-
Ọlọ́run Pè É Ní “Ìyá Ọba”Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017 | No. 5
-
-
Ó ti lé lọ́dún mẹ́wàá báyìí tí Ábúráhámù kó ìdílé rẹ̀ kọjá Odò Yúfírétì, tí wọ́n sì tẹ̀dó sí ilẹ̀ Kénáánì. Sárà ń ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn tinútinú bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ibi tí wọ́n ń lọ, àmọ́ ó mọ̀ pé ipa pàtàkì lòún máa kó nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọmọ kan tó máa di orílẹ̀-èdè ńlá. Ipa wo wá ni Sárà máa kó nínú ìlérí náà? Àgàn ni Sárà, ó sì ti lé lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75] báyìí. Ó ṣeé ṣe kó tún máa ronú pé, ‘Báwo ni ìlérí Jèhófà ṣe máa ṣẹ nígbà tó jẹ́ pé èmi ni ìyàwó Ábúráhámù?’ Kò lè yà wá lẹ́nu tí ọ̀rọ̀ náà bá ń jẹ ẹ́ lọ́kàn tàbí tára rẹ̀ kò balẹ̀.
-
-
Ọlọ́run Pè É Ní “Ìyá Ọba”Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017 | No. 5
-
-
Dípò tí Sárà á fi máa ronú ohun tó fi sílẹ̀, ọjọ́ iwájú ló ń rò. Ìdí nìyẹn tó fi ń ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń kó káàkiri. Ó máa ń ṣèrànwọ́ láti tú àgọ́, tí wọ́n á sì tún lọ pàgọ́ sí ibòmíì. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn kiri. Ó tún fara da àwọn ìṣòro àti àyípadà míì. Jèhófà tún ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù sọ, síbẹ̀ kò sọ̀rọ̀ nípa Sárà!—Jẹ́nẹ́sísì 13:14-17; 15:5-7.
Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, Sárà pinnu láti sọ àbá kan tó ti ń wá sí i lọ́kàn tipẹ́ fún Ábúráhámù ọkọ rẹ̀. Fọkàn yàwòrán bí ojú rẹ̀ ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tó fẹ́ sọ̀rọ̀, ó ní: “Wàyí o, jọ̀wọ́! Jèhófà ti sé mi mọ́ kúrò nínú bíbímọ.” Ó wá sọ fún ọkọ rẹ̀ pé kó fi ìránṣẹ́bìnrin òun, ìyẹn Hágárì ṣe aya, kó lè bímọ fún un. Ṣé ẹ mọ bó ṣe máa rí lára Sárà bó ṣe ń sọ fún ọkọ rẹ̀ pé kó fẹ́ ìyàwó míì? Lójú wa, ó lè dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe, àmọ́ kì í ṣe ohun àjèjì láyé ìgbà yẹn pé kí ọkùnrin fẹ́ ìyàwó kejì, tàbí pé kó ní àlè, kó báa lè bí ọmọ.b Ṣé ó lè jẹ́ pé Sárà ń ronú pé ọ̀nà yìí ni ìlérí Ọlọ́run máa gbà ṣẹ pé àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù máa di orílẹ̀-èdè ńlá?Ohun yòówù kó wà lọ́kàn rẹ̀, ohun tá a mọ̀ ni pé ó múra tán láti yááfì ohun kan. Kí ni Ábúráhámù sọ? Bíbélì sọ pé: “[Ábúráhámù] fetí sí ohùn [Sárà].”—Jẹ́nẹ́sísì 16:1-3.
Ǹjẹ́ ibi kankan wà tó sọ pé Jèhófà ló mú kí Sárà dá àbá yẹn? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, a rí i pé ojú èèyàn ni Sárà fi ń wo ọ̀rọ̀ náà. Ohun tó rò ni pé Ọlọ́run ló fa àwọn ìṣòro tí òun ní àti pé kò sí ọ̀nà àbáyọ kankan mọ́ fún òun. Àmọ́ ojútùú tí òun alára mú wá máa kó ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn bá a. Síbẹ̀, àbá tó mú wá fi hàn pé kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan. Nínú ayé tá a wà yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn kì í ro ti ẹlòmíì mọ tiwọn, àmọ́ irú ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan tí Sárà ní yìí wúni lórí gan-an. Tí àwa náà bá fi ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣáájú, tá a sì yẹra fún ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan, àpẹẹrẹ Sárà là ń tẹ̀ lé yẹn.
-