Ẹ̀KỌ́ 04
Ta Ni Ọlọ́run?
Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń sin oríṣiríṣi ọlọ́run tàbí òrìṣà. Àmọ́, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run kan tó “tóbi ju gbogbo àwọn ọlọ́run míì lọ.” (2 Kíróníkà 2:5) Ta ni Ọlọ́run yẹn? Kí ló mú kó ju gbogbo àwọn ọlọ́run tó kù táwọn èèyàn ń jọ́sìn lọ? Nínú ẹ̀kọ́ yìí, wàá kọ́ ohun tí Ọlọ́run yìí fẹ́ kó o mọ̀ nípa òun.
1. Kí ni orúkọ Ọlọ́run, báwo la sì ṣe mọ̀ pé ó fẹ́ ká mọ orúkọ náà?
Ọlọ́run sọ orúkọ ara ẹ̀ fún wa nínú Bíbélì. Ó ní: “Èmi ni Jèhófà. Orúkọ mi nìyẹn.” (Ka Àìsáyà 42:5, 8.) Orúkọ náà “Jèhófà” wá látinú èdè Hébérù tí ẹ̀rí fi hàn pé ó túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di.” Jèhófà fẹ́ ká mọ orúkọ rẹ̀ yìí. (Ẹ́kísódù 3:15) Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà tí orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú Bíbélì!a “Ọlọ́run tòótọ́ lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé” nìkan ló ń jẹ́ orúkọ náà Jèhófà.—Diutarónómì 4:39.
2. Kí ni Bíbélì sọ fún wa nípa Jèhófà?
Bíbélì sọ pé nínú gbogbo ọlọ́run táwọn èèyàn ń sìn, Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run tòótọ́. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Àkọ́kọ́, Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ láyè àtọ̀run, òun nìkan sì ni “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.” (Ka Sáàmù 83:18.) Ìkejì, òun ni “Olódùmarè,” èyí tó túmọ̀ sí pé ó lágbára láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́. Ìkẹta, òun ló “dá ohun gbogbo” tó wà láyé àtọ̀run. (Ìfihàn 4:8, 11) Ìkẹrin, Jèhófà nìkan ṣoṣo ni kò níbẹ̀rẹ̀, títí ayé ló sì máa wà.—Sáàmù 90:2.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn orúkọ oyè tí Ọlọ́run ní àti orúkọ rẹ̀ tó ju gbogbo orúkọ lọ. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ kó o mọ orúkọ òun àti ìdí tó fi jẹ́ kó o mọ̀ ọ́n.
3. Ọlọ́run ní orúkọ oyè tó pọ̀, àmọ́ orúkọ kan ṣoṣo ló ní
Tó o bá fẹ́ rí ìyàtọ̀ tó wa nínú orúkọ oyè ẹnì kan àti orúkọ ẹ̀ gangan, Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín orúkọ oyè bí “Olúwa,” àti orúkọ Ọlọ́run gangan?
Bíbélì sọ pé ọ̀pọ̀ ọlọ́run àti olúwa làwọn èèyàn ń sìn. Ka Sáàmù 136:1-3, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Ta ni “Ọlọ́run àwọn ọlọ́run” àti “Olúwa àwọn olúwa”?
4. Jèhófà fẹ́ kó o mọ orúkọ òun, ó sì fẹ́ kó o máa lò ó
Báwo lo ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ kó o mọ orúkọ òun? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣó o rò pé Jèhófà fẹ́ ká mọ orúkọ òun? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Jèhófà fẹ́ ká máa lo orúkọ òun. Ka Róòmù 10:13, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà?
Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ táwọn èèyàn bá rántí orúkọ ẹ tí wọ́n sì fi pè ẹ́?
Lérò tìẹ, báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tó o bá ń lo orúkọ rẹ̀?
5. Jèhófà fẹ́ kó o sún mọ́ òun
Obìnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Kàǹbódíà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Soten sọ pé ‘ìgbà tóun mọ orúkọ Ọlọ́run ni inú òun dùn jù lọ!’ Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Nínú fídíò yẹn, báwo ló ṣe rí lára Soten nígbà tó mọ orúkọ Ọlọ́run?
Tó o bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ ẹnì kan, orúkọ ẹ̀ ni wàá kọ́kọ́ fẹ́ mọ̀. Ka Jémíìsì 4:8a, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ni Jèhófà fẹ́ kó o ṣe?
Tó o bá mọ orúkọ Ọlọ́run tó o sì ń lò ó, báwo nìyẹn á ṣe jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ọlọ́run kan ṣoṣo ló ṣáà wà, orúkọ tó bá wù ẹ́ lo lè pè é.”
Ṣé ìwọ gbà pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run?
Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé fún wọn pé Ọlọ́run fẹ́ ká máa lo orúkọ òun?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo. Ó fẹ́ ká mọ orúkọ yẹn, ká sì máa lò ó, ìyẹn á jẹ́ ká lè sún mọ́ ọn.
Kí lo rí kọ́?
Kí ló mú kí Jèhófà yàtọ̀ sí gbogbo ọlọ́run yòókù táwọn èèyàn ń jọ́sìn?
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo orúkọ Ọlọ́run?
Kí ló fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kó o sún mọ́ òun?
ṢÈWÁDÌÍ
Wo àwọn nǹkan márùn-ún tó jẹ́ ká gbà pé Ọlọ́run wà.
Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run kò ní ìbẹ̀rẹ̀.
Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ ìdí tó fi yẹ ká máa lo orúkọ Ọlọ́run, bá ò tiẹ̀ mọ bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ náà níbẹ̀rẹ̀.
Ṣé orúkọ tó bá wù wá la lè máa pe Ọlọ́run? Wo ìdí tá a fi sọ pé orúkọ àdáni kan ṣoṣo ló ní.