ORÍ KÌÍNÍ
“Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ó Kú, Ó Ń Sọ̀rọ̀ Síbẹ̀”
1. Kí ni kò jẹ́ kí ìdílé Ádámù àti Éfà lè wọ inú ọgbà Édẹ́nì mọ́? Kí ni ohun tí Ébẹ́lì fẹ́ kó ṣẹlẹ̀?
ÉBẸ́LÌ ń wo àwọn àgùntàn rẹ̀ bí wọ́n ṣe rọra ń jẹko lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè tó wà. Ó wá gbójú sókè wo ọ̀ọ́kán, bóyá láti wo ibì kan tó dà bíi pé àwọn nǹkan kan ti ń tàn yanran. Ó mọ̀ pé apá ibẹ̀ ni ọgbà Édẹ́nì wà, àti pé abẹ idà oníná kan tó ń yí nígbà gbogbo láìdáwọ́ dúró dí ojú ọ̀nà tó wọ ọgbà náà. Inú ọgbà yẹn ni àwọn òbí rẹ̀ ń gbé tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí àwọn àti àwọn ọmọ wọn kò tó ẹni tó ń wọbẹ̀ mọ́. Fojú inú wo bí afẹ́fẹ́ ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ tó ń fẹ́ yẹ́ẹ́ á ṣe máa fẹ́ irun orí Ébẹ́lì bó ṣe gbójú sókè tó ń ronú nípa Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó máa bi ara rẹ̀ pé, ǹjẹ́ àárín Ọlọ́run àti èèyàn máa tún lè pa dà gún régé? Ohun tí Ébẹ́lì fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ nìyẹn.
2-4. Báwo ni Ébẹ́lì ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ lóde òní?
2 Ébẹ́lì ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì lónìí. Ǹjẹ́ o gbọ́ nǹkan tó ń sọ? O lè rò pé ìyẹn kò lè ṣeé ṣe. Ó ṣe tán Ébẹ́lì, ọmọ kejì tí Ádámù bí ti kú tipẹ́tipẹ́, òkú rẹ̀ sì ti jẹrà mọ́nú ilẹ̀ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà sẹ́yìn báyìí. Ohun tí Bíbélì sì sọ nípa àwọn òkú ni pé: “Wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníw. 9:5, 10) Yàtọ̀ síyẹn, kò síbì kankan tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ tí Ébẹ́lì sọ sí nínú Bíbélì. Báwo la ṣe wá lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀?
3 Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ nípa Ébẹ́lì pé: “Nípasẹ̀ èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kú, ó ń sọ̀rọ̀ síbẹ̀.” (Ka Hébérù 11:4.) Nípasẹ̀ kí ni Ébẹ́lì ń sọ̀rọ̀? Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ni. Òun ni ẹni tó kọ́kọ́ ní irú ìgbàgbọ́ tó lágbára bẹ́ẹ̀. Ìgbàgbọ́ tó ní lágbára débi pé àpẹẹrẹ rẹ̀ ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ó sì jẹ́ àwòkọ́ṣe pàtàkì fún wa lóde òní. Tí a bá ń ka àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ pé Ébẹ́lì ṣe, tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìgbàgbọ́ rẹ̀, tí a sì ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ṣe ló máa dà bíi pé òun fúnra rẹ̀ ló ń bá wa sọ̀rọ̀.
4 Ẹ̀kọ́ wo la wá lè rí kọ́ lára Ébẹ́lì àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ nígbà tó jẹ́ pé ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀? Jẹ́ ká wò ó ná.
Àsìkò Téèyàn Ò Tíì Pọ̀ Láyé Ni Wọ́n Bí I
5. Nígbà tí Jésù sọ pé “ìgbà pípilẹ̀ ayé” ni Ébẹ́lì gbé láyé, kí ni ìyẹn túmọ̀ sí? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
5 Ìgbà tí wọ́n bí Ébẹ́lì kò jìnnà púpọ̀ sí ìgbà tí Ọlọ́run dá àwọn èèyàn méjì àkọ́kọ́. Jésù sì fi hàn nígbà tó yá, pé “ìgbà pípilẹ̀ ayé” ni Ébẹ́lì gbé láyé. (Ka Lúùkù 11:50, 51.) Ó hàn gbangba pé ayé tí Jésù ń sọ níhìn-ín ni àwọn èèyàn tó nírètí pé àwọn lè rí ìràpadà ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Lóòótọ́, Ébẹ́lì ni ẹni kẹrin lára àwọn tó kọ́kọ́ gbé láyé, àmọ́ ó jọ pé òun lẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run rí pé ó ṣeé rà pa dà nínú aráyé.a Ìyẹn jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe àárín àwọn tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere ni Ébẹ́lì dàgbà sí.
6. Irú àwọn òbí wo ni Ébẹ́lì ní?
6 Ìran èèyàn dáyé tàì-dáyé ni wọ́n ti wọ ìjàngbọ̀n. Ó jọ pé arẹwà àti akíkanjú èèyàn ni Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ òbí Ébẹ́lì. Ṣùgbọ́n, wọ́n ti balẹ̀ jẹ́ jìnnà, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn ti tẹ́. Ẹni pípé ni wọ́n tẹ́lẹ̀, wọn ì bá sì máa gbé ayé títí láé ni. Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run, ni Ọlọ́run bá lé wọn kúrò nínú Párádísè tó jẹ́ ilé wọn nínú ọgbà Édẹ́nì. Nítorí pé ìfẹ́ ọkàn tiwọn ni wọ́n fẹ́ tẹ́ lọ́rùn láì tiẹ̀ ro ti ẹnì kankan mọ́ tiwọn, títí kan àtọmọdọ́mọ wọn pàápàá, wọ́n pàdánù ipò pípé tí wọ́n wà àti ìyè ayérayé.—Jẹ́n. 2:15–3:24.
7, 8. Kí ni Éfà sọ nígbà tí wọ́n bí Kéènì, kí ló sì ṣeé ṣe kó ní lọ́kàn tó fi sọ bẹ́ẹ̀?
7 Nígbà tí Ọlọ́run lé Ádámù àti Éfà jáde kúrò nínú ọgbà yẹn, ìyà bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ wọ́n. Síbẹ̀, nígbà tí wọ́n bí àkọ́bí wọn, wọ́n sọ ọ́ ní Kéènì, ìyẹn “Ohun Tí A Mú Jáde.” Éfà sì sọ pé: “Mo ti mú ọkùnrin kan jáde nípasẹ̀ àrànṣe Jèhófà.” Ọ̀rọ̀ Éfà yìí fi hàn pé ó ní láti jẹ́ pé ìlérí tí Jèhófà ṣe nínú ọgbà Édẹ́nì ló ní lọ́kàn. Ọlọ́run sọ pé obìnrin kan máa bí “irú ọmọ” kan tí yóò pa ẹni burúkú tó kó Ádámù àti Éfà ṣìnà. (Jẹ́n. 3:15; 4:1) Àbí ṣe ni Éfà tiẹ̀ rò pé òun ni obìnrin tí Jèhófà sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn àti pé Kéènì ni “irú ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí náà?
8 Tó bá rò bẹ́ẹ̀, àṣìṣe ńlá ló ṣe o. Tí òun àti Ádámù bá sì lọ gbìn èrò yìí sí Kéènì lọ́kàn bó ṣe ń dàgbà, kò sí bí ìyẹn ò ṣe ní sọ ọ́ dẹni tó jọra rẹ̀ lójú. Nígbà tí Éfà wá bí ọmọkùnrin kejì, wọn kò sọ irú ọ̀rọ̀ ìwúrí bẹ́ẹ̀ nípa rẹ̀. Orúkọ tí wọ́n sọ ọ́ ni Ébẹ́lì, tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Èémí Àmíjáde,” tàbí “Asán.” (Jẹ́n. 4:2) Àbí wọ́n ti rò pé Ébẹ́lì kò ní fi bẹ́ẹ̀ rọ́wọ́ mú ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní orúkọ yẹn, bíi pé wọn kò gbójú lé e tó Kéènì? A ò lè sọ.
9. Kí làwọn òbí òde òní lè rí kọ́ lára àwọn òbí wa àkọ́kọ́?
9 Àwọn òbí òde òní lè rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ lára àwọn òbí wa àkọ́kọ́ yẹn. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ kí òbí máa fi ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ gbin ẹ̀mí ìgbéraga, lílépa ipò ọlá àti ìmọtara-ẹni-nìkan sí ọmọ rẹ̀ lọ́kàn. Ṣe ló yẹ kó máa kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run kí wọ́n sì jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó wá dunni pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ kò ṣe ojúṣe wọn. Àmọ́ ṣá, ìrètí wà fún àtọmọdọ́mọ wọn.
Kí Ló Mú Kí Ébẹ́lì Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Ọlọ́run?
10, 11. Irú iṣẹ́ wo ni Kéènì àti Ébẹ́lì ń ṣe? Ànímọ́ wo ni Ébẹ́lì wá ní?
10 Ó jọ pé bí àwọn ọmọkùnrin méjèèjì ṣe ń dàgbà, Ádámù kọ́ wọn ní iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n á fi máa ṣètìlẹyìn fún ìdílé náà. Kéènì di àgbẹ̀, Ébẹ́lì sì ń da àgùntàn.
11 Ṣùgbọ́n Ébẹ́lì tún ṣe ohun kan tó ṣe pàtàkì ju gbogbo ìyẹn lọ. Kí ló ṣe? Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, ó di ẹni tó ní ìgbàgbọ́, ìyẹn ànímọ́ àtàtà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa rẹ̀ nígbà tó yá. Àbẹ́ ò rí nǹkan! Nígbà yẹn, kò sí ẹ̀dá èèyàn tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere tí Ébẹ́lì lè fi ṣe àwòkọ́ṣe. Báwo ló ṣe wá dẹni tó ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run? Wo ìdí pàtàkì mẹ́ta tó fi lè ní ìgbàgbọ́.
12, 13. Báwo ni àwọn ohun tí Jèhófà dá tí Ébẹ́lì ń kíyè sí ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára?
12 Àwọn ohun tí Jèhófà dá. Lóòótọ́ Jèhófà ti fi ilẹ̀ gégùn-ún, ó sì ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú èyí tí kò jẹ́ kí iṣẹ́ àgbẹ̀ rọrùn. Síbẹ̀, ilẹ̀ ṣì ń mú oúnjẹ jáde dáadáa fún ìdílé àwọn Ébẹ́lì, èyí tí wọ́n ń jẹ tí wọ́n fi wà láàyè. Bákan náà, àwọn nǹkan yòókù tí Ọlọ́run dá ṣì wà tí kò fi gégùn-ún, irú bí àwọn ẹranko, tó fi mọ́ àwọn ẹyẹ àti ẹja. Kò sì fi àwọn òkè, adágún omi, odò àti òkun gégùn-ún, títí kan ojú ọ̀run, àwọsánmà, oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀. Gbogbo ibi tí Ébẹ́lì bá wò ló ti ń rí ẹ̀rí pé Jèhófà Ọlọ́run tó dá gbogbo nǹkan wọ̀nyí ní ìfẹ́, ọgbọ́n àti inú rere púpọ̀ gan-an. (Ka Róòmù 1:20.) Dájúdájú, bó ṣe ń ṣàṣàrò lórí nǹkan wọ̀nyí ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ á túbọ̀ máa lágbára.
13 Ó dájú pé Ébẹ́lì máa ń fara balẹ̀ ronú nípa àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Fojú inú wò ó bó ṣe ń tọ́jú agbo ẹran rẹ̀. Àwọn darandaran sábà máa ń rìn káàkiri gan-an. Torí náà, yóò máa da àwọn ẹran ọ̀sìn náà lọ sí orí àwọn òkè àti àfonífojì, yóò kó wọn sọdá odò, yóò dà wọ́n lọ sí ibikíbi tí wọ́n bá ti lè rí koríko tútù yọ̀yọ̀ jẹ, ibi tí wọ́n ti máa rí omi mu gan-an àti ibi ààbò tí wọ́n ti lè sinmi. Ó jọ pé nínú àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run tí kò mọ bí wọ́n ṣe ń dáàbò bo ara wọn rárá, tàwọn àgùntàn yọyẹ́. Àfi bíi pé ṣe ni Ọlọ́run dìídì dá wọn lọ́nà tó fi jẹ́ pé èèyàn ní láti máa tọ́ wọn sọ́nà, kó sì máa dáàbò bò wọ́n. Ó ṣeé ṣe kí Ébẹ́lì wá rí i pé òun náà nílò ìtọ́sọ́nà àti ààbò àti ìtọ́jú Ọlọ́run tó ní ọgbọ́n àti agbára ju ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ irú èrò bẹ́ẹ̀ ni yóò máa bá Ọlọ́run sọ nígbà tó bá ń gbàdúrà, ìyẹn á sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ máa pọ̀ sí i.
14, 15. Báwo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tó ń ṣẹ ṣe mú kí Ébẹ́lì rí nǹkan láti ṣàṣàrò lé lórí?
14 Àwọn ìlérí Jèhófà. Ádámù àti Éfà á ti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì tí Ọlọ́run fi lé àwọn jáde kúrò níbẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. Torí náà, Ébẹ́lì máa rí ọ̀pọ̀ nǹkan ṣàṣàrò lé lórí.
15 Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fi ilẹ̀ gégùn-ún. Ébẹ́lì alára yóò sì ti máa rí bí ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe ṣẹ, tí ilẹ̀ ń mú ẹ̀gún àti òṣùṣú jáde lóòótọ́. Jèhófà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé inú ìrora ni Éfà yóò máa lóyún, inú ìrora ni yóò sì máa bímọ. Ébẹ́lì á ti máa rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn náà ń ṣẹ lóòótọ́ bí ìyá rẹ̀ ṣe ń bí àwọn àbúrò rẹ̀. Jèhófà sì tún rí i ṣáájú pé ọkàn Éfà yóò máa fà sí Ádámù ọkọ rẹ̀ lọ́nà tó pàpọ̀jù, yóò sì fẹ́ máa fa ojú rẹ̀ mọ́ra ṣáá. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ṣe ni Ádámù yóò máa jọba lé e lórí. Gbogbo ìwọ̀nyẹn ni Ébẹ́lì á máa rí pé ó ń ṣẹlẹ̀ láàárín bàbá àti ìyá rẹ̀. Ébẹ́lì rí i pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ ló ṣẹ bó ṣe sọ gẹ́lẹ́. Gbogbo èyí mú kí Ébẹ́lì ní ìgbàgbọ́ tó dájú nínú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé “irú-ọmọ” kan ń bọ̀ wá ṣàtúnṣe gbogbo nǹkan tó ti wọ́ wá látinú ọgbà Édẹ́nì.—Jẹ́n. 3:15-19.
16, 17. Kí ló ṣeé ṣe kí Ébẹ́lì rí kọ́ lára àwọn kérúbù tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà?
16 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Lóòótọ́, kò sí ẹ̀dá èèyàn tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere tí Ébẹ́lì lè tẹ̀ lé nígbà yẹn, àmọ́ àwọn èèyàn nìkan kọ́ ni ẹ̀dá olóye tó wà nínú ayé lásìkò náà. Nígbà tí Jèhófà lé Ádámù àti Éfà jáde nínú ọgbà Édẹ́nì, ó rí i dájú pé kò sí èyíkéyìí nínú wọn tàbí àtọmọdọ́mọ wọn tó máa lè wọnú Párádísè orí ilẹ̀ ayé yẹn pa dà. Ohun tí Jèhófà ṣe ni pé ó fi àwọn kérúbù, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì tí ipò wọn ga gan-an ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ọgbà náà, ó sì fi abẹ idà tó ń jó lala, tó sì ń yí ara rẹ̀ láìdáwọ́ dúró síbi àbáwọlé rẹ̀.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:24.
17 Wá fojú inú wo bó ṣe máa rí lára Ébẹ́lì bó ṣe ń rí àwọn kérúbù yẹn nígbà tó wà lọ́mọdé. Bó ṣe ń rí wọn nínú ara ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n gbé wọ̀, yóò rí i pé agbára wọn bùáyà. “Idà” tó wà níbẹ̀, tó ń jó lala nígbà gbogbo, tó sì ń yí láìdáwọ́ dúró tún jẹ́ ohun àgbàyanu. Bí Ébẹ́lì ṣe ń dàgbà, ǹjẹ́ ó fìgbà kankan rí i pé ìdúró sú àwọn áńgẹ́lì náà, tí wọ́n sì fi ibi tí wọ́n ń ṣọ́ sílẹ̀? Ó tì o. Ojú ń mọ́, ilẹ̀ ń ṣú, ọdún ń gorí ọdún, títí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún fi ré kọjá, síbẹ̀ àwọn ẹ̀dá tó ní làákàyè wọ̀nyẹn kò kúrò ní ọ̀gangan ibi tí Ọlọ́run fi wọ́n ṣọ́. Ìyẹn jẹ́ kí Ébẹ́lì lè rí i pé Jèhófà Ọlọ́run ní àwọn ìránṣẹ́ tó jẹ́ olódodo àti adúróṣinṣin. Ó wá rí àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin àti ìgbọràn sí Jèhófà kọ́ lára àwọn kérúbù yẹn, èyí tí kò rí kọ́ nínú ìdílé rẹ̀. Ó dájú pé àpẹẹrẹ àwọn áńgẹ́lì yẹn máa mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára.
18. Àwọn nǹkan wo ló lè mú ká dẹni tó ní ìgbàgbọ́ lónìí?
18 Bí Ébẹ́lì ṣe ń ṣàṣàrò lórí gbogbo ohun tí Jèhófà fi hàn nípa ara rẹ̀, èyí tó ń rí nínú àwọn nǹkan tó dá, nínú àwọn ìlérí rẹ̀ àti àpẹẹrẹ àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣe ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ ń lágbára sí i. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rẹ̀ ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ lóòótọ́. Ó sì tún ń jẹ́ kó dá àwọn ọ̀dọ́ lójú pé wọ́n lè ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run, yálà àwọn ará ilé wọn sin Jèhófà tàbí wọn kò sìn ín. Lónìí, a ń rí àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run lára ìṣẹ̀dá tó yí wa ká, a ní Bíbélì lódindi, a sì tún ń rí àpẹẹrẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó ní ìgbàgbọ́. Dájúdájú, nǹkan wọ̀nyí lè mú kí àwa náà ní ìgbàgbọ́ lónìí.
Ìdí Tí Ẹbọ Ébẹ́lì Fi Ta Yọ
19. Òye òtítọ́ wo ló wá yé Ébẹ́lì nígbà tó yá?
19 Bí ìgbàgbọ́ tí Ébẹ́lì ní nínú Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i, ó fẹ́ ṣe ohun tó máa fi ìgbàgbọ́ tó ní yìí hàn. Ṣùgbọ́n, kí ni ọmọ aráyé lásán-làsàn lè ṣe fún Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run? Ó dájú pé Ọlọ́run kò nílò ẹ̀bùn tàbí ìrànlọ́wọ́ kankan lọ́dọ̀ èèyàn. Nígbà tó yá, òye òtítọ́ kan yé Ébẹ́lì. Ó yé e pé, tí òun bá lè fi ohun tó dára jù nínú nǹkan tí òun ní rúbọ sí Jèhófà tó sì jẹ́ pé ọkàn tó dáa lòun fi ṣe é, inú Jèhófà, Baba òun ọ̀run onífẹ̀ẹ́, yóò dùn sí i.
20, 21. Àwọn nǹkan wo ni Kéènì àti Ébẹ́lì fi rúbọ sí Jèhófà, kí ni Jèhófà sì ṣe?
20 Ni Ébẹ́lì bá mú lára àwọn àgùntàn rẹ̀ láti fi rúbọ. Ó yan àwọn tó dára jù, ìyẹn àkọ́bí, ó sì yan ibi tó rò pé ó dára jù lára wọn. Kéènì náà fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run kó sì gba ìbùkún, torí náà, ó kó lára àwọn èso oko rẹ̀ láti fi rúbọ. Ṣùgbọ́n ìdí tó fi fẹ́ rúbọ yàtọ̀ sí ti Ébẹ́lì. Ìyàtọ̀ yìí wá hàn kedere nígbà tí tẹ̀gbọ́n tàbúrò yìí rú ẹbọ wọn.
21 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni àwọn ọmọ Ádámù méjèèjì yìí fi iná sun ẹbọ wọn lórí pẹpẹ, níbi tí àwọn kérúbù náà ti lè rí wọn, torí àwọn nìkan ni aṣojú Jèhófà tí wọ́n lè rí sójú láyé ìgbà náà. Jèhófà sì dá wọn lóhùn! Bíbélì sọ pé: “Jèhófà fi ojú rere wo Ébẹ́lì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.” (Jẹ́n. 4:4) Bíbélì kò sọ bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ kí wọ́n mọ èyí.
22, 23. Kí nìdí tí Jèhófà fi fojú rere wo ẹbọ Ébẹ́lì?
22 Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fojú rere wo Ébẹ́lì? Ṣé torí ohun tí Ébẹ́lì fi rúbọ ni? Ẹ̀dá abẹ̀mí ni Ébẹ́lì pa, tó ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ iyebíye sílẹ̀, tó wá fi rúbọ. Àbí Ébẹ́lì kàn tiẹ̀ fòye mọ bí ẹbọ náà ṣe máa wúlò tó ni? Ó ṣẹlẹ̀ pé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà náà, Ọlọ́run fi ẹbọ ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò lábùkù ṣàpẹẹrẹ bó ṣe máa fi Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ẹni pípé rúbọ, ìyẹn “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run” tí wọ́n máa ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ láìṣẹ̀. (Jòh. 1:29; Ẹ́kís. 12:5-7) Àmọ́ ṣá o, Ébẹ́lì ò lè mọ gbogbo ìyẹn nígbà náà.
23 Ohun kan tó dá wa lójú ni pé: Ébẹ́lì fi èyí tó dára jù lára ohun tó ní rúbọ. Jèhófà sì fi ojú rere wo ẹbọ yẹn àti Ébẹ́lì tó rú ẹbọ náà. Ìfẹ́ Jèhófà àti ojúlówó ìgbàgbọ́ tó ní ló mú kó rú ẹbọ náà.
24. (a) Kí nìdí tí a kò fi lè sọ pé ẹbọ Kéènì ni kò dáa? (b) Báwo ló ṣe jẹ́ pé ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe títí dòní ni Kéènì ṣe?
24 Àmọ́ ti Kéènì kò rí bẹ́ẹ̀. Jèhófà “kò fi ojú rere kankan wo Kéènì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.” (Jẹ́n. 4:5) Kì í kúkú ṣe pé ẹbọ Kéènì ni kò dáa, torí Òfin tí Ọlọ́run fún Mósè lẹ́yìn náà sọ pé wọ́n lè fi irè oko rúbọ. (Léf. 6:14, 15) Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa Kéènì ni pé “àwọn iṣẹ́ tirẹ̀ burú.” (Ka 1 Jòhánù 3:12.) Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe títí dòní ni Kéènì ṣe. Ó rò pé téèyàn bá ṣáà ti ń ṣe ohun tí àwọn èèyàn á fi lè gbà pé ó ní ìfọkànsìn Ọlọ́run, ìyẹn náà ti tó. Ṣùgbọ́n kíá ni ìṣe rẹ̀ fi hàn pé kò ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, kò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn.
25, 26. Ìkìlọ̀ wo ni Jèhófà fún Kéènì, àmọ́ kí ni Kéènì ṣe?
25 Nígbà tí Kéènì wá rí i pé Jèhófà kò fojú rere wo òun, ṣé ó gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ébẹ́lì? Rárá o. Ṣe ló kanrí àbúrò rẹ̀ mọ́nú. Jèhófà rí ohun tí Kéènì ń rò lọ́kàn, ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gbà á nímọ̀ràn. Ó kìlọ̀ fún Kéènì pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ohun tó ń pète máa yọrí sí, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé ara rẹ̀ ṣì lè “yá gágá” tó bá lè yíwà pa dà.—Jẹ́n. 4:6, 7.
26 Kéènì kọ etí ikún sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run. Ó wá ní kí àbúrò òun tó fọkàn tán an yìí bá òun lọ sí pápá. Ibẹ̀ ni Kéènì ti lu Ébẹ́lì pa. (Jẹ́n. 4:8) Nípa báyìí, a lè sọ pé Ébẹ́lì ni ẹni àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe inúnibíni ẹ̀sìn sí, òun sì ni ẹni àkọ́kọ́ tó jẹ́ ajẹ́rìíkú. Ó kú lóòótọ́ o, àmọ́ ìtàn rẹ̀ ò kàn parí síbẹ̀.
27. (a) Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà máa jí Ébẹ́lì dìde? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè rí Ébẹ́lì lọ́jọ́ iwájú?
27 Ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì ké jáde sí Jèhófà Ọlọ́run lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ kó lè gbẹ̀san tàbí kó ṣèdájọ́ ẹni tó tá a sílẹ̀. Ọlọ́run sì ṣèdájọ́ lóòótọ́, torí ó fìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà jẹ Kéènì oníwà ìkà. (Jẹ́n. 4:9-12) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, a ń rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ìgbàgbọ́ Ébẹ́lì tó wà lákọsílẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ayé rẹ̀ kò ju nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún, tó fi hàn pé ẹ̀mí rẹ̀ kò gùn tí a bá fi wé bí ọjọ́ ayé wọn ṣe máa ń gùn nígbà yẹn, síbẹ̀ ó fi ìwọ̀nba tó lò láyé ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kó tó kú, ó mọ̀ pé òun ti rí ojú rere Jèhófà Baba òun ọ̀run, ó sì fẹ́ràn òun. (Héb. 11:4) Ìyẹn jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà tí kì í gbàgbé nǹkan á ṣì máa rántí rẹ̀, yóò sì jí i dìde sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. (Jòh. 5:28, 29) Ṣé wàá wà níbẹ̀ láti lè rí i nígbà yẹn? Wàá lè wà níbẹ̀ tó o bá pinnu pé wàá máa fi ẹ̀kọ́ tó o rí kọ́ lára Ébẹ́lì sílò, tó o sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó ta yọ.
a Ní èdè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “ìgbà pípilẹ̀ ayé” níhìn-ín jẹ mọ́ fífúnrúgbìn, èyí tó lè túmọ̀ sí mímú irú ọmọ jáde. Ìyẹn fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà ń tọ́ka sí àkọ́kọ́ nínú irú ọmọ ẹ̀dá èèyàn. Kí nìdí tó fi wá jẹ́ pé Ébẹ́lì ni Jésù tọ́ka sí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “ìgbà pípilẹ̀ ayé” dípò Kéènì tó jẹ́ ọmọ àkọ́kọ́ tí wọ́n bí láyé? Ìdí ni pé, ìwà Kéènì àti ìpinnu rẹ̀ fi hàn pé ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Kéènì wá dà bí ti àwọn òbí rẹ̀, torí kò jọ pé ó wà lára àwọn tó máa ní àjíǹde àti àwọn tó lè rí ìràpadà ẹ̀ṣẹ̀ gbà.