Wọ́n Kórìíra Wa Láìnídìí
“Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.”—JÒHÁNÙ 15:25.
1, 2. (a) Kí nìdí tó fi máa ń ṣe àwọn kan ní kàyéfì nígbà táwọn èèyàn bá ń pẹ̀gàn àwọn Kristẹni, àmọ́ kì nìdí tí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kó fi yà wá lẹ́nu? (b) Èwo la óò gbé yẹ̀ wo lára ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “kórìíra” nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
ÀWA Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn táwọn èèyàn fi ń sọ̀rọ̀ wa ní rere ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Àmọ́ ṣá o, àwọn èèyàn máa ń bà wá lórúkọ jẹ́ nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, òṣìṣẹ́ ìjọba kan ní ìlú St. Petersburg, ilẹ̀ Rọ́ṣíà, sọ pé: “Ohun tá a gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé wọ́n jẹ́ ẹ̀ya ìsìn kan tó máa ń ṣe àwọn nǹkan wọn níkọ̀kọ̀, tí wọ́n máa ń dúńbú àwọn ọmọdé tí wọ́n sì máa ń para wọn pẹ̀lú.” Àmọ́ lẹ́yìn tí òṣìṣẹ́ ìjọba náà bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣiṣẹ́ kan tó ní í ṣe pẹ̀lú àpéjọ àgbáyé wọn, ó wá sọ pé: “Ìsinsìnyí ni mo wá rí i pé èèyàn àtàtà tára wọn yọ̀ mọ́ọ̀yàn ni wọ́n . . . Èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni wọ́n, ara wọn balẹ̀, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an.” Ó wá fi kún un pé: “Mi ò mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń pa irú irọ́ yẹn mọ́ wọn.”—1 Pétérù 3:16.
2 Inú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kì í dùn nígbà táwọn èèyàn bá ń pè wọ́n ní aṣebi, síbẹ̀ kì í yà wọ́n lẹ́nu nígbà táwọn èèyàn bá ń sọ ohun tí ò dáa nípa wọn. Jésù ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kí ó tó kórìíra yín. . . . Ó jẹ́ láti lè mú ọ̀rọ̀ tí a kọ sínú Òfin wọn ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’”a (Jòhánù 15:18-20, 25; Sáàmù 35:19; 69:4) Ó ti sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣáájú pé: “Bí àwọn ènìyàn bá ti pe baálé ilé ní Béélísébúbù, mélòómélòó ni wọn yóò pe àwọn ti agbo ilé rẹ̀ bẹ́ẹ̀?” (Mátíù 10:25) Àwọn Kristẹni mọ̀ pé fífarada irú ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ ara “òpó igi oró” tí wọ́n gbà láti gbé nígbà tí wọ́n di ọmọlẹ́yìn Kristi.—Mátíù 16:24.
3. Báwo làwọn èèyàn ṣe máa ṣe inúnibíni sí àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ tó?
3 Ó ti pẹ́ gan-an táwọn èèyàn ti máa ń ṣenúnibíni sáwọn olùjọ́sìn tòótọ́, ó ti bẹ̀rẹ̀ láti àkókò “Ébẹ́lì olódodo.” (Mátíù 23:34, 35) Kì í sì í ṣe pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni inúnibíni yìí máa ń wáyé. Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun yóò jẹ́ “ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn” ní tìtorí orúkọ òun. (Mátíù 10:22) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà tún kọ̀wé pé gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run—títí kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wa—gbọ́dọ̀ mọ̀ pé àwọn èèyàn yóò ṣe inúnibíni sáwọn. (2 Tímótì 3:12) Kí ló máa mú kí wọ́n ṣe inúnibíni sí wa?
Ẹni Tó Ń Fa Ìkórìíra Láìnídìí
4. Báwo ni Bíbélì ṣe tú àṣírí ẹni tó wà nídìí gbogbo ìkórìíra láìnídìí yìí?
4 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé àtìbẹ̀rẹ̀ ni ẹni àìrí kan ti dá ìkórìíra yìí sílẹ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò ìpa ìkà tí wọ́n pa ọkùnrin tó kọ́kọ́ jẹ́ ẹni ìgbàgbọ́ láyé, ìyẹn Ébẹ́lì. Bíbélì sọ pé Kéènì, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó jẹ́ apànìyàn “pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà,” Sátánì Èṣù. (1 Jòhánù 3:12) Kéènì tẹ̀ lé ìwà Sátánì, Èṣù sì lò ó láti mú ète búburú rẹ̀ ṣẹ. Bíbélì tún jẹ́ ká rí ipa tí Sátánì kó nínú ìyà tí Jóòbù àti Jésù Kristi fojú winá rẹ̀. (Jóòbù 1:12; 2:6, 7; Jòhánù 8:37, 44; 13:27) Ìwé Ìṣípayá kò tiẹ̀ fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ rárá nípa ẹni tó wà nídìí inúnibíni táwọn èèyàn ń ṣe sáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, ó sọ pé: “Èṣù yóò máa bá a nìṣó ní sísọ àwọn kan nínú yín sí ẹ̀wọ̀n kí a lè dán yín wò ní kíkún.” (Ìṣípayá 2:10) Bẹ́ẹ̀ ni o, Sátánì ló wà nídìí gbogbo bí àwọn èèyàn ṣe ń kórìíra àwọn èèyàn Ọlọ́run láìnídìí.
5. Kí nìdí tí Sátánì fi kórìíra àwọn olùjọsìn tòótọ́?
5 Kí ló fà á tí Sátánì fi kórìíra àwọn olùjọsìn tòótọ́? Ohun tó fà á ni pé Sátánì dìtẹ̀, ó gbéra ga, ó sì bá Jèhófà Ọlọ́run, “Ọba ayérayé” dupò. (1 Tímótì 1:17; 3:6) Ó sọ pé Ọlọ́run ti ń káni lọ́wọ́ kò jù nínú bó ṣe ń ṣàkóso àwọn nǹkan tó dá, ó tún ní kò sẹ́ni tó ń fọkàn tó dáa sin Jèhófà, pé ẹ̀mí ìmọtara ẹni nìkan ló ń jẹ́ káwọn èèyàn sìn ín. Sátánì wá sọ pé bí Ọlọ́run bá fàyè gba òun láti dán àwọn èèyàn wò, ó lóun lè yí gbogbo wọn padà kúrò nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Jóòbù 1:6-12; 2:1-7) Kí Sátánì lè sọ ara rẹ̀ di ọba aláṣẹ bíi ti Ọlọ́run ló ṣe fi ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ba orúkọ Jèhófà jẹ́, tó pè é ní aninilára, òpùrọ́, àti aláṣetì. Nítorí náà, fífẹ́ tó fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun ló ń mú kó máa bínú sáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run.—Mátíù 4:8, 9.
6. (a) Báwo ni ọ̀ràn ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ṣe kàn wá? (b) Báwo ni lílóye kókó yìí ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìwà títọ́ wa mọ́? (Wo àpótí, ojú ìwé 16.)
6 Ṣé o wá rí i bí ọ̀ràn yìí ṣe kàn ọ́? Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, wàá ti rí i pé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run gba ìsapá gidigidi, àmọ́ ó lérè tó pọ̀ jaburata. Ṣùgbọ́n, kí lo máa ṣe tó bá jẹ́ pé bí ipò nǹkan ṣe rí fún ọ mú kó ṣòro tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ kó ni ọ́ lára gan-an láti máa bá a lọ láti pa àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà mọ́? Tó bá dà bíi pé o ò rí àǹfààní kankan nínú sísin Jèhófà ńkọ́? Ṣé wàá wá tìtorí ìyẹn sọ pé kò sídìí kankan tó fi yẹ kéèyàn máa sin Jèhófà? Tàbí ṣé ìfẹ́ tó o ní sí Jèhófà àti ìmọrírì jíjinlẹ̀ tó o ní fún àwọn ànímọ́ rere rẹ̀ yóò sún ọ láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀? (Diutarónómì 10:12, 13) Àyè tí Jèhófà fi gba Sátánì láti fìyà jẹ wa láwọn ọ̀nà kan ni Jèhófà lò láti fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láǹfààní láti dáhùn ìṣáátá Sátánì.—Òwe 27:11.
“Nígbà Tí Àwọn Èèyàn Bá Gàn Yín”
7. Kí ni ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kan tí Èṣù ń lò tó fi ń gbìyànjú láti yí wa kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà?
7 Ẹ jẹ́ ká wá gbé ọ̀kan yẹ̀ wò wàyí lára àwọn ìwà àrékérekè tí Sátánì ń lò láti jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé òótọ́ ni ohun tóun ń sọ, ìyẹn ni bó ṣe ń lo irọ́ láti pẹ̀gàn. Jésù pe Sátánì ní “baba irọ́.” (Jòhánù 8:44) Orúkọ yẹn Èṣù, tá a fi ń pè é túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́,” tó fi hàn pé òun ni òléwájú nínú fífi ọ̀rọ̀ èké ba Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ń ṣeni láǹfààní, àti orúkọ mímọ́ rẹ̀ jẹ́. Èṣù máa ń dọ́gbọ́n sọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, ó tún máa ń fi ẹ̀sùn èké, àti irọ́ pátápátá pẹ̀gàn ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kan náà yìí ló sì ń lò láti ba àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórúkọ jẹ́. Nípa kíkó ẹ̀gàn tó pọ̀ gan-an bá àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí, ó lè mú kí àdánwò líle koko di èyí táá túbọ̀ nira gan-an fún wọn láti fara dà.
8. Báwo ni Sátánì ṣe mú ẹ̀gàn bá Jóòbù, kí sì ni ipa tó ní?
8 Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù yẹ̀ wò, ẹni tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Ẹni Ìkóguntì.” Ní àfikún sí mímú tí Sátánì mú kí Jóòbù pàdánù gbogbo ohun tó ní, tí gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ kú, tí àìsàn sì kọ lù ú, ó tún mú kí Jóòbù dà bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tí Ọlọ́run ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni táwọn èèyàn ń bọ̀wọ̀ fún gan-an ni Jóòbù tẹ́lẹ̀, ó wá dẹni táwọn èèyàn ń tẹ́ńbẹ́lú, títí kan àwọn ará ilé rẹ̀ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ pàápàá. (Jóòbù 19:13-19; 29:1, 2, 7-11) Síwájú sí i, Sátánì tún lo àwọn èké olùtùnú láti ‘fi ọ̀rọ̀ fọ́ Jóòbù sí wẹ́wẹ́,’ wọ́n kọ́kọ́ sọ pé ó ti ní láti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan, ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n wá dẹ́bi fún un ní tààràtà pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni. (Jóòbù 4:6-9; 19:2; 22:5-10) Ìyẹn á mà ba Jóòbù lọ́kàn jẹ́ gan-an o!
9. Báwo ni wọ́n ṣe mú kí Jésù dà bí ẹlẹ́ṣẹ̀ lójú àwọn èèyàn?
9 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run lẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn tó fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, ó wá di ẹni tí Sátánì ń kógun tì ju ti ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Nígbà tí Jésù wá sórí ilẹ̀ ayé, Sátánì wá bí òun ṣe máa sọ ọ́ di alábààwọ́n nípa tẹ̀mí lójú àwọn èèyàn, gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe sí Jóòbù, ó mú kí Jésù dà bí ẹlẹ́ṣẹ̀ lójú àwọn èèyàn. (Aísáyà 53:2-4; Jòhánù 9:24) Àwọn èèyàn pè é ní ọ̀mùtípara àti alájẹkì, wọ́n tiẹ̀ sọ pé ó “ní ẹ̀mí èṣù” pàápàá. (Mátíù 11:18, 19; Jòhánù 7:20; 8:48; 10:20) Wọ́n fi ẹ̀sùn èké kan Jésù pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run. (Mátíù 9:2, 3; 26:63-66; Jòhánù 10:33-36) Èyí dun Jésù gan-an, nítorí ó mọ̀ pé ó mú ẹ̀gàn bá Bàbá òun láìnídìí. (Lúùkù 22:41-44) Níkẹyìn, wọ́n kan Jésù mọ́gi bí arúfin kan tó jẹ́ ẹni ègún. (Mátíù 27:38-44) Kí Jésù lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ délẹ̀délẹ̀, ó fara da ọ̀pọ̀ “òdì ọ̀rọ̀ . . . láti ẹnu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”—Hébérù 12:2, 3.
10. Báwo ni ìyókù ẹni àmì òróró ṣe jẹ́ ẹni tí Sátánì dájú sọ ní ayé òde òní?
10 Bákan náà lóde òní, Èṣù ń gbógun ti àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi gan-an. Bíbélì ṣàpèjúwe Sátánì gẹ́gẹ́ bí “olùfisùn àwọn arákùnrin [Kristi] . . . , ẹni tí ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sán-tòru níwájú Ọlọ́run wa.” (Ìṣípayá 12:9, 10) Àtìgbà tí wọ́n ti lé e kúrò ní ọ̀run tí kò sì lè kúrò ní sàkání ilẹ̀ ayé mọ́ ló ti túbọ̀ ń sa gbogbo ipa rẹ̀ láti jẹ́ kí àwọn arákùnrin Kristi dà bí ẹni ẹ̀gàn. (1 Kọ́ríńtì 4:13) Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n ń bà wọ́n lórúkọjẹ́ nípa pípè wọ́n ní ẹgbẹ́ eléwu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe pe àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. (Ìṣe 24:5, 14; 28:22) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ níṣàájú, wọ́n tan irọ́ kálẹ̀ láti fi bà wọ́n lórúkọ jẹ́. Síbẹ̀, “nípasẹ̀ ògo àti àbùkù, nípasẹ̀ ìròyìn búburú àti ìròyìn rere,” àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi, tí àwọn “àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń ti lẹ́yìn ti sakun tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ‘láti pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, àti láti ṣe iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.’—2 Kọ́ríńtì 6:8; Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 12:17.
11, 12. (a) Kí ló lè jẹ́ ìdí fún àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn kan táwọn èèyàn ń sọ sáwọn Kristẹni? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni Kristẹni kan fi lè jìyà láìṣẹ̀ nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀?
11 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn tí wọ́n bá sọ sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ló jẹ́ “nítorí òdodo.” (Mátíù 5:10) Àwọn ìṣòro kan lè wáyé nítorí àìpé tiwa fúnra wa. Kò sí iyì kankan níbẹ̀ tá a bá ń “fara dà á nígbà tí [à] ń dẹ́ṣẹ̀, tí a sì ń gbá [wa] lábàrá.” Àmọ́ tí Kristẹni kan “nítorí ẹ̀rí-ọkàn sí Ọlọ́run, bá ní àmúmọ́ra lábẹ́ àwọn ohun tí ń kó ẹ̀dùn-ọkàn báni, tí ó sì jìyà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu, èyí jẹ́ ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà” lójú Jèhófà. (1 Pétérù 2:19, 20) Kí ló lè mú kí èyí ṣẹlẹ̀?
12 Wọ́n ti fìyà jẹ àwọn kan nítorí pé wọ́n kọ̀ láti kópa nínú àwọn ààtò ìsìnkú tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. (Diutarónómì 14:1) Àwọn èèyàn ti sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí nítorí pé wọ́n tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà rere tí Jèhófà gbé kalẹ̀. (1 Pétérù 4:4) Àwọn èèyàn ti fi àṣìṣe pe àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ òbí ní “aláìbìkítà” tàbí “aṣeniléṣe” nítorí pé wọ́n sọ pé ìtọ́jú tí kò ní lílo ẹ̀jẹ̀ nínú làwọn fẹ́ fún ọmọ àwọn. (Ìṣe 15:29) Àwọn Kristẹni kan ti dẹni táwọn ẹbí àtàwọn aládùúgbò ta nù lẹ́gbẹ́ nítorí pé wọ́n di ìránṣẹ́ Jèhófà. (Mátíù 10:34-37) Gbogbo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń jìyà láìṣẹ̀, wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ táwọn wòlíì àti Jésù fúnra rẹ̀ fi lélẹ̀.—Mátíù 5:11, 12; Jákọ́bù 5:10; 1 Pétérù 2:21.
Fífara Dà Á Nígbà Tí Wọ́n Bá Ń Pẹ̀gàn Wa
13. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in nípa tẹ̀mí nígbà táwọn èèyàn bá ń pẹ̀gàn wa?
13 Nígbà táwọn èèyàn bá ń pẹ̀gàn wa nítorí ohun tá a gbà gbọ́, ìyẹn lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, bíi ti wòlíì Jeremáyà, ká sì máa rò pé a ò ní lè máa sin Ọlọ́run nìṣó. (Jeremáyà 20:7-9) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in nípa tẹ̀mí? Gbìyànjú láti fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn náà wò ó. Ojú aṣẹ́gun ló fi ń wo àwọn tó bá dúró ṣinṣin nígbà àdánwò, kì í kà wọ́n sẹ́ni tí a ṣẹ́gun. (Róòmù 8:37) Fojú inú wo àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láìka bí Èṣù ṣe ń tàbùkù wọn sí, ìyẹn àwọn bíi Ébẹ́lì, Jóòbù, Màríà ìyà Jésù, àtàwọn mìíràn tó jẹ́ olóòótọ́ láyé ìgbàanì, títí kan àwọn tá a jọ jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní. (Hébérù 11:35-37; 12:1) Ronú lórí ọ̀nà tí wọ́n gbà pa ìwà títọ́ wọn mọ́. Àwọn adúróṣinṣin tó pọ̀ rẹpẹtẹ yìí ń pè wá pé ká wá dara pọ̀ mọ́ àwọn láti di aṣẹ́gun nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.—1 Jòhánù 5:4.
14. Báwo ni àdúrà àtọkànwá ṣe lè fún wa lókun láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ olóòótọ́?
14 Bí ‘ìrònú tí ń gbéni lọ́kàn sókè bá di púpọ̀ nínú wa,’ a lè gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà, ó sì dájú pé yóò tù wá nínú yóò sì fún wa lókun. (Sáàmù 50:15; 94:19) Yóò fún wa ní ọgbọ́n tá a nílò láti kojú àdánwò náà, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti máa ronú nípa ọ̀ràn pàtàkì náà, ìyẹn ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, táwọn èèyàn ń tìtorí rẹ̀ kórìíra àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láìnídìí. (Jákọ́bù 1:5) Jèhófà sì tún lè fún wa ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Fílípì 4:6, 7) Ìbàlẹ̀ ọkàn tí Ọlọ́run ń fúnni yìí yóò mú ká lè fara balẹ̀ ká sì dúró gbọn-in, tá ò fi ní máa ṣiyèméjì tàbí ká bẹ̀rù nígbà tí wàhálà tó légbá kan bá dé. Jèhófà lè lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mẹ́sẹ̀ wa dúró ká lè fara da ohunkóhun tó bá fàyè gbà láti ṣẹlẹ̀ sí wa.—1 Kọ́ríńtì 10:13.
15. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa bínú nígbà tá a bá ń jìyà?
15 Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa bínú sí àwọn tó ń kórìíra wa láìnídìí? Ẹ rántí pé olórí elénìní wa ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. (Éfésù 6:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan mọ̀ọ́mọ̀ ń ṣenúnibíni sí wa, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń ṣàtakò sí àwọn èèyàn Ọlọ́run ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí àìmọ̀kan wọn tàbí kó jẹ́ pé àwọn ẹlòmíràn ló ń lò wọ́n. (Dáníẹ́lì 6:4-16; 1 Tímótì 1:12, 13) Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí “gbogbo onírúurú ènìyàn” ní àǹfààní láti ‘rí ìgbàlà kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.’ (1 Tímótì 2:4) Kódà, àwọn kan lára àwọn tó ń ṣàtakò sí wa tẹ́lẹ̀ ti di Kristẹni arákùnrin wa báyìí nítorí pé wọ́n ti rí i pé ìwà wa dára. (1 Pétérù 2:12) Láfikún sí i, a lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ Jósẹ́fù, ọmọ Jékọ́bù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù jìyà gan-an nítorí ohun táwọn ọbàkan rẹ̀ ṣe sí i, síbẹ̀ kò bá wọn ṣọ̀tá. Kí nìdí? Nítorí ó fòye mọ̀ pé Jèhófà lọ́wọ́ sí ọ̀ràn náà, pé òun ló mú kí ọ̀ràn náà rí bó ṣe rí kó lè mú ète Rẹ̀ ṣẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 45:4-8) Bákan náà ni Jèhófà lè fàyè gba ìyà èyíkéyìí tó lè jẹ wá láìnídìí kí ó lè já sí ìyìn orúkọ rẹ̀.—1 Pétérù 4:16.
16, 17. Kí nìdí tá ò fi ní láti dààmú púpọ̀ nípa ohun táwọn alátakò ń ṣe láti dí iṣẹ́ ìwàásù náà lọ́wọ́?
16 A ò ní láti máa dààmú púpọ̀ tó bá dà bíi pé àwọn alátakò ń kẹ́sẹ járí nínú ṣíṣe ìdíwọ́ fún ìlọsíwájú ìhìn rere náà. Jèhófà ti ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì báyìí nípasẹ̀ ìjẹ́rìí tí à ń ṣe kárí ayé, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra sì ń wọlé wá. (Hágáì 2:7) Kristi Jésù, Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà náà, sọ pé: “Àwọn àgùntàn mi ń fetí sí ohùn mi, mo sì mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi. Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun, . . . kò sì sí ẹnì kankan tí yóò já wọn gbà kúrò ní ọwọ́ mi.” (Jòhánù 10:27-29) Àwọn áńgẹ́lì mímọ́ tún ń kópa nínú iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí náà pẹ̀lú. (Mátíù 13:39, 41; Ìṣípayá 14:6, 7) Nítorí náà, kò sí ohun táwọn alátakò lè sọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí wọ́n lè ṣe tó lè dojú ète Ọlọ́run dé.—Aísáyà 54:17; Ìṣe 5:38, 39.
17 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ohun táwọn alátakò ń ṣe máa ń yí lé wọn lórí. Ní ìlú kan nílẹ̀ Áfíríkà, ọ̀pọ̀ irọ́ làwọn èèyàn ti tàn kálẹ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kódà wọ́n sọ pé olùjọsìn Èṣù ni wọ́n. Nítorí ìdí èyí, gbogbo ìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí bá délé Grace ni Grace máa ń sá lọ sí ẹ̀yìnkùlé, tá sì sá pa mọ́ títí tí wọ́n á fi lọ. Lọ́jọ́ kan, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ na ọ̀kan lára àwọn ìwé wa sókè, ó sì sọ fún gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ kà á nítorí pé ó máa mú kí wọ́n fi ẹ̀sìn wọn sílẹ̀. Èyí ló mú kí Grace fẹ́ mọ̀ nípa wọn. Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí tún padà wá, dípò tí ì bá fi sá pa mọ́, ńṣe ló bá wọn fọ̀rọ̀ wérọ̀ tó sì gba ẹ̀dà kan lára ìwé ọ̀hún. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, ó sì ṣe ìrìbọmi ní ọdún 1996. Grace wá ń lo àkókò rẹ̀ nísinsìnyí láti wá àwọn mìíràn táwọn èèyàn ti lè sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún.
Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Rẹ Lágbára Nísinsìnyí
18. Kí nìdí tó fi yẹ ká a fún ìgbàgbọ́ wa lókun kí àdánwò líle koko tó dé, báwo la sì ṣe lè ṣe èyí?
18 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìgbàkigbà ni Sátánì lè kórìíra wa láìnídìí, ó ṣe pàtàkì pé ká mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára nísinsìnyí. Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Ìròyìn kan tó wá láti orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti ń ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ohun kan tó hàn kedere ni pé: Kì í ṣòro fáwọn tí wọ́n ní àṣà tó dára nípa tẹ̀mí, tí wọ́n sì ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún òtítọ́ Bíbélì láti mú ìdúró wọn nígbà tí àdánwò bá dé. Ṣùgbọ́n àwọn tó jẹ́ pé nígbà tí ‘àkókò rọgbọ’ pàápàá, wọ́n máa ń pa ìpàdé jẹ́, wọn kì í jáde òde ẹ̀rí déédéé, wọ́n sì máa ń juwọ́ sílẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn kéékèèké, sábà máa ń ṣubú lábẹ́ ìdánwò ‘líle koko.’” (2 Tímótì 4:2) Tó o bá rí àwọn ibi tó ti yẹ kó o ṣàtúnṣe, tètè ṣe bẹ́ẹ̀ ní kíámọ́sá.—Sáàmù 119:60.
19. Kí ni ìwà títọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà táwọn èèyàn ń kórìíra wọn láìnídìí mú jáde?
19 Ìdúróṣinṣin àwọn olùjọsìn tòótọ́ nígbà tí wọ́n bá ń jìyà nítorí pé Sátánì kórìíra wọn jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn dájú pé Jèhófà ní ẹ̀tọ́ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ ọba aláṣẹ, pé ó yẹ kó máa lò ipò náà àti pé ó ń lò ó lọ́nà tó bá òdodo mu. Ìṣòtítọ́ wọn ń mú inú Ọlọ́run dùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn lè pẹ̀gàn wọn, àmọ́ ẹni tí iyì rẹ̀ ga ju ayé òun ọ̀run lọ ni ‘ojú kò tì pé ká máa pè é ní Ọlọ́run wọn.’ Láìsí àní-àní, ní ti gbogbo irú àwọn olóòótọ́ bẹ́ẹ̀, a lè sọ pé: “Ayé kò sì yẹ wọ́n.”—Hébérù 11:16, 38.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ náà “kórìíra” ní ìtumọ̀ bíi mélòó kan tó yàtọ̀ síra wọn nínú Ìwé Mímọ́. Ní àwọn àyíká ọ̀rọ̀ kan, ohun tó wulẹ̀ túmọ̀ sí ni láti nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan díẹ̀. (Diutarónómì 21:15, 16) Ọ̀rọ̀ náà “kórìíra” tún lè túmọ̀ sí kéèyàn máà fẹ́ràn ohun kan rárá, àmọ́ kó máà ní èrò àtiṣe ìpalára fún nǹkan ọ̀hún, kàkà bẹ́ẹ̀ kó máa yẹra fún un nítorí pé kò fẹ́ máa rí i. Àmọ́, ọ̀rọ̀ náà “kórìíra” tún lè túmọ̀ sí kéèyàn máa bínú ẹnì kan ṣáá, kéèyàn sì fẹ́ kí ìyà máa jẹ onítọ̀hún. Èyí gan-an ni apá tá a óò jíròrò lára ọ̀rọ̀ náà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ló mú káwọn èèyàn máa kórìíra àwọn olùjọsìn tòótọ́ láìnídìí?
• Báwo ni Sátánì ṣe lo ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nígbà tó ń gbìyànjú láti ba ìwà títọ́ Jóòbù àti ti Jésù jẹ́?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń fún wa lókun láti dúró gbọn-in nígbà tá a bá ń dojú kọ ìkórìíra látọ̀dọ̀ Sátánì?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Wọ́n Fòye Mọ Ohun Tó Fà Á
Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ukraine, níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà fún ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún sọ pé: “Ipò táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà kì í ṣe èyí tó yẹ ká máa fojú ìwà táwọn èèyàn ń hù sí wa lásán wò. . . . Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba wọ̀nyẹn wulẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ wọn ni. Nígbà tí ìjọba bá yí padà, àwọn òṣìṣẹ́ wọ̀nyẹn náà á yí ìṣe wọn padà, àmọ́ àwa kì í yí padà. A mọ̀ pé Bíbélì ti sọ ohun tó ń fa ìṣòro wa gan-an.
“A ò ka ara wa sí aláìmọwọ́mẹsẹ̀ táwọn ìkà èèyàn wulẹ̀ ń fìyà jẹ. Ohun tó ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á ni òye kedere tá a ní nípa ọ̀ràn tó ṣẹlẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì, ìyẹn ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní láti ṣàkóso. . . . Ohun tá à ń jà fún kì í ṣe ọ̀ràn tó kan kìkì ire ti ẹ̀dá ènìyàn nìkan, àmọ́ ó tún kan ire Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run pẹ̀lú. A ní òye tó ga nípa ohun tó wà nídìí ọ̀ràn náà gan-an. Èyí ló fún wa lókun tó sì jẹ́ ká lè pa ìwà títọ́ wa mọ́ kódà nígbà tá a wà nínú ipò tó burú jáì.”
[Àwòrán]
Victor Popovych, tí wọ́n mú ní ọdún 1970
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ta ló wà lẹ́yìn ẹ̀gàn tí wọ́n mú bá Jésù?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jóòbù, Màríà, àtàwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní, irú bíi Stanley Jones gbárùkù ti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ