Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Àwọn Ọba Kìíní
“NÍGBÀ tí olódodo bá di púpọ̀, àwọn ènìyàn a máa yọ̀; ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni burúkú bá ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn a máa mí ìmí ẹ̀dùn.” (Òwe 29:2) Ìwé Àwọn Ọba Kìíní fi hàn kedere pé òótọ́ pọ́ńbélé ni òwe yìí. Ó sọ ìtàn ìgbésí ayé Sólómọ́nì, ẹni tó jẹ́ pé lákòókò ìṣàkóso rẹ̀, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní aásìkí gan-an, ààbò sì wà. Ìwé Àwọn Ọba Kìíní tún sọ nípa bí orílẹ̀-èdè náà ṣe pín sí méjì lẹ́yìn ikú Sólómọ́nì, ó sì tún sọ nípa àwọn ọba mẹ́rìnlá tó jẹ lẹ́yìn rẹ̀. Àwọn kan lára àwọn ọba wọ̀nyí jẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, àwọn kan sì jẹ nílẹ̀ Júdà. Méjì péré lára àwọn ọba wọ̀nyí ló ṣe olóòótọ́ sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Kò tán síbẹ̀ o, ìwé náà tún sọ nípa ìgbòkègbodò àwọn wòlíì mẹ́fà, Èlíjà sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wòlíì náà.
Wòlíì Jeremáyà ló kọ ìwé Àwọn Ọba Kìíní, ìlú Jerúsálẹ́mù àti Júdà ló sì ti kọ ọ́. Ìtàn inú rẹ̀ dá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún 1040 sí ọdún 911 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bí ọdún mọ́kàndínláàádóje [129]. Nígbà tí Jeremáyà ń ṣàkójọ ìwé náà, kò sí àní-àní pé ó lo àwọn àkọsílẹ̀ ìgbà láéláé kan, irú bí “ìwé àwọn àlámọ̀rí Sólómọ́nì.” Àwọn ìwé tí kì í ṣe apá kan Bíbélì yìí kò sí mọ́.—1 Àwọn Ọba 11:41; 14:19; 15:7.
ỌBA ỌLỌ́GBỌ́N KAN TÓ JẸ́ KÍ ÀLÀÁFÍÀ ÀTI AÁSÌKÍ GBILẸ̀
Ìròyìn kan tó ṣeni ní kàyéfì ló ṣáájú nínú ìwé Àwọn Ọba Kìíní. Ìròyìn ọ̀hún sọ nípa bí Ádóníjà ọmọ Dáfídì Ọba ṣe gbìyànjú láti gbàjọba mọ́ bàbá rẹ̀ lọ́wọ́. Ọpẹ́lọpẹ́ pé wòlíì Nátánì tètè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà ni kò jẹ́ kí ohun tí Ádóníjà ń gbèrò lọ́kàn láti ṣe bọ́ sí i, wọ́n sì fi Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì jọba. Inú Jèhófà dùn gan-an sí ohun tí ọba tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ náà tọrọ lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fún un ní “ọkàn-àyà ọgbọ́n àti òye,” ó tún fún un ní “ọrọ̀ àti ògo.” (1 Àwọn Ọba 3:12, 13) Ọgbọ́n ọba yìí kò láfiwé bẹ́ẹ̀ ló sì tún ní ọrọ̀ tó pọ̀ jaburata ju ti ẹnikẹ́ni lọ. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní àlàáfíà àti aásìkí lákòókò rẹ̀.
Lára àwọn ilé tí Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ tó sì parí ni tẹ́ńpìlì Jèhófà àtàwọn onírúurú ilé ìjọba mìíràn. Jèhófà mú un dá Sólómọ́nì lójú pé: ‘Òun yóò fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì ní tòótọ́, fún àkókò tí ó lọ kánrin,’ ìyẹn bí ọba náà kò bá ṣàìgbọràn. (1 Àwọn Ọba 9:4, 5) Ọlọ́rùn tòótọ́ tún kìlọ̀ fún un nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i tó bá ṣàìgbọràn. Àmọ́, nígbà tó yá, Sólómọ́nì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyàwó tí wọ́n jẹ́ àjèjì. Àwọn obìnrin wọ̀nyí sì mú kó lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Jèhófà wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé òun yóò pín ìjọba rẹ̀ sí méjì. Ọdún 997 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Sólómọ́nì kú, èyí tó fòpin sí ogójì ọdún tó fi jọba. Rèhóbóámù ọmọ rẹ̀ sì gorí ìtẹ́.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
1:5—Kí nìdí tí Ádóníjà fi gbìyànjú láti gbàjọba nígbà tí Dáfídì kò tíì kú? Bíbélì kò sọ. Síbẹ̀ a lè sọ pé níwọ̀n bí àwọn ẹ̀gbọ́n Ádóníjà méjì tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin ti kú, ìyẹn Ámínónì àti Ábúsálómù, tó sì tún jọ pé Kíléábù, ọmọkùnrin mìíràn tí Dáfídì ní náà ti kú, Ádóníjà ronú pé òun ni ipò ọba tọ́ sí, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ló dàgbà jù lára àwọn ọmọkùnrin Dáfídì tó ṣẹ́ kù sílẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 3:2-4; 13:28, 29; 18:14-17) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí Jóábù akíkanjú olórí ogun àti àlùfáà àgbà Ábíátárì tó jẹ́ ẹni pàtàkì ṣe wà lẹ́yìn Ádóníjà ló mú kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé ìjọba náà yóò bọ́ sọ́wọ́ òun. Bíbélì kò sọ bóyá Ádóníjà mọ èrò ọkàn Dáfídì pé Sólómọ́nì ni yóò di ọba lẹ́yìn òun. Àmọ́ Ádóníjà kò pe Sólómọ́nì àtàwọn mìíràn tí wọ́n dúró ti Dáfídì gbágbáágbá sí ibi “ìrúbọ” kan tó ṣe. (1 Àwọn Ọba 1:9, 10) Èyí fi hàn pé ńṣe ló ka Sólómọ́nì sí ẹni tó ń bá òun du ipò.
1:49-53; 2:13-25—Kí nìdí tí Sólómọ́nì tún fi pa Ádóníjà lẹ́yìn tó ti dárí jì í? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bátí-ṣébà kò mọ ìdí tí Ádóníjà fi bẹ̀ ẹ́ pé kó bá òun sọ fún ọba pé kó fún òun ní Ábíṣágì láti fi ṣaya, Sólómọ́nì mọ ohun tó mú kí Ádóníjà ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Ábíṣágì, arẹwà obìnrin, síbẹ̀ aya Dáfídì làwọn èèyàn kà á sí. Gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn lákòókò yẹn, ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti bọ́ sórí ìtẹ́ Dáfídì nìkan ló lè fi Ábíṣágì ṣaya. Ádóníjà lè ti rò pé tóun bá fi Ábíṣágì ṣaya, òun á tún lè gbìyànjú láti di ọba. Àmọ́, ńṣe ni Sólómọ́nì rí ohun tí Ádóníjà ṣe yìí bíi pé ó fẹ́ gba ipò ọba, kò sì dárí jì í mọ́.
6:37–8:2—Ìgbà wo ni wọ́n ya tẹ́ńpìlì náà sí mímọ́? Oṣù kẹjọ ọdún 1027 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ́ ọ tán, ìyẹn ọdún kọkànlá tí Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso. Ó dà bíi pé kíkó àwọn ohun èlò àtàwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ sínú tẹ́ńpìlì náà àtàwọn ìpalẹ̀mọ́ mìíràn gbà tó oṣù mọ́kànlá. Ó ní láti jẹ́ oṣù keje ọdún 1026 ṣáájú sànmáánì Kristẹni ni ìyàsímímọ́ náà wáyé. Ìtàn náà kọ́kọ́ sọ nípa àwọn ilé mìíràn tí Sólómọ́nì kọ́ lẹ́yìn tó parí tẹ́ńpìlì náà kó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ nípa ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì náà. Láìsí àní-àní, ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ ni láti lè sọ nípa gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn iṣẹ́ ilé kíkọ́ tó wáyé nígbà yẹn.—2 Kíróníkà 5:1-3.
9:10-13—Ṣé bí Sólómọ́nì ṣe fún Ọba Hírámù ti ìlú Tírè ní ogún [20] ìlú nílẹ̀ Gálílì bá Òfin Mósè mu? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kìkì àgbègbè táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé nìkan ni Òfin tó wà nínú Léfítíkù 25:23, 24 náà wà fún. Ó lè jẹ́ pé àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì ló ń gbénú àwọn ìlú tí Sólómọ́nì fún Hírámù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ààlà Ilẹ̀ Ìlérí làwọn ìlú náà wà. (Ẹ́kísódù 23:31) Ó sì tún lè jẹ́ pé ńṣe lohun tí Sólómọ́nì ṣe fi hàn pé kò tẹ̀ lé ohun tí Òfin náà sọ délẹ̀délẹ̀, bí irú ìgbà tó “mú ẹṣin pọ̀ sí i fún ara rẹ̀” àti bó ṣe fẹ́ ìyàwó jọ rẹpẹtẹ. (Diutarónómì 17:16, 17) Èyí ó wù kó jẹ́, ẹ̀bùn náà kò dùn mọ́ Hírámù nínú rárá. Bóyá nítorí pé àwọn abọ̀rìṣà tó ń gbénú àwọn ìlú náà kò tún wọn ṣe tàbí kó jẹ́ pé ibi táwọn ìlú náà wà kò dára.
11:4—Ṣé a lè sọ pé Sólómọ́nì ń ṣèrànrán lọ́jọ́ ogbó rẹ̀ ló jẹ́ kó di aláìṣòótọ́? Kò jọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Sólómọ́nì kéré gan-an nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogójì ọdún ló fi ṣàkóso, síbẹ̀ kò tíì di arúgbó kùjọ́kùjọ́. Bákan náà, kì í ṣe pé ó kúkú fi ìjọsìn Jèhófà sílẹ̀ pátápátá. Ó jọ pé ńṣe ló mú ìjọsìn mìíràn mọ́ ìjọsìn Jèhófà.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
2:26, 27, 35. Ohunkóhun tí Jèhófà bá sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ máa ń ṣẹ. Mímú tí wọ́n mú Ábíátárì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Élì kúrò lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà mú “ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó ti sọ lòdì sí ilé Élì” ṣẹ. Bí wọ́n sì ṣe fi Sádókù tó wá láti ìlà ìdílé Fíníhásì rọ́pò Ábíátárì mú ọ̀rọ̀ tó wà nínú Númérì 25:10-13 ṣẹ.—Ẹ́kísódù 6:25; 1 Sámúẹ́lì 2:31; 3:12; 1 Kíróníkà 24:3.
2:37, 41-46. Ó léwu gan-an kí ẹnì kan máa rò pé òun lè ré àwọn ìlànà Ọlọ́run kọjá kóun sì mú un jẹ! Àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ kúrò lójú ‘ọ̀nà híhá tó lọ sí ìyè’ yóò jìyà nítorí ìwà òmùgọ̀ tí wọ́n hù yẹn.—Mátíù 7:14.
3:9, 12-14. Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà àtọkànwá táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá gbà pé kó fún wọn ní ọgbọ́n, òye, àti ìtọ́sọ́nà láti lè ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.—Jákọ́bù 1:5.
8:22-53. Sólómọ́nì sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìmọrírì látọkànwá nípa Jèhófà pé ó jẹ́ Ọlọ́run inú rere onífẹ̀ẹ́, tó ń mú àwọn ìlérí tó ṣe ṣẹ, àti Olùgbọ́ àdúrà! Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí Sólómọ́nì sọ nínú àdúrà ìyàsímímọ́ tó gbà, èyí á jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yìí àtàwọn ànímọ́ mìíràn tó tún ní.
11:9-14, 23, 26. Nígbà tí Sólómọ́nì di aláìgbọràn lọ́jọ́ alẹ́ rẹ̀, Jèhófà gbé àwọn alátakò dìde sí i. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”—1 Pétérù 5:5.
11:30-40. Ọba Sólómọ́nì wá ọ̀nà láti pa Jèróbóámù nítorí àsọtẹ́lẹ̀ tí Áhíjà sọ nípa Jèróbóámù. Ẹ ò rí i pé ohun tí ọba yìí ṣe lọ́tẹ̀ yìí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó ṣe ní ogójì ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. Lákòókò náà, ó kọ̀ láti gbẹ̀san lára Ádóníjà àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ mìíràn! (1 Àwọn Ọba 1:50-53) Ìdí tí ìwà rẹ̀ fi yí padà ni pé ó ti fi Jèhófà sílẹ̀.
ÌJỌBA TÓ WÀ NÍṢỌ̀KAN TẸ́LẸ̀ PÍN SỌ́TỌ̀Ọ̀TỌ̀
Jèróbóámù àti gbogbo àwọn èèyàn Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ Ọba Rèhóbóámù wọ́n sì sọ fún un pé kó mú ẹrù tí Sólómọ́nì bàbá rẹ̀ dì lé àwọn lórí fúyẹ́. Dípò kí Rèhóbóámù ṣe ohun tí wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣe fáwọn, ńṣe ló halẹ̀ mọ́ wọ́n pé òun á mú kí ẹrù náà túbọ̀ wúwo sí i. Èyí ló mú káwọn ẹ̀yà mẹ́wàá dìtẹ̀ sí i tí wọ́n sì fi Jèróbóámù ṣe ọba wọn. Bí ìjọba náà ṣe pín sí méjì nìyẹn. Rèhóbóámù ń ṣàkóso lórí ìjọba gúúsù, tó jẹ́ ẹ̀yà Júdà àti Bẹ́ńjámínì, Jèróbóámù sì ń ṣàkóso lórí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti àríwá Ísírẹ́lì.
Káwọn èèyàn náà má bàa lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ máa jọ́sìn, Jèróbóámù gbé ère ọmọ màlúù aláwọ̀ wúrà méjì kalẹ̀, ọ̀kan ní Dánì èkejì sì wà ní Bẹ́tẹ́lì. Lára àwọn ọba tó jẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì lẹ́yìn Jèróbóámù ni Nádábù, Bááṣà, Éláhì, Símírì, Tíbínì, Ómírì, Áhábù, àti Ahasáyà. Nílẹ̀ Júdà sì rèé, àwọn ọba tó jẹ lẹ́yìn Rèhóbóámù ni Ábíjámù, Ásà, Jèhóṣáfátì àti Jèhórámù. Lára àwọn tó sì ṣe wòlíì lákòókò àwọn ọba wọ̀nyí ni Áhíjà, Ṣemáyà, àti èèyàn Ọlọ́run kan tí Bíbélì kò dárúkọ rẹ̀. Jéhù, Èlíjà, àti Mikáyà náà tún wà lára wọn.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
18:21—Kí nìdí táwọn èèyàn náà kò fi fèsì nígbà tí Èlíjà sọ pé kí wọ́n yan ẹni tí wọ́n máa tẹ̀ lé, yálà Jèhófà tàbí Báálì? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ti rí i pé àwọn kò fún Jèhófà ní ìjọsìn tó tọ́ sí i, èyí tó béèrè lọ́wọ́ wọn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn sì wá ń tipa bẹ́ẹ̀ dá wọn lẹ́bi. Tàbí kẹ̀, ó lè jẹ́ pé ẹ̀rí ọkàn wọn ti yigbì débi pé wọn ò róhun tó burú nínú jíjọ́sìn Báálì bí wọ́n tiẹ̀ ń sọ pé olùjọ́sìn Jèhófà làwọn. Lẹ́yìn ìgbà tí Jèhófà fi agbára rẹ̀ hàn ni wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé: “Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́! Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!”—1 Àwọn Ọba 18:39.
20:34—Lẹ́yìn tí Jèhófà ti jẹ́ kí Áhábù ṣẹ́gun àwọn ará Ásíríà, kí nìdí tí Áhábù fi dá Bẹni-Hádádì ọba wọn sí? Dípò kí Áhábù pa Bẹni-Hádádì, ńṣe ló bá a dá májẹ̀mú tí yóò mú káwọn òpópónà kan nílùú Damásíkù tó jẹ́ olú ìlú Síríà di ti Áhábù, kò sì sí àní-àní pé títa ọjà bàsá tàbí ọjà mìíràn ló fẹ́ lo àwọn òpópónà náà fún. Ṣáájú ìgbà yẹn, bàbá Bẹni-Hádádì náà ti gba àwọn òpópónà kan nílùú Samáríà kó lè máa fi ṣòwò. Nítorí náà, kí Áhábù lè máa ráyè ṣòwò ní Damásíkù ló jẹ́ kó dá ẹ̀mí Bẹni-Hádádì sí.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
12:13, 14. Nígbà tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì gan-an, ó yẹ ká wá ìmọ̀ràn lọ sọ́dọ̀ àwọn tó gbọ́n tí wọ́n sì dàgbà dénú, tí wọ́n mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa tí wọn ò sì fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn ìlànà Ọlọ́run.
13:11-24. Bí ẹnì kan bá fún wa nímọ̀ràn kan tàbí àbá kan tó dà bíi pé ó kọ wá lóminú, kódà bó tiẹ̀ jẹ́ pé onígbàgbọ́ bíi tiwa tó fẹ́ kó dára fún wa ló fún wa nímọ̀ràn náà, ó yẹ ká gbé e yẹ̀ wò dáadáa bóyá ó bá ìtọ́sọ́nà rere tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu.—1 Jòhánù 4:1.
14:13. Jèhófà máa ń yẹ̀ wá wò dáadáa láti mọ ibi tá a dára sí. Bó ti wù kí ohun tó dára tí Ọlọ́run rí nínú wa ti kéré tó, ó lè mú un dàgbà bá a ti ń sa gbogbo ipá wa láti sìn ín.
15:10-13. A gbọ́dọ̀ fi tọkàntara kọ ìpẹ̀yìndà ká sì máa gbé ìjọsìn mímọ́ ga.
17:10-16. Opó ìlú Sáréfátì rí i pé wòlíì ni Èlíjà ó sì ṣe é lálejò bó ti tọ́ àti bó ti yẹ, Jèhófà sì bù kún ohun tí ìgbàgbọ́ sún un ṣe yìí. Lọ́jọ́ òní náà, Jèhófà máa ń kíyè sáwọn ohun tá à ń ṣe láti fi hàn pé a nígbàgbọ́, ó sì máa ń bù kún àwọn tó ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà lónírúurú ọ̀nà.—Mátíù 6:33; 10:41, 42; Hébérù 6:10.
19:1-8. Nígbà táwọn èèyàn bá ń ṣe inúnibíni sí wa lójú méjèèjì, ká fọkàn balẹ̀ pé Jèhófà yóò dúró tì wá.—2 Kọ́ríńtì 4:7-9.
19:10, 14, 18. Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò dá nìkan wà rárá. Jèhófà àti ẹgbẹ́ àwọn ara karí ayé wà fún wọn.
19:11-13. Jèhófà kì í ṣe ọlọ́run inú afẹ́fẹ́ tàbí ti inú àwọn ìṣẹ̀dá mìíràn.
20:11. Nígbà tí Bẹni-Hádádì ń fọ́nnu pé òun á pa Samáríà run, ọba Ísírẹ́lì dá a lóhùn pé: “Kí ẹni tí ń di [ìhámọ́ra láti lọ sógun] má ṣògo nípa ara rẹ̀ bí ẹni tí ń tú [ìhámọ́ra] kúrò” lẹ́yìn tó ti ti ogun dé tó sì ti ṣẹ́gun. Tí wọ́n bá fún wa ní iṣẹ́ tuntun kan láti bójú tó, a ò gbọ́dọ̀ dá ara wa lójú ju bó ṣe yẹ lọ.—Òwe 27:1; Jákọ́bù 4:13-16.
Ìwé Àwọn Ọba Kìíní Wúlò fún Wa Gan-an
Nígbà tí Mósè ń sọ̀rọ̀ lórí Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì lórí Òkè Sinai, ó sọ fún wọn pé: “Wò ó, èmi ń fi ìbùkún àti ìfiré sí iwájú yín lónìí: ìbùkún, kìkì bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín tí èmi ń pa láṣẹ fún yín lónìí; àti ìfiré, bí ẹ̀yin kò bá ní ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yà ní ti gidi kúrò lójú ọ̀nà tí mo ń pa láṣẹ fún yín lónìí.”—Diutarónómì 11:26-28.
Ẹ ò rí i pé ìwé Àwọn Ọba Kìíní jẹ́ ká rí i pé òdodo ọ̀rọ̀ gbáà lohun tí Mósè sọ lókè yìí, ó sì ṣe pàtàkì! Gẹ́gẹ́ báwa náà ti rí i, ìwé yìí tún kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ mìíràn tó ṣe kókó. Láìsí àní-àní, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yè ó sì ń sa agbára.—Hébérù 4:12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Tẹ́ńpìlì Jèhófà àtàwọn ilé mìíràn tí Sólómọ́nì kọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30, 31]
Lẹ́yìn tí Jèhófà fi agbára rẹ̀ hàn, àwọn ènìyàn náà pariwo pé: “Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!”