Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
10 Ọkùnrin kan wà ní Kesaríà tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù, ọ̀gá ọmọ ogun* kan nínú àwùjọ tí wọ́n ń pè ní àwùjọ Ítálì.* 2 Onífọkànsìn tó bẹ̀rù Ọlọ́run ni òun àti gbogbo agbo ilé rẹ̀, ó ń fún àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ ọrẹ àánú, ó sì máa ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run nígbà gbogbo. 3 Ní nǹkan bí wákàtí kẹsàn-án+ ọjọ́,* ó rí áńgẹ́lì Ọlọ́run kedere nínú ìran, tí ó wọlé wá bá a, ó sì sọ pé: “Kọ̀nílíù!” 4 Kọ̀nílíù tẹjú mọ́ ọn, ẹ̀rù ń bà á, ó sì bi í pé: “Ṣé kò sí o, Olúwa?” Ó sọ fún un pé: “Àwọn àdúrà àti àwọn ọrẹ àánú rẹ ti dé iwájú Ọlọ́run, ó sì ti mú kó rántí rẹ.+ 5 Nítorí náà, rán àwọn èèyàn sí Jópà, kí o sì ní kí wọ́n pe ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Símónì, tí wọ́n tún ń pè ní Pétérù wá. 6 Ọkùnrin yìí ni àlejò tó wà* lọ́dọ̀ Símónì, oníṣẹ́ awọ, tó ní ilé sétí òkun.” 7 Gbàrà tí áńgẹ́lì tó bá a sọ̀rọ̀ lọ, ó pe méjì lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ọmọ ogun kan tó jẹ́ onífọkànsìn lára àwọn tó ń ṣèránṣẹ́ fún un, 8 ó sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn, ó sì rán wọn lọ sí Jópà.
9 Lọ́jọ́ kejì, bí wọ́n ṣe ń bá ìrìn àjò wọn lọ, tí wọ́n sì ń sún mọ́ ìlú náà, Pétérù lọ sórí ilé ní nǹkan bíi wákàtí kẹfà* láti gbàdúrà. 10 Àmọ́ ebi bẹ̀rẹ̀ sí í pa á gan-an, ó sì fẹ́ jẹun. Bí wọ́n ṣe ń ṣe oúnjẹ lọ́wọ́, ó bọ́ sójú ìran,+ 11 ó rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, ohun kan* sì ń sọ̀ kalẹ̀ tó dà bí aṣọ ọ̀gbọ̀ fífẹ̀ tí wọ́n ń fi àwọn igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí ayé; 12 oríṣiríṣi ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti àwọn ẹran tó ń fàyà fà* lórí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ló wà nínú rẹ̀. 13 Lẹ́yìn náà, ohùn kan sọ fún un pé: “Dìde, Pétérù, máa pa, kí o sì máa jẹ!” 14 Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Rárá o, Olúwa, mi ò jẹ ohunkóhun tó jẹ́ ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́ rí.”+ 15 Ohùn náà tún sọ fún un lẹ́ẹ̀kejì pé: “Yéé pe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.” 16 Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà kẹta, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a gbé e* lọ sí ọ̀run.
17 Nígbà tí Pétérù ṣì ń ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìran tó rí túmọ̀ sí, àwọn ọkùnrin tí Kọ̀nílíù rán níṣẹ́ wá béèrè ibi tí ilé Símónì wà, wọ́n sì dúró sí ẹnubodè.+ 18 Wọ́n nahùn sókè, wọ́n sì béèrè bóyá wọ́n gba Símónì tí wọ́n ń pè ní Pétérù lálejò níbẹ̀. 19 Bí Pétérù ṣe ń ronú nípa ìran náà lọ́wọ́, ẹ̀mí+ sọ fún un pé: “Wò ó! Àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń béèrè rẹ. 20 Torí náà, dìde, sọ̀ kalẹ̀, kí o sì bá wọn lọ, má ṣiyèméjì rárá, nítorí èmi ni mo rán wọn wá.” 21 Pétérù bá sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn ọkùnrin náà, ó sì sọ pé: “Èmi ni ẹni tí ẹ̀ ń wá. Kí lẹ bá wá o?” 22 Wọ́n sọ pé: “Kọ̀nílíù,+ ọ̀gá ọmọ ogun, ọkùnrin kan tó jẹ́ olódodo, tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí gbogbo orílẹ̀-èdè Júù sì ń ròyìn rẹ̀ dáadáa, ni áńgẹ́lì mímọ́ kan fún ní àṣẹ àtọ̀runwá pé kó ránṣẹ́ pè ọ́ láti wá sí ilé òun, kí ó lè gbọ́ ohun tí o ní láti sọ.” 23 Nítorí náà, ó ní kí wọ́n wọlé, ó sì gbà wọ́n lálejò.
Lọ́jọ́ kejì, ó dìde, ó sì bá wọn lọ, lára àwọn arákùnrin tó wá láti Jópà náà bá a lọ. 24 Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, ó wọ Kesaríà. Ní ti tòótọ́, Kọ̀nílíù ti ń retí wọn, ó sì ti pe àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ. 25 Bí Pétérù ṣe wọlé, Kọ̀nílíù pàdé rẹ̀, ó kúnlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì tẹrí ba* fún un. 26 Àmọ́ Pétérù gbé e dìde, ó sọ pé: “Dìde; èèyàn lèmi náà.”+ 27 Bí ó ṣe ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé, ó sì rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n pé jọ. 28 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin náà mọ̀ dáadáa pé kò bófin mu rárá fún Júù láti dara pọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ ẹ̀yà míì tàbí kó wá sọ́dọ̀ rẹ̀,+ síbẹ̀ Ọlọ́run fi hàn mí pé kí n má ṣe pe èèyàn kankan ní ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́.+ 29 Nítorí náà, mo wá láìjanpata nígbà tí wọ́n ránṣẹ́ pè mí. Ní báyìí, mo fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi ránṣẹ́ pè mí.”
30 Kọ̀nílíù wá sọ pé: “Ọjọ́ mẹ́rin sẹ́yìn, tí a bá kà á láti wákàtí yìí, mò ń gbàdúrà nínú ilé mi ní wákàtí kẹsàn-án;* ni ọkùnrin kan tó wọ aṣọ títàn yòò bá dúró síwájú mi, 31 ó sì sọ pé: ‘Kọ̀nílíù, àdúrà rẹ ti gbà, a sì ti rántí àwọn ọrẹ àánú rẹ níwájú Ọlọ́run. 32 Torí náà, ránṣẹ́ sí Jópà, kí o sì pe Símónì tí wọ́n ń pè ní Pétérù wá. Ọkùnrin yìí jẹ́ àlejò ní ilé Símónì, oníṣẹ́ awọ, létí òkun.’+ 33 Nítorí náà, mo ránṣẹ́ sí ọ ní kíá, o sì ṣe dáadáa bí o ṣe wá síbí. Ní báyìí, gbogbo wa wà níwájú Ọlọ́run láti gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà* ti pàṣẹ pé kí o sọ.”
34 Ni Pétérù bá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, ó ní: “Ní báyìí, ó ti wá yé mi dáadáa pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,+ 35 àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.+ 36 Ó ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ó lè kéde ìhìn rere àlàáfíà+ fún wọn nípasẹ̀ Jésù Kristi, ẹni yìí ni Olúwa gbogbo èèyàn.+ 37 Ẹ mọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀ káàkiri gbogbo Jùdíà, bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì+ lẹ́yìn ìrìbọmi tí Jòhánù wàásù: 38 nípa Jésù tó wá láti Násárẹ́tì, bí Ọlọ́run ṣe fi ẹ̀mí mímọ́+ àti agbára yàn án, tí ó sì lọ káàkiri ilẹ̀ náà, tí ó ń ṣe rere, tí ó sì ń wo gbogbo àwọn tí Èṣù ń ni lára sàn,+ torí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 39 Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe ní ilẹ̀ àwọn Júù àti ní Jerúsálẹ́mù; àmọ́ wọ́n pa á bí wọ́n ṣe gbé e kọ́ sórí òpó igi.* 40 Ọlọ́run jí ẹni yìí dìde ní ọjọ́ kẹta,+ ó sì jẹ́ kó fara hàn kedere,* 41 kì í ṣe fún gbogbo èèyàn, bí kò ṣe fún àwọn ẹlẹ́rìí tí Ọlọ́run ti yàn ṣáájú, fún àwa, tí a bá a jẹ, tí a sì bá a mu lẹ́yìn tí ó dìde kúrò nínú ikú.+ 42 Bákan náà, ó pàṣẹ fún wa pé ká wàásù fún àwọn èèyàn ká sì jẹ́rìí kúnnákúnná+ pé ẹni yìí ni Ọlọ́run pàṣẹ pé kí ó jẹ́ onídàájọ́ alààyè àti òkú.+ 43 Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sí,+ pé gbogbo ẹni tó bá gbà á gbọ́ máa rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀.”+
44 Nígbà tí Pétérù ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ nípa nǹkan yìí, ẹ̀mí mímọ́ bà lé gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.+ 45 Ẹnu ya àwọn onígbàgbọ́* tó ti dádọ̀dọ́* tí wọ́n bá Pétérù wá, torí pé ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́ tú jáde sórí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú. 46 Nítorí wọ́n gbọ́ tí wọ́n ń sọ àwọn èdè àjèjì,* tí wọ́n sì ń gbé Ọlọ́run ga.+ Nígbà náà, Pétérù dáhùn pé: 47 “Ṣé ẹnikẹ́ni lè sọ pé ká má fi omi batisí àwọn èèyàn yìí,+ àwọn tó ti gba ẹ̀mí mímọ́ bí àwa náà ṣe gbà á?” 48 Nítorí náà, ó pàṣẹ pé kí a batisí wọn ní orúkọ Jésù Kristi.+ Lẹ́yìn náà, wọ́n ní kó lo ọjọ́ díẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn.