Kí Nìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Máa Ṣọ́nà?
“Ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.”—MÁT. 24:42.
1. Ṣàpèjúwe ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wà lójúfò sí àkókò tá a wà yìí àtohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká wa. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
LÁWỌN àpéjọ agbègbè wa, a máa ń rí aago kan lójú tẹlifíṣọ̀n tó ń dún kẹ, kẹ, kẹ títí ìpàdé á fi bẹ̀rẹ̀. Tá a bá ti rí aago yìí, a mọ̀ pé ó ti tó àkókò láti jókòó, ká sì gbádùn orin táwọn ẹgbẹ́ akọrin Watchtower máa ń kọ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀. Bákan náà, a mọ̀ pé àsìkò ti tó láti múra ọkàn wa sílẹ̀ fún àwọn àsọyé tá a máa gbọ́. Àmọ́, báwo ló ṣe máa rí táwọn kan ò bá pọkàn pọ̀, tí wọ́n ń rìn kiri tàbí tí wọ́n ń bára wọn sọ̀rọ̀ láìka ti pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti bẹ̀rẹ̀? Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò wà lójúfò sí ohun táago sọ àtohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká wọn, wọn ò kíyè sí pé alága ti wà lórí pèpéle, pé orin ti ń dún àti pé àwùjọ ti jókòó jẹ́ẹ́. Àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká túbọ̀ wà lójúfò torí pé ohun ńlá kan máa tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo nìyẹn?
2. Kí nìdí tí Jésù fi sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣọ́nà?
2 Nígbà tí Jésù ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́.” Jésù tún wá tẹnu mọ́ ọn fún wọn pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Mát. 24:3; ka Máàkù 13:32-37.) Nígbà tí Mátíù ń ròyìn ohun kan náà, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wà lójúfò, ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀. . . . Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” Ó tún sọ fún wọn lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.”—Mát. 24:42-44; 25:13.
3. Kí nìdí tá a fi ń fọwọ́ pàtàkì mú ìkìlọ̀ Jésù?
3 Ọwọ́ pàtàkì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú ìkìlọ̀ Jésù yìí. Ìdí sì ni pé a mọ̀ pé òpin ti dé tán àti pé àkókò tó kù kí “ìpọ́njú ńlá” bẹ̀rẹ̀ kò tó nǹkan mọ́. (Dán. 12:4; Mát. 24:21) Kárí ayé ni ogun ti ń jà, ìṣekúṣe ń peléke sí i, ìwàkiwà túbọ̀ ń gbilẹ̀, ọ̀rọ̀ ìsìn ò lójú, àìtó oúnjẹ, àjàkálẹ̀ àrùn àti ìmìtìtì ilẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ káàkiri. A tún rí i pé àwa èèyàn Jèhófà ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà kárí ayé. (Mát. 24:7, 11, 12, 14; Lúùkù 21:11) Ìdí nìyẹn tá a fi ń fojú sọ́nà fún ohun tí Jésù máa ṣe fún wa tó bá dé, àti bó ṣe máa mú kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ṣẹ.—Máàkù 13:26, 27.
ỌJỌ́ NÁÀ Ń SÚN MỌ́LÉ
4. (a) Kí ló mú ká gbà pé Jésù ti mọ ìgbà tí ogun Amágẹ́dọ́nì máa jà? (b) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ ìgbà tí ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀, kí ló dá wa lójú?
4 A mọ̀ pé ó ní àkókò pàtó tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè máa ń bẹ̀rẹ̀. Síbẹ̀, kò sí bá a ṣe mọ̀ ọ́n ṣe tó, a ò lè mọ ọdún pàtó tí ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀, ká má tíì wá sọ ọjọ́ tàbí wákátì tó máa bẹ̀rẹ̀. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mát. 24:36) Àmọ́ lẹ́yìn tí Jésù pa dà sọ́run, Jèhófà fún un lágbára láti pa ayé Sátánì run. (Ìṣí. 19:11-16) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Jésù ti wá mọ ìgbà tí ogun Amágẹ́dọ́nì máa jà. Àmọ́ àwa ò mọ̀ ọ́n. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká wà lójúfò títí dìgbà ìpọ́njú ńlá. Ohun kan ni pé àtilẹ̀ ni Jèhófà ti mọ ìgbà tí gbogbo nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀. Ó ti pinnu àkókò pàtó tí òpin máa dé. Ohun tó ń retí ni pé kí àkókò náà tó kí ìpọ́njú ńlá bẹ̀rẹ̀, ó sì dájú pé “kì yóò pẹ́.” (Ka Hábákúkù 2:1-3.) Kí ló mú kí èyí dá wa lójú?
5. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà máa ń ṣẹ lásìkò pàtó tó ní lọ́kàn.
5 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà máa ń ṣẹ lásìkò pàtó tó ní lọ́kàn. Àpẹẹrẹ kan ni bó ṣe dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lóko ẹrú ní Íjíbítì nídè lásìkò tó sọ gẹ́lẹ́. Nígbà tí Mósè ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ tí wọ́n jáde lóko ẹrú, ìyẹn Nísàn 14, ọdún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó sọ pé: “Ní òpin irínwó ọdún ó lé ọgbọ̀n [430] náà, àní ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yìí gan-an pé, gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.” (Ẹ́kís. 12:40-42) “Irínwó ọdún ó lé ọgbọ̀n [430]” náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́dún 1943 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Gál. 3:17, 18) Nígbà tó yá, Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: “Kí o mọ̀ dájú pé irú-ọmọ rẹ yóò di àtìpó ní ilẹ̀ kan tí kì í ṣe tiwọn, wọn yóò sì ní láti sìn wọ́n, àwọn wọ̀nyí yóò sì ṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́ dájúdájú fún irínwó [400] ọdún.” (Jẹ́n. 15:13; Ìṣe 7:6) “Irínwó [400] ọdún” tí Bíbélì ní wọ́n á fi ṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́ bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1913 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ṣẹlẹ́yà lẹ́yìn tí wọ́n já Ísákì lẹ́nu ọmú, ó sì parí nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì lọ́dún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Jẹ́n. 21:8-10; Gál. 4:22-29) Àbí ẹ ò rí nǹkan, ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́rin ṣáájú ni Jèhófà ti sọ àkókò pàtó tóun máa dá àwọn èèyàn òun nídè!
6. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀?
6 Jóṣúà wà lára àwọn tí Jèhófà dá nídè kúrò ní Íjíbítì, ó sì rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé: ‘Ẹ̀yin mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.’ (Jóṣ. 23:2, 14) Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa dáàbò bo àwa náà nígbà ìpọ́njú ńlá, ó sì dá wa lójú pé kò ní já wa kulẹ̀. Àmọ́ ṣá o, tá a bá fẹ́ la òpin ètò búburú yìí já, àfi ká máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.
Ó ṢE PÀTÀKÌ KÁ WÀ LÓJÚFÒ TÁ A BÁ FẸ́ RÍ ÌGBÀLÀ
7, 8. (a) Kí ni iṣẹ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ láyé àtijọ́, ẹ̀kọ́ wo sì ni èyí kọ́ wa? (b) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ táwọn ẹ̀ṣọ́ bá sùn lọ lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Sọ àpẹẹrẹ kan.
7 A lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká wà lójúfò látinú ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe nígbà àtijọ́. Láyé àtijọ́, àwọn ìlú ńlá bíi Jerúsálẹ́mù máa ń ní odi gìrìwò tó yí i ká. Odi yìí máa ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, àtorí odi yìí ni àwọn ẹ̀ṣọ́ ti máa ń ṣọ́ ohun tó ń lọ láyìíká torí pé ó ga dáadáa. Tọ̀sántòru làwọn ẹ̀ṣọ́ yìí sì máa ń wà lórí odi náà àti lẹ́nu bodè. Iṣẹ́ wọn ni láti ta àwọn ará ìlú lólobó tí wọ́n bá rí ewu tó ń bọ̀. (Aísá. 62:6) Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé kí àwọn ẹ̀ṣọ́ yìí wà lójúfò, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ohun tó ń lọ láyìíká wọn, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ wẹ́rẹ́ logun á wọlé táá sì pa àwọn èèyàn.—Ìsík. 33:6.
8 Òpìtàn Júù kan tó ń jẹ́ Josephus sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. Ó sọ pé ohun tó mú káwọn ọmọ ogun Róòmù ráyè wọ Ilé Gogoro Antonia tí wọ́n kọ́ mọ́ odi Jerúsálẹ́mù ni pé àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà lẹ́nu bodè ti sùn lọ fọnfọn! Àtibẹ̀ làwọn ọmọ ogun Róòmù ti rọ́ wọ tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì dáná sun ún. Èyí ló fa ìpọ́njú tó tíì burú jù lọ táwọn Júù fojú winá nílùú Jerúsálẹ́mù.
9. Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn ò mọ̀ lónìí?
9 Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lónìí ló ní àwọn aṣọ́bodè, wọ́n sì máa ń lo kámẹ́rà àtàwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé míì láti ṣọ́ ohun tó ń lọ. Wọ́n máa ń ṣọ́ àwọn tó bá fẹ́ pẹ́ ọ̀nà wọ̀lú àtàwọn ọ̀tá tó bá fẹ́ ṣe wọ́n ní jàǹbá. Àmọ́, àwọn nǹkan téèyàn lè fojú rí àtàwọn èèyàn tó bá fẹ́ kógun wọ̀lú nìkan láwọn aṣọ́bodè àtàwọn kámẹ́rà yìí lè rí. Wọn ò mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tí Kristi ń ṣàkóso àtàwọn ohun tó ń ṣe, àti bó ṣe máa tó ṣèdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè. (Aísá. 9:6, 7; 56:10; Dán. 2:44) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá wà lójúfò nípa tẹ̀mí, tá a sì ń ṣọ́nà, a máa wà ní ìmúratán nígbàkigbà tọ́jọ́ ìdájọ́ yìí bá dé.—Sm. 130:6.
MÁ ṢE JẸ́ KÍ OHUNKÓHUN PÍN ỌKÀN RẸ NÍYÀ BÓ O ṢE Ń ṢỌ́NÀ
10, 11. (a) Kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún, kí sì nìdí? (b) Kí ló mú kó o gbà pé Èṣù ti fọ́ àwọn èèyàn lójú kí wọ́n má bàa kọbi ara sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì?
10 Fojú inú wo ẹ̀ṣọ́ kan tó ti wà lójúfò ní gbogbo òru. Ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í tòògbé tó bá ti ń di ọwọ́ àfẹ̀mọ́jú. Bákan náà, bá a ṣe ń sún mọ́ òpin ètò yìí, ó lè túbọ̀ ṣòro láti wà lójúfò. Àdánù gbáà ló máa jẹ́ tá a bá lọ sùn nípa tẹ̀mí! Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun mẹ́ta tó lè mú ká dẹra nù, débi pé tá ò bá ṣọ́ra a lè má wà lójúfò mọ́.
11 Èṣù ń mú káwọn èèyàn kọtí ikún sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí Jésù tó kú, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòh. 12:31; 14:30; 16:11) Jésù mọ̀ pé Èṣù máa fi àwọn èèyàn sínú òkùnkùn tẹ̀mí kí wọ́n má bàa fọkàn sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀, àti pé Èṣù ò fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òpin ti sún mọ́. (Sef. 1:14) Ìsìn èké ni Sátánì ń lò láti fọ́ ojú inú àwọn èèyàn. Kí lo máa ń kíyè sí tó o bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀? Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé Èṣù ti fọ́ ojú inú àwọn aláìgbàgbọ́ tó fi jẹ́ pé wọn ò mọ̀ pé Ọlọ́run máa tó pa ayé búburú yìí run àti pé Kristi ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run? (2 Kọ́r. 4:3-6) Tó o bá lọ wàásù, ṣé àwọn èèyàn máa ń sọ fún ẹ pé, “Mi ò ráyè”? Lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe ni wọ́n máa ń kọtí ikún tá a bá sọ fún wọn pé ìparun rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí ayé yìí.
12. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ kí Èṣù tàn wá jẹ?
12 Lóòótọ́, àwọn èèyàn ò kọbi ara sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ má ṣe jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ débi tó ò fi ní wà lójúfò mọ́. Ìwọ náà mọ̀ pé ìyẹn léwu. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni pé: “Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀.” Ó wá fi kún un pé, yóò dé “gẹ́gẹ́ bí olè ní òru.” (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:1-6.) Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” (Lúùkù 12:39, 40) Láìpẹ́, Sátánì máa mú káwọn èèyàn gbà pé “àlàáfíà àti ààbò” ti dé sáyé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀tàn lásán ni. Wọ́n á wá rò pé ìtura ti dé. Àwa ńkọ́? Tá a bá ‘wà lójúfò, tí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́,’ ọjọ́ ìdájọ́ yẹn kò ní “bá [wa] lójijì gẹ́gẹ́ bí yóò ti dé bá àwọn olè.” Ìdí nìyẹn tá a fi gbọ́dọ̀ máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tí Jèhófà ń sọ fún wa.
13. Àkóbá wo ni ẹ̀mí ayé ń ṣe fún àwọn èèyàn? Kí la lè ṣe tí ẹ̀mí ayé kò fi ní kó èèràn ràn wá?
13 Ẹ̀mí ayé ń mú káwọn èèyàn máa sùn nípa tẹ̀mí. Kòókòó-jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé tọ́pọ̀ ń lé kiri kò jẹ́ kí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí” jẹ wọ́n lọ́kàn mọ́. (Mát. 5:3) Bí wọ́n á ṣe kó nǹkan jọ ni wọ́n ń wá, èyí sì máa ń mú kí “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” jọba lọ́kàn wọn. (1 Jòh. 2:16) Àwọn eré ìnàjú táyé ń gbé lárugẹ ti mú káwọn èèyàn di “olùfẹ́ adùn,” àwọn eré ọ̀hún sì túbọ̀ ń burú sí i bọ́dún ṣe ń gorí ọdún. (2 Tím. 3:4) Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi gba àwa Kristẹni nímọ̀ràn pé ká ‘má ṣe máa wéwèé tẹ́lẹ̀ fún àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara,’ èyí tó ń mú kéèyàn sùn nípa tẹ̀mí.—Róòmù 13:11-14.
14. Ìkìlọ̀ wo ló wà nínú Lúùkù 21:34, 35?
14 Ká má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ayé máa darí wa, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run ni ká jẹ́ kó máa darí wa. Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń mú ká lóye àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.[1] (1 Kọ́r. 2:12) Síbẹ̀, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé kò dìgbà tí nǹkan ńlá bá dojú kọ wá ká tó sùn nípa tẹ̀mí, tá ò bá ṣọ́ra àwọn nǹkan kéékèèké pàápàá lè mú ká sùn nípa tẹ̀mí. (Ka Lúùkù 21:34, 35.) Àwọn míì tiẹ̀ lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé à ń ṣọ́nà, àmọ́ a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kíyẹn mú ká dẹra nù. (2 Pét. 3:3-7) Kàkà bẹ́ẹ̀, tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa, a gbọ́dọ̀ máa pé jọ déédéé pẹ̀lú àwọn ará láwọn ìpàdé ìjọ.
15. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù? Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn ṣe lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà?
15 Ara àìpé wa lè mú kó ṣòro fún wa láti wà lójúfò. Jésù mọ̀ pé ó rọrùn fún àwa èèyàn aláìpé láti dẹra nù torí àìpé wa. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn kí wọ́n tó pa á. Ó ní láti bẹ Jèhófà pé kó fún òun lókun lásìkò yẹn kóun má bàa bọ́hùn. Jésù wá ní kí Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù máa ṣọ́nà bóun ṣe ń gbàdúrà. Àmọ́ wọn ò mọ bí ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó. Kàkà kí wọ́n wà lójúfò bí Ọ̀gá wọn ṣe sọ, àárẹ̀ mú wọn torí àìpé ẹ̀dá, wọ́n sì sùn lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ Jésù náà, ó wà lójúfò, ó sì ń gbàdúrà kíkankíkan sí Baba rẹ̀. Ohun kan náà ló yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ṣe lásìkò yẹn.—Máàkù 14:32-41.
16. Báwo la ṣe lè wà lójúfò bí Jésù ṣe sọ nínú Lúùkù 21:36?
16 Kéèyàn “wà lójúfò” nípa tẹ̀mí kọjá pé kó máa wu èèyàn láti ṣe ohun tó tọ́. Ọjọ́ mélòó kan kí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Gẹtisémánì tó wáyé, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí kan náà pé kí wọ́n máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà. (Ka Lúùkù 21:36.) Torí náà, ká tó lè máa ṣọ́nà nípa tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà nígbà gbogbo.—1 Pét. 4:7.
MÁA BÁ A NÌṢÓ NÍ ṢÍṢỌ́NÀ
17. Báwo la ṣe lè gbara dì fún ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?
17 Jésù sọ pé òpin máa dé “ní wákàtí tí [a] kò ronú pé yóò jẹ́,” torí náà, kì í ṣe àkókò yìí ló yẹ ká máa tòògbé nípa tẹ̀mí. Àsìkò yìí kọ́ ló yẹ ká máa lé àwọn nǹkan tí ayé Sátánì ń gbé lárugẹ àtàwọn nǹkan tí ara àìpé wa ń fẹ́. (Mát. 24:44) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àá rí ohun tí Ọlọ́run àti Kristi sọ pé àwọn máa ṣe fún wa láìpẹ́ àti ọ̀nà tá a lè gbà máa ṣọ́nà. Torí náà, ó yẹ ká fọwọ́ gidi mú ìjọsìn Ọlọ́run, ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì rí i pé ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ló gbawájú láyé wa. A gbọ́dọ̀ fiyè sí àkókò tá a wà yìí àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ká lè gbara dì fún ohun tó ń bọ̀. (Ìṣí. 22:20) Ìdí ni pé ẹ̀mí wa lè lọ sí i tá ò bá wà lójúfò!