Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Diutarónómì 14:21 kà pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ òkú ẹran èyíkéyìí.” Ǹjẹ́ èyí ta ko ohun tó wà nínú Léfítíkù 11:40 tó kà pé: “Ẹni tí ó bá sì jẹ ohun èyíkéyìí lára òkú rẹ̀ yóò fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́”?
Àwọn ẹsẹ Bíbélì méjèèjì yìí kò ta ko ara wọn. Ńṣe ni ẹsẹ àkọ́kọ́ ń tún òfin Ọlọ́run sọ, ìyẹn òfin tó sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ jẹ òkú ẹran, bóyá èyí tí ẹranko ẹhànnà pa. (Ẹ́kísódù 22:31; Léfítíkù 22:8) Ẹsẹ Bíbélì kejì sì ń ṣàlàyé ohun tó yẹ kí ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣe tó bá rú òfin yẹn, bóyá tó ṣèèṣì rú u.
Pé Òfin Mósè ka nǹkan kan léèwọ̀ kò túmọ̀ sí pé àwọn kan kò ní rú òfin náà nígbà mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, òfin sọ pé àwọn èèyàn kò gbọ́dọ̀ jalè, wọn kò gbọ́dọ̀ pànìyàn, wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Síbẹ̀ náà, ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wà fáwọn tó bá rú àwọn òfin tí Ọlọ́run ṣe yìí. Àwọn ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí àwọn òfin náà ṣe wúwo tó, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe ohun tí wọ́n ní láti fọwọ́ kékeré mú.
Bí ẹnì kan bá rú òfin tó ka jíjẹ òkú ẹran léèwọ̀, ẹni náà yóò di aláìmọ́ lójú Jèhófà, ó sì di dandan kó ṣe àwọn ohun tí òfin là kalẹ̀ kó tó lè mọ́. Bó bá kọ̀ láti ṣe ohun tí òfin náà sọ kó bàa lè mọ́, yóò “dáhùn fún ìṣìnà rẹ̀.”—Léfítíkù 17:15, 16.