‘Ẹ̀mí Mímọ́ Darí Wọn’
“A kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”—2 PÉT. 1:21.
ÀWỌN OHUN TÓ YẸ KÁ RONÚ LÉ LÓRÍ
Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe jẹ́ kí àwọn tó kọ Bíbélì mọ ohun tí wọ́n máa kọ sílẹ̀?
Kí ló fi hàn pé Bíbélì jẹ́ ìwé tí Ọlọ́run mí sí?
Kí lo lè máa ṣe lójoojúmọ́ kó o lè máa bá a nìṣó láti mọrírì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
1. Kí nìdí tá a fi nílò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí?
IBO la ti wá? Kí nìdí tá a fi wà láyé? Ibo là ń lọ? Kí nìdí táyé fi rí bó ṣe rí yìí? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú? Àwọn ìbéèrè tí àwọn èèyàn jákèjádò ayé máa ń béèrè nìyí. Báwo ni à bá ṣe mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè pàtàkì míì bí kò bá sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí? Ká ní kò sí Ìwé Mímọ́ ni, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa nìkan ni à bá máa fi ṣàríkọ́gbọ́n. Tó bá jẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa la fi ń ṣàríkọ́gbọ́n, ǹjẹ́ a ó lè ní irú èrò tí onísáàmù náà ní nípa “òfin Jèhófà”?—Ka Sáàmù 19:7.
2. Kí ló máa jẹ́ ká lè máa fi ìmọrírì hàn fún Bíbélì tó jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?
2 Àmọ́, ohun tó bani nínú jẹ́ ni pé àwọn kan ti jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ní fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì di tútù. (Fi wé Ìṣípayá 2:4.) Wọn kò tọ ipa ọ̀nà tó mú inú Jèhófà dùn mọ́. (Aísá. 30:21) Kò yẹ kí irú èyí ṣẹlẹ̀ sí wa. Kò yẹ ká jẹ́ kí ìmọrírì tá a ní fún Bíbélì àti àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì dín kù, bó sì ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn. Ẹ̀bùn pàtàkì látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ ni Bíbélì. (Ják. 1:17) Kí ló máa jẹ́ ká lè mú kí ìmọrírì tá a ní fún “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” jinlẹ̀ sí i? Ohun pàtàkì kan tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká ronú nípa bí Ọlọ́run ṣe darí àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́. Èyí gba pé ká máa rántí àwọn kan lára àwọn ẹ̀rí pelemọ tó fi hàn pé Ọlọ́run ló mí sí àwọn tó kọ ọ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ kó máa wù wá láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ ká sì máa fi àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò.—Héb. 4:12.
BÁWO NI “Ẹ̀MÍ MÍMỌ́” ṢE “DARÍ WỌN”?
3. Báwo ni ‘ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí’ àwọn wòlíì àtàwọn míì tó kọ Bíbélì?
3 Ọlọ́run lo àwọn ogójì [40] ọkùnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti kọ Bíbélì, ó sì gbà wọ́n ní nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ ọdún ó lé mẹ́wàá [1,610], bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọdún 98 Sànmánì Kristẹni. Wòlíì ni àwọn kan lára wọn, ‘ẹ̀mí mímọ́ ló sì darí’ wọn. (Ka 2 Pétérù 1:20, 21.) Ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí “darí” nínú ẹsẹ Bíbélì yìí wá látinú èdè Gíríìkì. Ó sì túmọ̀ sí láti súnni ṣe nǹkan, láti gbé ẹnì kan, tàbí kí ẹnì kan jẹ́ kí a ṣí òun nípò pa dà. Ìwé Ìṣe 27:15 lo ọ̀rọ̀ kan náà láti ṣàpèjúwe ọkọ̀ ojú omi kan tí ẹ̀fúùfù sún tàbí tó gbá lọ sí apá ibòmíì. Torí náà, nígbà tí Bíbélì bá sọ pé ‘ẹ̀mí mímọ́ darí’ àwọn wòlíì àti àwọn èèyàn tó kọ Bíbélì, ohun tó túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run bá wọn sọ̀rọ̀, ó fi èrò rẹ̀ sí wọn lọ́kàn, ó sì fi ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀, tàbí ẹ̀mí mímọ́ darí wọn. Nípa báyìí, kì í ṣe èrò wọn ni wọ́n kọ sílẹ̀, bí kò ṣe èrò Ọlọ́run. Ìgbà míì tiẹ̀ wà tí àwọn wòlíì tàbí àwọn míì tí Ọlọ́run mí sí láti kọ Bíbélì kì í mọ ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ohun tí wọ́n kọ. (Dán. 12:8, 9) Torí náà, òótọ́ ni pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí” kò sì sí èrò èèyàn nínú rẹ̀.—2 Tím. 3:16.
4-6. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà mú kí àwọn tó kọ Bíbélì mọ ohun tó yẹ kí wọ́n kọ? Ṣe àpèjúwe.
4 Àmọ́, báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe jẹ́ kí àwọn tó kọ Bíbélì mọ ohun tí wọ́n máa kọ sílẹ̀? Ṣé bí wọ́n ṣe máa kọ ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ gẹ́lẹ́ ni wọ́n ṣe rí i gbà ni, àbí èrò tí wọ́n máa kọ sílẹ̀ lọ́rọ̀ ara wọn ni Ọlọ́run máa ń fi sí wọn lọ́kàn? Ronú nípa ọkùnrin oníṣòwò kan tó fẹ́ kọ lẹ́tà. Bó bá jẹ́ pé ó ní bó ṣe fẹ́ kọ lẹ́tà náà, ó lè kọ ọ́ fúnra rẹ̀ tàbí kó pè é ní àpèkọ fún akọ̀wé rẹ̀. Akọ̀wé á lọ tẹ lẹ́tà náà, ọkùnrin oníṣòwò náà á sì buwọ́ lù ú. Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ńṣe ló kàn máa sọ kókó pàtàkì tó fẹ́ kí akọ̀wé yẹn kọ lẹ́tà lé lórí, tí akọ̀wé náà á sì pinnu bó ṣe máa kọ ọ́ tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tó máa lò. Lẹ́yìn náà, ọkùnrin oníṣòwò yẹn lè wá ṣàyẹ̀wò ohun tí akọ̀wé náà kọ, á sì ní kó lọ ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ. Ní òpin rẹ̀, ọ̀gá náà á wá buwọ́ lu lẹ́tà yẹn, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ẹni tó kọ lẹ́tà náà sí á sì gbà pé ìsọfúnni náà ti wá.
5 Bákan náà, àwọn apá kan wà nínú Bíbélì tó jẹ́ pé “ìka Ọlọ́run” fúnra rẹ̀ ló kọ ọ́. (Ẹ́kís. 31:18) Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ńṣe ni Jèhófà máa pe ọ̀rọ̀ náà gan-an tó fẹ́ kí wọ́n kọ sílẹ̀ ní àpèkọ. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Ẹ́kísódù 34:27 sọ pé: “Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè pé: ‘Kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀ fún ara rẹ, nítorí ní ìbámú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni mo bá ìwọ àti Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú.’” Bákan náà, Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà pé: “Kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí èmi yóò bá ọ sọ fún ara rẹ sínú ìwé kan.”—Jer. 30:2.
6 Àmọ́ ṣá o, lọ́pọ̀ ìgbà dípò kí Jèhófà sọ ohun tó fẹ́ kí wọ́n kọ, ńṣe ló máa ń fi èrò kan sí ọkàn àwọn tó kọ Bíbélì lọ́nà ìyanu, á sì gbà wọ́n láyè láti lo ọ̀rọ̀ ara wọn láti kọ ọ́ sílẹ̀. Oníwàásù 12:10 sọ pé: “Akónijọ wá ọ̀nà àtirí àwọn ọ̀rọ̀ dídùn àti àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́.” Lúùkù tó kọ ọ̀kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere ‘tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye, láti kọ̀wé wọn ní ìṣètò tí ó bọ́gbọ́n mu.’ (Lúùkù 1:3) Ẹ̀mí Ọlọ́run rí i dájú pé àìpé àwọn èèyàn kò kó àbààwọ́n bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
7. Báwo ni ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe hàn gbangba nínú bó ṣe lo àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì?
7 Ọgbọ́n gíga tí Ọlọ́run ní hàn gbangba nínú bó ṣe lo àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì. Ọ̀rọ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn mọ ohun tí ẹnì kan fẹ́ sọ, ó sì tún máa ń ṣàgbéyọ ìmọ̀lára ẹni náà. Tó bá jẹ́ pé àwọn ańgẹ́lì ni Jèhófà lò láti kọ Bíbélì ńkọ́? Ǹjẹ́ wọ́n á lè kọ bí nǹkan ṣe sábà máa ń rí lára àwa èèyàn, irú bí ìbẹ̀rù, ìbànújẹ́ àti ìjákulẹ̀? Ọlọ́run gba àwọn ọkùnrin aláìpé láyè pé kí wọ́n lo ọ̀rọ̀ ara wọn láti ṣàlàyé èrò tí ẹ̀mí mímọ́ gbé wá sí wọn lọ́kàn, nípa bẹ́ẹ̀ ó mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin, kó sì fani mọ́ra.
ÀWỌN Ẹ̀RÍ TÓ FI HÀN PÉ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN NI BÍBÉLÌ
8. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Bíbélì yàtọ̀ sí àwọn ìwé ẹ̀sìn yòókù?
8 Ẹ̀rí púpọ̀ jaburata ló wà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, ó sì jẹ́ ìwé tó ní ìmísí Ọlọ́run. Kò sí ìwé ìsìn mìíràn tó jẹ́ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run bíi Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù ní ọ̀pọ̀ ìwé tí wọ́n kọ, lára irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ ni ìwé orin ìsìn tí wọ́n ń pè ní Vedic, àkójọpọ̀ àwọn àlàyé tó dá lórí àwọn orin ààtò ẹ̀sìn náà, àwọn àlàyé nípa ìmọ̀ ọgbọ́n orí tí wọ́n pè ní Upanishads àti àwọn ewì àtẹnudẹ́nu tí wọ́n ń pè ní Ramayana àti Mahabharata. Ìwé mìíràn tó ń jẹ́ Bhagavad Gita, ní àwọn ìtọ́ni nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa hùwà, ó sì jẹ́ apá kan ìwé Mahabharata. Àwọn ẹlẹ́sìn Búdà náà ní ìwé tí wọ́n ń pè ní Tipitaka (Apá Mẹ́ta). Apá àkọ́kọ́ dá lórí àwọn òfin àti ìlànà tí àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tó jẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. Apá kejì dá lórí ẹ̀kọ́ ìsìn Búdà. Apá kẹta dá lórí àkọsílẹ̀ àwọn ìwàásù tí Búdà fúnra rẹ̀ ṣe. Búdà kò sọ pé òun jẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ nǹkan díẹ̀ ló sọ nípa Ọlọ́run. Ìwé àwọn ẹlẹ́sìn Confucius jẹ́ àkópọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù, ọ̀nà tí wọ́n á máa gbà pidán àtàwọn orin. Lóòótọ́, ìwé mímọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí kọ́ni pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà, ó sì sọ pé ó mọ ohun gbogbo àti pé ó máa ń mọ ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀, àmọ́ kò sí ibì kankan tó ti sọ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, èyí tó fara hàn ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà nínú Bíbélì.
9, 10. Kí la lè rí kọ́ nípa Ọlọ́run látinú Bíbélì?
9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun díẹ̀ ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìwé ẹ̀sìn sọ nípa Ọlọ́run, tí wọ́n bá tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ rárá, Bíbélì ní tiẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn ohun tó ń ṣe. Ó jẹ́ ká mọ onírúurú ànímọ́ tó ní. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ alágbára gbogbo, ọlọ́gbọ́n àti onídàájọ́ òdodo, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa. (Ka Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 4:19.) Síwájú sí i, Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Lọ́rọ̀ kan ṣá, bí Bíbélì ṣe wà fún gbogbo èèyàn fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Àwọn onímọ̀ èdè sọ pé nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin dín ọ̀ọ́dúnrún [6,700] èdè làwọn èèyàn ń sọ lóde òní. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún [100] lára àwọn èdè yẹn ló jẹ́ pé tá a bá dá gbogbo èèyàn tó wà láyé sí ọ̀nà mẹ́wàá, ìdá mẹ́sàn-án nínú wọn ló ń sọ àwọn èdè náà. Wọ́n sì ti túmọ̀ odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ sí egbèjìlá [2,400] èdè. Èyí tó fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹnì kankan lórí ilẹ̀ ayé tí kò lè rí, ó kéré tán, apá kan lára Bíbélì kà ní èdè rẹ̀.
10 Jésù sọ pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi náà sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.” (Jòh. 5:17) ‘Láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, Jèhófà ni Ọlọ́run.’ Torí náà, ronú nípa àwọn ohun tó ti gbé ṣe! (Sm. 90:2) Bíbélì nìkan ló jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe, àwọn ohun tó ń ṣe lọ́wọ́ àtàwọn ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Ìwé Mímọ́ tún kọ́ wa láwọn ohun tó ń mú inú rẹ̀ dùn àtàwọn ohun tó kórìíra, ó sì sọ bá a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run. (Ják. 4:8) Ẹ má ṣe jẹ́ ká gba ìlépa àwọn nǹkan tara tàbí àníyàn láyè láti mú wa jìnnà sí Ọlọ́run.
11. Ọgbọ́n tí kò láfiwé tó sì ṣeé gbára lé wo la rí nínú Bíbélì?
11 Ọgbọ́n tí kò láfiwé tó sì ṣeé gbára lé tó wà nínú Bíbélì tún fi hàn pé Orísun kan tó ju ẹ̀dá èèyàn lọ fíìfíì ni ìwé náà ti wá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ta ni ó ti wá mọ èrò inú Jèhófà, kí ó lè fún un ní ìtọ́ni?” (1 Kọ́r. 2:16) Ẹsẹ Bíbélì yẹn dá lórí ohun tí wòlíì Aísáyà béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀, ó ní: “Ta ni ó ti wọn ẹ̀mí Jèhófà, ta sì ni, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tí ń gbà á nímọ̀ràn, tí ó lè mú kí ó mọ ohunkóhun?” (Aísá. 40:13) Kò sẹ́ni náà. Abájọ tó fi jẹ́ pé tá a bá ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì tó dá lórí ìgbéyàwó, ọmọ títọ́, eré ìnàjú, ẹgbẹ́ kíkó, ṣíṣiṣẹ́ kára, jíjẹ́ olóòótọ́ àti bó ṣe yẹ ká máa hùwà sílò, a máa rí àbájáde tó kàmàmà! Kò ṣẹlẹ̀ rí pé kéèyàn rí ìmọ̀ràn burúkú nínú Bíbélì. Àmọ́, ọgbọ́n àwọn èèyàn kò pọ̀ tó débi tí ìmọ̀ràn wọn á fi máa gbéṣẹ́ nígbà gbogbo. (Jer 10:23) Ìgbà gbogbo làwọn èèyàn máa ń tún àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n ń fúnni ṣe bí wọ́n bá ti rí i pé àwọn ìmọ̀ràn táwọn ti mú wá tẹ́lẹ̀ kò gbéṣẹ́ mọ́. Bíbélì sọ pé: ‘Bí èémí àmíjáde ni ìrònú àwọn ènìyàn jẹ́.’—Sm. 94:11.
12. Kí làwọn èèyàn ti ń ṣe láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá kí wọ́n lè pa Bíbélì run?
12 Ẹ̀rí míì tó fi hàn pé Ọlọ́run òtítọ́ ni Òǹṣèwé Bíbélì ni ohun tí ìtàn fi hàn nípa ìsapá àwọn èèyàn láti pa Bíbélì run. Lọ́dún 168 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ọba Síríà náà Áńtíókọ́sì Kẹrin, pàṣẹ pé kí àwọn èèyàn wá gbogbo àwọn ìwé Òfin tó ní ìmísí kàn kí wọ́n sì dáná sun wọ́n. Lọ́dún 303 Sànmánì Kristẹni, Olú Ọba Róòmù Diocletian pàṣẹ pé kí wọ́n wó ilé ìpàdé àwọn Kristẹni, kí wọ́n sì dáná sun àwọn Ìwé Mímọ́ wọn. Ọdún mẹ́wàá gbáko ni wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ibi yìí. Lẹ́yìn ọ̀rúndún kọkànlá, àwọn póòpù ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti dá iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì sí onírúurú èdè dúró, torí pé wọn kò fẹ́ kí àwọn èèyàn ní ìmọ̀ Bíbélì. Láìka gbogbo ohun tí Sátánì àtàwọn aṣojú rẹ̀ ti ṣe yìí sí, Bíbélì ṣì wà títí di àkókò yìí. Jèhófà kò gba ẹnikẹ́ni láyè láti pa ẹ̀bùn tó fún aráyé yìí run.
Ẹ̀RÍ TÓ MÚ KÍ Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN GBA BÍBÉLÌ GBỌ́
13. Àwọn ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Bíbélì jẹ́ ìwé tí Ọlọ́run mí sí?
13 Àwọn ẹ̀rí míì ṣì wà tó fi hàn pé Bíbélì jẹ́ ìwé tí Ọlọ́run mí sí, irú bí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣe bára mu, bí ohun tó sọ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe péye, bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ní ìmúṣẹ, bí kò ṣe fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, bó ṣe máa ń yí ìgbésí ayé èèyàn pa dà, bí àwọn ìtàn inú rẹ̀ ṣe jóòótọ́ àti bó ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí lọ́nà tó tẹ́ni lọ́rùn. Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó mú kí àwọn kan gbà pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá.
14-16. (a) Kí ló mú kí ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí, Híńdù àti onígbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀, gbà pé Bíbélì ní ìmísí Ọlọ́run? (b) Ẹ̀rí tó fi hàn pé Bíbélì ní ìmísí Ọlọ́run wo lo fẹ́ràn láti máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
14 Ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí ni Anwara tó ń gbé orílẹ̀-èdè kan ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Nígbà tó lọ gbé ní Amẹ́ríkà ti Àríwá fún ìgbà díẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sí ilé rẹ̀. Anwar sọ pé: “Nígbà yẹn, mo ní èrò tí kò tọ́ nípa ẹ̀sìn Kristẹni torí àwọn Ogun Ìsìn àti bí wọ́n ṣe máa ń ṣe ìwádìí kí wọ́n lè gbógun ti àwọn tí kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì. Àmọ́ torí pé mo fẹ́ràn láti máa tọpinpin, mo gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Kò pẹ́ tí Anwar fi pa dà sí ìlú rẹ̀, kò sì rí àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ó kó lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù, ó sì pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó wá sọ pé: “Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ ṣe ní ìmúṣẹ, bí àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ ṣe bára mu, bí Bíbélì kò ṣe ta kora àti ìfẹ́ tí àwọn olùjọ́sìn Jèhófà ní sí ara wọn mú kó dá mi lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.” Anwar ṣe ìrìbọmi lọ́dún 1998.
15 Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] ni Asha. Inú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn Híńdù ni wọ́n bí i sí. Ó sọ pé: “Ìgbà tí mo bá lọ sí tẹ́ńpìlì tàbí tí mo bá ní ìṣòro nìkan ni mo máa ń gbàdúrà, àmọ́ mi ò kì í rántí Ọlọ́run nígbà tí nǹkan bá ń lọ dáadáa fún mi.” Ó tún sọ pé: “Àmọ́ ìgbésí ayé mi yí pa dà pátápátá nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù fún mi.” Asha kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì wá mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rẹ́ rẹ̀. Kí ló jẹ́ kó gbà pé Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni Bíbélì? Ó ṣàlàyé pé: “Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè tí mo ní. Ó jẹ́ kí n ní ìgbàgbọ́ láìjẹ́ pé mo rí Ọlọ́run, ìyẹn ni pé, láìjẹ́ pé mo lọ forí balẹ̀ fún ère nínú tẹ́ńpìlì.”
16 Inú ìsìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Paula dàgbà, àmọ́ nígbà tó bàlágà, ó di onígbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀. Lẹ́yìn náà, nǹkan kan wá ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé: “Mo pàdé ọ̀rẹ́ mi ọkùnrin kan tí mi ò rí fún ọ̀pọ̀ oṣù. Ìyẹn jẹ́ ní àkókò kan tí àwọn ọ̀dọ́ kan ń pe ara wọn ní abẹ́gbẹ́yodì. Nígbà tí mo rí bó ti ṣe yí pa dà, tó mọ́ tónítóní, tó sì láyọ̀, mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘Kí ló ṣe ẹ́, ibo lo wà látọjọ́ yìí?’ Ó sọ pé òun ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún mi.” Bí ẹni tó ti fìgbà kan rí jẹ́ onígbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀ yìí ṣe rí bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì ṣe lágbára tó láti yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà, mú kí òun náà nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó sì gbà pé ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí.
“Ọ̀RỌ̀ RẸ JẸ́ FÌTÍLÀ FÚN ẸSẸ̀ MI”
17. Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ tó o sì ń ṣàṣàrò lórí rẹ̀?
17 Bíbélì jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu kan tí Jèhófà pèsè nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti máa kà á lójoojúmọ́, ìfẹ́ tó o ní fún un àti fún Ẹni tó ṣe é á sì túbọ̀ jinlẹ̀. (Sm. 1:1, 2) Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í kà á, rí i dájú pé o gbàdúrà, kó o béèrè pé kí Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ darí ìrònú rẹ. (Lúùkù 11:13) Èrò Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì, torí náà bó o ṣe ń ṣàṣàrò lórí ohun tí Bíbélì sọ, ńṣe lò ń mú kí ìrònú rẹ bá ti Ọlọ́run mu.
18. Kí nìdí tó o fi fẹ́ máa bá a nìṣó láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì?
18 Bí ìmọ̀ pípéye tó o ní nípa òtítọ́ ṣe ń pọ̀ sí i, máa gbé ìgbé ayé rẹ lọ́nà tó bá ohun tí o kọ́ mu. (Ka Sáàmù 119:105.) Máa wo inú Ìwé Mímọ́ bó o ṣe máa ń wo dígí. Tó o bá sì rí i pé ó yẹ kó o ṣe àtúnṣe, rí i dájú pé o ṣe bẹ́ẹ̀. (Ják. 1:23-25) Máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bí idà láti fi gbèjà ara rẹ, kó o sì fi gé àwọn ẹ̀kọ́ èké kúrò lọ́kàn àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn tútù. (Éfé. 6:17) Bó o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, máa kún fún ọpẹ́ pé òótọ́ ni ‘ẹ̀mí mímọ́ darí’ àwọn wòlíì àtàwọn ọkùnrin tí Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ìfẹ́ tó o ní fún Ẹni tó ṣe é a sì túbọ̀ jinlẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọ̀dọ̀ ẹni tó bá buwọ́ lu lẹ́tà la máa ń gbà pé lẹ́tà náà ti wá