“Mo Mà Nífẹ̀ẹ́ Òfin Rẹ O!”
“Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”—SÁÀMÙ 119:97.
1, 2. (a) Báwo ni ipò nǹkan ṣe rí fún ẹni tí Ọlọ́run mí sí láti kọ Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà? (b) Kí lohun tó ṣe nígbà tó wà nínú ìṣòro, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?
NǸKAN ò rọrùn rárá fún ẹni tó kọ Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà [119]. Àwọn ọ̀tá tí wọ́n jẹ́ ọ̀yájú tí wọn ò ka òfin Ọlọ́run sí ń fi í ṣẹ̀sín wọ́n sì ń bà á lórúkọ jẹ́. Àwọn ọmọ aládé ń gbìmọ̀ ọ̀tẹ̀ sí i, wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí i. Àwọn ọ̀tá yí i ká, kódà wọ́n tún fẹ́ pa á. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ò jẹ́ kó “lè sùn nítorí ẹ̀dùn-ọkàn.” (Sáàmù 119:9, 23, 28, 51, 61, 69, 85, 87, 161) Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ìṣòro yìí, onísáàmù náà kọrin pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”—Sáàmù 119:97.
2 O lè máa ronú pé, “Báwo ni òfin Ọlọ́run ṣe lè tu onísáàmù yìí nínú?” Dídá tó dá a lójú pé ọ̀rọ̀ òun jẹ Jèhófà lógún ló fún un lókun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá rẹ̀ ti fayé sú u, inú onísáàmù yìí dùn torí pé ó mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú pípa òfin Ọlọ́run mọ́. Ó mọ̀ pé ọ̀nà tó tọ́ ni Jèhófà gbà ń bá òun lò. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ìtọ́sọ́nà tó wà nínú òfin Ọlọ́run tí onísáàmù yìí ń tẹ̀ lé mú kó gbọ́n ju àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ, kódà ó tún dáàbò bò ó. Pípa tó ń pa òfin náà mọ́ sì jẹ́ kó ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn.—Sáàmù 119:1, 9, 65, 93, 98, 165.
3. Kí nìdí tí kò fi rọrùn fún àwọn Kristẹni láti máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run lónìí?
3 Lọ́nà kan náà, àwọn kan lára ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní ń rí ìdánwò ìgbàgbọ́ tó le koko. A lè má ní ìṣòro tó lè gbẹ̀mí ẹni bíi ti onísáàmù yìí, síbẹ̀ “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé yìí. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà láyìíká wa ni kì í tẹ̀ lé òfin Ọlọ́run. Wọ́n jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, agbéraga àti aláfojúdi. (2 Tímótì 3:1-5) Ìgbà gbogbo làwọn ọ̀dọ́ Kristẹni máa ń rí àwọn ohun tí kì í jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti hùwà mímọ́. Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ó lè má rọrùn láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti láti ṣe ohun tó tọ́. Báwo la ṣe wá lè dáàbò bo ara wa?
4. Báwo ni onísáàmù náà ṣe fi hàn pé òun mọrírì òfin Ọlọ́run, ǹjẹ́ kò yẹ káwa Kristẹni náà ṣe bíi tiẹ̀?
4 Ohun kan tó jẹ́ kí onísáàmù náà dúró ṣinṣin nígbà tó wà nínú ìṣòro ni pé ó máa ń wá àyè láti kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú òfin Ọlọ́run, ó sì máa ń ṣe àṣàrò lé e lórí. Ohun tó mú kó nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run nìyẹn. Àní, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹsẹ tó wà nínú Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà ló mẹ́nu kan àwọn kan lára ọ̀nà oríṣiríṣi tí òfin Jèhófà pín sí.a Lónìí, àwa Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́. (Kólósè 2:14) Àmọ́ àwọn ìlànà inú Òfin yẹn ṣì wúlò fún wa. Àwọn ìlànà wọ̀nyí tu onísáàmù náà nínú, wọ́n sì lè tu àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń sapá láti borí ìṣòro tó wà lóde òní náà nínú.
5. Kí làwọn kókó tá a fẹ́ gbé yẹ̀ wò nínú Òfin Mósè?
5 Ẹ jẹ́ ká wo bí kókó mẹ́ta péré nínú Òfin Mósè ṣe lè fún wa níṣìírí. Àwọn ni ètò tí Ọlọ́run ṣe nípa Sábáàtì, ètò tó ṣe nípa pípèéṣẹ́ àti òfin tó ṣe nípa ojúkòkòrò. Tá a bá gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yẹ̀ wò, a ó rí i pé ó ṣe pàtàkì ká lóye àwọn ìlànà tó wà nínú àwọn òfin wọ̀nyí ká bàa lè fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro ní àkókò tá à ń gbé yìí.
Ṣíṣe Ohun Tó Ní Í Ṣe Pẹ̀lú Ìjọsìn Wa sí Ọlọ́run
6. Àwọn ohun wo ló ṣe pàtàkì pé kí gbogbo èèyàn ní?
6 Ọlọ́run dá àwa èèyàn lọ́nà tí a ó fi nílò àwọn nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, kéèyàn tó lè ní ìlera tó dára, èèyàn gbọ́dọ̀ ní oúnjẹ, ohun mímu àti ibùgbé tó dára. Síbẹ̀, àwa èèyàn tún ní láti bójú tó “àìní [wa] nípa ti ẹ̀mí.” A ò lè ní ojúlówó ayọ̀ tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 5:3) Bíbójútó àìní wa nípa tẹ̀mí, ìyẹn ṣíṣe ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa, ṣe pàtàkì gidigidi lójú Jèhófà débi pé ó pàṣẹ fáwọn èèyàn rẹ̀ láti máa dá àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe dúró lọ́jọ́ kan lọ́sẹ̀ kí wọ́n lè fi ọjọ́ náà ṣe àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run.
7, 8. (a) Báwo ni Ọlọ́run ṣe fi ìyàtọ̀ sáàárín Sábáàtì àtàwọn ọjọ́ yòókù? (b) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ṣètò Sábáàtì?
7 Ètò tí Ọlọ́run ṣe nípa Sábáàtì fi hàn kedere pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa wá àyè láti ṣe ohun tó máa mú kí àjọṣe òun àti Ọlọ́run dán mọ́rán sí i. Ìtàn bí Jèhófà ṣe pèsè mánà nínú aginjù ni Bíbélì ń sọ níbi tí ọ̀rọ̀ náà “sábáàtì” ti kọ́kọ́ fara hàn. Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé ọjọ́ kìíní sí ọjọ́ kẹfà ni kí wọ́n máa kó oúnjẹ tí òun pèsè lọ́nà ìyanu yìí. Àmọ́, kí wọ́n kó “oúnjẹ ọjọ́ méjì ní ọjọ́ kẹfà” torí pé kò ní sí nǹkan kan láti kó lọ́jọ́ keje. Ọjọ́ keje yóò jẹ́ “sábáàtì mímọ́ fún Jèhófà,” ìyẹn ọjọ́ tí kálukú wọn yóò wà nílé tí wọn ò ní jáde. (Ẹ́kísódù 16:13-30) Òfin kan nínú Òfin Mẹ́wàá sọ pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí lọ́jọ́ Sábáàtì. Ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ náà. Ikú sì ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tó bá rú òfin yìí nínú wọn.—Ẹ́kísódù 20:8-11; Númérì 15:32-36.
8 Òfin Sábáàtì fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kí nǹkan máa lọ déédéé fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì fẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú òun. Abájọ tí Jésù fi sọ pé: “Sábáàtì wáyé nítorí ènìyàn, kì í sì í ṣe pé ènìyàn wáyé nítorí sábáàtì.” (Máàkù 2:27) Kì í ṣe pé Sábáàtì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní láti sinmi nìkan ni, ó tún fún wọn láǹfààní láti sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wọn àti láti fi ìfẹ́ tí wọ́n ní sí i hàn. (Diutarónómì 5:12) Ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, irú bí ìjọsìn ìdílé, àdúrà gbígbà àti ṣíṣàṣàrò lórí Òfin Ọlọ́run. Ètò yìí kò ní jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi gbogbo àkókò àti okun wọn lépa àwọn nǹkan tara. Sábáàtì tí wọ́n ń ṣe jẹ́ kí wọ́n máa rántí pé àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wọn. Jésù tún mẹ́nu kan ìlànà pàtàkì tí kò ṣeé yí padà yẹn nígbà tó sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.’”—Mátíù 4:4.
9. Ẹ̀kọ́ wo làwa Kristẹni lè rí kọ́ látinú ètò Sábáàtì?
9 Òfin tó sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa sinmi lọ́jọ́ Sábáàtì kò de àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí, síbẹ̀ ètò Sábáàtì ju ohun tó yẹ kéèyàn kàn fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀ lásán lọ. (Kólósè 2:16) Ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí máa rán wa létí pé àwọn ohun tó máa jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run dán mọ́rán sí i ló yẹ kó gbapò iwájú nígbèésí ayé wa? A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn nǹkan tara tàbí eré ìnàjú gbà wá lọ́kàn débi pé a ò ní ráyè fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. (Hébérù 4:9,10) Nítorí náà, á dára ká bi ara wa pé: “Kí ló ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé mi? Ǹjẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́, àdúrà, ìpàdé ìjọ àti ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló gbawájú nínú ìgbésí ayé mi? Àbí kẹ̀, àwọn nǹkan mìíràn ni mò ń jẹ́ kí wọ́n gba àkókò mi tí mi ò fi rí àyè fún àwọn nǹkan tẹ̀mí wọ̀nyí?” Bí a bá fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́ láyé wa, Jèhófà jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn ohun kòṣeémánìí nígbèésí ayé ò ní wọ́n wa.—Mátíù 6:24-33.
10. Báwo la ṣe lè jàǹfààní tá a bá ń ya àkókò sọ́tọ̀ fún àwọn nǹkan tẹ̀mí?
10 Tí a bá ń ya àkókò sọ́tọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìwé mìíràn tó ń ṣàlàyé Bíbélì tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ inú wọn, èyí lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Jákọ́bù 4:8) Láti nǹkan bí ogójì ọdún sẹ́yìn ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Susan ti ń ya àkókò sọ́tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Àmọ́ ó ní ó sábà máa ń sú òun nígbà tí òun kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, pé kò rọrùn fún òun rárá. Àmọ́ bó ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i ló túbọ̀ ń gbádùn rẹ̀. Ní báyìí, inú rẹ̀ kì í dùn rárá bí kò bá dá kẹ́kọ̀ọ́ nítorí ìdí kan tàbí òmíràn. Ó sọ pé: “Ìkẹ́kọ̀ọ́ ti jẹ́ kí n mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí bàbá. Mo lè gbẹ́kẹ̀ lé e, mo sì tún lè gbàdúrà sí i fàlàlà. Ó máa ń mórí mi wú gan-an ni láti ronú nípa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó, bó ṣe ń bójú tó èmi alára, àti bó ṣe ń ràn mí lọ́wọ́.” Ká sòótọ́, ayọ̀ ńláǹlà làwa náà máa ní bí a bá ń ṣe àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run déédéé!
Òfin Tí Ọlọ́run Ṣe Nípa Pípèéṣẹ́
11. Ètò wo ni Ọlọ́run ṣe nípa pípèéṣẹ́?
11 Ìlànà kejì tó wà nínú Òfin Mósè, èyí tó fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ kí nǹkan lọ déédéé fún àwọn èèyàn rẹ̀, ni àǹfààní tí wọ́n ní láti pèéṣẹ́. Jèhófà pàṣẹ pé bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ àgbẹ̀ bá kórè oko wọn, wọ́n ní láti gba àwọn aláìní láyè láti wá kórè àwọn ohun tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn táwọn olùkórè bá ti ṣiṣẹ́ wọn tán. Àwọn àgbẹ̀ kò gbọ́dọ̀ kórè eteetí oko wọn pátápátá bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọ́dọ̀ padà wá ká èso àjàrà tàbí ólífì tó bá ṣẹ́ kù lára igi. Wọn kò gbọ́dọ̀ padà wá kó àwọn ìtí ọkà tí wọ́n bá gbàgbé sínú oko. Èyí jẹ́ ètò onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ṣe nítorí àwọn tálákà, àwọn àtìpó, àwọn ọmọ òrukàn àtàwọn opó. Lóòótọ́ o, pípèéṣẹ́ kì í ṣe iṣẹ́ kékeré, síbẹ̀ bí wọ́n bá ṣe é, kò ní sí pé wọ́n lọ ń ṣagbe.—Léfítíkù 19:9, 10; Diutarónómì 24:19-22; Sáàmù 37:25.
12. Àǹfààní wo ni ètò pípèéṣẹ́ fún àwọn àgbẹ̀?
12 Òfin tí Ọlọ́run ṣe nípa pípèéṣẹ́ kò sọ bí irúgbìn táwọn àgbẹ̀ máa fi sílẹ̀ fún àwọn aláìní ṣe gbọ́dọ̀ pọ̀ tó. Àwọn àgbẹ̀ fúnra wọn ló máa pinnu bí ọkà tí wọ́n máa fi sílẹ̀ láìkórè ní eteetí oko wọn ṣe máa pọ̀ tó. Bí Ọlọ́run ṣe fún àwọn àgbẹ̀ láyè láti pinnu ohun tí wọ́n máa fún àwọn aláìní yìí kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìwà ọ̀làwọ́. Ó fún wọn láǹfààní láti fi ìmoore wọn hàn sí Olùpèsè ìkórè, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe ni “ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí àwọn òtòṣì ń [yin Olùṣẹ̀dá rẹ̀] lógo.” (Òwe 14:31) Ẹnì kan tó jẹ́ ọlọ́làwọ́ bẹ́ẹ̀ ni Bóásì. Ó rí i dájú pé obìnrin opó kan tó ń jẹ́ Rúùtù tó máa ń pèéṣẹ́ lóko rẹ̀ ń rí ọkà púpọ̀. Jèhófà sì rọ̀jò ìbùkún sórí Bóásì nítorí ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ yìí.—Rúùtù 2:15, 16; 4:21, 22; Òwe 19:17.
13. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú òfin ayé ìgbàanì tí Ọlọ́run ṣe nípa pípèéṣẹ́?
13 Ìlànà tó wà nínú òfin tí Ọlọ́run ṣe nípa pípèéṣẹ́ kò tíì yí padà. Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ọ̀làwọ́, pàápàá sí àwọn aláìní. Bí a bá sì ṣe lawọ́ sí ni ìbùkún wa ṣe máa pọ̀ tó. Jésù sọ pe: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín. Wọn yóò da òṣùwọ̀n àtàtà, tí a kì mọ́lẹ̀, tí a mì pọ̀, tí ó sì kún àkúnwọ́sílẹ̀ sórí itan yín. Nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n padà fún yín.”—Lúùkù 6:38.
14, 15. Báwo la ṣe lè fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn, àwọn àǹfààní wo ló sì ṣeé ṣe kí èyí ṣe àwa àtàwọn tá a ràn lọ́wọ́?
14 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé ká “máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Nípa bẹ́ẹ̀, kò sí àní-àní pé ó yẹ ká máa ṣàníyàn nípa bí àwọn ará wa á ṣe rí ìtọ́sọ́nà Bíbélì tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbàkigbà tí wọ́n bá rí ìdánwò ìgbàgbọ́. Àmọ́, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí wọ́n tún nílò ìrànlọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì, bí àpẹẹrẹ, bóyá nípa bí wọ́n ṣe máa dé Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí bí wọ́n ṣe máa ra ohun tí wọ́n máa jẹ? Ǹjẹ́ àwọn àgbàlagbà, àwọn aláìsàn tàbí àwọn tí kò lè jáde nílé wà nínú ìjọ yín tí wọ́n á fẹ́ kí ẹnì kan wá kí wọn tàbí kó wá bá wọn ṣe nǹkan kan? Bí a bá ń jẹ́ kí ìṣòro àwọn ará wa ká wa lára, Jèhófà yóò lè rí wa lò láti dáhùn àdúrà àwọn tó jẹ́ aláìní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe àwa Kristẹni ni pé ká máa ran ara wa lọ́wọ́, síbẹ̀ ẹni tó ń ṣèrànwọ́ náà tún máa ń jàǹfààní. Tá a bá ń fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sáwọn tá a jọ ń sin Ọlọ́run, a ó ní ìdùnnú àti ayọ̀ tó pọ̀ gan-an, inú Jèhófà yóò sì dùn sí wa.—Òwe 15:29.
15 Ọ̀nà pàtàkì mìíràn táwa Kristẹni gbà ń fi hàn pé a kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan ni pé a máa ń lo àkókò àti okun wa láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú. (Mátíù 28:19, 20) Ẹni tó bá ti ran ẹlòmíràn lọ́wọ́ débi pé onítọ̀hún ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà yóò mọ̀ pé òótọ́ lohun tí Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
Ṣíṣọ́ra fún Ojúkòkòrò
16, 17. Kí ni òfin kẹwàá kà léèwọ̀, kí sì nìdí tó fi kà á léèwọ̀?
16 Ohun kẹta tá a máa gbé yẹ̀ wò nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni òfin kẹwàá tó ka ojúkòkòrò léèwọ̀. Òfin náà sọ pé: “Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ ilé ọmọnìkejì rẹ. Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ aya ọmọnìkejì rẹ, tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.” (Ẹ́kísódù 20:17) Kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè múni sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nítorí pé kò sẹ́ni tó lè rí ọkàn ẹlòmíì. Àmọ́ o, òfin pàtàkì yìí mú kí òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ga ju òfin èèyàn lọ. Ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé Jèhófà, ẹni tó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn, gan-an lẹni tí wọ́n máa jíhìn fún. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Ìyẹn nìkan kọ́ o, òfin yìí tún jẹ́ kéèyàn mọ ohun tó ń mú àwọn èèyàn hu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà tí kò bófin mu.—Jákọ́bù 1:14.
17 Òfin tí Ọlọ́run ṣe nípa ojúkòkòrò jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ rí i pé wọ́n ní láti jìnnà sí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, ìwọra àti ìráhùn nípa bí ipò nǹkan ṣe rí fún wọn. Bákan náà, òfin yìí tún jẹ́ kí wọ́n jìnnà sí olè jíjà àti ìṣekúṣe. Kò sí báwọn kan ò ṣe ní ní àwọn nǹkan tara tó wù wá tàbí kí wọ́n yọrí ọlá jù wa lọ lọ́nà kan tàbí òmíràn. Tí a bá lọ ń jẹ́ kí ìrònú nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gbà wá lọ́kàn, inú wa lè máa bà jẹ́ ká sì máa ṣe ìlara àwọn ẹlòmíì. Bíbélì sọ pe ojúkòkòrò wà lára ohun tó ń fi hàn pé èèyàn ní “ipò èrò-orí tí kò ní ìtẹ́wọ́gbà,” èyí tó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run kò fẹ́ kéèyàn jẹ́ olójúkòkòrò. Nítorí náà, ohun tó dára jù ni pé ká má ṣe jẹ́ olójúkòkòrò.—Róòmù 1:28-30.
18. Ẹ̀mí wo ló gba àwọn èèyàn lọ́kàn lóde òní, àwọn ìṣòro wo ló sì lè kó ni sí?
18 Ẹ̀mí tó gba àwọn èèyàn lọ́kàn lóde òní ni ìlépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti ìbánidíje. Àwọn oníṣòwò máa ń lo ìpolówó ọjà láti mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe jáde. Ńṣe ni wọ́n sì máa ń ṣe ìpolówó yìí lọ́nà tó fi máa dà bíi pé téèyàn ò bá ra àwọn nǹkan tuntun wọ̀nyẹn, kò lè láyọ̀. Irú ẹ̀mí tí Òfin Jèhófà sì kà léèwọ̀ gan-an nìyí. Ohun mìíràn tó jọ ọ́, èyí tí Òfin Jèhófà tún kà léèwọ̀ ni lílépa ipò ọlá láìka ohunkóhun tó lè náni sí àti kíkó ọrọ̀ jọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ kò dára, ó ní: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:9, 10.
19, 20. (a) Àwọn ohun wo ló ṣe pàtàkì gan-an fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run mọ àwọn ewu tó wà nínú ìlépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, wọ́n sì máa ń ṣọ́ra kí wọ́n má kó sínú ewu wọ̀nyẹn. Bí àpẹẹrẹ, onísáàmù náà gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Tẹ ọkàn-àyà mi síhà àwọn ìránnilétí rẹ, kí ó má sì jẹ́ sí èrè. Òfin ẹnu rẹ dára fún mi, pàápàá ju ẹgbẹẹgbẹ̀rún wúrà àti fàdákà lọ.” (Sáàmù 119:36, 72) Tó bá dá wa lójú pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, a ó máa kíyè sára ká má bàa jìn sí ọ̀fìn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, ojúkòkòrò àti àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ipò téèyàn wà nígbèésí ayé. ‘Ìfọkànsin Ọlọ́run’ ló máa ń jẹ́ kéèyàn lè ní ìbùkún tó ga jù lọ kì í ṣe kíkó nǹkan tara jọ.—1 Tímótì 6:6.
20 Àwọn ìlànà tó wà nínú Òfin tí Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ wúlò gidigidi lákòókò tó le gan-an tá à ń gbé yìí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wúlò nígbà tí Jèhófà fi wọ́n fún Mósè. Bí a bá ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà wọ̀nyí tó ni wọn yóò ṣe máa yé wa sí i tí a ó sì túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ wọn, èyí á sì jẹ́ ká túbọ̀ láyọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì ló wà nínú Òfin náà fún àǹfààní wa, ìtàn ìgbésí ayé àti ìrírí àwọn èèyàn tó wà nínú Bíbélì sì jẹ́ ká rí bí ẹ̀kọ́ wọ̀nyí ti ṣe pàtàkì tó. A ó gbé díẹ̀ lára ìtàn wọ̀nyí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tá a bá yọwọ́ ẹsẹ mẹ́rin kan nínú Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà, gbogbo ẹsẹ yòókù ló mẹ́nu kan, ó kéré tán, ọ̀kan lára nǹkan wọ̀nyí: àṣẹ, ìpinnu ìdájọ́, òfin, àṣẹ ìtọ́ni, ìlànà, ìránnilétí, àsọjáde, ìlànà àgbékalẹ̀, ọ̀nà tàbí ọ̀rọ̀ Jèhófà.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Kí nìdí tí ẹni tó kọ Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà fi nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà?
• Kí làwa Kristẹni lè rí kọ́ látinú ètò tí Ọlọ́run ṣe nípa Sábáàtì?
• Báwo ni òfin tí Ọlọ́run ṣe nípa pípèéṣẹ́ ṣe wúlò tó?
• Báwo ni òfin tí Ọlọ́run ṣe nípa ojúkòkòrò ṣe lè dáàbò bò wá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Kí ni òfin Sábáàtì fi hàn kedere pé ó ṣe pàtàkì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹ̀kọ́ wo ni òfin pípèéṣẹ́ kọ́ wa?