Inú Rere—Ànímọ́ Kan Tó Yẹ Kó Hàn Nínú Ọ̀rọ̀ àti Ìṣe Wa
Ó DÁJÚ pé tẹ́nì kan bá fi inú rere hàn sí wa inú wa máa ń dùn, ọkàn wa máa ń balẹ̀, á sì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ wa. Kò sí àní-àní pé a máa ń fẹ́ káwọn míì fi inúure hàn sí wa, àmọ́ báwo làwa náà ṣe lè ní ànímọ́ yìí?
Inú rere túmọ̀ sí pé ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ wá lógún. Èyí sì máa hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. Ànímọ́ yìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, ó sì kọjá kéèyàn kàn máa hùwà jẹ́jẹ́ káwọn èèyàn lè máa fojúure wò ó. Ká fi inúure hàn gba pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú ká sì máa fi ara wa sípò wọn. Yàtọ̀ síyẹn, inú rere wà lára èso ti ẹ̀mí tí àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ ní. (Gál. 5:22, 23) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ onínúure. Ẹ wá jẹ́ ká wo bí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ṣe máa ń fi inúure hàn, ká sì wo bá a ṣe lè fara wé wọn.
GBOGBO ÈÈYÀN NI JÈHÓFÀ Ń FI INÚ RERE HÀN SÍ
Jèhófà máa ń fi inú rere hàn sí gbogbo èèyàn títí kan “àwọn aláìlọ́pẹ́ àti àwọn ẹni burúkú.” (Lúùkù 6:35) Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà máa ń mú ‘kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.’ (Mát. 5:45) Ó ṣe kedere pé àwọn tí kò gbà pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá gan-an ń gbádùn àwọn ohun tó pèsè, wọ́n sì ń láyọ̀ déwọ̀n àyè kan.
Àpẹẹrẹ kan tó ta yọ ni bí Jèhófà ṣe fi inú rere hàn sí Ádámù àti Éfà. Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, “wọ́n gán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì ṣe bàǹtẹ́ fún ara wọn.” Àmọ́, Jèhófà mọ̀ pé wọ́n máa nílò aṣọ tó bora dáadáa táá jẹ́ kí wọ́n lè gbé níta Édẹ́nì níbi tí “ẹ̀gún àti òṣùṣú” á ti máa hù lórí ilẹ̀ tí Jèhófà ti gégùn-ún fún. Torí náà, Jèhófà fi inú rere hàn sí wọn, ó sì fi “awọ ṣe ẹ̀wù gígùn” fún wọn.—Jẹ́n. 3:7, 17, 18, 21.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa ń fi inú rere hàn sí “àwọn ènìyàn burúkú àti rere,” síbẹ̀, ó máa ń dìídì fi inúure hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé wòlíì Sekaráyà, inú áńgẹ́lì kan bà jẹ́ nígbà táwọn èèyàn dáṣẹ́ dúró, tí wọn ò sì tún tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́ mọ́. Jèhófà fetí sí ohun tí áńgẹ́lì náà sọ, ó sì fi ‘ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ tí ń tuni nínú’ dá áńgẹ́lì náà lóhùn. (Sek. 1:12, 13) Ohun tí Jèhófà ṣe fún wòlíì Èlíjà náà nìyẹn. Ìgbà kan wà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá Èlíjà débi pé ó ní kí Jèhófà pa òun. Jèhófà mọ bọ́rọ̀ yìí ṣe rí lára Èlíjà, ó sì rán áńgẹ́lì kan pé kó fún un lókun. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà jẹ́ kó dá a lójú pé àwọn míì náà ṣì ń jọ́sìn òun. Àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe yìí fún Èlíjà lókun, ó sì mú kó máa fìtara bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ. (1 Ọba 19:1-18) Èwo nínú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló fi àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká jẹ́ onínúure?
JÉSÙ FI ÀPẸẸRẸ TÓ TA YỌ LÉLẸ̀
Onínúure ni Jésù nígbà tó wà láyé, ó sì máa ń gba tàwọn èèyàn rò. Kì í kanra mọ́ wọn tàbí kó fipá mú kí wọ́n ṣe ohun tó fẹ́. Jésù fìfẹ́ rọ àwọn èèyàn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. . . . Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere.” (Mát. 11:28-30) Torí pé Jésù jẹ́ onínúure, àwọn èèyàn máa ń tẹ̀ lé e lọ sí ibikíbi tó bá ń lọ. “Àánú” àwọn èèyàn ṣe Jésù, torí náà, ó fún wọn lóúnjẹ, ó wò wọ́n sàn, ó sì “kọ́ wọn ní ohun púpọ̀” nípa Baba rẹ̀.—Máàkù 6:34; Mát. 14:14; 15:32-38.
Bí Jésù ṣe máa ń fi òye báni lò tún jẹ́ ká rí i pé onínúure ni. Táwọn èèyàn bá wá sọ́dọ̀ Jésù, ṣe ló máa ń “fi inú rere gbà wọ́n” tí wọ́n bá tiẹ̀ wá lásìkò tí kò rọrùn fún un. (Lúùkù 9:10, 11) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí obìnrin kan tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fọwọ́ kan aṣọ Jésù, kò jágbe mọ́ ọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin náà jẹ́ aláìmọ́ lábẹ́ Òfin Mósè. (Léf. 15:25-28) Jésù fàánú hàn sí obìnrin tó ti jìyà fún ọdún méjìlá yìí, ó sì sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.” (Máàkù 5:25-34) Àbí ẹ ò rí i pé onínúure ni Jésù!
INÚ RERE KÌ Í ṢE Ọ̀RỌ̀ ẸNU LÁSÁN
Àwọn àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé inúure kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, ó gba pé ká ṣe nǹkan kan láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Jésù tẹnu mọ́ kókó yìí nínú àpèjúwe tó ṣe nípa ará Samáríà kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Samáríà àtàwọn Júù kórìíra ara wọn, síbẹ̀ ọkùnrin ará Samáríà yẹn fàánú hàn sí ẹnì kan tí wọ́n jà lólè, tí wọ́n lù bí ẹni máa kú tí wọ́n sì fi sílẹ̀ lójú ọ̀nà. Inúure mú kí ará Samáríà yẹn fọ egbò ọkùnrin náà, ó sì gbé e lọ sí ilé èrò kan. Lẹ́yìn náà, ó fún olùtọ́jú ilé èrò náà ní owó táá fi tọ́jú ọkùnrin náà, ó sì ṣèlérí pé òun máa san owó tó kù tí òun bá pa dà wá.—Lúùkù 10:29-37.
Lóòótọ́, ohun tá a bá ṣe ló ń fi hàn pé a jẹ́ onínúure, síbẹ̀ a tún lè fi inúure hàn tá a bá ń sọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn míì. Bíbélì sọ pé, “àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” (Òwe 12:25) Tá a bá jẹ́ onínúure, tá a sì ní ìwà rere, àá máa sọ ohun táá gbé àwọn míì ró, ìyẹn á sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.a Ọ̀rọ̀ wa á fún wọn lókun, á sì jẹ́ kí wọ́n lè fara da àwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú.—Òwe 16:24.
BÁ A ṢE LÈ JẸ́ ONÍNÚURE
Gbogbo èèyàn ló lè fi inúure hàn torí pé Ọlọ́run dá wa ní “àwòrán rẹ̀.” (Jẹ́n. 1:27) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gágun Róòmù kan tó ń jẹ́ Júlíọ́sì ló ń ṣọ́ Pọ́ọ̀lù nígbà tó fẹ́ lọ jẹ́jọ́ ní Róòmù. Ọ̀gágun yìí hùwà sí Pọ́ọ̀lù “pẹ̀lú inú rere ẹ̀dá ènìyàn, ó sì gbà á láyè láti lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí ó sì gbádùn ìtọ́jú wọn” nílùú Sídónì. (Ìṣe 27:3) Nígbà tó yá, àwọn aráàlú Málítà náà tún ‘ṣe inú rere àrà ọ̀tọ̀’ sí Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì tó wẹ̀ dé etíkun lẹ́yìn tí ọkọ̀ wọn rì. Àwọn ará ìlú náà tiẹ̀ dáná igi fún wọn kí wọ́n lè yáná. (Ìṣe 28:1, 2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n ṣe yìí wúni lórí, síbẹ̀ inúure kọjá ohun téèyàn ń ṣe lẹ́ẹ̀kan.
Tá a bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, ó yẹ kó mọ́ wa lára láti máa fi inúure hàn nígbà gbogbo. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi ní ká fi inú rere ‘wọ ara wa láṣọ.’ (Kól. 3:12) Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti fi inúure hàn. Kí nìdí? Ó lè jẹ́ torí pé ojú ń tì wá tàbí pé à ń ṣiyè méjì. Nígbà míì, ó lè jẹ́ torí àtakò tàbí torí pé àwa náà láhun díẹ̀. Síbẹ̀, tá a bá gbára lé ẹ̀mí mímọ́ tá a sì ń fara wé Jèhófà, àá jẹ́ onínúure.—1 Kọ́r. 2:12.
Ǹjẹ́ a lè ronú nípa àwọn ohun tá a lè ṣe táá mú ká túbọ̀ jẹ́ onínúure? Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn míì? Ṣé mo máa ń kíyè sí ohun táwọn míì nílò? Ìgbà wo ni mo fi inúure hàn sí ẹni tí kì í ṣe ìdílé mi tàbí ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kẹ́yìn?’ Lẹ́yìn náà, ó yẹ ká sapá láti túbọ̀ mọ àwọn tá a jọ wà, pàápàá àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ mọ̀ wọ́n, àá mọ ohun tí wọ́n ń kojú àti bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó yẹ ká ṣe ohun tí àwa náà máa fẹ́ káwọn míì ṣe fún wa ká sọ pé àwa la wà ní ipò wọn. (Mát. 7:12) Tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, ó dájú pé ó máa bù kún wa bá a ṣe ń sapá láti túbọ̀ jẹ́ onínúure.—Lúùkù 11:13.
INÚ RERE MÁA Ń JẸ́ KÁWỌN MÍÌ NÍFẸ̀Ẹ́ WA
“Inú rere” wà lára àwọn ànímọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ òun sí òjíṣẹ́ Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 6:3-6) Pọ́ọ̀lù máa ń sọ̀rọ̀ tó ń tuni lára, ó sì máa ń ran àwọn míì lọ́wọ́ torí pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ẹ́ lógún, èyí sì mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. (Ìṣe 28:30, 31) Tí àwa náà bá ń fi inúure hàn sáwọn èèyàn, á rọrùn fún wọn láti wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Tá a bá ṣenúure sí àwọn tó ń ta kò wá, ọkàn wọn lè rọ̀ kí wọ́n má sì ta kò wá mọ́. (Róòmù 12:20) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n lè wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Nínú Párádísè tó ń bọ̀, ó dájú pé inú àwọn tó jíǹde máa dùn gan-an tí wọ́n bá rí bí àwọn èèyàn ṣe ń fi inúure hàn, kódà ó lè jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa rí irú ẹ̀ nìyẹn. Wọ́n máa mọrírì ẹ̀ gan-an, ó sì dájú pé ìyẹn á mú káwọn náà máa ṣenúure sáwọn míì. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi inúure hàn tí kò sì ran àwọn míì lọ́wọ́ kò ní lè gbé nínú Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn tí Jèhófà máa fojú rere hàn sí tí wọ́n á sì gbé títí láé làwọn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tó sì ń ṣenúure síra wọn. (Sm. 37:9-11) Ó dájú pé tó bá dìgbà yẹn, ọkàn wa máa balẹ̀, àlàáfíà sì máa jọba! Àmọ́, kó tó dìgbà yẹn, àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fi inúure hàn sáwọn míì?
ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍNÚ KÉÈYÀN JẸ́ ONÍNÚURE
Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn tí ó ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́” máa ń ṣe ara rẹ̀ láǹfààní. (Òwe 11:17) Àwọn èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni tó jẹ́ onínúure, wọ́n sì máa ń ran òun náà lọ́wọ́. Jésù sọ pé: “Òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n padà fún yín.” (Lúùkù 6:38) Torí náà, onínúure máa ń ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi tí wọ́n á jọ bá ara wọn kalẹ̀.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará tó wà ní ìjọ Éfésù pé: “Kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà.” (Éfé. 4:32) Táwọn ará nínú ìjọ bá ń gbé ara wọn ró, tí wọ́n jẹ́ onínúure, tí wọ́n sì ń ran ara wọn lọ́wọ́, ìjọ máa tura, wọ́n á sì wà níṣọ̀kan. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ kì í sọ̀rọ̀ àbùkù sáwọn míì tàbí kí wọ́n máa fọ̀rọ̀ gún wọn lára, ibi táwọn èèyàn dáa sí ni wọ́n máa ń wò. Dípò kí wọ́n máa ṣòfófó, ṣe ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ táá gbé àwọn míì ró. (Òwe 12:18) Ìyẹn sì máa ń mú káwọn ará inú ìjọ máa fayọ̀ sin Jèhófà.
A ti rí i báyìí pé tá a bá máa jẹ́ onínúure, ó gbọ́dọ̀ hàn nínú ọ̀rọ̀ wa àti ohun tá a bá ṣe fáwọn míì. Tá a bá jẹ́ onínúure, à ń fara wé Jèhófà Ọlọ́run wa nìyẹn. (Éfé. 5:1) Èyí á mú kí ìjọ túbọ̀ wà níṣọ̀kan, káwọn míì sì wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá sí ẹni tó ń fi inú rere hàn nígbà gbogbo.
a Tó bá yá, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìwà rere nínú àpilẹ̀kọ alápá mẹ́sàn-án tá a ti ń jíròrò èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.