Àkọsílẹ̀ Mátíù
11 Lẹ́yìn tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá (12) ní ìtọ́ni, ó gbéra níbẹ̀ láti lọ máa kọ́ni, kó sì máa wàásù nínú àwọn ìlú wọn.+
2 Àmọ́ nínú ẹ̀wọ̀n tí Jòhánù wà,+ ó gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ Kristi, ó wá rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀+ 3 kí wọ́n lọ bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tó Ń Bọ̀, àbí ká máa retí ẹlòmíì?”+ 4 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń rí fún Jòhánù:+ 5 Àwọn afọ́jú ti ń ríran báyìí,+ àwọn arọ ń rìn, à ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀+ mọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń sọ ìhìn rere fún àwọn aláìní.+ 6 Aláyọ̀ ni ẹni tí kò rí ohunkóhun tó máa mú kó kọsẹ̀ nínú mi.”+
7 Nígbà tí àwọn yìí ń lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn èrò náà nípa Jòhánù pé: “Kí lẹ jáde lọ wò ní aginjù?+ Ṣé esùsú* tí atẹ́gùn ń gbé kiri ni?+ 8 Kí wá lẹ jáde lọ wò? Ṣé ọkùnrin tó wọ aṣọ àtàtà* ni? Ṣebí inú ilé àwọn ọba ni àwọn tó wọ aṣọ àtàtà máa ń wà? 9 Ká sòótọ́, kí ló wá dé tí ẹ jáde lọ? Ṣé kí ẹ lè rí wòlíì ni? Àní mo sọ fún yín, ó ju wòlíì lọ dáadáa.+ 10 Ẹni yìí la kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi ṣáájú rẹ,* ẹni tó máa ṣètò ọ̀nà rẹ dè ọ́!’+ 11 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, nínú àwọn tí obìnrin bí, kò tíì sí ẹni tó tóbi ju Jòhánù Arinibọmi lọ, àmọ́ ẹni kékeré nínú Ìjọba ọ̀run tóbi jù ú lọ.+ 12 Láti àwọn ọjọ́ Jòhánù Arinibọmi títí di báyìí, Ìjọba ọ̀run ni ohun tí àwọn èèyàn ń fi agbára lépa, ọwọ́ àwọn tó ń sapá gidigidi sì ń tẹ̀ ẹ́.+ 13 Torí pé gbogbo wọn, àwọn Wòlíì àti Òfin, sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ títí dìgbà Jòhánù;+ 14 tí ẹ bá sì fẹ́ gba èyí gbọ́, òun ni ‘Èlíjà tó máa wá.’+ 15 Kí ẹni tó bá ní etí fetí sílẹ̀.
16 “Ta ni màá fi ìran yìí wé?+ Ó dà bí àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n jókòó nínú ọjà, tí wọ́n ń pe àwọn tí wọ́n jọ ń ṣeré, 17 pé: ‘A fun fèrè fún yín, àmọ́ ẹ ò jó; a pohùn réré ẹkún, àmọ́ ẹ ò kẹ́dùn, kí ẹ sì lu ara yín.’ 18 Bákan náà, Jòhánù wá, kò jẹ, kò sì mu, àmọ́ àwọn èèyàn sọ pé, ‘Ẹlẹ́mìí èṣù ni.’ 19 Ọmọ èèyàn wá, ó ń jẹ, ó sì ń mu,+ àmọ́ àwọn èèyàn sọ pé, ‘Wò ó! Ọkùnrin alájẹkì, ti kò mọ̀ ju kó mu wáìnì lọ, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’+ Síbẹ̀ náà, a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo* nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.”*+
20 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í gan àwọn ìlú tó ti ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn iṣẹ́ agbára rẹ̀, torí pé wọn ò ronú pìwà dà: 21 “O gbé, ìwọ Kórásínì! O gbé, ìwọ Bẹtisáídà! torí ká ní àwọn iṣẹ́ agbára tó ṣẹlẹ̀ nínú yín bá ṣẹlẹ̀ ní Tírè àti Sídónì ni, tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n á ti ronú pìwà dà, nínú aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú.+ 22 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, Tírè àti Sídónì máa lè fara dà á ní Ọjọ́ Ìdájọ́ jù yín lọ.+ 23 Àti ìwọ, Kápánáúmù,+ ṣé a máa gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Inú Isà Òkú* nísàlẹ̀ lo máa lọ;+ torí ká ní àwọn iṣẹ́ agbára tó ṣẹlẹ̀ nínú rẹ bá ṣẹlẹ̀ ní Sódómù ni, ì bá ṣì wà títí dòní yìí. 24 Àmọ́ mo sọ fún yín pé, ilẹ̀ Sódómù máa lè fara dà á ní Ọjọ́ Ìdájọ́ jù yín lọ.”+
25 Nígbà náà, Jésù sọ pé: “Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, mo yìn ọ́ ní gbangba, torí pé o fi àwọn nǹkan yìí pa mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ọmọdé.+ 26 Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, torí pé ohun tí o fọwọ́ sí nìyí. 27 Baba mi ti fa ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́,+ kò sì sẹ́ni tó mọ Ọmọ délẹ̀délẹ̀ àfi Baba;+ bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó mọ Baba délẹ̀délẹ̀ àfi Ọmọ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ṣí i payá fún.+ 28 Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń ṣe làálàá, tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, màá sì tù yín lára. 29 Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí,+ ara sì máa tù yín.* 30 Torí àjàgà mi rọrùn,* ẹrù mi sì fúyẹ́.”