Jékọ́bù Mọyì Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí
IGBÉSÍ ayé Jékọ́bù kún fún hílàhílo àti ìṣòro. Bí arákùnrin rẹ̀ ṣe ń bínú bí apààyàn ló jẹ́ kí Jékọ́bù sá lọ fún ẹ̀mí rẹ̀. Dípò kí wọ́n jẹ́ kó fẹ́ obìnrin tó wù ú, ńṣe la tàn án jẹ, ló bá fẹ́ ẹlòmíràn lákọ̀ọ́kọ́ tí ìyàwó rẹ̀ wá di mẹ́rin ní àbárèbábọ̀, ọ̀pọ̀ ìṣòro sì wá tibẹ̀ yọ. (Jẹ́nẹ́sísì 30:1-13) Odindi ogún ọdún gbáko ló fi ṣiṣẹ́ sin ọkùnrin kán báyìí tí ìyẹn sì tún rẹ́ ẹ jẹ. Ó bá áńgẹ́lì wọ̀yá ìjà ló bá di aláàbọ̀ ara. Wọ́n fipá bá ọmọbìnrin rẹ̀ lòpọ̀, làwọn ọmọkùnrin rẹ̀ bá fa ìjọ̀ngbọ̀n tí wọ́n sì pààyàn lọ rẹpẹtẹ, àní ó sunkún gidigidi nígbà tí ìyàwó àtọmọ tó fẹ́ràn gan-an kú ikú òjijì. Ńṣe ló fi arúgbó ara sá kúrò nílùú nítorí ìyàn, ó gbà pé ọjọ́ ayé òun “kéré níye, ó sì kún fún wàhálà.” (Jẹ́nẹ́sísì 47:9) Láìfi gbogbo àwọn ìṣòro wọ̀nyí pè, Jékọ́bù jẹ́ ẹni tẹ̀mí tó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Ṣé ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run wá jẹ́ àṣìṣe ni? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ tá a bá gbé díẹ̀ yẹ̀ wò nínú àwọn ìrírí Jékọ́bù?
Jékọ́bù Yàtọ̀ Gan-an Sí Arákùnrin Rẹ̀
Kò sí ohun kan mìíràn tó fa arukutu láàárín òun àtẹ̀gbọ́n rẹ̀ ju pé Jékọ́bù mọyì àwọn nǹkan tẹ̀mí nígbà tí Ísọ̀ fojú tẹ́ńbẹ́lú wọn. Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ sí májẹ̀mú ìlérí tí a ṣe fun Ábúráhámù ó sì tún ń dáàbò bo ìlà ìdílé tí Ọlọ́run yàn gẹ́gẹ́ bí ajogún. Nípa bẹ́ẹ̀ Jèhófà “nífẹ̀ẹ́” rẹ̀. Jékọ́bù jẹ́ “aláìlẹ́gàn,” èyí túmọ̀ sí ẹni tó níwà tó dára gan-an. Lódìkejì, Ísọ̀ ní tirẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ ka ogún rẹ̀ nípa tẹ̀mí sí pàtàkì ló jẹ́ kó tà á fún Jékọ́bù nítorí nǹkan bín-ń-tín. Nítorí pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn Jékọ́bù, ó gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ ó sì tipa bẹ́ẹ̀ gba ogún tẹ̀mí tó jẹ́ ti arákùnrin rẹ̀, ìyẹn ló mú kí Ísọ̀ bínú gan-an. Jékọ́bù ní láti fi ohun gbogbo tó nífẹ̀ẹ́ sí sílẹ̀ ṣùgbọ́n ohun tó ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e kò jẹ́ kó rẹ̀wẹ̀sì.—Málákì 1:2, 3; Jẹ́nẹ́sísì 25:27-34; 27:1-45.
Nínú àlá kan tí Jékọ́bù lá, Ọlọ́run fi àwọn áńgẹ́lì kan hàn án tí wọ́n ń lọ tí wọ́n ń bọ̀ lórí àkàsọ̀ kan tí a gbé dúró sórí ilẹ̀ ayé, tí orí rẹ̀ sì kan ọ̀run. Ọlọ́run sì sọ pé òun á pa Jékọ́bù àti irú ọmọ rẹ̀ mọ́. “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni gbogbo àwọn ìdílé ilẹ̀ yóò bù kún ara wọn dájúdájú. Sì kíyè sí i, èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà tí ìwọ ń lọ, èmi yóò sì mú ọ padà sí ilẹ̀ yìí, nítorí pé èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí èmi yóò fi ṣe ohun tí mo ti sọ fún ọ ní tòótọ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 28:10-15.
Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Jèhófà fìdí i rẹ̀ múlẹ̀ pé ìlérí tí òun ṣe fún Ábúráhámù àti Ísáákì yóò jẹ́ kí ìdílé Jékọ́bù rí ìbùkún tẹ̀mí. A mú un dá Jékọ́bù lójú pé àwọn áńgẹ́lì lè ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tínú Ọlọ́run bá dùn sí, ó sì dájú pé Ọlọ́run yóò dáàbò bò wọ́n. Nítorí pé Jékọ́bù moore, ó jẹ́jẹ́ láti jẹ́ olóòótọ́ si Jèhófà.—Jẹ́nẹ́sísì 28:16-22.
Kì í kúkú ṣe pé Jékọ́bù já ogun Ísọ̀ gbà. Ká tó bí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyẹn ni Jèhófà ti sọ pe ‘ẹ̀gbọ́n ni yóò sin àbúrò.’ (Jẹ́nẹ́sísì 25:23) Ẹni kan lè wá béèrè pé ‘Báwo ni ò bá ṣe rọrùn tó ká sọ pé Ọlọ́run ti jẹ́ ká kọ́kọ́ bí Jékọ́bù?’ Ohun tó ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé kọ́ wa ní òtítọ́ kan tó ṣe pàtàkì. Ọlọ́run kì í bù kún àwọn tó bá rò pé ẹ̀tọ́ àwọn ni, ṣùgbọ́n ó máa ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí àwọn tó bá yàn. Abájọ tó fi jẹ́ pé Jékọ́bù lá fún ní ogún ìbí tá ò sì fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí kò mọyì ogún ìbí náà. Bákan náà, nítorí pé àwọn Júù nípa tara ò mọyì ogún tẹ̀mí bíi ti Ísọ̀ la ṣe fi Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí rọ́pò wọn. (Róòmù 9:6-16, 24) Lónìí pẹ̀lú, à o le jogún àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà àfi tá a bá ṣiṣẹ́ fún un kódà ká sọ pé inú ìdílé tàbí àyíká àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run la ti bí wa. Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ rí ìbùkún Ọlọ́run gbọ́dọ̀ sapá láti jẹ́ olùṣèfẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì mọyì àwọn nǹkan tẹ̀mí lóòótọ́.
Lábánì Tẹ́wọ́ Gbà Á
Nígbà tí Jékọ́bù dé Padani-árámù láti wá ìyàwó láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀, ó pàdé Rákélì tó jẹ́ ọmọbìnrin Lábánì lẹ́bàá kànga, ó gbé òkúta ńlá kan tá a fi dé orí kànga náà kúrò kó lè bàa fún àwọn ẹran tí Rákélì ń dà lómi mu.a Ńṣe ni Rákélì sáré lọ sílé láti sọ pé Jékọ́bù ti dé, kíá ni Lábánì náà yára wá pàdé rẹ̀. Tí Lábánì bá ní kí òun rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn tí ìdílé wọn gbà lọ́wọ́ ìránṣẹ́ Ábúráhámù nígbà kan rí, ìjákulẹ̀ ńlá ni yóò jẹ́ fún un, nítorí Jékọ́bù kò mú ohunkóhun dáni ní tiẹ̀. Ṣùgbọ́n o, Lábánì rí ẹni tí yóò fi ṣèfà jẹ, ìyẹn òṣìṣẹ́ aláápọn.—Jẹ́nẹ́sísì 28:1-5; 29:1-14.
Jékọ́bù sọ ìtàn ara rẹ̀. Kò ṣe kedere bóyá ó mẹ́nu ba ọgbọ́n arúmọjẹ tó lò láti gba ogún ìbí tàbí kò mẹ́nu bà á, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Lábánì gbọ́ “gbogbo nǹkan wọ̀nyí” ó sọ pé: “Egungun mi àti ẹran ara mi ni ìwọ ní tòótọ́.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé a lè pe gbólóhùn yìí ní gbígba Jékọ́bù tọwọ́tẹsẹ̀ tàbí ká sọ pé jíjẹ́ tí Jékọ́bù jẹ́ mọ̀lẹ́bí Lábánì ló mú kó ṣètọ́jú rẹ̀. Bó ṣe wù ó jẹ́, kò pẹ́ tí Lábánì fi ronú nípa ọ̀nà tó máa gbà tú ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ jẹ.
Lábánì dá ohun tí yóò di ọ̀ràn àríyànjiyàn fún ogún ọdún tí ó tẹ̀ lé e sílẹ̀. Ó béèrè pé: “Arákùnrin mi ha ni ọ́, ó ha sì yẹ kí o sìn mí lásán bí?” Ó tún béèrè pé: “Sọ fún mi, Kí ni owó ọ̀yà rẹ yóò jẹ́?” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Lábánì ṣe bí ẹni pé òun jẹ́ àbúrò ìyá rẹ̀ tó lójú àánú, síbẹ̀ ó sọ àjọṣe mọ̀lẹ́bí tó wà láàárín òun àti Jékọ́bù di irú èyí tó wà láàárín òṣìṣẹ́ àti agbaniṣíṣẹ́. Níwọ̀n bó sì tí jẹ́ pé ìfẹ́ Rákélì ti kó sí Jékọ́bù lórí, lọ́gán ló dáhùn pé: “Mo ṣe tán láti sìn ọ́ fún ọdún méje nítorí Rákélì ọmọbìnrin rẹ, èyí àbúrò”—Jẹ́nẹ́sísì 29:15-20.
Kíá ló ti wọnú àdéhùn ìgbéyàwó nípa sísan owó orí ìyàwó fún ìdílé ìyàwó. Lẹ́yìn-ò-rẹyìn ni Òfin Mósè wá sọ pé àádọ́ta ṣékélì owó fàdákà la ó máa san lórí wúńdíá tí a bá ti fi ẹ̀tàn bá lòpọ̀. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nì, Scholar Gordon Wenham gbà pé èyí ni “owó orí ìyàwó tó pọ̀ jù lọ” nítorí ọ̀pọ̀ ló “kéré sí èyí.” (Diutarónómì 22:28, 29) Jékọ́bù ò lè san irú owó bẹ́ẹ̀. Ó yáa gbà láti sin Lábánì fún ọdún méje. Wenham ń báa lọ pé: “Níwọ̀n ìgbà to jẹ́ pé ní Bábílónì àtijọ́, òṣìṣẹ́ kàn kì í gbà ju ààbọ̀ ṣékélì sí ṣékélì kan lọ lóṣù (tá a bá ṣírò ìyẹn lọ́dún méje, yóò wà láàárín ṣékélì méjìlélógójì sí ṣékélì mẹ́rìnlélọ́gọ́rin) a jẹ́ pe owó orí tó pọ̀ ni Jékọ́bù fẹ́ san kó bàa lè fẹ́ Rákélì.” Kíá ni Lábánì gbà láì janpata.—Jẹ́nẹ́sísì 29:19.
Lójú Jékọ́bù, bí “ọjọ́ díẹ̀” lọdún méje rí nítorí pe ó nífẹ̀ẹ́ Rákélì gàn-an. Lẹ́yìn ìyẹn, ló fẹ́ ìyàwó tá a faṣọ bò lójú lọ́jọ́ ìgbéyàwó nítorí kò tiẹ̀ fura rárá pé inú méjì ni Lábánì fi ń bá òun lò. Fojú inú wò irú ìyàlẹ́nu tí yóò jẹ́ fún Jékọ́bù nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́ tó rí i pé Léà lòun sùn tì kì í ṣe Rákélì! Jékọ́bù béèrè pé: “Kí ni ìwọ ṣe fún mi yìí? Kì í ha ṣe nítorí Rákélì ni mo fi sìn ọ́? Nítorí náà, èé ṣe tí o fi ṣe àgálámàṣà sí mi?” Lábánì fèsì pé: “Kì í ṣe àṣà láti ṣe báyìí lọ́dọ̀ wa, láti fi obìnrin tí ó jẹ́ àbúrò fúnni ṣáájú àkọ́bí. Ṣe ayẹyẹ ọ̀sẹ̀ obìnrin yìí pé. Lẹ́yìn ìyẹn, a ó sì fi obìnrin kejì yìí fún ọ pẹ̀lú fún iṣẹ́ ìsìn tí ìwọ bá lè ṣe fún mi fún ọdún méje sí i.” (Jẹ́nẹ́sísì 29:20-27) Tóò, Jékọ́bù ti há báyìí, kò sí lè ṣe ohunkóhun mọ́ ju pé tó bá jẹ́ pé ó ṣì fẹ́ láti fẹ́ Rákélì, àfi kó gba ohun tí Lábánì sọ.
Ọdún méje ti ọ̀tẹ̀ yìí kò rọgbọ bí ọdún méje tàkọ́kọ́. Báwo ni Jékọ́bù ṣe lè gbójú fo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí Lábánì yìí dá? Báwo ló ṣe fẹ́ máa wo Léà tóun náà lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Lábánì? Ṣé kò kúkú sí ohun to kan Lábánì nínú wàhálà tó dá sílẹ̀ fún Léà àti Rákélì lọ́jọ́ iwájú. Tiẹ̀ nìkan ṣáá ló jẹ ẹ́ lógún. Owú àti ìbínú ló jọba nínú Rákélì nígbà tí Léà bí ọmọkùnrin mẹ́rin ní tẹ̀-lé-ǹ-tẹ̀-lé tòun ò sì tí ì rí ọmọ bí. Rákélì tó ń wá ọmọ lójú méjèèjì fi ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún Jékọ́bù kó lè bímọ fún òun, ìyẹn ló mú kí Léà náà jowú ló bá fún Jékọ́bù ní ìránṣẹ́bìnrin tiẹ̀ náà. Bí Jékọ́bù ṣe fẹ́ ìyàwó mẹ́rin tó sì bí ọmọ méjìlá nìyẹn ṣùgbọ́n ìdílé rẹ̀ ò láyọ̀. Síbẹ̀, Jèhófà sọ Jékọ́bù di orílẹ̀-èdè ńlá.—Jẹ́nẹ́sísì 29:28–30:24.
Jèhófà Sọ Ọ́ Di Ọlọ́rọ̀
Bí Jékọ́bù tilẹ̀ rí ọ̀pọ̀ àdánwò, síbẹ̀ ó ri i pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú òun bó ṣe ṣèlérí. Lábánì náà rí i, nítorí pé agbo ẹran kékeré ni Lábánì ní nígbà tí Jékọ́bù dé, ṣùgbọ́n ńṣe ló pọ̀ gan-an nígbà tí Jékọ́bù ń bójú tó o. Nítorí pé Lábánì ò fẹ́ kí Jékọ́bù lọ, ó ni kó sọ iye tí yóò máa gbà gẹ́gẹ́ bi owó ọ̀yà, Jékọ́bù ní òun ń fẹ́ àwọn ẹran tí àwọ̀ wọn ò wọ́pọ̀ nínú agbo ẹran Lábánì. Lágbègbè yẹn, ohun tó wọ́pọ̀ ni pe kí àwọn àgùntàn ní àwọ̀ funfun, káwọn ewúrẹ́ sì láwọ̀ dúdú tàbí pupa rúsúrúsú; àwọn tó máa ń ní àwọ̀ tó-tò-tó kì í pọ̀ rárá. Nítorí ìyẹn, Lábánì ti rò pé ohun kékeré ni Jékọ́bù ń béèrè yẹn, kíá ló gbà láti ya gbogbo ẹran tí àwọ̀ wọn ò wọ́pọ̀ sọ́tọ̀ kí agbo ẹran rẹ̀ máa bàa dàpọ̀ mọ́ ti Jékọ́bù. Ó ti gbà pé èrè kékeré ni Jékọ́bù máa rí níbẹ̀ ìdí ni pé tí a bá dá àwọn ọmọ àgùntàn sí ọgọ́rùn-ún, ohun tó gbà kò tó ìdá ogún tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń gbà gẹ́gẹ́ bí owó ọ̀yà. Ṣùgbọ́n àṣìṣe ńlá gbáà ni Lábánì ṣe, nítorí Jèhófà wà pẹ̀lú Jékọ́bù.—Jẹ́nẹ́sísì 30:25-36.
Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe darí ọ̀ràn náà, àwọn ẹran Jékọ́bù sanra dáadáa wọ́n sì láwọ̀ tí kò wọ́pọ̀ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 30:37-42) Èrò tí Jékọ́bù ní nípa bí àwọn ẹran ọ̀sìn ṣe ń mú irú ọmọ jáde kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, Nahum Sarna ṣàlàyé pé, “Bí èèyàn bá lo ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, ó ṣeé ṣe láti rí ẹran tó ní àwọ̀ tó-tò-tó nípa jíjẹ́ kí . . . ẹran tó láwọ̀ kan ṣoṣo ṣùgbọ́n tí àwọ̀ tó-tò-tó wà nínú apilẹ̀ àbùdá rẹ̀ gun ẹran mìíràn tóun náà ní àwọ̀ kan ṣoṣo pẹ̀lú àwọ̀ tó-tò-tó nínú apilẹ̀ àbùdá tiẹ̀ náà, a sì lè dá irú àwọn ẹran bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa . . . àwọn irú ọmọ tí wọ́n bá mú jáde.”
Bí Lábánì ṣe rí bí àgbo ẹran Jékọ́bù ṣe ń tóbi sí i, kíá ló tún ti ń wá bí yóò ṣe dabarú àdéhùn wọn nípa àwọn ẹran tí yóò jẹ́ tí ọmọ ẹ̀gbọ̀n rẹ̀—bóyá abilà, aláwọ̀ adíkálà, aláwọ̀ pàtápàtá tàbí aláwọ̀ tó-tò-tó. Èrè tiẹ̀ nìkan ló ń wá, àmọ́ bó ṣe wù kí Lábánì gbìyànjú láti dabarú àdéhùn wọn tó, Jèhófà rí i dájú pé ọrọ̀ Jékọ́bù ń pọ̀ sí í. Kò sí ohun tí Lábánì lè ṣe ju pé kó ti ìka àbámọ̀ bọnu lọ. Kò pẹ́ tí Jékọ́bù fi di ọlọ́rọ̀ ńlá, tó ni agbo ẹran, ìránṣẹ́ tó pọ̀, àwọn ràkúnmí àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kì í ṣe nítorí mímọ̀ọ́ṣe Jékọ́bù bí kò ṣe pé Jèhófà wà lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà to yá, ó ṣàlàyé fún Rákélì àti Léà pé: “Baba yín sì ti fi mí ṣe ṣeréṣeré, ó sì ti yí owó ọ̀yà mi padà ní ìgbà mẹ́wàá, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò jẹ́ kí ó pa mí lára. . . . Ọlọ́run ń gba ọ̀wọ́ ẹran baba yín kúrò, ó sì ń fi wọ́n fún mi.” Jèhófà tún mú un dá Jékọ́bù lójú pé Òun rí gbogbo ohun tí Lábánì ńṣe ṣùgbọ́n Jékọ́bù ò gbọ́dọ̀ fòyà. Ọlọ́run sọ pé: “Padà sí ilẹ̀ rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, èmi yóò sì ṣe dáadáa sí ọ.”—Jẹ́nẹ́sísì 31:1-13; 32:9.
Lẹ́yìn tí Jékọ́bù ti jára rẹ̀ gbà pátápátá kúrò lọ́wọ́ Lábánì oníbékebèke, ó yáa gba ilé lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ogún ọdún ti kọjá báyìí, síbẹ̀ ó sì tún ń bẹ̀rù Ísọ̀ àgàgà ìgbà tó tiẹ̀ wá gbọ́ pé Ísọ̀ ti gbèrú débi pé irinwó ọkùnrin ló ń kó kiri báyìí. Kí ni Jékọ́bù máa wá ṣe báyìí? Gbogbo ìgbà ló fi jẹ́ ẹni tẹ̀mí tó sì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ó lo ìgbàgbọ́. Níwọ̀n ìgbà tó ti mọ̀ pé ìwà ọ̀làwọ́ èyíkéyìí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ò tọ́ sí òun, ó gbàdúrà, ó sì jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé kí Ọlọ́run wo ti ìlérí Rẹ̀ kó dá òun àti ìdílé òun nídè kúrò lọ́wọ́ Ísọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 32:2-12.
Nígbà tó yá, ohun tá ò retí ló ṣẹlẹ̀. Àjèjì kan tó wá dì áńgẹ́lì nígbẹ̀yìn gbẹ́yín bá Jékọ́bù wọ̀yá ìjà lóru, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tó fọwọ́ kan Jékọ́bù ní itan báyìí, ńṣe ni ìgbáròkó rẹ̀ yẹ̀. Jékọ́bù sọ pé áńgẹ́lì ò ní lọ àfi tó bá bù kún òun. Nígbà tó yá, wòlíì Hóséà sọ pé Jékọ́bù “sunkún, kí ó lè fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere fún ara rẹ̀.” (Hóséà 12:2-4; Jẹ́nẹ́sísì 32:24-29) Jékọ́bù mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì tóun kọ́kọ́ rí ní í ṣe pẹ̀lú bí májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá nípa irú ọmọ rẹ̀ yóò ṣe ní ìmúṣẹ. Ohun tó fà á nìyẹn tó fi fi gbogbo ara wọ̀yá ìjà náà kó lè rí ìbùkún gbà. Lọ́tẹ̀ yìí Ọlọ́run yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ísírẹ́lì èyí tó túmọ̀ sí “Ẹni tó ń bá Ọlọ́run wọ̀yá ìjà, (Ẹni tó rọ̀ mọ́ Ọlọ́run)” tàbí “Ọlọ́run Ń Wọ̀jà”
Ṣé Ìwọ Náà Fẹ́ Wọ̀yá Ìjà?
Bíbá áńgẹ́lì wọ̀yá ìjà àti bíbá Ísọ̀ rẹ́ nìkan kọ́ ni gbogbo ìṣòro tí Jékọ́bù gbọ́dọ̀ borí. Àmọ́, àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí fi irú ènìyàn tó jẹ́ hàn. Níbi tí Ísọ̀ ò ti lè fara da ebi díẹ̀ nítorí ogún ìbí ni Jékọ́bù ti fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ja fitafita láti rí ìbùkún gbà kódà ó bá áńgẹ́lì wọ̀yá ìjà. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣèlérí, Jékọ́bù rí ìtọ́sọ́nà àti ààbò gbà látọ̀run, ó di baba ńlá fún orílẹ̀-èdè ńlá kan, ó sì di baba ńlá Mèsáyà.—Mátíù 1:2, 16.
Ṣé ìwọ náà á fẹ́ sapá láti rí ojú rere Jèhófà, kó o wọ̀yá ìjà, ká sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀? Lónìí, ìgbésí ayé kún fún ọ̀pọ̀ ìṣòro àti àwọn àdánwò fáwọn tó bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ìgbà mìíràn sì rèé, o ní láti jà fitafita kó o tó lè ṣèpinnu to tọ́. Àmọ́ ṣá o, àpẹẹrẹ dáradára tí Jékọ́bù fi lélẹ̀ mórí wa yá gan-an. Ó ń mú ká di ìrètí tí Jèhófà gbé ka iwájú wa mu ṣinṣin pé òun yóò san wá lẹ́san.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jọ ìgbà tí Rèbékà tó jẹ́ ìyá Jékọ́bù fún àwọn ràkúnmí Élíésérì lómi. Nígbà yẹn náà, Rèbékà sáré lọ sọ nílé pé àlejò kan ti dé. Bí Lábánì ṣe rí àwọn ohun èlò wúrà tí wọ́n fún arábìnrin rẹ̀, kíá ló sáré lọ pàdé Élíésérì.—Jẹ́nẹ́sísì 24:28-31, 53.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Jékọ́bù fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ jà fitafita kó bàa lè rí àwọn ìbùkún gbà