Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
A San Èrè fún Ìgbàgbọ́ Àwọn Òbí
FÚN àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ayọ̀ abara bíńtín máa ń bá ìbí ọmọkùnrin rìn. Ó túmọ̀ sí pé, ìlà ìran yóò máa bá a nìṣó, àti pé, ilẹ̀ tí a jogún yóò ṣì jẹ́ ti ìdílé. Ṣùgbọ́n, ní nǹkan bí ọdún 1593 ṣááju Sànmánì Tiwa, bíbí ọmọkùnrin lè ti dà bíi ègún ju ìbùkún lọ fún àwọn Hébérù. Èé ṣe? Nítorí Fáráò ti Íjíbítì, tí ó ń bẹ̀rù bí àwọn Júù ṣe ń yára gbèrú ní ìpínlẹ̀ tí ó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀, ti pàṣẹ pé kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin wọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí.—Ẹ́kísódù 1:12, 15-22.
Ní àkókò ìgbìdánwò burúkú ti ìpalápalù ẹ̀yà yí ni Ámúrámù àti Jókébédì, tọkọtaya Hébérù kan, bí ọmọkùnrin jòjòló rírẹwà kan. Ó rọrùn láti finú wòye bí ìbẹ̀rù ti lè bo ayọ̀ wọn mọ́lẹ̀ tó nígbà tí wọ́n rántí àṣẹ Fáráò. Síbẹ̀, bí Ámúrámù àti Jókébédì ṣe wo ọmọdékùnrin wọn kékeré lójú, wọ́n pinnu lọ́nà tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in láti má ṣe pa á tì, láìka ohun tí yóò yọrí sí sí.—Ẹ́kísódù 2:1, 2; 6:20.
Gbígbégbèésẹ̀ Nínú Ìgbàgbọ́
Fún oṣù mẹ́ta, Ámúrámù àti Jókébédì pa ọmọ wọn mọ́. (Ẹ́kísódù 2:2) Ṣùgbọ́n, èyí léwu, níwọ̀n bí àwọn Hébérù àti àwọn ará Íjíbítì ti ń gbé nítòsí ara wọn. Ó ṣeé ṣe kí a ṣekú pa ẹnikẹ́ni tí a bá gbá mú tí ń dojú àṣẹ Fáráò dé—ọmọkùnrin jòjòló náà yóò sì kú pẹ̀lú. Nígbà náà, kí ni àwọn òbí tí wọ́n mọṣẹ́ níṣẹ́ wọ̀nyí lè ṣe láti dá ẹ̀mí wọn àti ti ọmọkùnrin wọn sí?
Jókébédì kó ìtí òrépèté jọ. Òrépèté jẹ́ koríko tí ó yi, tí ó fara jọ ọparun, ó sì ní pòròpórò onígun mẹ́ta, tí ó nípọn tó ìka ọwọ́. Ó lè ga tó mítà mẹ́fà. Àwọn ará Íjíbítì lo igi yìí láti fi ṣe bébà, ẹní, ìgbòkùn, sálúbàtà, àti ọkọ̀ ojú omi fífúyẹ́.
Jókébédì fi pòròpórò náà ṣe àpótí tí ó fẹ̀ tó láti gba ọmọ rẹ̀ jòjòló. Lẹ́yìn náà, ó lo ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì àti ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ láti fi rẹ́ àpótí náà pọ̀, kí omi má baà lè wọ̀ ọ́. Lẹ́yìn náà, Jókébédì gbé ọmọ rẹ̀ sínú ọkọ̀ náà, ó sì rọra gbé e sáàárín esùsú ní bèbè Odò Náílì.—Ẹ́kísódù 2:3.
A Rí Ọmọ Ọwọ́ Náà
Míríámù, ọmọbìnrin Jókébédì, lúgọ nítòsí, láti rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e. Kò pẹ́ kò jìnnà, ọmọbìnrin Fáráò wá sí odò Náílì láti wẹ̀.a Bóyá Jókébédì mọ̀ pé ọmọ́ ọba náà máa ń wá sí apá Náílì yí déédéé, tí ó sì mọ̀ọ́mọ̀ gbé àpótí náà sí ibi tí yóò ti tètè rí i. Bí ó ti wù kí ó rí, kò pẹ́ tí ọmọbìnrin Fáráò fi tajú kán rí àpótí náà, tí a rọra gbé sáàárín esùsú, ó sì ké sí ọ̀kan lára àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ láti lọ gbé e wá. Nígbà tí ó rí ọmọ tí ń ké nínú rẹ̀, a ru ìyọ́nú rẹ̀ sókè. Ó fura pé ọmọ Hébérù ni èyí ní láti jẹ́. Síbẹ̀, báwo ni òun yóò ṣe jẹ́ kí a ṣekú pa irú ọmọ rírẹwà bí èyí? Yàtọ̀ sí inú rere ẹ̀dá, ìgbàgbọ́ lílókìkí àwọn ará Íjíbítì pé, gbígbanisọ́run sinmi lórí àkọsílẹ̀ àwọn ìṣe onínúure tí ènìyàn ṣe nígbà tí ó ń bẹ láyé, lè ti nípa lórí ọmọbìnrin Fáráò.b—Ẹ́kísódù 2:5, 6.
Míríámù, tí ń wòran láti òkèèrè, tọ ọmọbìnrin Fáráò lọ. Ó béèrè pé: “Ṣé kí n lọ bá ọ dìídì pe obìnrin olùṣètọ́jú kan láti inú àwọn obìnrin Hébérù kí ó lè máa bá ọ ṣètọ́jú ọmọ náà?” Ọmọ ọba náà dáhùn pé: “Lọ!” Míríámù sáré lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀. Wéré, Jókébédì ti dé iwájú ọmọbìnrin Fáráò. Ọmọ ọba náà wí fún un pé: “Gbé ọmọ yìí dání lọ, kí o sì máa bá mi ṣètọ́jú rẹ̀, èmi fúnra mi yóò sì fún ọ ní owó ọ̀yà rẹ.” Ó ti lè ṣeé ṣe pé, ọmọbìnrin Fáráò ti mọ̀ kí ó tó di ìsinsìnyí pé, Jókébédì ni ìyá ọmọ náà.—Ẹ́kísódù 2:7-9, NW.
Jókébédì tọ́jú ọmọ rẹ̀ títí dìgbà tí ó fi já ọmú lẹ́nu rẹ̀.c Èyí fún un ní ọ̀pọ̀ àǹfààní ṣíṣeyebíye láti kọ́ ọ nípa Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà. Nígbà tí ó ṣe, Jókébédì dá ọmọ náà pa dà fún ọmọbìnrin Fáráò, tí ó sọ ọmọdékùnrin náà ní Mósè, tí ó túmọ̀ sí, “ẹni tí a yọ nínú omi.”—Ẹ́kísódù 2:10.
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n fún Wa
Ámúrámù àti Jókébédì lo àǹfààní kúkúrú tí wọ́n ní dáradára láti fi kọ́ ọmọ wọn ní àwọn ìlànà ìjọsìn mímọ́ gaara. Ó yẹ kí àwọn òbí lónìí ṣe ohun kan náà. Ní tòótọ́, ó di dandan fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Sátánì Èṣù “ń rìn káàkiri bíi kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pa ẹnì kan jẹ.” (Pétérù Kíní 5:8) Yóò fẹ́ láti fi àwọn èwe tí ó ṣeyebíye—lọ́kùnrin lóbìnrin—tí wọ́n ní ìrètí dídi ìránṣẹ́ dáradára fún Jèhófà, ṣe ìjẹ. Pé wọ́n jẹ́ ọmọdé kò ní kí ó ṣàánú wọn! Lójú ìwòye èyí, àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ wọn jòjòló, láti bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà.—Òwe 22:6; Tímótì Kejì 3:14, 15.
Ní Hébérù 11:23, a ṣàkọsílẹ̀ ìsapá Ámúrámù àti Jókébédì láti tọ́jú ọmọ wọn jòjòló pa mọ́, ní oṣù mẹ́ta rẹ̀ àkọ́kọ́ láyé, gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́. Àwọn òbí méjèèjì wọ̀nyí, tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, fi hàn pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé agbára ìgbanilà Jèhófà, nípa kíkọ̀ láti pa ọmọ wọn tì, a sì bù kún wọn nítorí èyí. Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ fi hàn pé, a rọ̀ mọ́ àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà pẹ́kípẹ́kí, ní níní ìgbọ́kànlé pé, ohunkóhun tí Jèhófà bá yọ̀ǹda fún láti wá sórí wa, yóò ṣiṣẹ́ fún ire àti ayọ̀ wa ayérayé nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—Róòmù 8:28.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ará Íjíbítì jọ́sìn odò Náílì gẹ́gẹ́ bí ọlọ́run tí ń fúnni lọ́mọ. Wọ́n gbà gbọ́ pé omi rẹ̀ ní agbára láti jẹ́ kí a rí ọmọ bí àti láti mú ẹ̀mí gùn pàápàá.
b Àwọn ará Íjíbítì gbà gbọ́ pé, nígbà ikú, ẹ̀mí ènìyàn yóò ka àkàsórí níwájú Osiris, irú àmúdánilójú bíi, “Èmi kò pọ́n ènìyàn kankan lójú rí,” “Èmi kò já ọmú gbà lẹ́nu ọmọ tí ń mọmú rí,” àti “Èmi ti fún ẹni tí ebi ń pa lóúnjẹ, mo sì ti fún ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ ní omi mu.”
c Ní ìgbà láéláé, àwọn ọmọ máa ń mọmú fún àkókò gígùn ju bí ó ṣe wọ́pọ̀ lónìí lọ. Ó ṣeé ṣe kí Sámúẹ́lì ti tó ọmọ ọdún mẹ́ta, ó kéré tán, kí a tó gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, Aísíìkì sì jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún márùn-ún.