O Lè Mú Kí Agbára Ìrántí Rẹ Já Fáfá
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN dá ọpọlọ èèyàn lọ́nà tó fi ní àgbàyanu agbára láti rántí nǹkan. Ó ṣeé gẹ́gẹ́ bí ibi ìkó-nǹkan-sí téèyàn ti lè mú lára ohun tó wà níbẹ̀ lò láìpàdánù àwọn ohun iyebíye tó ti kó síbẹ̀. Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá ọpọlọ bá ohun tó pète rẹ̀ fún mu, pé kí ẹ̀dá èèyàn wà láàyè títí láé.—Sm. 139:14; Jòh. 17:3.
Ṣùgbọ́n o lè rò pé o ti lè gbàgbé nǹkan jù. Àfi bíi pé ohun tó wà lọ́pọlọ rẹ máa ń pòórá nígbà tó o bá fẹ́ rántí rẹ̀. Kí lo lè ṣe láti mú kí agbára ìrántí rẹ já fáfá?
Nífẹ̀ẹ́ sí Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀
Nínífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká ẹni jẹ́ kókó pàtàkì kan tó lè mú kí agbára ìrántí ẹni já fáfá. Bó bá ti di àṣà wa pé ká máa kíyè sí nǹkan, ká máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn èèyàn, ká sì máa fọkàn sí ohun tó ń lọ ní àyíká wa, iyè wa yóò jí pépé. Ìyẹn á jẹ́ kó rọrùn fún wa bákan náà láti fọkàn sí àwọn ohun tó wúlò gidigidi, nígbà tí a bá kà nípa wọn tàbí tí a bá gbọ́ wọn.
Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé èèyàn máa ń gbàgbé orúkọ àwọn ẹlòmíràn. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a mọ̀ pé àwọn èèyàn ṣe pàtàkì, ìyẹn àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa, àwọn tí a wàásù fún, àti àwọn ẹlòmíràn tí a jọ ń ní àjọṣe bí a ṣe ń bójú tó àwọn nǹkan pàtàkì ní ìgbésí ayé. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa rántí àwọn orúkọ tí kò yẹ kí á gbàgbé rárá? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ orúkọ àwọn èèyàn mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n lára àwọn tó wà nínú ìjọ kan tó kọ lẹ́tà sí. Bó ṣe nífẹ̀ẹ́ sí wọn tó hàn nítorí pé, yàtọ̀ sí pé ó mọ orúkọ wọn, ó tún mẹ́nu kan àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ pàtó kan nípa ọ̀pọ̀ lára wọn. (Róòmù 16:3-16) Àwọn kan nínú àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní máa ń ṣe dáadáa gan-an ní ti ká rántí orúkọ àwọn èèyàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń ti ìjọ kan bọ́ sí òmíràn. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Ó ṣeé ṣe kó ti di àṣà wọn láti máa pe orúkọ ẹnì kan lọ́pọ̀ ìgbà tí wọ́n bá ń bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́. Wọ́n á sapá láti rántí bí ìrísí ojú ẹni tó ń jẹ́ orúkọ yẹn ṣe rí. Ẹ̀wẹ̀, wọ́n máa ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn èèyàn lọ́kan-ò-jọ̀kan lóde ẹ̀rí tàbí nígbà tí wọ́n bá jọ ń jẹun. Bí ìwọ náà bá bá ẹnì kan pàdé, ṣé wàá lè rántí orúkọ rẹ̀? Kọ́kọ́ rí i pé ìdí pàtàkì kan wà tó fi yẹ kí o rántí orúkọ yẹn; lẹ́yìn náà wá gbìyànjú láti lò lára àwọn àbá tí a dá lókè yìí.
Rírántí ohun tí o kà tún ṣe pàtàkì pẹ̀lú. Kí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ ṣe dáadáa lórí kókó yìí? Lára ohun tó ń ṣèrànlọ́wọ́ ni nínífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ò ń kà àti pé kó tún yé ọ. Ó yẹ kí ohun tó ò ń kà jẹ ọ́ lógún gan-an débi pé yóò gba gbogbo àfiyèsí rẹ. O kò ní lè rántí ohun tó ò ń kà bó bá jẹ́ pé ibòmíràn ni ọkàn rẹ wà nígbà tí ò ń kàwé. Ohun tó ò ń kà yóò túbọ̀ yé ọ sí i bí o bá ń fi í wé àwọn nǹkan tí o mọ̀, àti ìmọ̀ tó o ti ní tẹ́lẹ̀. Bi ara rẹ léèrè pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè lo ìsọfúnni yìí ní ìgbésí ayé mi, ìgbà wo ni mo sì lè lò ó? Báwo ni mo ṣe lè lò ó láti fi ran ẹlòmíràn lọ́wọ́?’ Òye á sì túbọ̀ yé ọ sí i bí ó bá jẹ́ pé gbólóhùn ọ̀rọ̀ lo máa ń kà dípò kíka ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan. Ohun tí ìwé yẹn ń wí àti àwọn lájorí èrò ibẹ̀ á wá tètè yé ọ, èyí á mú kí wọ́n rọrùn láti rántí.
Fara Balẹ̀ Ṣàtúnyẹ̀wò
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ sọ nípa bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti máa ṣàtúnyẹ̀wò. Nínú ìwádìí kan, ọ̀jọ̀gbọ́n ní yunifásítì kan fi hàn gbangba pé béèyàn bá fi ìṣẹ́jú kan ṣàtúnyẹ̀wò lójú ẹsẹ̀, ohun tó máa rántí yóò jẹ́ ìlọ́po méjì èyí tí ì bá jẹ́ tẹ́lẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, gbàrà tí o bá ti parí ìwé tí ò ń kà, tàbí tí o bá ti parí apá pàtàkì kan nínú rẹ̀, fọkàn ṣàtúnyẹ̀wò àwọn lájorí èrò inú rẹ̀ kí o lè fi wọ́n sọ́kàn. Ronú nípa bí o ṣe lè fúnra rẹ ṣàlàyé àwọn kókó tuntun tó o bá kọ́. Fífi ọkàn ṣàtúnyẹ̀wò ohun tó o kà ní kété tó o bá ti kà á tán kò ní jẹ́ kó o tètè gbàgbé kókó yẹn.
Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ sí ìgbà yẹn, wá àyè láti ṣàtúnyẹ̀wò ohun tó o kà nípa fífi ìsọfúnni náà tó ẹlòmíràn létí. O lè sọ ọ́ fún ará ilé rẹ, ẹnì kan nínú ìjọ, ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, ẹni tẹ́ ẹ jọ ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́, aládùúgbò rẹ, tàbí ẹnì kan tó o bá bá pàdé ní òde ẹ̀rí. Má kàn tún àwọn kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀ sọ, tún gbìyànjú láti rí i pé o ṣe àlàyé inú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ṣe nípa wọn pẹ̀lú. Bó o bá ṣe èyí, ìwọ yóò jàǹfààní, yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi àwọn ohun tó ṣe pàtàkì sọ́kàn; yóò sì tún ṣàǹfààní fún àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.
Ṣàṣàrò Lórí Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì
Láfikún sí ṣíṣàtúnyẹ̀wò ohun tó o ti kọ́ àti sísọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíràn, ìwọ yóò rí i pé tó o bá fúnra rẹ ń ṣàṣàrò lórí àwọn ohun pàtàkì tí o ti kọ́, yóò ṣe ọ́ láǹfààní. Ásáfù àti Dáfídì tí wọ́n jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì ṣe bẹ́ẹ̀. Ásáfù sọ pé: “Èmi yóò rántí àwọn iṣẹ́ Jáà; nítorí ó dájú pé èmi yóò rántí ìṣe ìyanu rẹ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.” (Sm. 77:11, 12) Bákan náà, Dáfídì kọ̀wé pé: “Mo ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní àwọn ìṣọ́ òru,” ó sì tún sọ pé: “Mo ti rántí àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn; mo ti ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ.” (Sm. 63:6; 143:5) Ǹjẹ́ o máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?
Tí o bá ń ronú jinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, lórí àwọn ìṣe Jèhófà, àwọn ànímọ́ rẹ̀, àti àwọn ohun tó sọ pé òun ń fẹ́, yóò ṣèrànwọ́ fún ọ ju rírántí àwọn kókó pàtàkì nìkan lọ. Bí ó bá ti di àṣà rẹ láti máa ronú lọ́nà bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ kí àwọn nǹkan tó ṣe kókó gidi wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Yóò tún irú ẹni tó o jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ṣe. Àwọn nǹkan tí yóò máa wà ní ìrántí rẹ yóò jẹ́ àwọn ohun tí ò ń rò lọ́kàn.—Sm. 119:16.
Ipa Tí Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Kó
Bó bá di pé kí á rántí àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ nípa àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà àti ohun tí Jésù Kristi sọ, a kò dá ìyẹn dá àwa nìkan. Ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé kó tó kú, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nígbà tí èmi ṣì wà pẹ̀lú yín ni mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín. Ṣùgbọ́n olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, èyí tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, èyíinì ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, tí yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín.” (Jòh. 14:25, 26) Mátíù àti Jòhánù ń bẹ lára àwọn tó wà níbẹ̀ nígbà yẹn. Ṣé ẹ̀mí mímọ́ sì wá jẹ́ irú olùrànlọ́wọ́ yẹn fún wọn lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ní nǹkan bí ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, Mátíù parí kíkọ àkọ́kọ́ nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtàn ìgbésí ayé Kristi, títí kan ìtàn pàtàkì bí Ìwàásù Lórí Òkè àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àmì nípa wíwàníhìn-ín Kristi àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan. Ní ọdún márùndínláàádọ́rin lẹ́yìn ikú Jésù, àpọ́sítélì Jòhánù kọ ìwé Ìhìn Rere tirẹ̀, títí kan kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tí Jésù sọ ní alẹ́ tí ó lò kẹ́yìn, ní èyí tí àwọn àpọ́sítélì àti Olúwa fi jọ wà pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé kí ó tó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀. Ó dájú pé Mátíù àti Jòhánù rántí àwọn ohun tí Jésù sọ tí ó sì ṣe nígbà tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ kó ipa pàtàkì nínú rírí i dájú pé wọn kò gbàgbé àwọn kókó pàtàkì tí Jèhófà ń fẹ́ kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ǹjẹ́ ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni! Lóòótọ́, ẹ̀mí mímọ́ kì í fi ohun tí èèyàn kò tíì kọ́ rárá sí i lọ́kàn, àmọ́, ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ti pé ó ń mú kí á rántí àwọn ohun pàtàkì tí a ti kọ́ tẹ́lẹ̀. (Lúùkù 11:13; 1 Jòh. 5:14) Bí ìlò rẹ̀ bá sì ti yá, yóò mú kí iyè wa sọ sí i tí a ó fi lè “máa rántí àwọn àsọjáde tí àwọn wòlíì mímọ́ ti sọ ní ìṣáájú àti àṣẹ Olúwa àti Olùgbàlà.”—2 Pét. 3:1, 2.
‘Ẹ Má Ṣe Gbàgbé’
Jèhófà kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọnmọ gbọnmọ pé: ‘Ẹ má ṣe gbàgbé o.’ Kì í ṣe pé ó ń retí pé gbogbo ohun tí òun ṣe ni kí wọ́n máa rántí lọ́nà tó pé pérépéré. Ṣùgbọ́n wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìlépa ohun tara wọn wá gbà wọ́n lọ́kàn débi pé wọn ò ní fi ohun tí Jèhófà ṣe sọ́kàn tààrà mọ́. Gbogbo ìgbà ni wọ́n ní láti máa rántí bí Jèhófà ṣe dá wọn nídè nígbà tí áńgẹ́lì rẹ̀ pa àwọn àkọ́bí ní Íjíbítì àti nígbà tí Jèhófà pín Òkun Pupa níyà tó sì tún mú kó padà bọ̀ sípò, ó sì mú kí Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ kú sómi. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti rántí pé Ọlọ́run fún àwọn ní Òfin lórí Òkè Sínáì àti pé ó ṣamọ̀nà àwọn la aginjù kọjá wọnú Ilẹ̀ Ìlérí. Wọn kò ní gbàgbé ní ti pé bí wọ́n bá ti ń rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí wọ́n á jẹ́ kó nípa tó jinlẹ̀ lórí ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́.—Diu. 4:9, 10; 8:10-18; Ẹ́kís. 12:24-27; Sm. 136:15.
Àwa pẹ̀lú ní láti kíyè sára ká má ṣe gbàgbé. Bí a ṣe ń forí ti pákáǹleke ayé yìí, a ní láti máa rántí Jèhófà, kí á máa fi irú Ọlọ́run tó jẹ́ sọ́kàn. Kò tún yẹ ká gbàgbé ìfẹ́ tó fi hàn ní ti fífi tó fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ẹni tó pèsè ìràpadà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a lè ní ìwàláàyè pípé títí láé. (Sm. 103:2, 8; 106:7, 13; Jòh. 3:16; Róòmù 6:23) Kíka Bíbélì déédéé, àti kíkópa lójú méjèèjì nínú àwọn ìpàdé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni yóò mú kí àwọn òtítọ́ tó ṣeyebíye wọ̀nyí máa wà lọ́kàn wa nígbà gbogbo.
Bó bá di pé o fẹ́ ṣe ìpinnu, ì báà jẹ́ ìpinnu ńlá tàbí kékeré, rántí àwọn òtítọ́ pàtàkì wọ̀nyí, kí o sì jẹ́ kí wọ́n darí ìrònú rẹ. Má ṣe gbàgbé o. Yíjú sí Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà. Dípò kí o kàn fi ojú ti ara aláìpé wo àwọn ọ̀ràn, tàbí kí o tẹ̀ lé ohun tí ọkàn rẹ tí ó jẹ́ aláìpé bá ṣáà ti sọ, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Ìmọ̀ràn tàbí àwọn ìlànà wo látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló yẹ kó nípa lórí ìpinnu mi?’ (Òwe 3:5-7; 28:26) O kò lè rántí ohun tí o kò kà rí tàbí nǹkan tí o kò gbọ́ rí. Ṣùgbọ́n bí ìmọ̀ pípéye àti ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà bá ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni àkójọ ìmọ̀ tí ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú kó o rántí yóò ṣe máa pọ̀ sí i, fífẹ́ràn tó o túbọ̀ ń fẹ́ràn Jèhófà yóò sì wá sún ọ láti hùwà ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀.