‘Ki ni Akoko Wí?’
‘KI NI akoko wi?’ Bawo ni iwọ ti beere ibeere yẹn lemọlemọ tó? Ninu sanmani wa ode oni ti nyara kánkán, akoko njẹ wá lọkan nigbagbogbo. Ọpọjulọ ninu awọn igbokegbodo wa ojoojumọ—jíjí ni owurọ, lilọ si ibi iṣẹ, jíjẹun, bibẹ awọn ọrẹ wò, ati bẹẹbẹẹ lọ—ni a ndari gírígírí nipasẹ akoko. A sì gbarale eto awọn nǹkan—awọn aago ńlá, aago ọwọ, ìró aago, redio—lati sọ fun wa ohun ti akoko wí.
Ki ni nipa awọn akoko Bibeli nigba ti awọn eniyan ko ni awọn aago bi tiwa? Bawo ni wọn ṣe nka akoko? Njẹ akọsilẹ Bibeli ha funni ni itọkasi eyikeyi nipa eyi bi? Mimọ akoko ọjọ nigba ti iṣẹlẹ Bibeli kan ṣẹlẹ le fun ọ ni ijinlẹ oye akọtun ninu Ọrọ Ọlọrun ki o si fi igbadun kún ikẹkọọ Bibeli rẹ.
Awọn Atọ́ka Akoko Ti Ọlọrun Fifunni
Ni awọn ọjọ ijimiji akoko iṣẹlẹ kan ni a saba maa nsami si nipa ṣiṣakiyesi oorun tabi oṣupa, “awọn orisun imọlẹ nla meji” ti Ẹlẹdaa ti sọ lọ́jọ̀ si awọn ọrun “lati paala saaarin ọsan ati oru.” (Jẹnẹsisi 1:14-16, NW) Fun apẹẹrẹ, o jẹ “nigba ti ọ̀yẹ̀ . . . là” ni awọn angẹli meji rọ Lọti ati idile rẹ lati sá kuro ninu Sodomu ilu ti o ti gbérọ naa. (Jẹnẹsisi 19:15, 16) Ó sì jẹ́ “nigba asalẹ” ni iranṣẹ Aburahamu oluṣotitọ dé eti kanga nibi ti o ti pade Rebeka.—Jẹnẹsisi 24:11, 15.
Ni akoko kan, awọn itọkasi akoko ti o ṣe rẹgi gan an ni a fifunni. Fun apẹẹrẹ, Abimeleki, ọmọkunrin Onidaajọ Gidioni ti ó jẹ́ oniwa-ipa, ni a gbà nimọran lati kọlu ilu Ṣekemu “ni owurọ, lojukannaa bi oorun bá . . . ti là.” (Onidaajọ 9:33) Lọna ti o han gbangba idi ọlọgbọn ẹwẹ wà lẹhin eyi. Titan yòò oorun ti o ṣẹṣẹ ngoke bọ lẹhin awọn ọmọ ogun Abimeleki gbọdọ ti mu ki o ṣoro gan an fun awọn olugbeja Ṣekemu lati moye awọn ọmọ ogun agbejakoni ninu “ojiji oke wọnni.”—Onidaajọ 9:36-41.
Awọn Akanlo-ede Akoko
Awọn ara Heberu lo awọn ọrọ ti o jinlẹ nitumọ ti o sì dun-ungbọ lati tọka si akoko. Kii ṣe kiki pe wọn gbe imọlara ayika ati aṣa adugbo wá sọkan nikan ni ṣugbọn wọn tun ṣipaya ohun kan nipa awọn ayika igbesẹ naa.
Fun apẹẹrẹ, Jẹnẹsisi 3:8 (NW) sọ fun wa pe o jẹ “nǹkan bi apa akoko ọjọ ti afẹfẹ nfẹ” nigba ti Jehofa bá Adamu ati Efa sọrọ ni ọjọ ti wọn dẹṣẹ. Eyi ni a loye pe o sunmọ irọlẹ nigba ti afẹfẹ tutu yoo dide, ni mimu itura alaafia kuro lọwọ oru ọjọ naa wa. Gẹgẹ bi o ti saba maa nri, gẹgẹ bi ọjọ ti nlọ sopin, o jẹ́ akoko lati tura ki o sì sinmi. Sibẹ, Jehofa ko jẹ ki ọran idajọ wiwuwo kan falẹ titi di ọjọ keji nigba ti akoko ṣì wa lati bojuto o.
Ni ọwọ keji ẹwẹ, Jẹnẹsisi 18:1, 2 (NW) fihan pe awọn angẹli Jehofa wá sinu agọ Aburahamu ni Mamre “ni nǹkan bi imooru ọjọ.” O yaworan oorun ọjọkanri ti ntani ni àtàrí ni awọn oke Judea. Oru naa le ninilara. O jẹ akoko naa lọna aṣa lati jẹun ati lati sinmi. (Wo Jẹnẹsisi 43:16, 25; 2 Samuẹli 4:5.) Bẹẹ gẹgẹ, Aburahamu “jokoo ni ẹnu ọna agọ,” nibi ti afẹfẹ ti ńfẹ́ diẹdiẹ le wa, boya ni sisinmi lẹhin ounjẹ rẹ̀. Awa lè mọriri ẹmi alejo ṣiṣe ọkunrin agbalagba yii pupọ sii nigba ti a kà pe o ‘sare lọ lati pade’ awọn alejo naa ati lẹhin naa o ‘yara lọ sinu agọ’ lati sọ fun Sara lati pese burẹdi, lẹhin eyi ti o “sare lọ sinu agbo” ‘ti o si nyara mu un wà ni sẹpẹ.’ Gbogbo eyi ni akoko imooru ọjọ!—Jẹnẹsisi 18:2-8.
Awọn Wakati Òru ti Awọn Heberu
Lọna ti o han gbangba awọn Heberu pín oru si saa akoko mẹta, ti a npe ni “awọn ìṣọ́.” Ọkọọkan wọn kari idamẹta akoko naa laaarin igba ti ọjọ rọ̀ ati igba ti oorun yọ, tabi nǹkan bi wakati mẹrin, o sinmi le asiko ti ó jẹ́. (Saamu 63:6, NW) O jẹ “ni ibẹrẹ iṣọ aarin oru,” eyi ti o bẹrẹ ni nǹkan bi aago mẹwaa ni oru si nǹkan bi aago meji owurọ, ni Gidioni gbejako ibudo awọn ara Midiani. Igbejakoni ni akoko yii ni kedere bá awọn oluṣọ naa lojiji. Dajudaju, Gidioni oniṣọra ki ba ti le yan akoko ọgbọn ogun ti o dara ju fun igbejakoni rẹ!—Onidaajọ 7:19, NW.
Ni akoko Ijadelọ kuro, Jehofa sì “fi afẹfẹ lile ila-oorun mú okun bì sẹ́hìn ni gbogbo òru,” ni yiyọnda fun awọn ọmọ Isirẹli lati rekọja lori ilẹ gbigbẹ. Ni akoko ti awọn ara Ijibiti bá wọn, o ti jẹ “ìṣọ́ owurọ,” nisinsinyi Jehofa si ko idarudapọ ba ibudo awọn ara Ijibiti, nikẹhin ni pipa wọn run nipa mimu omi naa “padà bọ̀sí ipò rẹ nigba ti ilẹ mọ.” (Ẹkisodu 14:21-27) Nitori naa o fẹrẹẹ gba gbogbo oru fun okun naa lati pinya ati fun awọn ọmọ Isirẹli lati rekọja rẹ̀.
Ni Ọgọrun un Ọdun Kìn-ínní
Nigba ti o fi maa di ọgọrun un ọdun kìn-ínní, awọn Juu ti bẹrẹ sii lo kíkà oniwakati 12 fun ọjọ. Eyi ni idi ti Jesu fi wi ninu ọkan lara awọn akawe rẹ pe: “Wakati mejila ki nbẹ ninu ọ̀sán kan?” (Johanu 11:9) Iwọnyi ni a kà lati igba ti oorun yọ si igba ti oorun wọ̀, tabi lati nǹkan bi aago mẹfa owurọ si aago mẹfa irọlẹ. Nipa bayii, “wakati kẹta” yoo jẹ́ nǹkan bi aago mẹsan an owurọ. Akoko yii ni a tú ẹmi mimọ jade ni ọjọ Pẹntikọsi. Nigba ti awọn eniyan fẹsun jijẹ awọn ti wọn “kún fun ọti waini didun” kàn awọn ọmọ-ẹhin, Peteru yara fopin si ifẹsunkanni yẹn. Dajudaju ko si ẹni ti o le ti mutiyo ni wakati owurọ bẹẹ!—Iṣe 2:13, 15, NW.
Lọna ti o farajọra, gbolohun ọrọ Jesu “ounjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹni ti o rán mi” ni itumọ afikun nigba ti a ba gbé akoko ti o wémọ́ ọn yẹwo. “O . . . jẹ iwọn wakati kẹfa ọjọ,” gẹgẹ bi Johanu 4:6 ti wi, tabi nǹkan bi ọjọ́kanrí. Lẹhin fifẹsẹrin la ilu oloke ti Samaria já ni gbogbo owurọ, Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ ni ebi yoo ti pa ti orungbẹ yoo si ti gbẹ. Idi niyi ti awọn ọmọ-ẹhin fi rọ̀ ọ́ lati jẹun nigba ti wọn pada dé pẹlu ounjẹ. Oye wọn nipa okun ati ohun agbéniró ti Jesu ńrígbà lati inu ṣiṣe iṣẹ Jehofa ko pọ̀. Ko si iyemeji pe ọrọ ti Jesu sọ ju ọrọ afiwe lọ. Oun ni a gbéró niti gidi nipa ṣiṣe iṣẹ Ọlọrun ani bi o tilẹ jẹ pe o ti gbọdọ jẹ ọpọlọpọ wakati sẹhin ti oun ti jẹun.—Johanu 4:31-34.
Gẹgẹ bi yiyọ oorun ati wiwọ oorun ti yatọ ni ibamu pẹlu akoko ọdun, ni gbogbo igba kiki ifojudiwọn akoko iṣẹlẹ ni a fifunni. Nipa bayii, a saba maa nka nipa awọn iṣẹlẹ ti nṣẹlẹ ni wakati kẹta, kẹfa, tabi kẹsan an—ti ntumọ niye igba si ohun ti o sunmọ awọn akoko wọnni. (Matiu 20:3, 5; 27:45, 46; Maaku 15:25, 33, 34; Luuku 23:44; Johanu 19:14; Iṣe 10:3, 9, 30) Bi o ti wu ki o ri, nigba ti ohun ti akoko jẹ ba ṣe pataki fun itan naa, awọn gbolohun akoko pato pupọ sii ni a fifunni. Fun apẹẹrẹ si ọkunrin naa ti o daniyan lati mọ̀ bi a ba mu ara ọmọkunrin rẹ dá nipa agbara Jesu, awọn ẹru dahun pe: “Ni àná, ni wakati keje [nnkan bi agogo kan ọsan] ni iba naa fi i silẹ.”—Johanu 4:49-54.
Awọn Ipin Ti Òru
Ni akoko ijọbalenilori Roomu, o jọ bi ẹni pe awọn Juu ti bẹrẹ sii lo pipin oru si ìṣọ́ mẹrin ti Giriiki ati Roomu dipo mẹta ti wọn nlo tẹlẹri. Ni Maaku 13:35 (NW) Jesu lọna ti o han gbangba tọka si ipin mẹrin naa. Ìṣọ́ “ọjọ́rọ̀” bẹrẹ lati igba ti oorun bá wọ̀ titi di nǹkan bi aago mẹsan an alẹ. Ìṣọ́ keji, ìṣọ́ “ọ̀gànjọ́ òru,” bẹrẹ ni nǹkan bi aago mẹsan an o si pari ni ògànjọ́ òru. “Igba kikọ akukọ” kari lati ọ̀gànjọ́ òru titi di nǹkan bii aago mẹta. Ati ìṣọ́ ikẹhin, “ni kutukutu owurọ,” dopin ni igba ti ọ̀yẹ̀ bá là, ni nǹkan bii aago mẹfa.
Ìṣọ́ “igba kíkọ akukọ” ni pataki jẹ eyi ti o fa ọkan ifẹ mọra nitori awọn ọrọ Jesu si Peteru ni Maaku 14:30 pe: “Ki akukọ ki ó tó kọ nigba meji, iwọ yoo sẹ́ mi nigba mẹta.” Nigba ti awọn oluṣalaye kan diimu pe “igba meji” tọka si awọn akoko pato—ọ̀gànjọ́ òru ati ilẹ̀mọ́, ní itẹlera—A Dictionary of Christ and the Gospels, ti a tẹ̀ lati ọwọ James Hastings, tọka si i pe “otitọ naa ni pe awọn akukọ maa nkọ laaarin òru, ni Ila-oorun gẹgẹ bi o ti jẹ ni ibikibi, ni awọn akoko ti ko baramu lati ọ̀gànjọ́ òru siwaju.” Lọna ti o han kedere, Jesu ko tọka si akoko pàtó naa nigba ti Peteru yoo sẹ́ ẹ. Kaka bẹẹ, oun funni ni ami kan lati sami si awọn ọrọ rẹ̀ fun Peteru, eyi ti o ni imuṣẹ wẹ́kú ni alẹ ọjọ yẹn gan an.—Maaku 14:72.
O jẹ ni “igba ìṣọ́ kẹrin òru”—laaarin aago mẹta si mẹfa owurọ—ni Jesu, ní ririn lori omi Okun Galili, wa sọdọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ, ti wọn wà ninu ọkọ oju-omi “ti o fi ọgọrọọrun ọpa-iwọn jinna si ilẹ.” Boya o rọrun lati loye idi ti awọn ọmọ-ẹhin fi “daamu, wipe: ‘Iwin kan ni!’ Wọn si kigbe jade ninu ibẹru wọn.” (Matiu 14:23-26, NW) Ni ọwọ keji ẹwẹ, eyi fihan pe Jesu gbọdọ ti lo akoko ti o pọ̀ ni gbigbadura ni oun nikan ni ori oke naa. Niwọn bi eyi ti jẹ kété lẹhin ti a ti bẹ́ Johanu Arinibọmi lórí lati ọwọ Hẹrọdu Antipa ati gan an ṣaaju Irekọja, eyi ti o sami si ibẹrẹ ọdun ti o kẹhin iṣẹ-ojiṣẹ Jesu lori ilẹ-aye, dajudaju Jesu ní ohun pupọ lati ronu jinlẹ lé lori ninu adura ara-ẹni rẹ si Baba rẹ̀.
Papọ pẹlu awọn ìṣọ́ mẹrin, kika wakati mejila ti akoko oru ni o tun wa ni lilo. Ki a baa le sin Pọọlu sọna laisewu lọ si Kesaria, apaṣẹ ẹgbẹ ọmọ-ogun Kilaudiọsi Lisiasi sọ fun awọn ọgagun rẹ̀ lati mura awọn jagunjagun 470 silẹ “ni wakati kẹta òru.” (Iṣe 23:23, 24) Nipa bayii Pọọlu ni a fòru mú kuro ni Jerusalẹmu laisewu.
Mọ Akoko Ọjọ
Kíkà ati ríronú jinlẹ lori awọn akọsilẹ ohun ti o ṣẹlẹ laaarin awọn eniyan Ọlọrun igbaani jẹ orisun idunnu ati okun tẹmi. Bi iwọ ba le pa akoko ti o wémọ́ ọn pọ ninu igbeyẹwo rẹ, dajudaju yoo mu ayọ ikẹkọọ Bibeli rẹ pọ sii. Eeṣe ti o fi rí bẹẹ? Nitori pe ni ọna yii o le ni imọ daradara nipa Ọrọ Ọlọrun. Awọn itẹjade bii Insight on the Scriptures ati New World Translation of the Holy Scriptures With References jẹ aranṣe ṣiṣeyebiye ninu ọran yii (mejeeji ni a tẹ̀jáde lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.). Wọn yoo ràn ọ lọwọ lati rí idahun nigba ti o ba beere lọwọ araarẹ pe: ‘Ki ni akoko wí?’