ àwọn ẹni burúkú.
ARÁYÉ WỌ SÀNMÁNÌ TUNTUN
Bí ayé tó wà ṣáájú Ìkún Omi ṣe pa run, aráyé wọ sànmánì tuntun. Ọlọ́run yọ̀ǹda pé kéèyàn máa jẹ ẹran, àmọ́ ó fòfin de jíjẹ ẹ̀jẹ̀. Jèhófà fàṣẹ sí pípa apànìyàn, ó dá májẹ̀mú òṣùmàrè, ó sì ṣèlérí pé òun ò ní mú Àkúnya Omi wá mọ́. Àwọn ọmọ Nóà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta di orírun tàbí baba ńlá gbogbo ẹ̀dá ènìyàn, ṣùgbọ́n Nímírọ́dù ọmọ-ọmọ Nóà di “ọdẹ alágbára ńlá ní ìlòdì sí Jèhófà.” Dípò kí àwọn èèyàn tàn kálẹ̀ kí wọ́n tẹ̀ dó káàkiri ayé, wọ́n pinnu láti kọ́ ìlú ńlá kan tó ń jẹ́ Bábélì àti ilé gogoro kan pẹ̀lú, láti lè ṣe orúkọ olókìkí fún ara wọn. Ète wọn wọmi nígbà tí Jèhófà da èdè wọn rú, tó sì tú gbogbo wọn ká orí ilẹ̀ ayé.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
8:11—Bí Ìkún Omi bá pa àwọn igi run, ibo ni àdàbà náà ti rí ewé ólífì? Ó lè tipa ọ̀kan nínú ọ̀nà méjì yìí rí i. Níwọ̀n bí ólífì ti jẹ́ igi tí ẹ̀mí rẹ̀ yi, ó ṣeé ṣe kó wà lábẹ́ omi láìkú fún oṣù mélòó kan nígbà Àkúnya Omi. Nígbà tí ìkún omi náà wá fà, igi ólífì tí omi ti bò tẹ́lẹ̀ yìí á tún di èyí tó padà wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, á sì padà rúwé. Ó sì tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ara ólífì tó lalẹ̀ hù lẹ́yìn tí ìkún omi fà ni àdàbà náà ti já ewé wá fún Nóà.
9:20-25—Kí nìdí tí Nóà fi fi Kénáánì gégùn-ún? Ó lè jẹ́ pé Kénáánì hu ìwà àrífín tàbí ìwà ọ̀yájú kan sí Nóà, bàbá bàbá rẹ̀. Hámù, bàbá Kénáánì sì lè rí èyí kò má ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ tó tún ń sọ ọ́ kiri. Àmọ́ àwọn ọmọ Nóà méjì yòókù, Ṣémù òun Jáfẹ́tì, gbéra kánmọ́ wọ́n sì bo bàbá wọn láṣìírí. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ gba ìre, ṣùgbọ́n Kénáánì forí gba ègún, ìyà sì jẹ Hámù nítorí bá a ṣe dójú ti ọmọ rẹ̀.
10:25—Báwo la ṣe “pín ilẹ̀ ayé níyà” lọ́jọ́ Pélégì? Ọdún 2269 sí 2030 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Pélégì gbé láyé. “Ọjọ́ rẹ̀” ni Jèhófà mú kí ìpínyà ńlá wáyé ní ti pé ó da èdè àwọn tó ń kọ́ ìlú Bábélì rú, ó sì tú wọn ká gbogbo orí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 11:9) Bí a ṣe “pín ilẹ̀ ayé [tàbí àwọn èèyàn ayé] níyà” lọ́jọ́ Pélégì nìyẹn.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
9:1; 11:9. Kò sí ètekéte tàbí ìsapá yòówù kéèyàn ṣe tó lè dojú ète Jèhófà dé.
10:1-32. Àkọọ́lẹ̀ ìtàn ìran méjì tá a kọ sínú Bíbélì nípa Ìkún Omi, ọ̀kan ṣáájú Ìkún Omi, ìyẹn orí kárùn-ún, ìkejì lẹ́yìn Ìkún Omi, ìyẹn orí kẹwàá, fi hàn pé ọ̀dọ̀ Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ ni gbogbo èèyàn ti wá nípasẹ̀ ọmọ mẹ́ta tí Nóà bí. Àwọn ará Ásíríà, ará Kálídíà, àwọn Hébérù, àwọn ará Síríà àtàwọn ẹ̀yà Arébíà kan jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ṣémù. Àwọn ará Etiópíà, ará Íjíbítì, àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn ẹ̀yà kan ní ilẹ̀ Áfíríkà àti Arébíà jẹ́ àtọmọdọ́mọ Hámù. Nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ Yúróòpù, ilẹ̀ Ìráànì, Íńdíà àti apá ìyókù ilẹ̀ Éṣíà jẹ́ àtọmọdọ́mọ Jáfẹ́tì. Ńṣe ni gbogbo èèyàn bára wọn tan, ọ̀kan ò sì ju kan lọ lójú Ọlọ́run. (Ìṣe 17:26) Òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí ló yẹ kó máa darí irú ojú tó yẹ ká máa fi wo àwọn èèyàn yòókù àti bí a ṣe ń hùwà sí wọn.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Lè Sa Agbára
Apá àkọ́kọ́ ìwé Jẹ́nẹ́sísì yìí la ti lè rí ìtàn pípéye kan ṣoṣo tó wà nípa ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìran èèyàn. Inú àkọsílẹ̀ yìí la ti rí ìjìnlẹ̀ òye nípa ète tí Ọlọ́run fi dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Ó mà fini lọ́kàn balẹ̀ o pé bó ti wù kí ọmọ ènìyàn sapá tó, bí Nímírọ́dù ti ṣe, ète Ọlọ́run á ṣẹ dandan ni!
Nígbà tí ẹ bá ń ka Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ yín láti fi múra sílẹ̀ fún Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, tẹ́ ẹ bá ń yẹ ohun tó wà lábẹ́ ẹ̀ka “Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́” wò, ẹ óò lè lóye àwọn kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣòro láti lóye. Àlàyé tá a ṣe lábẹ́ “Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa” yóò jẹ́ kẹ́ ẹ mọ bẹ́ ẹ ṣe lè jàǹfààní látinú Bíbélì kíkà ti ọ̀sẹ̀ náà. A tún lè lò ó tí ọ̀rọ̀ bá jẹ mọ́ ọn nígbà tá a bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ nígbà Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Ní tòótọ́, Ọ̀rọ̀ Jèhófà yè, ó sì lè sa agbára nínú ìgbésí ayé wa.—Hébérù 4:12.