Ṣé Ìgbà Tó O Bá Rí Òfin Bíbélì Lo Tó Lè Ṣe Ohun Tó Yẹ?
NÍGBÀ tó o wà lọ́mọdé, ó ṣeé ṣe kí àwọn òbí rẹ fún ẹ láwọn òfin má-ṣe-tibí má-ṣe-tọ̀hún. Nígbà tó o wá dàgbà tán, ó rí i pé wọ́n fẹ́ràn rẹ ló jẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Bó o ṣe dàgbà yìí pàápàá, o ṣì lè máa lo àwọn kan lára ìlànà tó o ti kọ́ nílé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò sí lábẹ́ àwọn òbí rẹ mọ́.
Jèhófà, Baba wa ọ̀run, tipa Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wa ní ọ̀pọ̀ òfin tó ṣe pàtó. Bí àpẹẹrẹ, ó ka ìbọ̀rìṣà, àgbèrè, panṣágà àti olè jíjà léèwọ̀. (Ẹ́kísódù 20:1-17; Ìṣe 15:28, 29) Bí a ṣe ń “dàgbà sókè nínú ohun gbogbo” nípa tẹ̀mí, à ń rí i pé Jèhófà fẹ́ràn wa dáadáa, àti pé àwọn àṣẹ rẹ̀ kò káni lọ́wọ́ kò ju bó ṣe yẹ lọ.—Éfésù 4:15; Aísáyà 48:17, 18; 54:13.
Àmọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipò nǹkan ló wà tó jẹ́ pé kò sí òfin pàtó nípa rẹ̀. Ìyẹn ni àwọn kan fi rò pé, tí Bíbélì ò bá ṣe òfin pàtó kan lórí nǹkan kan, ó fi hàn pé ohun tó wu àwọn làwọn lè ṣe. Wọ́n máa ń sọ pé, bí Ọlọ́run bá ka nǹkan yẹn sóhun pàtàkì, ì bá ti ṣe òfin gbòógì kan nípa rẹ̀ láti sọ ohun tó fẹ́ ká ṣe.
Àwọn tó máa ń ronú lọ́nà yìí, sábà máa ń ṣe àwọn ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu, tí wọ́n máa ń kábàámọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Àṣìṣe wọn ni pé, wọn ò ṣàkíyèsí pé òfin nìkan kọ́ ló wà nínú Bíbélì, àwọn ohun tó fi èrò Ọlọ́run hàn wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Bí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ń mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan, á jẹ́ ká dẹni tó ní ẹ̀rí ọkàn tá a fi Bíbélì tọ́, ká sì máa ṣe àwọn ìpinnu tó bá èrò Ọlọ́run mu. Nígbà tá a bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, a máa ń mú inú rẹ̀ dùn, a sì máa ń jàǹfààní ṣíṣe tá à ń ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.—Éfésù 5:1.
Àwọn Àpẹẹrẹ Pàtàkì Látinú Bíbélì
Tá a bá wo ìtàn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà ayé àtijọ́ nínú Bíbélì, a máa ń rí àwọn ipò tí wọ́n ti gbé ohun tó jẹ́ èrò Jèhófà nípa ọ̀ràn yẹ̀ wò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ti Jósẹ́fù. Nígbà tí aya Pọ́tífárì fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́, kò tíì sí àkọsílẹ̀ òfin kankan látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó ka panṣágà léèwọ̀. Síbẹ̀, àní láìtiẹ̀ sí òfin pàtó kan, Jósẹ́fù fi òye mọ̀ pé yàtọ̀ sí pé bíbá aya aláya lò pọ̀ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí ẹ̀rí ọkàn òun, ó tún jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ “sí Ọlọ́run.” (Jẹ́nẹ́sísì 39:9) Dájúdájú, Jósẹ́fù mọ̀ pé ìwà panṣágà lòdì sí èrò àti ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ọlọ́run sọ ní Édẹ́nì ṣe fi hàn.—Jẹ́nẹ́sísì 2:24.
Ẹ jẹ́ ká mú àpẹẹrẹ mìíràn. Nínú Ìṣe 16:3, a rí i kọ́ pé kí Pọ́ọ̀lù tó mú Tímótì dání lọ sáwọn ìrìn-àjò tó rìn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ó kọ́kọ́ dá adọ̀dọ́ rẹ̀ ná. Síbẹ̀, a rí i kà ní ẹsẹ kẹrin pé lẹ́yìn ṣíṣe èyí, Pọ́ọ̀lù àti Tímótì ń la àwọn ìlú ńlá lọ, wọ́n sì ń fi “àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù ti ṣe ìpinnu lé lórí” jíṣẹ́ fún àwọn ará tó wà níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìpinnu pé àwọn Kristẹni ò sí lábẹ́ òfin ìdádọ̀dọ́ mọ́ wà lára àwọn àṣẹ yìí o! (Ìṣe 15:5, 6, 28, 29) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi rò pé ó ṣe pàtàkì pé kí Tímótì dádọ̀dọ́? Ó jẹ́ “nítorí àwọn Júù tí wọ́n wà ní àwọn ibi wọnnì, nítorí gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan mọ̀ pé Gíríìkì ni baba” Tímótì. Pọ́ọ̀lù ò fẹ́ ṣe ohun tí yóò bí ẹnikẹ́ni nínú tàbí tó lè mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀. Ohun tó jẹ ẹ́ lógún ni pé kí gbogbo Kristẹni máa “dámọ̀ràn ara [wọn] fún ìtẹ́wọ́gbà olúkúlùkù ẹ̀rí-ọkàn ẹ̀dá ènìyàn níwájú Ọlọ́run.”—2 Kọ́ríńtì 4:2; 1 Kọ́ríńtì 9:19-23.
Ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù àti Tímótì ń gbà ronú nìyẹn. Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Róòmù 14:15, 20, 21 àti 1 Kọ́ríńtì 8:9-13; 10:23-33, kí o rí bí ire tẹ̀mí àwọn ẹlòmíràn ṣe jẹ Pọ́ọ̀lù lógún gidigidi tó, pàápàá àwọn tó bá lè tipa ohun téèyàn ṣe kọsẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun náà lè máà kúkú lòdì. Pọ́ọ̀lù sì kọ̀wé nípa Tímótì pé: “Èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀ tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ yín. Nítorí gbogbo àwọn yòókù ń wá ire ara wọn, kì í ṣe ti Kristi Jésù. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ ẹ̀rí tí ó fúnni nípa ara rẹ̀, pé bí ọmọ lọ́dọ̀ baba ni ó sìnrú pẹ̀lú mi fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere.” (Fílípì 2:20-22) Àpẹẹrẹ pàtàkì mà làwọn Kristẹni méjèèjì yìí fi lélẹ̀ fún wa lónìí o! Wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Jèhófà àti ti Ọmọ rẹ̀ dípò kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́rùn tàbí kí wọ́n máa ṣe ohun tó wù wọ́n nígbà tí kò bá sí òfin kan pàtó nípa ohun kan. Wọ́n máa ń ronú lórí ipa tí ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yóò ní lórí àwọn ẹlòmíràn nípa tẹ̀mí.
Ẹ jẹ́ ká tún wo ti Jésù Kristi, àwòkọ́ṣe wa tó gba iwájú jù lọ. Nígbà tó ń ṣe Ìwàásù Lórí Òkè, ó ṣàlàyé kedere pé béèyàn bá ti lè lóye ìdì tí Ọlọ́run fi ṣe òfin kan, á tiẹ̀ pa òfin yẹn mọ́ ju ohun tí òfin náà ní ká ṣe tàbí èyí tó kà léèwọ̀ lọ. (Mátíù 5:21, 22, 27, 28) Kò sí èyíkéyìí nínú Jésù, Pọ́ọ̀lù, Tímótì tàbí Jósẹ́fù, tó kàn gbà pé níbi tí kò bá ti sí òfin pàtó kan tí Ọlọ́run ṣe lórí nǹkan kan, èèyàn lé ṣe ohunkóhun tó bá sáà ti wù ú. Nítorí kí wọ́n lè ṣe ohun tó bá èrò Ọlọ́run mu, wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà tí Jésù pè ní àṣẹ méjì títóbi jù lọ, ìyẹn ni láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì ẹni.—Mátíù 22:36-40.
Àwa Kristẹni Òde Òní Ńkọ́?
Ó dájú pé a ò gbọ́dọ̀ máa fojú tá a fi ń wo ìwé òfin wo Bíbélì, ká máa retí pé kó to gbogbo ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́ sílẹ̀ pátápátá. À ń mú inú Jèhófà dùn gan-an bí a bá fúnra wa ṣe ohun tó bá èrò rẹ̀ mu, kódà bí kò bá tiẹ̀ sí òfin pàtó kan tó sọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Ìyẹn ni pé, dípò kí á máa retí àtirí gbogbo ohun tí Ọlọ́run bá ń fẹ́ ká ṣe pátá ní àkọsílẹ̀, ńṣe ni à ń ‘fúnra wa ṣàwárí ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́.’ (Éfésù 5:17; Róòmù 12:2) Kí nìdí tí èyí fi ń mú inú Jèhófà dùn? Ìdí ni pé, ó fi hàn pé ṣíṣe ohun tó wù wá àti rírí ẹ̀tọ́ wa gbà kò jẹ wá lógún bíi pé ká ṣe ohun tó wu Ọlọ́run. Ó tún fi hàn pé a mọrírì ìfẹ́ tó fẹ́ wa débi pé a fẹ́ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ rẹ̀, tí ìfẹ́ yìí á fi di ohun tí ń darí wa nínú gbogbo nǹkan tá a bá ń ṣe. (Òwe 23:15; 27:11) Àti pé, tá a bá ń hùwà lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu, ó máa ń fi kún ìlera wa nípa tẹ̀mí àti nípa tara.
Ẹ jẹ́ ká wo bí a ṣe lè tẹ̀ lé ìlànà yìí nínú àwọn ọ̀ràn tiwa fúnra wa.
Ohun Ìnàjú Tí A Yàn
Ẹ wo àpẹẹrẹ ọmọkùnrin kan tó fẹ́ ra àwo orin kan. Ohùn orin tó gbọ́ yìí dùn gan-an, ṣùgbọ́n, ohun tó rí lára páálí orin yẹn kò dùn mọ́ ọn nítorí ó fi hàn pé orin ìṣekúṣe àti ọ̀rọ̀ rírùn ni olórin yẹn ń kọ. Lẹ́yìn náà, ó mọ̀ pé ọ̀pọ̀ jù lọ orin tí olórin yìí ti ṣe ló jẹ́ orin ìbínú àti oníwà jàgídíjàgan. Nítorí pé ọmọkùnrin yìí fẹ́ràn Jèhófà, ó fẹ́ mọ èrò Jèhófà àtohun tí ìfẹ́ rẹ̀ jẹ́ lórí ọ̀ràn yìí. Báwo ni yóò ṣe fúnra rẹ̀ ṣàwárí ohun tí Ọlọ́run máa fẹ́ kó ṣe?
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn ará Gálátíà, ó sọ àwọn ohun tó jẹ́ iṣẹ́ ti ara àti èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kó o ti mọ èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run tí í ṣe: ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu. Ṣùgbọ́n kí ni àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ́ iṣẹ́ ti ara? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Wàyí o, àwọn iṣẹ́ ti ara fara hàn kedere, àwọn sì ni àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, ìlara, mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí. Ní ti nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń kìlọ̀ ṣáájú fún yín, lọ́nà kan náà gẹ́gẹ́ bí mo ti kìlọ̀ ṣáájú fún yín, pé àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—Gálátíà 5:19-23.
Ṣàkíyèsí gbólóhùn tó kẹ́yìn nínú àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù tò sílẹ̀ yìí, ìyẹn, “nǹkan báwọ̀nyí.” Kò sọ gbogbo ohun tí a lè kà sí iṣẹ́ ti ara tán pátá. Ìyẹn ni pé, èèyàn ò kàn lè máa rò ó pé, ‘Ìwé Mímọ́ gbà mí láyè láti ṣe ohunkóhun tí kò bá ti sí lára àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn pé ó jẹ́ iṣẹ́ ti ara.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tó bá kà á yóò ní láti lo làákàyè rẹ̀ láti fi mọ àwọn nǹkan tí kò sí lára ohun tó mẹ́nu kàn, ṣùgbọ́n tó jẹ́ ara “nǹkan báwọ̀nyí.” Àwọn tó bá ń bá a lọ láti ṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ pé kò sí lára ohun tó mẹ́nu kàn ṣùgbọ́n tó jẹ́ ara “nǹkan báwọ̀nyí,” kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.
Nípa báyìí, ó yẹ ká máa róye, tàbí ká máa fi òye mọ ohun tí inú Jèhófà ò dùn sí. Ǹjẹ́ èyí ṣòro láti mọ̀? Jẹ́ ká sọ pé dókítà tó ń tọ́jú rẹ ní kó o máa jẹ èso àti ewébẹ̀ dáadáa, ṣùgbọ́n kó o má máa jẹ súìtì, pẹpẹmẹ́ńtì àti nǹkan báwọ̀nyí. Ṣé yóò ṣòro fún ọ láti mọ ara èwo lo máa ka ṣingọ́ọ̀mù mọ́ nínú ohun tó yẹ kó o jẹ àtèyí tí kò yẹ? Wàyí o, tún padà wo èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run àti àwọn iṣẹ́ ti ara. Ara èwo nínú méjèèjì lo máa ka orin tí a mẹ́nu kàn níṣàájú mọ́? Ó dájú pé kò jẹ mọ́ ànímọ́ bíi ìfẹ́, ìwà rere, ìkóra-ẹni-níjàánu tàbí èyíkéyìí nínú àwọn ànímọ́ tó wé mọ́ èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run. Èèyàn ò ṣẹ̀ṣẹ̀ nílò òfin pàtó kan kó tó lè fi òye mọ̀ pé irú orin bẹ́ẹ̀ kò bá èrò Ọlọ́run mu. Ìlànà kan náà ni yóò kan irú àwọn ìwé tá a fẹ́ kà, sinimá tàbí fídíò àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n tá a fẹ́ wò, eré orí kọ̀ǹpútà tá a fẹ́ ṣe, ibi ìkósọfúnnisí orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tá a máa lọ wò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìrísí Tó Bójú Mu
Bíbélì sì tún fún wa ní àwọn ìlànà nípa ọ̀ràn aṣọ wíwọ̀ àti ọ̀nà tá a lè gbà múra. Àwọn ìlànà yìí mú kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láti lè mú kí ìrísí wọn jẹ́ èyí tó dára. Síbẹ̀, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kì í wò ó pé ìyẹn ti wá ṣí àyè sílẹ̀ fáwọn láti máa wọ aṣọ àti láti máa múra bó kàn ṣe wù àwọn, bí kò ṣe kí wọ́n máa ṣe ohun tí yóò mú inú Baba wọn ọ̀run dùn. Gẹ́gẹ́ bí ohun tá a ti rí, ó hàn pé bí Jèhófà ò bá tiẹ̀ gbé òfin kalẹ̀ nípa nǹkan kan, kò fi hàn pé kò kọbi ara sí ohun táwọn èèyàn rẹ̀ ń ṣe. Ọ̀nà ìgbàránṣọ máa ń yàtọ̀ láti ibì kan síkejì, ó sì tiẹ̀ máa ń yí padà látìgbàdégbà láàárín àgbègbè kan náà pàápàá. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ti fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní àwọn ìlànà tó ṣe kókó tí yóò máa ṣamọ̀nà wọn nígbà gbogbo níbi gbogbo.
Bí àpẹẹrẹ, 1 Tímótì 2:9, 10 sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, mo ní ìfẹ́-ọkàn pé kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, èyíinì ni, nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere.” Nípa bẹ́ẹ̀, tí àwọn obìnrin Kristẹni, àti ọkùnrin pẹ̀lú, bá fẹ́ múra, ó yẹ kí wọ́n máa ronú nípa irú ìmúra tí àwọn èèyàn tó yí wọn ká gbà pé ó yẹ àwọn tí wọ́n “jẹ́wọ́ gbangba pé wọ́n ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.” Ní pàtàkì, ó yẹ kí Kristẹni kan ronú dáadáa nípa ohun tí ìmúra rẹ̀ lè gbìn sọ́kàn àwọn èèyàn nípa ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó ń sọ fáwọn èèyàn. (2 Kọ́ríńtì 6:3) Kristẹni tó jẹ́ ẹni àwòkọ́ṣe, kì í wonkoko mọ́ ohun tó kà sí ọ̀nà tóun fẹ́ gbà ṣe nǹkan tòun, tàbí ohun tó kà sí ẹ̀tọ́ òun, kàkà bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe ní di ẹni tó ń fa ìpínyà ọkàn tàbí ohun ìkọ̀sẹ̀ fáwọn ẹlòmíràn ní yóò jẹ ẹ́ lógún.—Mátíù 18:6; Fílípì 1:10.
Nígbà tí Kristẹni kan bá rí i pé ọ̀nà ìgbàmúra kan ń bí àwọn èèyàn nínú tàbí pé ó fẹ́ máa mú àwọn mìíràn kọsẹ̀, ó lè ṣe bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nípa jíjẹ́ kí ire tẹ̀mí àwọn èèyàn jẹ òun lógún ju ohun tó wu òun lọ. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 11:1) Pọ́ọ̀lù sì kọ̀wé nípa Jésù pé: “Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.” Ó hàn gbangba pé kókó ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ fáwọn Kristẹni ni pé: “Ó yẹ kí àwa tí a ní okun máa ru àìlera àwọn tí kò lókun, kí a má sì máa ṣe bí ó ti wù wá. Kí olúkúlùkù wa máa ṣe bí ó ti wu aládùúgbò rẹ̀ nínú ohun rere fún gbígbé e ró.”—Róòmù 15:1-3.
Bí A Ṣe Lè Mú Kí Agbára Ìmòye Wa Túbọ̀ Jí Pépé
Báwo la ṣe lè mú kí agbára ìmòye wa jí pépé débi tá a ó fi lè mọ bá a ṣe lè ṣe ohun tó wu Jèhófà, kódà nígbà tí kò bá fúnni ní ìtọ́ni tó ṣe pàtó lórí ọ̀ràn kan? Bí a bá ń ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójoojúmọ́, tà a ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ déédéé, tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, agbára ìmòye wa yóò túbọ̀ dára sí i. Irú ìtẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀ kì í hàn kedere lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bí ìdàgbàsókè ọmọdé ṣe ń rí ni ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí ṣe máa ń rí, kì í yára hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó gba sùúrù, ká má sì jẹ́ kó sú wa tá ò bá tètè rí ìtẹ̀síwájú tá à ń fẹ́. Àmọ́ o, bí àkókò téèyàn lò ṣe pọ̀ tó kọ́ ni yóò mú kí agbára ìmòye wa túbọ̀ jí pépé. A ní láti fi àkókò yẹn máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ sẹ́yìn, kí á sì máa sa gbogbo agbára wa láti fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹn sílò nígbèésí ayé wa.—Hébérù 5:14.
Kí á kúkú sọ pé, nígbà tó jẹ́ pé àwọn òfin Ọlọ́run máa ń fi bí a ṣe jẹ́ onígbọràn tó hàn, ńṣe ni àwọn ìlànà Ọlọ́run ń fi bí a ṣe jẹ́ ẹni tẹ̀mí sí àti bá a ṣe ń fẹ́ láti máa ṣe ohun tó wù ú hàn. Nítorí náà, bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ohun tí yóò máa jẹ wá lógún ni bí a ṣe máa fara wé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀. A óò fẹ́ láti máa ṣe ìpinnu tó bá èrò Ọlọ́run mu gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn. Bí a ṣe ń mú inú Baba wa ọ̀run dùn nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ayọ̀ wa yóò máa pọ̀ sí i.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọ̀nà ìgbàránṣọ máa ń yàtọ̀ láti ibì kan síkejì, àmọ́ àwọn ìlànà Bíbélì ló yẹ ká máa lò láti fi mọ irú aṣọ tó yẹ ká wọ̀