Fifi Ẹ̀jẹ̀ Gba Ẹmi Là—Bawo?
“Ẹ yan ìyè nipa fifeti silẹ si ohùn [Ọlọrun] . . . , nitori oun ni ìyè yin ati gigun awọn ọjọ yin.”—DEUTARONOMI 30:19, 20, NW.
1. Bawo ni awọn Kristian tootọ ṣe tayọ ninu ọ̀wọ̀ wọn fun iwalaaye?
ỌPỌLỌPỌ eniyan sọ pe awọn bọwọ fun iwalaaye, ni fifunni gẹgẹ bi ẹri oju-iwoye wọn nipa ijiya iku, iṣẹyun, tabi ṣiṣọdẹ ẹran. Bi o ti wu ki o ri, ọna akanṣe kan wà ti awọn Kristian tootọ ngbà fi ọwọ han fun iwalaaye. Saamu 36:9 wi pe: “Pẹlu rẹ [Ọlọrun] ni orisun iye wà.” Niwọn bi iwalaaye ti jẹ ẹbun lati ọdọ Ọlọrun, awọn Kristian tẹwọ gba oju-iwoye rẹ nipa ẹ̀jẹ̀ iwalaaye.
2, 3. Eeṣe ti a fi nilati gba ohun ti Ọlọrun sọ rò lori ẹ̀jẹ̀? (Iṣe 17:25, 28)
2 Iwalaaye wa sinmi lori ẹ̀jẹ̀, eyi ti ngbe afẹfẹ oxygen kaakiri ara wa, ti nmu afẹfẹ carbon dioxide kuro, ti o njẹ ki a mu ara wa bá iyipada igbona ati itutu mu, o si nran wa lọwọ lati bá awọn arun jagun. Ẹni naa ti o pese iwalaaye wa tun ṣeto o si pese agbayanu idipọ sẹ́ẹ̀lì olomi, ti ngbe iwalaaye ró ti a npe ni ẹ̀jẹ̀. Eyi nfi ifẹ rẹ ti nbaa niṣo han ninu pipa iwalaaye eniyan mọ.—Jẹnẹsisi 45:5; Deutaronomi 28:66; 30:15, 16.
3 Awọn Kristian ati awọn eniyan ni gbogbogboo nilati beere lọwọ araawọn pe: ‘Njẹ ẹ̀jẹ̀ le gba ẹmi mi là kiki nipa awọn ete ìṣiṣẹ́ adanida rẹ, tabi ẹ̀jẹ̀ ha le gba ẹmi là ni ọna gbigbooro sii bi?’ Nigba ti ọpọ julọ awọn eniyan mọ isopọ laaarin iwalaaye ati awọn ete ìṣiṣẹ́ deedee ẹ̀jẹ̀, pupọpupọ sii ni o ni ninu niti gidi. Ilana iwa híhù awọn Kristian, Musulumi, ati Juu papọ dari afiyesi si Olufunni ni Iye ti o sọ ero rẹ nipa iwalaaye ati nipa ẹ̀jẹ̀. Bẹẹni, Ẹlẹdaa wa ni pupọ lati sọ nipa ẹ̀jẹ̀.
Iduro Gbọnyingbọnyin Ọlọrun Lori Ẹ̀jẹ̀
4. Ni ibẹrẹpẹpẹ ninu itan eniyan, ki ni Ọlọrun sọ nipa ẹ̀jẹ̀?
4 Ẹ̀jẹ̀ ni a mẹnukan ni igba ti o ju 400 lọ ninu Ọrọ Ọlọrun, Bibeli. Lara awọn eyi ti o jẹ́ akọkọ bẹrẹ julọ ninu ofin Jehofa ni: “Ohun gbogbo ti o wà laaye ti o si nrin yoo jẹ ounjẹ fun yin. . . . Ṣugbọn ẹyin ko gbọdọ jẹ ẹran ti o ni ẹ̀jẹ̀ iwalaaye rẹ lara rẹ sibẹ.” Oun fikun un pe: “Nitori fun ẹ̀jẹ̀ iwalaaye rẹ ni emi yoo beere ijihin dajudaju.” (Jẹnẹsisi 9:3-5, New International Version) Jehofa sọ iyẹn fun Noa, baba nla idile eniyan. Nipa bayii, gbogbo ẹda araye ni a fi tó leti pe Ẹlẹdaa wo ẹ̀jẹ̀ gẹgẹ bi eyi ti o duro fun iwalaaye. Olukuluku ẹni ti o ba jẹ́wọ́ lati mọ Ọlọrun gẹgẹ bi Olufunni ni Iye nipa bayii yẹ ki o mọ pe Ó mú iduro gbọnyingbọnyin nipa lilo ẹ̀jẹ̀ iwalaaye.
5. Ki ni idi ti o ṣe pataki julọ ti awọn ọmọ Isirẹli kii fii jẹ ẹ̀jẹ̀?
5 Ọlọrun tun mẹnukan ẹ̀jẹ̀ nigba ti o nfun Isirẹli ni akojọ Ofin rẹ. Lefitiku 17:10, 11, ni ibamu pẹlu ẹda itumọ Jewish Tanakh, kà pe: “Bi ẹnikẹni ninu ile Isirẹli tabi ti awọn alejo ti wọn ngbe laaarin wọn ba jẹ ẹ̀jẹ̀ eyikeyi, emi yoo kọ oju mi lodi si ẹni naa ti o jẹ ẹ̀jẹ̀, emi yoo si ke e kuro laaarin awọn eniyan rẹ̀. Nitori ẹmi ara wà ninu ẹ̀jẹ̀.” Ofin yẹn lè ni awọn anfaani ilera, ṣugbọn pupọ sii ni o wemọ ọn. Nipa kika ẹ̀jẹ̀ si akanṣe, awọn ọmọ Isirẹli ni wọn nilati fi ìgbara wọn lé Ọlọrun fun iwalaaye han. (Deutaronomi 30:19, 20) Bẹẹni, idi pataki ti wọn fi nilati yẹra fun jijẹ ẹ̀jẹ̀ ni, kii ṣe pe o lè jẹ́ elewu si ilera, ṣugbọn pe ẹ̀jẹ̀ ni itumọ akanṣe fun Ọlọrun.
6. Bawo ni o ṣe le dá wa loju pe Jesu di iduro Ọlọrun mu lori ẹ̀jẹ̀?
6 Nibo ni isin Kristian duro si lori fifi ẹ̀jẹ̀ gba ẹmi eniyan là? Jesu mọ ohun ti Baba rẹ sọ nipa lilo ẹ̀jẹ̀. Jesu “ko ṣaitọ kankan, a ko [si] ba arekereke kankan ni ete rẹ.” Iyẹn tumọ si pe oun pa Ofin mọ lọna pipe, eyi ti o ní ninu ofin nipa ẹ̀jẹ̀. (1 Peteru 2:22, Knox) Oun tipa bayii gbé apẹerẹ titayọ kalẹ fun awọn ọmọlẹhin rẹ, eyi ti o ní ninu apẹẹrẹ titayọ ti ọ̀wọ̀ fun iwalaaye ati ẹ̀jẹ̀.
7, 8. Bawo ni o ṣe ṣe kedere pe ofin Ọlọrun lori ẹ̀jẹ̀ kan awọn Kristian?
7 Itan fi ohun ti o ṣẹlẹ lẹhin naa hàn wá nigba ti ajọ igbimọ ẹgbẹ Oluṣakoso Kristian kan pinnu yala awọn Kristian nilati pa gbogbo ofin Isirẹli mọ. Labẹ itọsọna atọrunwa, wọn sọ pe awọn Kristian ni a ko sọ ọ́ di dandan fun lati pa akojọ Ofin Mose mọ́ ṣugbọn pe o “pọndandan” lati “pa fífà sẹhin mo kuro ninu awọn ohun ifirubọ fun oriṣa ati kuro ninu ẹ̀jẹ̀ ati kuro ninu awọn ohun ìlọ́lọ́rùnpa [ẹran ti a ko ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ silẹ] ati kuro ninu agbere.” (Iṣe 15:22-29, NW) Wọn tipa bayii mu un ṣe kedere pe yiyẹra fun ẹ̀jẹ̀ ṣe pataki niti iwa rere gẹgẹ bi o ti jẹ niti yiyẹra fun ibọriṣa ati iwa palapala ti o lékenkà.a
8 Awọn Kristian ijimiji di ikaleewọ yẹn mu. Ni sisọrọ lori eyi, ọmọwe ara Britain Joseph Benson sọrọ pe: “Ìkàléèwọ̀ yii ti jijẹ ẹ̀jẹ̀, ti a fi fun Noa ati gbogbo iran atẹle rẹ̀, ti a si tun sọ fun awọn ọmọ Isirẹli . . . ni a ko tii parẹ lae, ṣugbọn, ni idakeji, a ti jẹrii sii labẹ Majẹmu Titun, Iṣe xv.; o si tipa bẹẹ di aigbọdọmaṣe titilọ gbére.” Sibẹ, njẹ ohun ti Bibeli sọ nipa ẹ̀jẹ̀ ha le fagi lé lilo rẹ ninu iṣegun ode oni, iru bii fifajẹ sini lara, eyi ti o ṣe kedere pe a ko lo ni ọjọ Noa tabi ni akoko awọn apọsteli?
Ẹ̀jẹ̀ Ninu Tabi Gẹgẹ bi Oogun
9. Bawo ni a ṣe lo ẹ̀jẹ̀ lọna iṣegun ni akoko igbaani, ni iyatọ ifiwera pẹlu ipo Kristian wo?
9 Lilo ẹ̀jẹ̀ gẹgẹ bi oogun kii ṣe ti igbalode rara. Iwe naa Flesh and Blood, lati ọwọ Reay Tannahill, tọka jade pe fun nǹkan bi 2,000 ọdun, ni Ijibiti ati nibomiran, “ẹ̀jẹ̀ ni a kà si ọna iwosan gbigbeṣẹ julọ fun arun ẹ̀gbà.” Awọn ara Roomu gbagbọ pe wárápá ni a lè wosan nipa gbigba ẹ̀jẹ̀ eniyan sinu. Tertullian kọwe nipa “ilo iṣegun” ti ẹ̀jẹ̀ yii pe: “Ẹ ronu nipa awọn wọnni ti wọn fi ifẹ lilagbara oniwọra gba ẹ̀jẹ̀ ti o ṣẹṣẹ nda jade lara awọn odaran buburu ni ibi iran kan ninu pápá iworan . . . ti wọn si gbé e lọ lati fi wo wárápá wọn san.” Eyi jẹ ni iyatọ gédégédé si ohun ti awọn Kristian ṣe: “Ko tilẹ si ẹ̀jẹ̀ awọn ẹranko paapaa ninu ounjẹ wa . . . Nigba iwadii ẹjọ awọn Kristian, iwọ gbe burẹdi ẹlẹ̀jẹ̀ ninu fun wọn. Niti tootọ, iwọ ni idaniloju pe [ó] jẹ alaibofin mu fun wọn.” Gbe ohun ti o tumọ si yẹwo: Dipo ki wọn gba ẹ̀jẹ̀, eyi ti o duro fun iwalaaye, awọn Kristian ijimiji ṣetan lati dojukọ ewu iku.—Fiwe 2 Samuẹli 23:15-17.
10, 11. Eeṣe ti a fi le gbà pe ọpa idiwọn Ọlọrun lori ẹ̀jẹ̀ fagi lé gbigba ẹ̀jẹ̀ sara?
10 Dajudaju, láyé igba naa a kii fa ẹ̀jẹ̀ sini lara, nitori awọn aṣeyẹwo pẹlu ifajẹsinilara bẹrẹ kete ṣaaju ọrundun kẹrindinlogun. Sibẹ, ni ọrundun kẹtadinlogun, ọjọgbọn imọ ijinlẹ kan nipa ẹya ara ẹda ni University of Copenhagen ṣatako pe: ‘Awọn wọnni ti wọn nasẹ lilo ẹ̀jẹ̀ eniyan wọle fun iwosan inu lọhun un ti awọn aisan ni o farahan pe wọn ṣì í lò wọn si ndẹṣẹ lọna wiwuwo. Awọn ajẹniyan ni a dalẹbi. Eeṣe ti a ko fi tẹgantẹgan korira awọn wọnni ti wọn kó abawọn ba ọna ọfun wọn pẹlu ẹ̀jẹ̀ eniyan? Bakan naa ni gbigba ẹ̀jẹ̀ ajeji lati inu iṣan ẹ̀jẹ̀ kan ti a ge , yala nipasẹ ẹnu tabi nipasẹ awọn ohun eelo ifajẹsinilara. Awọn olubẹrẹ iṣẹ abẹ yii ni ofin atọrunwa fi sinu ipaya.’
11 Bẹẹni, ani ninu awọn ọrundun ti o ti kọja paapaa, awọn eniyan ri pe ofin Ọlọrun fagilé gbigba ẹ̀jẹ̀ sinu awọn iṣan ati mimu un pẹlu. Ni mimọ eyi daju le ran awọn eniyan lọwọ lonii lati loye ipo ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dì mú, ọkan ti o ba iduro Ọlọrun mu. Nigba ti wọn ka iwalaaye si iyebiye gan an ti wọn si mọriri itọju iṣegun, awọn Kristian tootọ bọwọ fun iwalaaye gẹgẹ bi ẹbun lati ọdọ Ẹlẹdaa, nitori naa wọn ko gbiyanju lati gbé iwalaaye ró nipa gbigba ẹ̀jẹ̀.—1 Samuẹli 25:29.
O Ha Ngba Iwalaaye Là Lọna Iṣegun Bi?
12. Awọn eniyan onironu le fi ọgbọn gbe ki ni yẹwo nipa ifajẹsinilara?
12 Fun ọpọ ọdun awọn ògbógi ti sọ pe ẹ̀jẹ̀ ngba iwalaaye là. Awọn dokita le sọ pe ẹnikan ti o padanu ẹ̀jẹ̀ pupọpupọ ni a fa ẹ̀jẹ̀ si lara ti ara rẹ̀ si yá. Nitori naa awọn eniyan le ṣe kayefi pe, ‘Bawo ni iduro Kristian ti bá ọgbọn mu tabi ṣai bá ọgbọn mu tó niti iṣegun?’ Ṣaaju ki ó to gbe ilana iṣegun pataki eyikeyi yẹwo, onironu eniyan kan yoo pinnu awọn anfaani ti o ṣeeṣe ati awọn ewu ti o ṣeeṣe pẹlu. Ki ni nipa ifajẹsinilara? Otitọ gidi naa ni pe awọn ifajẹsinilara kún fun ọpọlọpọ ewu. Wọn tilẹ le ṣekupani paapaa.
13, 14. (a) Ki ni awọn ọna diẹ ninu eyi ti ifajẹsinilara fi jasi elewu? (b) Bawo ni iriiri pope ṣe ṣakawe ewu ilera ẹ̀jẹ̀?
13 Lẹnu aipẹ yii, Dokita L. T. Goodnough ati J. M. Shuck ṣakiyesi pe: “Awujọ oniṣegun ti mọ tipẹtipẹ pe nigba ti ipese ẹ̀jẹ̀ ti jẹ alailewu debí ti a mọ ọna lati mu un ki o jẹ bẹẹ tó, ifajẹsinilara mewu lọwọ nigba gbogbo. Akọtun aisan ti o ṣe lemọlemọ julọ ti njẹ jade lati inu ifajẹsinilara nbaa lọ lati jẹ arun mẹdọwu oni non-A, ati non-B (NANBH); awọn ijẹ jade aisan titun miiran ti o ṣeeṣe tun ni ninu arun mẹdọwu oriṣi B [hepatitis B], alloimmunization, eyi ti o niiṣe pẹlu fifa ẹ̀jẹ̀ ti ko ba ni lara mu si ni lara, iyọrisi ifajẹsinilara ti o gbodi, agbara idena arun ti a di lọwọ [immunologic suppression], ati akunya eroja iron.” Ni ṣíṣèdíyelé ‘afarabalẹ ṣe’ lori ọkan ṣoṣo lara awọn ewu wiwuwo wọnni, irohin naa fikun un pe: “A foju sọna pe nǹkan bii 40,000 awọn eniyan [ni United States nikan] yoo ni arun mẹdọwu NANBH lọdọọdun ati pe ohun ti o pọ tó 10 ipin ninu ọgọrun awọn wọnyi ni oo ni aisan mẹdọsunki [cirrhosis] ati/tabi káńsà ẹ̀dọ̀.”—The American Journal of Surgery, June 1990.
14 Gẹgẹ bi ewu kiko arun lati inu ẹ̀jẹ̀ ti a fà sini lara ti di eyi ti a mọ kaakiri, awọn eniyan ntun oju iwoye wọn nipa ifajẹsinilara gbé yẹwo. Fun apẹẹrẹ, lẹhin ti a yinbọn lu pope ni 1981, a tọju rẹ ni ile iwosan a si yọnda ki o maa lọ sile. Lẹhin naa oun nilati pada fun oṣu meji, ipo rẹ si buru to bẹẹ ti o fi dabi pe oun le nilati fẹhinti gẹgẹ bi aláàárẹ̀ kan. Eeṣe? Oun ni akoran kokoro saitomẹgalofairọsi [cytomegalovirus] lati inu ẹ̀jẹ̀ ti a fun un. Awọn kan le ṣe kayefi pe, ‘Bi ẹ̀jẹ̀ ti a fun pope paapaa ba jẹ elewu, ki ni nipa awọn ifajẹsinilara ti a fifun awa eniyan gbáàtúù?’
15, 16. Eeṣe ti awọn ifajẹsinilara ko fi wa laisewu ani bi a ba tilẹ ti ṣayẹwo ẹ̀jẹ̀ naa fun awọn arun?
15 ‘Ṣugbọn ṣe wọn ko le ṣayẹwo ẹ̀jẹ̀ fun awọn arun ni?’ ẹnikan le beere. O dara, gbe apẹẹrẹ iṣayẹwo fun arun mẹdọwu oriṣi B. yẹwo. Patient Care (February 28, 1990) tọka jade pe: “Iṣẹlẹ mẹdọwu lẹhin ifajẹsinilara lọ silẹ ni titẹle iṣayẹwo ẹ̀jẹ̀ fun [un] kari aye, ṣugbọn ipin 5 si 10 ninu ọgọrun ọran arun mẹdọwu lẹhin ifajẹsinilara ni a ṣi nfa nipasẹ arun mẹdọwu oriṣi B.”
16 Ṣiṣeeṣe ki iru ayẹwo bẹẹ ni aṣiṣe ni a tun ri pẹlu ewu miiran ti ẹ̀jẹ̀ nfa—AIDS. De iwọn ti o ga gidigidi, arun AIDS naa ti o kari aye ti ta awọn eniyan jí si ewu inu ẹ̀jẹ̀ ti a ti kó eeran bá. Ki a gbà pe, awọn aṣeyẹwo ni a nṣe nisinsinyi lati ṣayẹwo ẹ̀jẹ̀ fun ẹri kokoro fairọsi naa. Bi o ti wu ki o ri, awọn ẹ̀jẹ̀ ni a kii ṣayẹwo rẹ nibi gbogbo, o si dabi pe awọn eniyan le ni kokoro fairọsi AIDS ninu ẹ̀jẹ̀ wọn fun ọpọlọpọ ọdun laitu wọn fó nipasẹ awọn ayẹwo ti lọ́ọ́lọ́ọ́. Nitori naa awọn alaisan le ni AIDS—wọn ti ni AIDS—lati inu ẹ̀jẹ̀ ti a ti ṣayẹwo ti a si ti fọwọ si!
17. Bawo ni ifajẹsinilara ṣe le ṣe iparun ti o le má hàn gbangba loju ẹsẹ?
17 Dokita Goodnough ati Shuck tun mẹnukan “agbara idena arun ti a dilọwọ.” Bẹẹni, ẹri pọ pelemọ pe ani ẹ̀jẹ̀ ti a mu baramu lọna titọ paapaa le ba eto idena arun ara alaisan kan jẹ́, ni ṣiṣi ilẹkun silẹ fun káńsá ati iku. Nipa bayi, ayẹwo Canadian ti “awọn alaisan ti wọn ni káńsá ori ati ọrùn fihan pe awọn wọnni ti wọn gba ẹ̀jẹ̀ sara nigba imukuro kókó ara [kan] niriiri ilọ silẹ gan an ninu ipo agbara idena arun ara lẹ́hìn-ọ̀-rẹhìn.” (The Medical Post, July 10, 1990) Awọn dokita ni University of Southern California ti rohin pe: “Iwọn ìpadawa lẹẹkan sii fun gbogbo awọn káńsà gògóńgò ọfun jẹ ipin 14 ninu ọgọrun un fun awọn wọnni ti wọn ko gba ẹ̀jẹ̀ ati ipin 65 ninu ọgọrun fun awọn wọnni ti wọn gbà á. Fun káńsà ẹnu, ọfun, ati imu tabi iho imu, iwọn ìpadawa lẹkan sii jẹ ipin 31 ninu ọgọrun un laisi ifajẹsinilara ati ipin 71 ninu ọgọrun un pẹlu ifajẹsinilara.” (Annals of Otology, Rhinology & Laryngology, March 1989) Agbara idena ara ti a dilọwọ tun dabi ẹni pe o tẹnumọ otitọ naa pe awọn wọnni ti a fun ni ẹ̀jẹ̀ nigba iṣẹ abẹ ni o ṣeeṣe ki wọn ko akoran.—Wo apoti, oju-iwe 10.
Awọn Afidipo Eyikeyi fun Ẹ̀jẹ̀ Ha Wà Bi?
18. (a) Awọn ewu ti o wémọ́ ifajẹsinilara nyi awọn oniṣegun pada si ki ni? (b) Isọfunni nipa awọn afidipo wo ni iwọ le ṣajọpin rẹ̀ pẹlu oniṣegun rẹ?
18 Awọn kan le nimọlara pe, ‘Ifajẹsinilara lewu, ṣugbọn njẹ awọn afidipo eyikeyi ha wà bi?’ Dajudaju awa nfẹ itọju iṣegun ti o gbeṣẹ ti o jẹ ojulowo, nitori naa awọn ọna ti o ba ofin mu ti o si gbeṣẹ ha wà lati bojuto awọn iṣoro iṣegun pataki lai lo ẹ̀jẹ̀ bi? A layọ pe, bẹẹni. The New England Journal of Medicine (June 7, 1990) rohin pe: “Awọn oniṣegun, bi wọn ti tubọ nmọ awọn ewu [AIDS] ati awọn akoran miiran ti a ńta àtaré rẹ nipasẹ ifajẹsinilara nfa, ntun awọn ewu ati awọn anfaani ifajẹsinilara gbe yẹwo wọn si nyiju si awọn afidipo, eyi ti o ní yiyẹra fun ifajẹsinilara patapata ninu.”b
19. Eeṣe ti o fi le nigbọkanle pe iwọ le kọ ẹ̀jẹ̀ ki a si bojuto ọ lọna iṣegun pẹlu aṣeyọri si rere sibẹsibẹ?
19 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti kọ ifajẹsinilara tipẹtipẹ, kii ṣe nitori ewu ilera ni pataki, ṣugbọn nitori igbọran si ofin Ọlọrun lori ẹ̀jẹ̀. (Iṣe 15:28, 29) Sibẹ, awọn dokita olóye iṣẹ ti fi aṣeyọri si rere tọju awọn alaisan Ẹlẹrii lailo ẹ̀jẹ̀, pẹlu awọn ewu ti nbaa rin. Gan gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọpọlọpọ apẹẹrẹ ti a rohin rẹ ninu iwe iṣegun, Archives of Surgery (November 1990) jiroro gbigbé ọkan-aya si ara wọn lara awọn alaisan Ẹlẹrii ti ẹri ọkan wọn yọnda fun iru igbesẹ bẹẹ lai funni ni ẹ̀jẹ̀. Irohin naa wi pe: “Ohun ti o ju 25 ọdun iriri ṣiṣe iṣẹ abẹ ọkan-aya lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti yọrisi ipaarọ ọkan-aya ti o yọrisi rere lai funni ni awọn eelo ẹ̀jẹ̀ . . . Ko si iku ṣaaju tabi lẹhin iṣẹ abẹ ti o ṣẹlẹ, awọn ayẹwo ti o si kọkọ tẹle e ti fihan pe awọn alaisan wọnyi ni ko túbọ̀ rọrun fun ki ara wọn kọ ẹya ara ti a yọ si ti wọn.”
Ẹ̀jẹ̀ Ti O Niye Lori Julọ
20, 21. Eeṣe ti awọn Kristian fi nilati ṣọra pe wọn ko mu ẹmi-ironu naa “Ẹ̀jẹ̀ jẹ oogun buburu” dagba?
20 Bi o ti wu ki o ri, ibeere awadii ọkàn wò kan wà ti ẹnikọọkan wa nilati bi ara rẹ. ‘Bi mo ba ti pinnu lati maṣe gba ifajẹsinilara, eeṣe? Niti tootọ, ki ni o jẹ idi ipilẹ, ti o ṣe pataki mi?’
21 A ti mẹnukan pe awọn afidipo ti o gbeṣẹ wà si ẹ̀jẹ̀ ti ko fi ẹnikan sinu ọpọlọpọ ewu ti o so pọ mọ ifajẹsinilara. Awọn ewu iru bii imẹdọwu tabi AIDS ti sun ọpọlọpọ lati kọ ẹ̀jẹ̀ fun awọn idi ti ko tan mọ isin. Awọn kan jẹ́ abẹnugan nipa eyi, o fẹrẹ dabi ẹni pe wọn gbe akọle naa, “Ẹ̀jẹ̀ Jẹ Oogun Buburu.” O ṣeeṣe pe ki a fa Kristian kan wọnu itolọwọọwọ yẹn. Ṣugbọn o jẹ itolọwọọwọ lori opopona kan ti o di ni ipẹkun. Bawo ni o ti ri bẹẹ?
22. Oju-iwoye wo ti o jẹ otitọ nipa iwalaaye ati iku ni a gbọdọ ni? (Oniwaasu 7:2)
22 Awọn Kristian tootọ mọ daju pe ani pẹlu itọju iṣegun ti o dara julọ paapaa ninu awọn ile iwosan didara julọ, ni ori koko kan awọn eniyan ńkú. Pẹlu tabi lai si ifajẹsinilara, awọn eniyan ńkú. Lati sọ iyẹn kii ṣe jijẹ onigbagbọ ayanmọ. O jẹ didoju kọ otitọ. Iku jẹ otitọ igbesi-aye lonii. Awọn eniyan ti wọn ṣai ka ofin Ọlọrun si lori ẹ̀jẹ̀ niye igba nniriiri ipalara kiakia tabi ti a fi falẹ̀ lati inu ẹ̀jẹ̀. Awọn kan tilẹ nku lati inu ẹ̀jẹ̀ ti a fà si ni lara naa. Sibẹ, gbogbo wa gbọdọ mọ daju pe, awọn wọnni ti wọn nla ifajẹsinilara já ko tii jere iye ainipẹkun, nitori naa ẹ̀jẹ̀ ko fi ẹri han pe o ti gba iwalaaye wọn là titilọ gbére. Ni ọwọ keji ẹwẹ, ọpọ julọ awọn wọnni ti wọn kọ ẹ̀jẹ̀, nitori idi isin tabi ti iṣegun, sibẹ ti wọn gba itọju afidipo maa nṣe daradara lọna ilera. Wọn le tipa bayii mu iwalaaye wọn gun sii fun ọpọlọpọ ọdun—ṣugbọn kii ṣe lailopin.
23. Bawo ni awọn ofin Ọlọrun lori ẹ̀jẹ̀ ṣe tanmọ jijẹ ti a jẹ ẹlẹṣẹ ati aini fun irapada kan?
23 Pe gbogbo eniyan ti wọn wa laaye lonii jẹ alaipe ti wọn si nku diẹdiẹ ṣamọna wa sori koko pataki ohun ti Bibeli sọ nipa ẹ̀jẹ̀. Ọlọrun sọ fun gbogbo araye lati maṣe jẹ ẹ̀jẹ̀. Eeṣe? Nitori pe o duro fun iwalaaye. (Jẹnẹsisi 9:3-6) Ninu akojọ Ofin, ó ṣetolẹsẹẹsẹ awọn ofin ti ndari afiyesi si otitọ naa pe gbogbo eniyan jẹ ẹlẹṣẹ. Ọlọrun sọ fun awọn ọmọ Isirẹli pe nipa fifi ẹran ṣe irubọ, wọn le fihan pe ẹṣẹ wọn ni a nilati bo mọlẹ. (Lefitiku 4:4-7, 13-18, 22-30) Bi o tilẹ jẹ pe kii ṣe ohun ti o beere lọwọ wa lonii niyẹn, o ni ijẹpataki nisinsinyi. Ọlọrun pete lati pese ẹbọ ti o le ṣetutu ni kikun fun ẹṣẹ gbogbo onigbagbọ—irapada naa. (Matiu 20:28) Eyi ni idi ti a fi nilati ni oju-iwoye Ọlọrun nipa ẹ̀jẹ̀.
24. (a) Eeṣe ti yoo fi jẹ aṣiṣe lati ka awọn ewu ilera si koko pataki julọ nipa ẹ̀jẹ̀? (b) Niti gidi ki ni o nilati pilẹ oju-iwoye wa nipa lilo ẹ̀jẹ̀?
24 Yoo jẹ aṣiṣe lati gbajumọ awọn ewu ilera ẹ̀jẹ̀ ni pataki, nitori iyẹn kii ṣe ibi ti Ọlọrun dari afiyesi si. Awọn ọmọ Isirẹli ti le jere awọn anfaani ilera kan nipa ṣiṣai jẹ ẹ̀jẹ̀, gan an gẹgẹ bi wọn ti le janfaani nipa ṣiṣai jẹ ara ẹlẹdẹ tabi awọn ẹran jòkújòkú. (Deutaronomi 12:15, 16; 14:7, 8, 11, 12) Bi o ti wu ki o ri, ranti pe nigba ti Ọlọrun yọnda fun Noa lati jẹ ẹran, oun ko ka jijẹ ẹran ara iru awọn ẹran bẹẹ leewọ. Ṣugbọn oun paṣẹ pe awọn eniyan ko gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ̀. Ọlọrun ko dari afiyesi ni pataki si awọn ewu ilera ti o ṣeeṣe. Iyẹn kii ṣe koko pataki fun aṣẹ rẹ lori ẹ̀jẹ̀. Awọn olujọsin rẹ̀ nilati kọ̀ lati gbé iwalaaye wọn ró pẹlu ẹ̀jẹ̀, ni pataki kii ṣe nitori pe ṣiṣe bẹẹ jẹ alaiṣanfaani fun ilera, ṣugbọn nitori pe ko jẹ mimọ. Wọn kọ ẹ̀jẹ̀, kii ṣe nitori pe a ti sọ ọ́ di ibajẹ, ṣugbọn nitori pe o ṣeyebiye. Kiki nipasẹ ẹ̀jẹ̀ irubọ nikan ni wọn le ri idariji gbà.
25. Bawo ni ẹ̀jẹ̀ ṣe le gba iwalaaye là titilae?
25 Ohun kan naa ni o jẹ otitọ pẹlu wa. Ni Efesu 1:7, apọsteli Pọọlu ṣalaye pe: “Ninu [Kristi] ẹni ti awa ni irapada wa nipa ẹ̀jẹ̀ rẹ, idariji ẹṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ.” Bi Ọlọrun ba dari ẹṣẹ ẹnikan jì ti o si wo ẹni yẹn gẹgẹ bi olododo, ẹni naa ni ifojusọna fun iwalaaye ailopin. Nitori naa irapada ẹ̀jẹ̀ Jesu le gba iwalaaye là—titi ayeraye, nitootọ, titi ainipẹkun.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ofin naa pari pe: “Bi ẹ ba fi iṣọra pa ara yin mọ kuro ninu awọn nǹkan wọnyi, ẹ o ṣe rere. Alaafia fun yin!” (Iṣe 15:29, NW) Ọrọ naa “Alaafia fun yin” kii ṣe ileri ti o tumọsi pe, ‘Bi ẹyin ba fà sẹhin kuro ninu ẹ̀jẹ̀ tati agbere, ẹyin yoo ni ilera didara ju.’ O wulẹ jẹ ipari lẹta naa ni, iru bii, ‘O digbooṣe.’
b Ọpọlọpọ awọn afidipo gbigbeṣẹ si ifajẹsinilara ni a ṣatunyẹwo ninu iwe pẹlẹbẹ naa How Can Blood Save Your Life?, ti a tẹ̀ jade ni 1990 lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Njẹ O Le Ṣalaye?
◻ Ki ni idi pataki ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi kọ fifa ẹ̀jẹ̀ si ni lara?
◻ Ẹri wo ni o fidi rẹ mulẹ pe iduro Bibeli lori ẹ̀jẹ̀ ni ko ṣai bọgbọn mu lọna iṣegun?
◻ Bawo ni irapada ṣe so pọ mọ ofin Bibeli lori ẹ̀jẹ̀?
◻ Ọna kanṣoṣo wo ni ẹ̀jẹ̀ le gbà gba iwalaaye là titilae?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]
IFAJẸSINILARA ATI ÀKÓRÀN
Lẹhin atunyẹwo gbigbooro niti boya ifajẹsinilara le mu ki alaisan kan ṣí ara silẹ fun àkóràn, Dokita Neil Blumberg pari ero pe: “Ninu 12 iwadii [ọran naa] ti a ṣe niti iṣegun, 10 fihan pe ifajẹsinilara tanmọ ewu awọn àkóràn kokoro bacteria pupọ sii lọna hihan gbangba ati laisi idakun aisan miiran . . . Ni afikun, ifajẹsinilara ni akoko pipẹ diẹ ṣaaju iṣẹ abẹ le nipa lori agbara idena alaisan naa lodisi àkóràn bi ipa ti ifajẹ si ni lara ba ni lori agbara idena arun ba wa pẹ titi gẹgẹ bi awọn iwadii kan ti fihan . . . Bi a ba le mu awọn otitọ iwadii yii pọ sii ki a si fidi wọn mulẹ, o farahan pe awọn àkóràn mimuna lẹhin iṣẹ abẹ le jẹ ìjẹjade arun ṣiṣe pataki kanṣoṣo ti o wọpọ ti o niiṣe pẹlu fifa ẹjẹ ti o baramu sini lara.”—Transfusion Medicine Reviews, October 1990.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Awọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa ti a mu tobi. “Microliter ẹ̀jẹ̀ kọọkan (0.00003 ounce) ni lati million 4 si million 6 awọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa.”—“The World Book Encyclopedia”
[Credit Line]
Kunkel-CNRI/PHOTOTAKE NYC