Ìgbà Àti Àsìkò Wà Lọ́wọ́ Jèhófà
“Kì í ṣe tiyín láti mọ àwọn ìgbà tàbí àsìkò tí Baba ti fi sí abẹ́ àṣẹ òun fúnra rẹ̀.”—ÌṢE 1:7.
1. Báwo ni Jésù ṣe dáhùn ìbéèrè àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nípa ìgbà?
OHUN mìíràn wo ni àwọn “tí ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí a ń ṣe” ní Kirisẹ́ńdọ̀mù àti jákèjádò ilẹ̀ ayé lè máa béèrè bí kò ṣe ìgbà tí ètò àwọn nǹkan burúkú yìí yóò wá sópin, tí a óò sì fi ayé tuntun Ọlọ́run rọ́pò rẹ̀? (Ìsíkíẹ́lì 9:4; 2 Pétérù 3:13) Àwọn àpọ́sítélì Jésù béèrè àwọn ìbéèrè nípa ìgbà lọ́wọ́ rẹ̀ kí ó tó kú, àti lẹ́yìn tí ó jíǹde. (Mátíù 24:3; Ìṣe 1:6) Ṣùgbọ́n, nígbà tí Jésù ń fèsì, kò sọ fún wọn bí wọn yóò ṣe máa ka ọjọ́. Nígbà kan, ó fún wọn ní àmì alápá púpọ̀, nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ó wí fún wọn pé ‘kì í ṣe tiwọn láti mọ àwọn ìgbà tàbí àsìkò tí Baba ti fi sí abẹ́ àṣẹ òun fúnra rẹ̀.’—Ìṣe 1:7.
2. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Jésù kó fìgbà gbogbo mọ àkókò tí Baba rẹ̀ yàn fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò ṣẹlẹ̀ lákòókò òpin?
2 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Jèhófà, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni òun alára mọ àwọn àkókò tí Baba rẹ̀ yàn kí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, Jésù fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:36) Jésù múra tán láti mú sùúrù títí tí Baba rẹ̀ yóò fi ṣí àkókò náà gan-an payá fún un tí yóò pa ètò àwọn nǹkan burúkú ti ìsinsìnyí run.a
3. Kí ni a lè rí kọ́ láti inú ìdáhùn Jésù sí àwọn ìbéèrè tí a béèrè nípa ète Ọlọ́run?
3 Ohun méjì ni a lè rí fà yọ nínú ọ̀nà tí Jésù gbà dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbà tí àwọn nǹkan yóò ṣẹlẹ̀ láti mú ète Ọlọ́run ṣẹ. Àkọ́kọ́ ni pé, Jèhófà ní àkókò tí ó ti dá; èkejì ni pé, òun nìkan ṣoṣo ni ó dá àkókò náà, àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ kò sì ní láti máa retí pé kí ó fún àwọn ní ìsọfúnni pàtó nípa ìgbà tàbí àsìkò tí ó ti dá.
Ìgbà àti Àsìkò Jèhófà
4. Kí ni ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí “ìgbà” àti “àsìkò” nínú Ìṣe 1:7?
4 Kí ni “ìgbà” àti “àsìkò” túmọ̀ sí? Oríṣi ìgbà méjì ni ó wà nínú ọ̀rọ̀ Jésù tí a kọ sílẹ̀ nínú Ìṣe 1:7. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a tú sí ‘ìgbà’ túmọ̀ sí “àkókò tí a fi ṣe nǹkan,” àkókò (gígùn tàbí kúkúrú). “Àsìkò” ni ọ̀rọ̀ tí ìtumọ̀ rẹ̀ ń tọ́ka sí ìgbà kan pàtó tàbí ìgbà tí a ti yàn, àsìkò kan, tàbí sáà kan, tí àwọn nǹkan pàtó sàmì sí. Ní ti àwọn ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ méjèèjì yìí, W. E. Vine sọ pé: “Nínú Ìṣe 1:7, ‘Baba ti fi ìgbà (chronos), sáà, àti àsìkò (kairos), ìgbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtó sàmì sí, sábẹ́ àṣẹ Òun fúnra rẹ̀.”
5. Ìgbà wo ni Jèhófà sọ fún Nóà nípa ète Rẹ̀ láti pa ayé oníwà ìbàjẹ́ run, iṣẹ́ alápá méjì wo sì ni Nóà ṣe?
5 Ṣáájú Ìkún Omi, Ọlọ́run tí sọ pé ayé oníwà ìbàjẹ́ tí àwọn ènìyàn àti àwọn áńgẹ́lì ọlọ́tẹ̀ tí wọ́n para dà di ènìyàn mú wá kò ní kọjá 120 ọdún. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-3) Ẹni 480 ọdún ni Nóà olùṣèfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ nígbà náà. (Jẹ́nẹ́sísì 7:6) Kò bímọ, lẹ́yìn ìgbà náà, ó wà bẹ́ẹ̀ fún 20 ọdún. (Jẹ́nẹ́sísì 5:32) Ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá, ìgbà tí àwọn ọmọ Nóà ti dàgbà tí wọ́n sì ti gbéyàwó, ni Ọlọ́run tó wá sọ fún Nóà nípa ète Rẹ̀ láti mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 6:9-13, 18) Síbẹ̀síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fa iṣẹ́ alápá méjì lé Nóà lọ́wọ́, ti kíkọ́ áàkì àti wíwàásù fún àwọn alájọgbáyé rẹ̀, Jèhófà kò ṣí ìgbà tí ó yàn payá fún un.—Jẹ́nẹ́sísì 6:14; 2 Pétérù 2:5.
6. (a) Báwo ni Nóà ṣe fi hàn pé òun fi ọ̀ràn àkókò lé Jèhófà lọ́wọ́? (b) Báwo ni a ṣe lè tẹ́ lé àpẹẹrẹ Nóà?
6 Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún—bóyá ìlàjì ọ̀rúndún kan—“Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un.” Nóà ṣe bẹ́ẹ̀ “nípa ìgbàgbọ́,” láìmọ ọjọ́ náà gan-an pàtó. (Jẹ́nẹ́sísì 6:22; Hébérù 11:7) Jèhófà kò sọ àkókò náà gan-an tí nǹkan náà yóò ṣẹlẹ̀ fún un, àfìgbà tó ku ọ̀sẹ̀ kan kí Àkúnya náà bẹ̀rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 7:1-5) Ìgbẹ́kẹ̀lé kíkúnrẹ́rẹ́ àti ìgbàgbọ́ tí Nóà ní nínú Jèhófà jẹ́ kí ó fi ọ̀ràn àkókò lé Ọlọ́run lọ́wọ́. Ẹ wo bí Nóà yóò ti kún fún ọpẹ́ tó nígbà tó rí i pé Jèhófà dáàbò bo òun nígbà Ìkún Omi náà, tí ó sì jáde láti inú áàkì náà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn sórí ilẹ̀ ayé kan tí a fọ̀ mọ́! Bí a ti ń fojú sọ́nà fún ìrètí ìdáǹdè bẹ́ẹ̀, kò ha yẹ kí a ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ nínú Ọlọ́run?
7, 8. (a) Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn agbára ayé ṣe di èyí tí ó wà? (b) Lọ́nà wo ni Jèhófà gbà ‘gbé àṣẹ kalẹ̀ nípa àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀, tí ó sì pààlà ibùgbé tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn’?
7 Lẹ́yìn Ìkún Omi, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àtọmọdọ́mọ Nóà pa ìjọsìn tòótọ́ ti Jèhófà tì. Nítorí ète àtiwà lójú kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ìlú ńlá kan, àti ilé gogoro fún ìjọsìn èké. Jèhófà pinnu pé ó tó àkókò láti dá sí ọ̀ràn náà. Ó da èdè wọn rú, ó sì “tú wọn ká kúrò níbẹ̀ [ní Bábélì] sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 11:4, 8, 9) Lẹ́yìn náà, àwọn àwùjọ èdè di àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn kan nínú wọn sì gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí wọ́n sì wá di agbára ẹlẹ́kùnjẹkùn, àní agbára ayé pàápàá.—Jẹ́nẹ́sísì 10:32.
8 Ní ìbámu pẹ̀lú ìmúṣẹ ète Ọlọ́run, nígbà mìíràn òun ni ó ń pinnu ààlà ilẹ̀ orílẹ̀-èdè àti àkókò pàtó tí orílẹ̀-èdè kan yóò di alágbára àgbègbè rẹ̀, tàbí tí yóò di agbára ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 15:13, 14, 18-21; Ẹ́kísódù 23:31; Diutarónómì 2:17-22; Dáníẹ́lì 8:5-7, 20, 21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí apá yìí nínú ìgbà àti àsìkò Jèhófà, nígbà tí ó sọ fún àwọn amòye Gíríìkì ní Átẹ́nì pé: “Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, . . . láti ara ọkùnrin kan ni ó sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá, ó sì gbé àṣẹ kalẹ̀ nípa àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ àti àwọn ààlà ibùgbé tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 17:24, 26.
9. Báwo ni Jèhófà ti ṣe “yí ìgbà àti àsìkò padà” ní ti àwọn ọba?
9 Èyí kò túmọ̀ sí pé Jèhófà ni ó fa gbogbo ìṣẹ́gun ìṣèlú àti ìyípadà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Síbẹ̀, ó lè dá sí i nígbà tí ó bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀ láti lè mú ète rẹ̀ ṣẹ. Nípa báyìí, wòlíì Dáníẹ́lì, tí yóò fojú rí ìparẹ́ Agbára Ayé Bábílónì àti bí Mídíà òun Páṣíà yóò ṣe rọ́pò rẹ̀, wí nípa Jèhófà pé: “Ó . . . ń yí ìgbà àti àsìkò padà, ó ń mú àwọn ọba kúrò, ó sì ń fi àwọn ọba jẹ, ó ń fi ọgbọ́n fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó mọ ìfòyemọ̀.”—Dáníẹ́lì 2:21, Aísáyà 44:24–45:7.
“Àkókò Ti Ń Sún Mọ́lè”
10, 11. (a) Báwo ni ìgbà tí Jèhófà ti sọ àkókò tí òun yóò dá àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù nídè kúrò ní òǹdè ti pẹ́ tó? (b) Kí ní fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò mọ ìgbà tí a óò dá àwọn nídè ní pàtó?
10 Ní ohun tí ó lé ní ọ̀rúndún mẹ́rin ṣáájú, Jèhófà sọ ọdún náà pàtó tí òun yóò tẹ́ ọba Agbára Ayé Íjíbítì, tí òun yóò sì dá àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù sílẹ̀ kúrò ní oko ẹrú. Nígbà tí Ọlọ́run ń ṣí ète rẹ̀ payá fún Ábúráhámù, ó ṣèlérí pé: “Kí o mọ̀ dájú pé irú-ọmọ rẹ yóò di àtìpó ní ilẹ̀ kan tí kì í ṣe tiwọn, wọn yóò sì ní láti sìn wọ́n, àwọn wọ̀nyí yóò sì ṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́ dájúdájú fún irínwó ọdún. Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè tí wọn yóò sìn ni èmi yóò dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà, wọn yóò sì jáde kúrò pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ẹrù.” (Jẹ́nẹ́sísì 15:13, 14) Nígbà tí Sítéfánù ń ṣàkópọ̀ ìtàn Ísírẹ́lì níwájú Sànhẹ́dírìn, ó tọ́ka sí sáà onírínwó ọdún yìí, ó wí pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àkókò ti ń sún mọ́lé fún ìmúṣẹ ìlérí tí Ọlọ́run ti polongo ní gbangba fún Ábúráhámù, àwọn ènìyàn náà gbilẹ̀, wọ́n sì di púpọ̀ sí i ní Íjíbítì títí di ìgbà tí ọba mìíràn jẹ lórí Íjíbítì, ẹni tí kò mọ̀ nípa Jósẹ́fù.”—Ìṣe 7:6, 17, 18.
11 Fáráò tuntun yìí sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹrú. Mósè kò tí ì kọ ìwé Jẹ́nẹ́sísì nígbà náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ìlérí Jèhófà fún Ábúráhámù ti wà nínú ìtàn àtẹnudẹ́nu tàbí kí ó ti wà lákọọ́lẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ó dà bí pé ìsọfúnni tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní kò tó fún wọn láti ka ọjọ́ náà gan-an tí a óò dá wọn nídè kúrò lábẹ́ ìnilára wọn. Ọlọ́run mọ ìgbà tí òun yóò dá wọn nídè, ṣùgbọ́n ó hàn gbangba pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ìyà ń jẹ kò mọ̀ ọ́n. A kà pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ ọjọ́ wọnnì pé ọba Íjíbítì kú níkẹyìn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bá a lọ láti mí ìmí ẹ̀dùn nítorí ìsìnrú náà, wọ́n sì ń ké jáde nínú ìráhùn, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ sì ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ ṣáá nítorí ìsìnrú náà. Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run gbọ́ ìkérora wọn, Ọlọ́run sì rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. Nítorí náà, Ọlọ́run bojú wo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Ọlọ́run sì kíyè sí i.” —Ẹ́kísódù 2:23-25.
12. Báwo ni Sítéfánù ṣe fi hàn pé Mósè gbé ìgbésẹ̀ ṣáájú àsìkò Jèhófà?
12 Àìmọ àkókò náà gan-an tí a óò dá Ísírẹ́lì nídè ni a tún lè rí fà yọ nínú àkópọ̀ ọ̀rọ̀ Sítéfánù. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa Mósè, ó wí pé: “Nígbà tí àkókò ọdún ogójì rẹ̀ ń pé bọ̀, ó wá sí ọkàn-àyà rẹ̀ láti ṣe àbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tí ó sì tajú kán rí ẹnì kan tí a ń hùwà sí lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu, ó gbèjà rẹ̀, ó sì mú ẹ̀san ṣẹ ní kíkún fún ẹni tí a ń ṣe àìdára sí nípa ṣíṣá ará Íjíbítì náà balẹ̀. Ó rò pé àwọn arákùnrin òun yóò mòye pé Ọlọ́run ń fún wọn ní ìgbàlà láti ọwọ́ òun, ṣùgbọ́n wọn kò mòye èyí.” (Ìṣe 7:23-25) Níhìn-ín, Mósè gbé ìgbésẹ̀ ní 40 ọdún ṣáájú àkókò tí Ọlọ́run yàn. Sítéfánù tọ́ka sí i pé Mósè ní láti dúró fún 40 ọdún mìíràn kí ó tó di pé Ọlọ́run yóò ‘fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìgbàlà láti ọwọ́ rẹ̀.’—Ìṣe 7:30-36.
13. Báwo ni ipò tiwa ṣe jọ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣáájú kí a tó dá wọn nídè kúrò ní Íjíbítì?
13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “àkókò ti ń sún mọ́lé fún ìmúṣẹ ìlérí,” tí Ọlọ́run sì ti yan ọdún kan pàtó, Mósè àti gbogbo Ísírẹ́lì ní láti lo ìgbàgbọ́. Wọ́n ní láti dúró de àkókò tí Jèhófà ti yàn, ó sì hàn gbangba pé wọn kò lè ṣírò àkókò náà kí ó tó dé. Àwa pẹ̀lú mọ̀ dájú pé ìdáǹdè wa kúrò nínú ètò búburú ti àwọn nǹkan ìsinsìnyí ń sún mọ́lé. A mọ̀ pé a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1-5) Nítorí náà, kò ha yẹ kí a múra tán láti fi ìgbàgbọ́ wa hàn, kí a sì dúró de àkókò tí Jèhófà yàn fún ọjọ́ ńlá? (2 Pétérù 3:11-13) Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a lè kọrin ogo ti ìdáǹdè náà dáadáa, sí ìyìn Jèhófà.—Ẹ́kísódù 15:1-19.
‘Nígbà Tí Àkókò Dé’
14, 15. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run ti yan àkókò kan fún Ọmọ rẹ̀ láti wá sórí ilẹ̀ ayé, kí sì ni àwọn wòlíì àti áńgẹ́lì pàápàá ń bá a nìṣó láti máa ṣọ́nà fún?
14 Jèhófà ti yan àkókò kan pàtó fún Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo láti wá sí orí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkókò dé, Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ jáde, ẹni tí ó ti ara obìnrin jáde wá, tí ó sì wá wà lábẹ́ òfin.” (Gálátíà 4:4) Èyí jẹ́ ní ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run láti rán Irú-Ọmọ kan—‘Ṣílò, ẹni tí ìgbọràn àwọn ènìyàn yóò sì máa jẹ́ tirẹ̀.’—Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 49:10.
15 Wòlíì Ọlọ́run—àní àwọn áńgẹ́lì—ń wọ̀nà fún “àsìkò” náà tí Mèsáyà náà yóò fara hàn lórí ilẹ̀ ayé, tí ìgbàlà yóò sì ṣeé ṣe fún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀. Pétérù wí pé: “Ní ti ìgbàlà yìí gan-an, ìwádìí aláápọn àti ìwákáàkiri àfẹ̀sọ̀ṣe ni àwọn wòlíì ṣe, àwọn tí wọ́n ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi lélẹ̀ lọ́tọ̀ fún yín. Wọ́n ń bá a nìṣó ní ṣíṣe àyẹ̀wò nípa àsìkò náà gan-an tàbí irú àsìkò tí ẹ̀mí tí ń bẹ nínú wọn tọ́ka sí ní ti Kristi nígbà tí ó ń jẹ́rìí ṣáájú nípa àwọn ìjìyà fún Kristi àti nípa àwọn ògo tí yóò tẹ̀ lé ìwọ̀nyí. . . . Nǹkan wọ̀nyí gan-an ni àwọn áńgẹ́lì ń fẹ́ láti wò ní àwòfín.”—1 Pétérù 1:1-5, 10-12.
16, 17. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jèhófà fi ran àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní lọ́wọ́ láti máa fojú sọ́nà fún Mèsáyà? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣe nípa lórí ìfojúsọ́nà àwọn Júù?
16 Nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀, Dáníẹ́lì—ọkùnrin kan tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ dúró gbọn-in—Jèhófà ti fúnni ní àsọtẹ́lẹ̀ kan tí ó wé mọ́ “àádọ́rin ọ̀sẹ̀.” Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní láti mọ̀ pé ìfarahàn Mèsáyà tí a ṣèlérí náà ti ń sún mọ́lé. Lápá kan, àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé: “Láti ìjádelọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́ títí di ìgbà Mèsáyà Aṣáájú, ọ̀sẹ̀ méje yóò wà, àti ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta.” (Dáníẹ́lì 9:24, 25) Àwọn Júù, àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, àti àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì gbà lápapọ̀ pé ‘àwọn ọ̀sẹ̀’ tí a mẹ́nu kàn níhìn-ín túmọ̀ sí àwọn ọ̀sẹ̀ ọdún. “Ọ̀sẹ̀” 69 (tí ó jẹ́ 483 ọdún) ní Dáníẹ́lì 9:25 bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí Atasásítà Ọba Páṣíà pàṣẹ fún Nehemáyà “láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́.” (Nehemáyà 2:1-8) Wọ́n parí ní 483 ọdún lẹ́yìn náà—ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa, nígbà tí a batisí Jésù, tí a sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án, tí ó sì tipa báyìí di Mèsáyà, tàbí Kristi.—Mátíù 3:13-17.
17 Kò sí ẹni tí ó lè sọ bóyá àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní mọ àkókò náà gan-an tí 483 ọdún náà bẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jòhánù Oníbatisí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, “àwọn ènìyàn náà ti ń fojú sọ́nà, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ọkàn-àyà wọn nípa Jòhánù pé: ‘Àbí òun ni Kristi náà ni?’” (Lúùkù 3:15) Àwọn kan nínú àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ so ìrètí yìí mọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ yìí, Matthew Henry kọ̀wé pé: “A sọ fún wa . . . bí àwọn ènìyàn ṣe lo iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìbatisí Jòhánù láti ronú nípa Mèsáyà náà, àti láti ronú pé ó wà lẹ́nu ilẹ̀kùn. . . . Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ Dáníẹ́lì ti ń pé lọ nísinsìnyí.” Ìwé náà, Manuel Biblique, lédè Faransé láti ọwọ́ Vigouroux, Bacuez, àti Brassac sọ pé: “Àwọn ènìyàn mọ̀ pé àádọ́rin ọ̀sẹ̀ àwọn ọdún tí Dáníẹ́lì sọ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé; kò ya ẹnikẹ́ni lẹ́nu láti gbọ́ tí Jòhánù Oníbatisí ń kéde pé ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.” Júù, Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, Abba Hillel Silver, kọ̀wé pé gẹ́gẹ́ bí “ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ lílókìkì” ti ìgbà yẹn ti wí, “wọ́n ń retí Mèsáyà náà ní nǹkan bí apá ìlàjì ọ̀rúndún kìíní ti Sànmánì Tiwa.”
A Gbé E Ka Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀—Kì Í Ṣe Kíka Ọjọ́
18. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ran àwọn Júù lọ́wọ́ láti mọ àkókò tí wọn yóò máa retí kí Mèsáyà náà fara hàn, ẹ̀rí mímúná dóko jù lọ wo ni ó wà pé Jésù ni Mèsáyà náà?
18 Bí ó tilẹ̀ hàn gbangba pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ran àwọn Júù lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tí ó wé mọ́ ìgbà tí Mèsáyà náà yóò fara hàn, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé lẹ́yìn náà fi hàn pé èyí kò yí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn lọ́kàn padà láti gbà pé Jésù ni Mèsáyà náà. Nígbà tí kò pé ọdún kan mọ́ tí Jésù yóò kú, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ta ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ń sọ pé mo jẹ́?” Wọ́n fèsì pé: “Jòhánù Oníbatisí; ṣùgbọ́n àwọn mìíràn, Èlíjà, àti síbẹ̀ àwọn mìíràn, pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì ìgbàanì ti dìde.” (Lúùkù 9:18, 19) A kò ní àkọsílẹ̀ kankan pé Jésù fìgbà kan ṣàyọlò àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀sẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ láti fẹ̀rí hàn pé òun ni Mèsáyà náà. Ṣùgbọ́n, ní àkókò kan, ó wí pé: “Èmi ní ẹ̀rí tí ó tóbi ju ti Jòhánù lọ, nítorí pé àwọn iṣẹ́ náà gan-an tí Baba mi yàn lé mi lọ́wọ́ láti ṣe ní àṣeparí, àwọn iṣẹ́ náà tìkára wọn tí èmi ń ṣe, ń jẹ́rìí nípa mi pé Baba ni ó rán mi wá.” (Jòhánù 5:36) Dípò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí tí a ṣí payá, ìwàásù Jésù, àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó yí ikú rẹ̀ ká (òkùnkùn ìyanu, fífa aṣọ ìkélé tẹ́ńpìlì ya, àti ìsẹ̀lẹ̀) jẹ́rìí sí i pé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run rán.—Mátíù 27:45, 51, 54; Jòhánù 7:31; Ìṣe 2:22.
19. (a) Báwo ni àwọn Kristẹni ìjímìjí yóò ṣe mọ̀ pé ìparun Jerúsálẹ́mù ti sún mọ́lé? (b) Èé ṣe tí àwọn Kristẹni tí wọ́n sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù ṣì fi nílò ìgbàgbọ́ púpọ̀ sí i?
19 Bákan náà, lẹ́yìn ikú Jésù, a kò fún àwọn Kristẹni ìjímìjí ní ìsọfúnni kankan tí wọn yóò fi ṣírò àkókò ìparun ètò àwọn nǹkan Júù tí ń bọ̀. Lóòótọ́, àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa àwọn ọ̀sẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ ti mẹ́nu kan ìparun ètò yẹn. (Dáníẹ́lì 9:26b, 27b) Ṣùgbọ́n èyí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn òpin “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” (455 ṣááju Sànmánì Tiwa sí 36 Sànmánì Tiwa). Lédè mìíràn, lẹ́yìn tí àwọn Kèfèrí àkọ́kọ́ ti di ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọdún 36 Sànmánì Tiwa, àwọn Kristẹni kò ní ìsọfúnni mìíràn mọ́ nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ti Dáníẹ́lì orí 9. Lọ́dọ̀ tiwọn, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ni yóò fi hàn pé ètò àwọn Júù kò ní pẹ́ dópin, kì í ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnnì tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dé òtéńté ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù kọlu Jerúsálẹ́mù, lẹ́yìn náà, wọ́n sì fà sẹ́yìn. Èyí fún àwọn Kristẹni olóòótọ́ àti elétíìgbọ́ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà láǹfààní láti ‘sá lọ sí àwọn òkè ńlá.’ (Lúùkù 21:20-22) Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni ìjímìjí wọnnì kò ti ní atọ́ka ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí lọ́wọ́, wọn kò mọ ìgbà tí ìparun Jerúsálẹ́mù yóò dé. Ẹ wo irú ìgbàgbọ́ tí ó béèrè lọ́wọ́ wọn láti fi ilé, oko, àti ọ̀nà wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì wà lẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù fún nǹkan bí ọdún mẹ́rin títí tí àwọn ọmọ ogun Róòmù fi padà wá ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, tí wọ́n sì pa ètò àwọn Júù run ráúráú!—Lúùkù 19:41-44.
20. (a) Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ Nóà, Mósè, àti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tí ó wà ní Jùdíà? (b) Kí ni a óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e?
20 Gẹ́gẹ́ bí Nóà, Mósè, àti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní Jùdíà, àwa lónìí pẹ̀lú ìgbọ́kànlè fi ìgbà àti àsìkò lé Jèhófà lọ́wọ́. Ìgbàgbọ́ wa tó lágbára pé a ń gbé ní àkókò òpin àti pé ìdáǹdè wa kù sí dẹ̀dẹ̀ sinmi lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gidi tí ń mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ, kò wulẹ̀ sinmi lórí kíka ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀. Síwájú sí i, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń gbé ní àkókò wíwàníhìn-ín Kristi, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé kí a fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìjẹ́pàtàkì lílo ìgbàgbọ́ àti bíbá a nìṣó láti máa ṣọ́nà. A gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti máa fi ìháragàgà fojú sọ́nà fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ arùmọ̀lárasókè tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Èyí ni kókó tí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò dá lé lórí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Lọ́nà Àtúnyẹ̀wò
◻ Ní ti ìgbà àti àsìkò Jèhófà, kí ni Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?
◻ Báwo ni ìgbà tí Nóà ti mọ̀ ṣáájú pé Ìkún Omi yóò bẹ̀rẹ̀ ti pẹ́ tó?
◻ Kí ni ó fi hàn pé Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò mọ àkókò náà pàtó tí a óò dá wọn nídè kúrò ní Íjíbítì?
◻ Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní láti inú Bíbélì nípa àwọn àpẹẹrẹ tí ó wé mọ́ ìgbà àti àsìkò Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ìgbàgbọ́ Nóà ràn án lọ́wọ́ láti fi ọ̀ràn àkókò lé Jèhófà lọ́wọ́