Ìwọ Ha Rántí Bí?
Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́? Bó bá jẹ́ pé o gbádùn rẹ̀, yóò dùn mọ́ ọ láti rántí àwọn kókó tó tẹ̀ lé yìí:
◻ Èé ṣe tó fi yẹ kí a ní ìgbọ́kànlé nínú àwọn ènìyàn tí Jèhófà yàn láti darí àwọn ènìyàn rẹ̀?
Àwọn tí wọ́n ní ànímọ́ yíyẹ láti lè darí àwọn ènìyàn Jèhófà lọ́nà tí ó fẹ́ kí wọ́n tọ̀ ní àkókò kan pàtó ni ó ń yan àwọn ẹrù iṣẹ́ kan pàtó fún.—8/15, ojú ìwé 14.
◻ Kí ni a rí kọ́ nínú ìrírí Jónà?
Tara Jónà nìkan ló ń rò ṣáá, kò ro tàwọn ẹlòmíràn. A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jónà nípa ṣíṣàì ka ara wa àti ìmọ̀lára tiwa sí pàtàkì jù.—8/15, ojú ìwé 19.
◻ Ọ̀nà wo ni a lè gbà sọ pé “orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára”? (Òwe 18:10)
Sísá tí a sá di orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà fúnra rẹ̀. (Sáàmù 20:1; 122:4) Ó túmọ̀ sí kíkọ́wọ́ ti ipò ọba aláṣẹ rẹ̀, gbígbé òfin àti ìlànà rẹ̀ lárugẹ, níní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí rẹ̀, àti fífún un ní ìjọsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe. (Aísáyà 50:10; Hébérù 11:6)—9/1, ojú ìwé 10.
◻ Báwo ni ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà wàásù níwájú àwọn lóókọ-lóókọ ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ kan fún wa?
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá Ágírípà Ọba sọ̀rọ̀, ó lo ọgbọ́n inú, ó tẹnu mọ́ àwọn kókó tí òun àti Ágírípà jọ gbà. Lọ́nà kan náà, ó yẹ kí a máa tẹnu mọ́ àwọn apá gbígbámúṣé inú ìhìn rere náà, kí a máa tẹnu mọ́ àwọn ìrètí tí a jọ ní. (1 Kọ́ríńtì 9:22)—9/1, ojú ìwé 31.
◻ Àwọn wo ni wọ́n ń jàǹfààní sùúrù Jèhófà?
Nítorí sùúrù Jèhófà, a ti fún ọ̀pọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ láǹfààní láti di ẹni tí ó la “ọjọ́ Jèhófà” já. (2 Pétérù 3:9-15) Sùúrù rẹ̀ tún ń jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ‘máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà wa yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.’ (Fílípì 2:12)—9/15, ojú ìwé 20.
◻ Báwo ni ìtumọ̀ Bíbélì ti Septuagint ṣe ṣeyebíye tó?
Ìtumọ̀ yìí kó ipa pàtàkì kan nínú títan ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀, tí Jésù Kristi jẹ́ Ọba rẹ̀ kalẹ̀. Nípasẹ̀ ẹ̀dà Septuagint, a fi ìpìlẹ̀ pàtàkì kan lélẹ̀ fún àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì àti àwọn Kèfèrí ní ọ̀rúndún kìíní láti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Ìjọba náà.—9/15, ojú ìwé 30.
◻ Kí ni àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá kọ́ wa nípa Ọlọ́run?
Èkíní, ó fi hàn pé Jèhófà jẹ́ “aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, [tí] ó ń lọ́ra láti bínú, [tí] ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” (Ẹ́kísódù 34:6) Èkejì ni pé, ó “ṣe tán láti dárí jini” nígbà tí ìyípadà èyíkéyìí nínú ọkàn-àyà bá jẹ́ ìpìlẹ̀ fún un láti nawọ́ àánú sí wa. (Sáàmù 86:5)—10/1, ojú ìwé 12, 13.
◻ Nígbà wo ni ipò àlàáfíà tí a ṣèlérí nínú Aísáyà 65:21-25 yóò nímùúṣẹ?
Gẹ́gẹ́ bí àwọn olùjọsìn Jèhófà tí wọ́n ṣọ̀kan nínú párádísè tẹ̀mí lónìí, àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn tí wọ́n jẹ́ “àgùntàn mìíràn” ń gbádùn àlàáfíà Ọlọ́run nísinsìnyí. (Jòhánù 10:16) Irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀ yóò sì nasẹ̀ dé Párádísè tí a lè fojú rí náà, nígbà tí ‘ìfẹ́ Ọlọ́run bá ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run.’ Ìgbà yẹn ni àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà yóò nímùúṣẹ ní kíkún. (Mátíù 6:10)—10/15, ojú ìwé 24.
◻ Èé ṣe tí àwọn Kristẹni fi ń ṣàyájọ́ ìgbéyàwó ṣùgbọ́n tí wọn kì í ṣàyájọ́ ọjọ́ ìbí?
Bíbélì kò fojú burúkú wo ìgbéyàwó. Nítorí náà, yálà àwọn Kristẹni kan yàn láti ṣàyájọ́ ìgbéyàwó wọn, ní ríronú lórí ìdùnnú ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti ìpinnu wọn láti ṣiṣẹ́ fún àṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni. Àmọ́ ṣá o, ìwọ̀nba ayẹyẹ ọjọ́ ìbí tí a mẹ́nu kàn nínú Bíbélì jẹ́ ti àwọn abọ̀rìṣà, a sì so ó pọ̀ mọ́ ìwà òǹrorò.—10/15, ojú ìwé 30, 31.
◻ Nínú àkàwé Pọ́ọ̀lù tí a kọ sílẹ̀ ní 1 Kọ́ríńtì 3:12, 13, kí ni “iná” dúró fún, kí ló sì yẹ kí gbogbo Kristẹni lóye?
Iná kan wà tí gbogbo wa dojú kọ nínú ìgbésí ayé—ìdánwò ìgbàgbọ́ wa. (Jòhánù 15:20; Jákọ́bù 1:2, 3) Olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni a óò dán wò. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé, bí a kò bá kọ́ wọn dáradára, àbájáde rẹ̀ lè bani nínú jẹ́. (1 Kọ́ríńtì 3:15)—11/1, ojú ìwé 11.
◻ Ọ̀nà wo ni Nóà fi “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn”? (Jẹ́nẹ́sísì 6:9)
Nóà bá Ọlọ́run rìn ní ti pé ó ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ fún un pé kí ó ṣe. Nítorí pé ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sọ́tọ̀ fún ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó gbádùn ipò ìbátan ọlọ́yàyà, tí ó ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.—11/15, ojú ìwé 10.
◻ Àǹfààní wo ni àìmọ àkókò náà gan-an tí ìbínú Ọlọ́run yóò dé sórí àwọn ẹni búburú ṣí sílẹ̀ fún wa?
Ó fún wa láǹfààní láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ní tòótọ́ àti pé a fẹ́ láti máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ títí láé. Ó tún fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, a sì gbọ́kàn lé ọ̀nà tí ó ń gbà bójú tó àwọn ọ̀ràn. Síwájú sí i, èyí ń ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò, kí a sì jí kalẹ̀ nípa tẹ̀mí. (Mátíù 24:42-44)—11/15, ojú ìwé 18.
◻ Kí ló túmọ̀ sí láti ní ìgbàgbọ́ “nínú orúkọ Ọmọ Ọlọ́run”? (1 Jòhánù 5:13)
Èyí túmọ̀ sí ṣíṣègbọràn sí gbogbo àṣẹ Kristi, títí kan àṣẹ tí ó pa pé ‘kí a nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ (Jòhánù 15:14, 17) Ìfẹ́ máa ń fẹ́ láti ṣoore fún àwọn ẹlòmíràn. Ó ń wó ẹ̀tanú ti ẹ̀yà, ẹ̀sìn, àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà palẹ̀.—12/1, ojú ìwé 7.
◻ Èé ṣe tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi jẹ́ “ẹni ìkórìíra”? (Mátíù 10:22)
Ìdí kan náà tí àwọn èèyàn fi ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni ìjímìjí ló mú kí wọ́n kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́nà àìtọ́. Èkíní, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ẹ̀sìn wọn ṣèwà hù lọ́nà tí ń mú kí àwọn kan fojú burúkú wò wọ́n. Ìkejì, wọ́n ti fi oríṣiríṣi ẹ̀sùn èké kàn wọ́n—irọ́ pátápátá àti lílọ́ àwọn ìgbàgbọ́ wọn po.—12/1, ojú ìwé 14.