Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JUNE 1-7
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 44-45
“Jósẹ́fù Dárí Ji Àwọn Ẹ̀gbọ́n Rẹ̀”
“Èmi Ha Wà ní Ipò Ọlọ́run Bí?”
Jósẹ́fù wá dẹkùn mú àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó ní kí ìránṣẹ́ tó ń bá òun bójú tó ilé lé wọn bá, kó mú wọn, kó sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ti jí ife òun. Nígbà tí wọ́n rí ife náà nínú àpò Bẹ́ńjámínì, wọ́n dá gbogbo wọn pa dà sọ́dọ̀ Jósẹ́fù. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fún Jósẹ́fù láǹfààní láti mọ irú ẹni táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ jẹ́. Júdà gbẹnu sọ fún gbogbo wọn, ó sì bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n ṣàánú àwọn, kódà ó ní kí wọ́n jẹ́ kí gbogbo àwọn mọ́kànlá yìí di ẹrú ní Íjíbítì. Jósẹ́fù kọ̀ jálẹ̀ pé kí gbogbo àwọn tó kù máa lọ sílé, ṣùgbọ́n Bẹ́ńjámínì gbọ́dọ̀ di ẹrú ní Íjíbítì.—Jẹ́nẹ́sísì 44:2-17.
Ọ̀rọ̀ yìí ká Júdà lára gan-an débi tó fi sọ pé: “Òun nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù fún ìyá rẹ̀, baba rẹ̀ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí ti ní láti wọ Jósẹ́fù lọ́kàn torí pé òun ni àkọ́bí Rákélì, ìyàwó tí Jékọ́bù fẹ́ràn jù, bẹ́ẹ̀ ìgbà tí Rákélì ń bí Bẹ́ńjámínì ló kú. Bó ṣe jẹ́ pé Jékọ́bù ò lè gbàgbé Rákélì, bákan náà lọ̀rọ̀ ṣe rí lára Jósẹ́fù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé okùn ìyá kan náà tó so Jósẹ́fù pọ̀ mọ́ Bẹ́ńjámínì ló mú kó fẹ́ràn rẹ̀ gan-an.—Jẹ́nẹ́sísì 35:18-20; 44:20.
Ṣe ni Júdà túbọ̀ múra sí ẹ̀bẹ̀ tó ń bẹ Jósẹ́fù pé kó má sọ Bẹ́ńjámínì dẹrú. Ó tiẹ̀ sọ pé òun ni kó sọ dẹrú dípò Bẹ́ńjámínì. Ó wá fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn yìí parí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó ní: “Báwo ni èmi yóò ṣe lọ sọ́dọ̀ baba mi láìsí ọmọdékùnrin náà pẹ̀lú mi, kí ó má bàa wá di pé èmi yóò wo ìyọnu àjálù tí yóò dé bá baba mi?” (Jẹ́nẹ́sísì 44:18-34) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé ó ti yí pa dà. Èyí fi hàn pé kì í ṣe pé ó ronú pìwà dà nìkan ni, ó tún fi hàn pé ó lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, pé kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan àti pé ó lójú àánú.
Jósẹ́fù ò lè pa á mọ́ra mọ́. Gbogbo bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀ ti dé góńgó. Ó ní káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde síta, ó wá bú sẹ́kún. Ẹkún yìí pọ̀ débi pé wọ́n gbọ́ láàfin Fáráò. Níkẹyìn, ó jẹ́wọ́ fún wọn pé: “Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín.” Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, síbẹ̀ ó gbá wọn mọ́ra, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ti dárí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe sóun jì wọ́n. (Jẹ́nẹ́sísì 45:1-15) Ohun tó ṣe yìí fi hàn pé ó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, ẹni tó máa ń dárí jini fàlàlà. (Sáàmù 86:5) Ṣé àwa náà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 813
Fífa Aṣọ Ya
Àwọn Júù àtàwọn ará Ìlà Oòrùn sábà máa ń fa aṣọ wọn ya tí wọ́n bá gbọ́ pé ẹnì kan tó sún mọ́ wọn kú láti fi hàn pé ó dùn wọ́n gan-an. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n sábà máa ń fa aṣọ náà ya débi àyà, kì í ṣe pé wọ́n máa fà á ya débi tí kò fi ní ṣeé wọ̀ mọ́.
Ìgbà àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ni ìgbà tí Rúbẹ́nì tó jẹ́ àkọ́bí Jékọ́bù pa dà wá síbi kòtò omi tí wọ́n ju Jósẹ́fù sí, tí kò sí bá a níbẹ̀, ṣe ni Rúbẹ́nì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọ pé: “Ọmọ náà ti lọ! Kí ni màá ṣe báyìí?” Nítorí pé Rúbẹ́nì ni àkọ́bí, ojúṣe rẹ̀ ni láti dáàbò bo àbúrò rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sọ fún Jékọ́bù bàbá wọn pé Jósẹ́fù ti kú, òun náà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀ (Jẹ 37:29, 30, 34), bákan náà, nígbà táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì, wọ́n fa aṣọ wọn ya láti fi hàn bó ṣe dùn wọ́n tó nígbà tí wọ́n sọ pé Bẹ́ńjámínì ló jí ife omi Jósẹ́fù.—Jẹ 44:13.
Wọ́n Kórìíra Wa Láìnídìí
Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa bínú sí àwọn tó ń kórìíra wa láìnídìí? Ẹ rántí pé olórí elénìní wa ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. (Éfésù 6:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan mọ̀ọ́mọ̀ ń ṣenúnibíni sí wa, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń ṣàtakò sí àwọn èèyàn Ọlọ́run ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí àìmọ̀kan wọn tàbí kó jẹ́ pé àwọn ẹlòmíràn ló ń lò wọ́n. (Dáníẹ́lì 6:4-16; 1 Tímótì 1:12, 13) Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí “gbogbo onírúurú ènìyàn” ní àǹfààní láti ‘rí ìgbàlà kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.’ (1 Tímótì 2:4) Kódà, àwọn kan lára àwọn tó ń ṣàtakò sí wa tẹ́lẹ̀ ti di Kristẹni arákùnrin wa báyìí nítorí pé wọ́n ti rí i pé ìwà wa dára. (1 Pétérù 2:12) Láfikún sí i, a lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ Jósẹ́fù, ọmọ Jékọ́bù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù jìyà gan-an nítorí ohun táwọn ọbàkan rẹ̀ ṣe sí i, síbẹ̀ kò bá wọn ṣọ̀tá. Kí nìdí? Nítorí ó fòye mọ̀ pé Jèhófà lọ́wọ́ sí ọ̀ràn náà, pé òun ló mú kí ọ̀ràn náà rí bó ṣe rí kó lè mú ète Rẹ̀ ṣẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 45:4-8) Bákan náà ni Jèhófà lè fàyè gba ìyà èyíkéyìí tó lè jẹ wá láìnídìí kí ó lè já sí ìyìn orúkọ rẹ̀.—1 Pétérù 4:16.
Bíbélì Kíkà
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ Jósẹ́fù tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn lo ife fàdákà tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ kan láti fi woṣẹ́, bó ṣe jọ pé Jẹ́nẹ́sísì 44:5 sọ?
Kò sídìí kankan tó fi yẹ ká gbà pé Jósẹ́fù lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wíwò èyíkéyìí.
Bíbélì jẹ́ ká mọ bí òye Jósẹ́fù ṣe jinlẹ̀ tó nípa bí kò ṣe dára kéèyàn máa lo agbára òkùnkùn láti mọ ọjọ́ ọ̀la. Nígbà tí wọ́n sọ pé kí Jósẹ́fù túmọ̀ àlá Fáráò lákòókò kan, léraléra ló tẹnu mọ́ ọn pé kìkì Ọlọ́run nìkan ló lè “kéde” ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn ló mú Fáráò alára wá gbà gbọ́ pé Ọlọ́run tí Jósẹ́fù ń jọ́sìn ni Ọlọ́run tòótọ́ tó mú kí Jósẹ́fù mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, kì í ṣe agbára òkùnkùn. (Jẹ́nẹ́sísì 41:16, 25, 28, 32, 39) Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún Mósè lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jèhófà sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ pidán tàbí woṣẹ́, ìyẹn sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.—Diutarónómì 18:10-12.
Kí nìdí tí Jósẹ́fù fi gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé òun ń lo ife fàdákà láti fi ‘mọ àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́nà jíjáfáfá’? (Jẹ́nẹ́sísì 44:5) Ó yẹ ká gbé ohun tó fà á tó fi sọ bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò.
Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù rìnrìn àjò lọ sí Íjíbítì láti ra oúnjẹ nítorí ìyàn tó mú gan-an. Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn làwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yìí kan náà tà á sí oko ẹrú. Àmọ́ báyìí, wọn ò mọ̀ pé ọwọ́ àbúrò àwọn, tó ti di alábòójútó oúnjẹ nílẹ̀ Íjíbítì làwọn ti ń wá ìrànlọ́wọ́. Jósẹ́fù kò sọ ẹni tóun jẹ́ fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pinnu pé òun á dán wọn wò. Láìsí àní-àní, Jósẹ́fù fẹ́ mọ̀ bóyá wọ́n ti ronú pìwà dà lóòótọ́. Ó tún fẹ́ mọ̀ bóyá wọ́n nífẹ̀ẹ́ Bẹ́ńjámínì àbúrò wọn àti Jékọ́bù bàbá wọn tó fẹ́ràn Bẹ́ńjámínì gan-an. Ìdí nìyẹn tí Jósẹ́fù fi lo ọgbọ́n arúmọjẹ kan.—Jẹ́nẹ́sísì 41:55–44:3.
Jósẹ́fù sọ fún ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí ó kó oúnjẹ kún inú àpò àwọn arákùnrin òun, kó sì dá owó wọn padà sẹ́nu àpò olúkálukú wọn, ó tún sọ pé kó fi ife fàdákà òun sẹ́nu àpò Bẹ́ńjámínì. Nígbà tí Jósẹ́fù ń ṣe gbogbo èyí, ńṣe ló kàn ń ṣe bí alábòójútó ilẹ̀ abọ̀rìṣà kan. Ó yí ìṣe àti èdè ẹnu rẹ̀ padà kó bàa lè jọ ti alábòójútó ilẹ̀ abọ̀rìṣà, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí lójú àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọn ò fura.
Nígbà tí Jósẹ́fù ko àwọn arákùnrin rẹ̀ lójú, ó ń lo ọgbọ́n arúmọjẹ rẹ̀ nìṣó, ìyẹn ló mú kó bi wọn pé: “Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé irú ènìyàn bí èmi lè mọ àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́nà jíjáfáfá?” (Jẹ́nẹ́sísì 44:15) Nípa bẹ́ẹ̀, ó hàn kedere pé arúmọjẹ lásán ló fi ife yẹn ṣe. Bó ṣe jẹ́ pé Bẹ́ńjámínì kò jí ife náà ló ṣe jẹ́ pé Jósẹ́fù kò lo ife náà láti fi woṣẹ́.
JUNE 8-14
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 46-47
“Jèhófà Pèsè Oúnjẹ Lásìkò Ìyàn”
w87 5/1 15 ¶2
Pípa Ìwàláàyè Mọ́ ní Àkókó Ìyàn
Ọdún méje tí oúnjẹ fi pọ̀ rẹpẹtẹ ti wá parí báyìí, ìyàn náà sì ti bẹ̀rẹ̀ bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Íjíbítì nìkan kọ́ ló ti ṣẹlẹ̀, “gbogbo ilẹ̀” ni ìyàn náà ti mú. Nígbà táwọn ará Íjíbítì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Fáráò pé kó fún àwọn ní oúnjẹ, Fáráò sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ bá Jósẹ́fù, kí ẹ sì ṣe ohunkóhun tó bá sọ.” Jósẹ́fù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ta ọkà fún àwọn ará Íjíbítì títí owó wọn fi tán. Nígbà tó yá, àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ni wọ́n fi ń ra oúnjẹ. Nígbà tí gbogbo ohun tí wọ́n ní tán, àwọn èèyàn náà wá sọ́dọ̀ Jósẹ́fù, wọ́n ń sọ pé: “Ra àwa àti ilẹ̀ wa, kí o fi fún wa lóúnjẹ, àwa yóò di ẹrú Fáráò, ilẹ̀ wa yóò sì di tirẹ̀.” Bí Jósẹ́fù ṣe ra gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Íjíbítì fún Fáráò nìyẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 41:53-57; 47:13-20.
Ìjọba Náà Mú Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ ní Ayé
Ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan. Ìyàn nípa tẹ̀mí ń han aráyé léèmọ̀. Bíbélì sọ èyí tẹ́lẹ̀, ó ní: “ ‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘èmi yóò sì rán ìyàn sí ilẹ̀ náà dájúdájú, ìyàn, tí kì í ṣe fún oúnjẹ, àti òùngbẹ, tí kì í ṣe fún omi, bí kò ṣe fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.’ ” (Ámósì 8:11) Ǹjẹ́ ìyàn ń han àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run náà léèmọ̀? Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fi ìyàtọ̀ hàn láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ àtàwọn ọ̀tá rẹ̀, ó ní: “Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò jẹun, ṣùgbọ́n ebi yóò pa ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò mu, ṣùgbọ́n òùngbẹ yóò gbẹ ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò yọ̀, ṣùgbọ́n ojú yóò ti ẹ̀yin.” (Aísá. 65:13) Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé ọ̀rọ̀ yìí ń ṣẹ?
À ń gba ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ìpèsè tẹ̀mí bí ìgbà tí omi odò tó túbọ̀ ń fẹ̀ tó sì ń jìn ń ṣàn wá sọ́dọ̀ wa. Àwọn ìtẹ̀jáde wa tó dá lórí Bíbélì, títí kan àwọn ohùn àtẹ́tísí àti fídíò, àwọn ìpàdé àti àpéjọ àgbègbè wa àtàwọn ohun tí à ń gbé jáde lórí Ìkànnì wa, para pọ̀ jẹ́ ọ̀pọ̀ yanturu ìpèsè tẹ̀mí tó ń rọ́ wá gbùúgbùú bí ibú omi tó ń ṣàn, nínú ayé tí ìyàn tẹ̀mí ti ń han àwọn èèyàn léèmọ̀ yìí. (Ìsík. 47:1-12; Jóẹ́lì 3:18) Ǹjẹ́ inú rẹ kò dùn gan-an bó o ṣe ń rí i tí àwọn ìlérí Jèhófà pé òun máa pèsè ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan ṣe ń ṣẹ sí ọ lára lójoojúmọ́ ayé? Ǹjẹ́ ò ń rí i dájú pé ò ń jẹun déédéé lórí tábìlì Jèhófà?
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 220 ¶1
Ìṣesí àti Ìfaraṣàpèjúwe
Fífọwọ́ pa ojú ẹni tó kú dé. Nígbà tí Jèhófà sọ fún Jékọ́bù pé “Jósẹ́fù yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú rẹ” (Jẹ 46:4), ohun tó ní lọ́kàn ni pé Jósẹ́fù máa fọwọ́ pa ojú Jékọ́bù dé nígbà tó bá kú, ojúṣe àkọ́bí lèyí sì jẹ́. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jèhófà ń sọ fún Jékọ́bù pé Jósẹ́fù ni kó gba ẹ̀tọ́ tó tọ́ sí àkọ́bí.—1Kr 5:2.
nwtsty, àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 7:14
gbogbo wọn lápapọ̀ jẹ́ márùndínlọ́gọ́rin (75): Kò dájú pé ńṣe ni Sítéfánù ń tọ́ka sí ẹsẹ Bíbélì kan ní pàtó látinú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù nígbà tó sọ pé iye àwọn ará ilé Jékọ́bù tó bá a lọ sí Íjíbítì jẹ́ márùndínlọ́gọ́rin (75). Iye yìí ò sí nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tí àwọn Másórẹ́tì kọ. Jẹ 46:26 sọ pé: “Gbogbo ọmọ Jékọ́bù tó bá a lọ sí Íjíbítì, yàtọ̀ sí ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹ́rìndínláàádọ́rin (66).” Àmọ́, ẹsẹ kẹtàdínlọ́gbọ̀n sọ pé: “Gbogbo ará ilé Jékọ́bù tó wá sí Íjíbítì jẹ́ àádọ́rin 70.” Níbí, ọ̀nà méjì ni wọ́n gbà ka àwọn èèyàn yẹn. Àkọ́kọ́, wọ́n ka iye àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Jékọ́bù gangan, ọ̀nà kejì ni pé wọ́n ka gbogbo àwọn tó tẹ̀ lé Jékọ́bù lọ sí Íjíbítì. Ìwé Ẹk 1:5 àti Di 10:22 náà sọ pé iye àwọn ọmọ Jékọ́bù tó bá a lọ sí Íjíbítì jẹ́ “àádọ́rin (70).” Bí Sítéfánù ṣe sọ pé iye wọn jẹ́ márùndínlọ́gọ́rin (75) jẹ́ ká rí i pé ó ka àwọn mọ̀lẹ́bí Jékọ́bù míì mọ́ wọn. Bó ṣe wà nínú Jẹ 46:20 nínú Bíbélì ìtúmọ̀ ti Septuagint, àwọn kan sọ pé ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ Jósẹ́fù, ìyẹn Mánásè àti Éfúrémù wà lára wọ́n, títí kan àwọn ọmọ tí wọ́n bí. Àwọn míì sì sọ pé ó ṣeé se káwọn ìyàwó àwọn ọmọ Jékọ́bù wà lára wọn, àmọ́ tí Jẹ 46:26 ò kà wọ́n mọ́ wọn. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé “márùndínlọ́gọ́rin (75)” ni iye gbogbo àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ lápapọ̀. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kó ní ìdí tí iye yìí fi wà nínú àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tó wà káàkiri ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni. Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn làwọn ọ̀mọ̀wé ti mọ̀ pé “márùndínlọ́gọ́rin (75)” ni iye tí Jẹ 46:27 àti Ẹk 1:5 ń tọ́ka sí bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì ti Septuagint. Láfikún síyẹn, ní ọgọ́rùn-ún ọdún ogún, wọ́n rí àwọn àjákù Àkájọ Ìwé Òkun Òkú méjì ti Ẹk 1:5 lédè Hébérù, “márùndínlọ́gọ́rin (75)” ni iye tí wọ́n sì tún lò nínú wọn. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀kan nínú àwọn ìwé yìí ní Sítéfánù ń tọ́ka sí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èyí ó wù kó jẹ́, iye tí Sítéfánù tọ́ka sí jẹ́ ká rí ọ̀nà míì tá a tún lè gbà ka iye àwọn àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù.
Bíbélì Kíkà
JUNE 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 48-50
“Àwọn Àgbàlagbà Ní Ohun Púpọ̀ Láti Kọ́ Wa”
it-1 1246 ¶8
Jékọ́bù
Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jékọ́bù kú, ó súre fún àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ tí Jósẹ́fù bí. Nípasẹ̀ ìdarí Jèhófà, Jékọ́bù gbé Éfúrémù tó jẹ́ àbúrò ga ju Mánásè tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n lọ. Jékọ́bù wá sọ fún Jósẹ́fù tó máa gba ogún onílọ̀ọ́po méjì tó tọ́ sí àkọ́bí pé: “Ilẹ̀ tí mo fún ọ fi ọ̀kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ, èyí tí mo fi idà àti ọrun mi gbà lọ́wọ́ àwọn Ámórì.” (Jẹ 48:1-22; 1Kr 5:1) Àmọ́, Jékọ́bù ò fipá gba ilẹ̀ tó wà nítòsí Ṣékémù lọ́wọ́ àwọn Ámórì, ṣe ló ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ wọn. (Jẹ 33:19, 20) Torí náà, ó jọ pé ìlérí tí Jékọ́bù ṣe fún Jósẹ́fù fi hàn pé ó nígbàgbọ́ pé àwọn àtọmọdọ́mọ òun máa ṣẹ́gun àwọn ará Kénáánì, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà bí i pé ó ti nímùúṣẹ nígbà tó sọ pé òun ti fi idà àti ọrun òun gba ilẹ̀ náà. (Wo ÀWỌN ÁMÓRÌ.) Ilẹ̀ tí wọ́n pín fún ẹ̀yà Éfúrémù àti Mánásè nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun ilẹ̀ yẹn jẹ́ ogún onílọ̀ọ́po méjì tí wọ́n sọ pé wọ́n máa fún Jósẹ́fù.
it-2 206 ¶1
Ọjọ́ Ìkẹyìn
Àsọtẹ́lẹ̀ Jékọ́bù Nígbà Tó Fẹ́ Kú. Nígbà tí Jékọ́bù sọ fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Ẹ kó ara yín jọ, kí n lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́jọ́ iwájú” tàbí lọ́jọ́ ìkẹyìn, ó ń tọ́ka sí àkókó kan lọ́jọ́ iwájú tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ṣẹ. (Jẹ 49:1) Ọgọ́rùn-ún méjì ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà ti sọ fún Ábúrámù (Ábúráhámù) tó jẹ́ bàbá-bàbá Jékọ́bù pé wọ́n máa fìyà jẹ àwọn ọmọ rẹ̀ fún ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún. (Jẹ 15:13) Torí náà, ‘ọjọ́ iwájú’ tí Jékọ́bù ń sọ níbí máa ní láti bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún tí àwọn ọmọ rẹ̀ fi máa jìyà. (Láti mọ púpọ̀ sí nípa Jẹ́nẹ́sísì orí 49, ẹ wo àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù.) Ó ṣeé ṣe kí àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún ṣẹ sára “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” lọ́jọ́ iwájú.—Ga 6:16; Ro 9:6.
Ìbùkún Làwọn Àgbàlagbà Jẹ́ Fáwọn Ọ̀dọ́
Àwọn àgbàlagbà tún lè ní ipa rere lórí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Nígbà tí Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù ti di arúgbó, ó ṣe ohun kan wẹ́rẹ́ tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́, ìyẹn sì nípa tó lágbára lórí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn olùjọsìn tòótọ́ tó gbé ayé lẹ́yìn rẹ̀. Ẹni àádọ́fà ọdún ni nígbà tó “pa àṣẹ nípa àwọn egungun rẹ̀,” pé nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá máa kúrò nílẹ̀ Íjíbítì níkẹyìn, kí wọ́n kó egungun òun dání lọ. (Hébérù 11:22; Jẹ́nẹ́sísì 50:25) Àṣẹ tó pa yẹn túbọ̀ fi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́kàn balẹ̀ ní gbogbo ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n fi jẹ́ ẹrú lẹ́yìn ikú Jósẹ́fù, wọ́n mọ̀ dájú pé ìdáǹdè àwọn ń bọ̀.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ìbùkún Ni fún Àwọn Tó Ń fi Ògo fún Ọlọ́run
Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀yà Gádì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ káwọn tẹ̀dó sí àgbègbè kan tó dáa fún ohun ọ̀sìn ní apá ìlà oòrùn odò Jọ́dánì. (Númérì 32:1-5) Gbígbé ní ibi tá a ń wí yìí yóò gba pé kí wọ́n fara da àwọn ìṣòro líle koko. Àfonífojì Jọ́dánì tó jẹ́ ìdènà fún àwọn tó bá fẹ́ gbógun dìde yóò jẹ́ ààbò fún àwọn ẹ̀yà tó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn. (Jóṣúà 3:13-17) Àmọ́, ohun tí ìwé The Historical Geography of the Holy Land, tí George Adam Smith kọ sọ nípa ilẹ̀ tó wà ní apá ìlà oòrùn Jọ́dánì ni pé: “Gbogbo ilẹ̀ náà ló tẹ́jú pẹrẹsẹ láìsí ìdènà kankan lórí òkè ńlá olórí pẹrẹsẹ ti àwọn ará Arabia. Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo ìgbà làwọn alákòókiri tí ebi ń pa máa ń ya bò wọ́n, àwọn kan lára wọn sì máa ń fi ibẹ̀ ṣe pápá ìjẹko lọ́dọọdún.”
Kí ni ẹ̀yà Gádì máa ṣe nínú irú ìṣòro tí kò dáwọ́ dúró bẹ́ẹ̀? Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jékọ́bù baba ńlá wọn kú ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú àkókò yẹn, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ní ti Gádì, ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí yóò gbé sùnmọ̀mí lọ bá a, ṣùgbọ́n òun yóò gbé sùnmọ̀mí lọ bá apá ẹ̀yìn pátápátá.” (Jẹ́nẹ́sísì 49:19) Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn lè kọ́kọ́ dà bí èyí tó ń bani nínú jẹ́. Àmọ́ ní ti gidi, ó túmọ̀ sí pé a ní kí àwọn ọmọ Gádì gbẹ̀san lára wọn. Jékọ́bù mú un dá wọn lójú pé tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn onísùnmọ̀mí náà yóò fi ìtìjú sá padà, àwọn ọmọ Gádì yóò sì lépa wọn láti ẹ̀yìn.
it-1 289 ¶2
Bẹ́ńjámínì
Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nígbà tó fẹ́ kú, ó sọ nípa Bẹ́ńjámínì ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n pé: “Bẹ́ńjámínì yóò máa fani ya bí ìkookò. Ní àárọ̀, yóò jẹ ẹran tó pa. Ní ìrọ̀lẹ́, yóò pín ẹrù ogun.” (Jẹ 49:27) Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé akin lójú ogun làwọn àtọmọdọ́mọ Bẹ́ńjámínì máa jẹ́. Àwọn tó mọ bí wọ́n ṣe ń fi kànnàkànnà ju òkúta làwọn èèyàn mọ àwọn ọmọ ogun Bẹ́ńjámínì sí, torí wọ́n lè fi ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì ta òkúta, tá á sì ba “ìbú fọ́nrán irun.” (Ond 20:16; 1Kr 12:2) Ọlọ́wọ́ òsì ni Éhúdù tó jẹ́ ọmọ Bẹ́ńjámínì, òun ló sì pa Ọba Ẹ́gílónì tó ń jẹ gàba lé wọn lórí. (Ond 3:15-21) Ó ṣe pàtàkì ká tún mọ̀ pé “àárọ̀” ìjọba Ísírẹ́lì ni Sọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì tó wá láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì “tó kéré jù nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì” di ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì. Akínkanjú ni Sọ́ọ̀lù, òun ló sì gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Filísínì. (1Sa 9:15-17, 21) Bákan náà, “ní ìrọ̀lẹ́” Ẹ́sítà Ayaba àti Módékáì tí wọ́n wá láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó fẹ́ pa wọ́n run lábẹ́ ìjọba Páṣíà.—Ẹst 2:5-7.
Bíbélì Kíkà
JUNE 22-28
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 1-3
“Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Fẹ́”
Máa Gbé Orúkọ Ńlá Jèhófà Ga
Ka Ẹ́kísódù 3:10-15. Nígbà tí Mósè pé ẹni ọgọ́rin [80] ọdún, Ọlọ́run sọ fún un pé: “Mú àwọn ènìyàn mi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì.” Lẹ́yìn náà ni Mósè bi Ọlọ́run ní ìbéèrè kan tó mọ́gbọ́n dání. Ó ní: ‘Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá wá bi mí pé kí ni orúkọ rẹ, kí ni kí n sọ fún wọn?’ Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn Ọlọ́run ti mọ orúkọ rẹ̀, kí wá nìdí tí Mósè fi ń béèrè orúkọ Ọlọ́run? Ìdí ni pé ó fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa irú Ọlọ́run tí Jèhófà jẹ́. Mósè fẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa dá wọn nídè lóòótọ́. Kò sì ṣòro fún wa láti lóye ìyẹn, torí pé ó ti pẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wà lóko ẹrú, wọ́n sì ti lè máa ṣiyè méjì pé bóyá ni Ọlọ́run lè dá àwọn nídè. Kódà, àwọn kan lára wọn ti ń sin àwọn òrìṣà ilẹ̀ Íjíbítì.—Ìsík. 20:7, 8.
kr 43, àpótí
ÌTUMỌ̀ ORÚKỌ ỌLỌ́RUN
INÚ ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tó túmọ̀ sí “láti di” ni orúkọ náà, Jèhófà ti wá. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ṣe ni ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù yìí sábà máa ń fi hàn pé ohun kan tàbí ẹnì kan mú kí nǹkan kan di ṣíṣe. Ìyẹn ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbà pé orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Ìtumọ̀ yìí bá Jèhófà mu gan-an ni torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá. Òun ló dá ayé àtọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá olóye, ó sì ń bá a lọ ní mímú kí ìfẹ́ rẹ̀ àti ète rẹ̀ di èyí tó ṣẹ.
Kí wá ni èsì Jèhófà sí ìbéèrè Mósè tó wà ní Ẹ́kísódù 3:13, 14 túmọ̀ sí? Mósè béèrè pé: “Ká ní mo wá dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ni ó rán mi sí yín,’ tí wọ́n sì sọ fún mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn?” Jèhófà wá dá a lóhùn pé: “Èmi Yóò Jẹ́ Ohun Tí Èmi Yóò Jẹ́.”
Kíyè sí i pé Mósè ò sọ pé kí Jèhófà sọ orúkọ tó ń jẹ́ fún òun. Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti mọ orúkọ Ọlọ́run dáadáa tẹ́lẹ̀. Ṣe ni Mósè fẹ́ kí Jèhófà ṣe nǹkan kan táá jẹ́ kí àwọn nígbàgbọ́ tó lágbára nínú irú Ọlọ́run tó jẹ́, ohun kan tó máa fi hàn pé orúkọ rẹ̀ ń rò ó lóòótọ́. Torí náà, bí Jèhófà ṣe sọ pé “Èmi Yóò Jẹ́ Ohun Tí Èmi Yóò Jẹ́,” ìyẹn ni pé èmi yòó di ohunkóhun tí mo bá fẹ́, ṣe ni Jèhófà ń tipa bẹ́ẹ̀ fi ọ̀kan nínú apá tó wúni lórí nípa irú ẹni tó jẹ́ hàn. Tó fi hàn pé nínú gbogbo ipò tó bá yọjú, yòó di ohunkóhun tó bá yẹ láti lè mú ète rẹ̀ ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà di Olùgbàlà, Afúnnilófin àti Olùpèsè fún Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kódà ó tún ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fún wọn. Nípa báyìí, Jèhófà máa ń yàn láti di ohunkóhun tó bá yẹ kó lè mú àwọn ìlérí tó ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ ṣẹ. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ Jèhófà lè fi hàn pé òun fúnra rẹ̀ máa ń yàn láti di ohunkóhun tó bá yẹ, ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ kò mọ síbẹ̀. Ó tún kan ohun tó ń mú kí àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ dà láti lè mú ète rẹ̀ ṣẹ.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ṣé Mósè Ti Gbáyé Rí àbí Ẹni Ìtàn Àròsọ Ni?
Àmọ́ ṣá o, ṣé kò ti pọ̀ jù láti retí pé kí ọmọbìnrin ọba Íjíbítì dáàbò bo irú ọmọ bẹ́ẹ̀? Ó tì o, nítorí pé ẹ̀sìn àwọn ará Íjíbítì fi kọ́ wọn pé ṣíṣoore jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó lè mú kí wọ́n rí ọ̀run wọ̀. Ní ti gbígbà tó gbà á ṣọmọ, awalẹ̀pìtàn Joyce Tyldesley sọ pé: “Ipò kan náà làwọn obìnrin àtàwọn ọkùnrin wà nílẹ̀ Íjíbítì. Ká ṣáà sọ pé ẹ̀tọ́ kan náà ni wọ́n ní lábẹ́ òfin àti nínú ọ̀ràn ìṣòwò, . . . àwọn obìnrin sì lè gbani ṣọmọ.” Ó wà lákọọ́lẹ̀ nínú òrépèté ìgbàanì kan pé obìnrin kan ní Íjíbítì gba àwọn ẹrú rẹ̀ ṣọmọ. Wàyí o, ní ti gbígbà tí wọ́n gba ìyá Mósè láti bá wọn tọ́jú ọmọ náà, ìwé The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Sísanwó fún ìyá tó bí Mósè láti bá wọn tọ́jú ọmọ náà . . . rán wa létí irú ìṣètò kan náà tó fara jọ èyí tó máa ń wáyé nínú àdéhùn ìgbàṣọmọ táwọn ara Mesopotámíà máa ń ṣe.”
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́kísódù
3:1—Irú àlùfáà wo ni Jẹ́tírò? Lákòókò àwọn baba-ńlá, olórí ìdílé ló máa ń sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún ìdílé rẹ̀. Ó dájú nígbà náà pé baba-ńlá tó jẹ́ olórí ẹ̀yà àwọn ará Mídíánì kan ni Jẹ́tírò. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, tí ìyàwó rẹ̀ Kétúrà bí fún un, làwọn ará Mídíánì, ìjọsìn Jèhófà lè máà fi bẹ́ẹ̀ ṣàjèjì sí wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 25:1, 2.
Bíbélì Kíkà
JUNE 29–JULY 5
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 4-5
“Màá Wà Pẹ̀lú Rẹ Bí O Ṣe Ń Sọ̀rọ̀”
Ojú Wo Ni Jèhófà Fi Ń Wo Àwíjàre?
“Mi ò kúnjú ìwọ̀n tó.” Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o kò tóótun láti jẹ́ òjíṣẹ́ ìhìn rere. Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà kan láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì nímọ̀lára pé àwọn kò kúnjú ìwọ̀n tó láti ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún wọn. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Mósè yẹ̀ wò. Nígbà tí Jèhófà gbé iṣẹ́ kan lé Mósè lọ́wọ́, ohun tó sọ ni pé: “Dákun, Jèhófà, ṣùgbọ́n èmi kì í ṣe ẹni tí ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó já geere, kì í ṣe láti àná, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ṣáájú ìgbà yẹn tàbí láti ìgbà tí o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, nítorí ẹnu mi wúwo, ahọ́n mi sì wúwo.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fọkàn rẹ̀ balẹ̀, Mósè fèsì pé: “Dákun, Jèhófà, ṣùgbọ́n, jọ̀wọ́, ránṣẹ́ nípa ọwọ́ ẹni tí ìwọ yóò rán.” (Ẹ́kís. 4:10-13) Kí ni Jèhófà wá ṣe?
Ǹjẹ́ Ò Ń Rí “Ẹni Tí A Kò Lè Rí”?
Kí Mósè tó pa dà sí Íjíbítì, Ọlọ́run kọ́ ọ ní ìlànà pàtàkì kan tó wá pa dà kọ sínú ìwé Jóòbù. Ìlànà náà ni pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà—ìyẹn ni ọgbọ́n.” (Jóòbù 28:28) Kí Mósè bàa lè ní irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ kó sì máa fi ọgbọ́n hùwà, Jèhófà bi í ní ìbéèrè tó jẹ́ kó rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ọlọ́run Olódùmarè àti àwa èèyàn. Ó ní: “Ta ní yan ẹnu fún ènìyàn tàbí ta ní yan ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ tàbí adití tàbí ẹni tí ó ríran kedere tàbí afọ́jú? Èmi Jèhófà ha kọ́ ni?”—Ẹ́kís. 4:11.
Ẹ̀kọ́ wo lèyí kọ́ Mósè? Ó kọ́ Mósè pé kò sídìí fún un láti bẹ̀rù. Jèhófà ló rán Mósè níṣẹ́, òun náà ló sì máa fún un ní ohunkóhun tó bá nílò kó lè jíṣẹ́ tó rán an sí Fáráò. Àti pé ta ni Fáráò níbi tí Jèhófà wà. Ó ṣe tán, kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí ẹ̀mí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa wà nínú ewu lábẹ́ àkóso ọba Íjíbítì. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí Mósè ti ṣàṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe dáàbò bo Ábúráhámù, Jósẹ́fù àti Mósè alára nígbà ayé àwọn Fáráò tó ti kọjá. (Jẹ́n. 12:17-19; 41:14, 39-41; Ẹ́kís. 1:22–2:10) Torí pé Mósè ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà “Ẹni tí a kò lè rí,” ó fìgboyà tọ Fáráò lọ ó sì kéde gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà pa láṣẹ pé kó sọ fún Fáráò.
Ojú Wo Ni Jèhófà Fi Ń Wo Àwíjàre?
Jèhófà kò gba iṣẹ́ yẹn lọ́wọ́ Mósè. Àmọ́, Jèhófà yan Áárónì láti ran Mósè lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. (Ẹ́kís. 4:14-17) Síwájú sí i, ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà dúró ti Mósè, ó sì ń pèsè ohunkóhun tó bá nílò fún un kó lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ tó gbé lé e lọ́wọ́. Lóde òní, ó yẹ kó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà máa lo àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Lékè gbogbo rẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé Jèhófà máa mú ká kúnjú ìwọ̀n láti ṣe iṣẹ́ tó pa láṣẹ fún wa pé ká ṣe.—2 Kọ́r. 3:5; wo àpótí náà “Ọdún Tí Mo Láyọ̀ Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Mi.”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ọ̀rọ̀ tí Sípórà sọ pé, “ọkọ ìyàwó ẹ̀jẹ̀ ni o jẹ́ fún mi” jẹ́ ohun tó ṣàjèjì. Kí ni gbólóhùn yìí fi hàn nípa Sípórà? Nípa fífaramọ́ ohun tí májẹ̀mú ìdádọ̀dọ́ sọ, Sípórà gbà pé òun wà nínú májẹ̀mú kan pẹ̀lú Jèhófà. Májẹ̀mú Òfin tí Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi hàn pé nínú májẹ̀mú kan, a lè ka Jèhófà sí ọkọ kí á sì ka ẹlòmíràn tó tún wà nínú májẹ̀mú náà sí ìyàwó. (Jeremáyà 31:32) Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí Sípórà ń pe Jèhófà ní “ọkọ ìyàwó ẹ̀jẹ̀” (nípasẹ̀ áńgẹ́lì náà), ó jọ pé ńṣe ni Sípórà ń fi hàn bí òun ṣe fara mọ́ ohun tí májẹ̀mú náà sọ. Ńṣe ló dà bíi pé ó tẹ́wọ́ gba ipò aya nínú májẹ̀mú ìdádọ̀dọ́, ó sì ka Jèhófà Ọlọ́run sí ọkọ. Èyí ó wù kó jẹ́, nítorí pé ó ṣègbọràn láìjáfara sí ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ kò sí nínú ewu mọ́.
it-2 12 ¶5
Jèhófà
Pé èèyàn “mọ” ẹnì kan tàbí ohun kan kò fìgbà gbogbo túmọ̀ sí pé a mọ ohun náà tàbí ẹni náà délẹ̀délẹ̀. Nábálì tó jẹ́ òpònú mọ orúkọ Dáfídì, síbẹ̀ ó béèrè pé, “Ta ni Dáfídì?” lédè míì, ó dà bí ìgbà tó ń sọ pé, “Kí ló tiẹ̀ ń fira ẹ̀ pè ná?” (1Sa 25:9-11; fi wé 2Sa 8:13.) Àpẹẹrẹ míì ni ti Fáráò tó sọ fún Mósè pé: “Ta ni Jèhófà, tí màá fi gbọ́ràn sí i lẹ́nu pé kí n jẹ́ kí Ísírẹ́lì lọ? Mi ò mọ Jèhófà rárá, mi ò sì ní jẹ́ kí Ísírẹ́lì lọ.” (Ẹk 5:1, 2) Nípa bẹ́ẹ̀, ṣe ni Fáráò ń fi hàn pé òun ò ka Jèhófà sí Ọlọ́run tòótọ́, pé Jèhófà kò ní ọlá àṣẹ kankan lórí ọba Íjíbítì àti pé kò sí ohun tó kàn án nípa bí nǹkan ṣe ń lọ níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lágbára láti ṣe gbogbo ohun tí Mósè àti Áárónì sọ. Àmọ́, Fáráò àti gbogbo àwọn ará Íjíbítì títí kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tó mọ ìtumọ̀ orúkọ Jèhófà àti irú ẹni tó jẹ́. Jèhófà jẹ́ kí Mósè rí bí òun ṣe máa ṣe bẹ́ẹ̀ ní ti pé á mú ohun tó ní lọ́kàn fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ, á dá wọn nídè, á mú wọn wọ Ilẹ̀ Ìlérí, á sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ìlérí tó ṣe fún àwọn baba ńlá wọn ṣẹ. Èyí máa mú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ ṣẹ, nígbà tó sọ pé: “Ẹ ó mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.”—Ẹk 6:4-8; wo OLÓDÙMARÈ.
Bíbélì Kíkà