ORÍ KARÙN-ÚN
Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
1, 2. Ta ni ó yẹ kí àwọn òbí wò fún ìrànlọ́wọ́ nínú títọ́ àwọn ọmọ wọn?
ÒBÍ onímọrírì kan sọ ní nǹkan bí 3,000 ọdún sẹ́yìn pé: “Àwọn ọmọ ni ìní Oluwa.” (Orin Dafidi 127:3) Ní tòótọ́, ayọ̀ jíjẹ́ òbí jẹ́ èrè ṣíṣeyebíye láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó púpọ̀ jù lọ tọkọtaya. Bí ó ti wù kí ó rí, kì í pẹ́ tí àwọn tí ó ní ọmọ fi ń mọ̀ pé, ní àfikún sí ayọ̀ náà, jíjẹ́ òbí ń mú ẹrù iṣẹ́ lọ́wọ́.
2 Pàápàá jù lọ lónìí, títọ́ ọmọ dàgbà jẹ́ ẹrù iṣẹ́ ńlá kan. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ ti ṣe é ní àṣeyọrí, onipsalmu tí a mí sí náà fi ọ̀nà náà hàn, ní wíwí pé: “Bí kò ṣe pé Oluwa bá kọ́ ilé náà, àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán.” (Orin Dafidi 127:1) Bí o bá ṣe tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jehofa pẹ́kípẹ́kí tó, ni ìwọ yóò ṣe jẹ́ òbí dáradára tó. Bibeli sọ pé: “Fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Oluwa; má sì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara rẹ.” (Owe 3:5) O ha múra tán láti fetí sí ìmọ̀ràn Jehofa bí o ti ń dáwọ́ lé ìwéwèé ológún ọdún ti títọ́ ọmọ?
TÍTẸ́WỌ́ GBA OJÚ ÌWÒYE BIBELI
3. Ẹrù iṣẹ́ wo ni àwọn bàbá ní nínú títọ́ àwọn ọmọ?
3 Nínú ọ̀pọ̀ agbo ilé kárí ayé, àwọn ọkùnrin ka títọ́ ọmọ sí iṣẹ́ obìnrin ní pàtàkì. Lóòótọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣàlàyé pé ẹrù iṣẹ́ bàbá jẹ́ ti ògúnnágbòǹgbò agbọ́bùkátà. Bí ó ti wù kí ó rí, ó tún sọ pé ó ní ẹrù iṣẹ́ nínú ilé. Bibeli sọ pé: “Múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ lóde, kí o sì fi ìtara túlẹ̀ ní oko rẹ; níkẹyìn èyí, kí o sì kọ́ ilé rẹ.” (Owe 24:27) Ní ojú Ọlọrun, bàbá àti ìyá jẹ́ alájùmọ̀ṣiṣẹ́ nínú dídá ọmọ lẹ́kọ̀ọ́.—Owe 1:8, 9.
4. Èé ṣe tí a kò fi gbọ́dọ̀ wo ọmọkùnrin gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó lọ́lá ju ọmọbìnrin lọ?
4 Ojú wo ni o fi ń wo àwọn ọmọ rẹ? Ìròyìn sọ pé, ní Asia, “a kì í fọ̀yàyà kí àwọn ọmọbìnrin jòjòló káàbọ̀ sílé ayé.” A ṣì ń ṣojúsàájú àwọn ọmọbìnrin ní àwọn ilẹ̀ Latin America, àní láàárín “àwọn ìdílé alákọ̀wé” pàápàá. Bí ó ti wù kí ó rí, òtítọ́ náà ni pé, àwọn ọmọbìnrin kì í ṣe àwọn ọmọ onípò kejì. Jakọbu, bàbá ìgbàanì kan tí a mọ̀ bí ẹní mowó, júwe gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀, títí kan àwọn ọmọbìnrin tí a bí fún un ní àkókò yẹn, gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi oore ọ̀fẹ́ fún [mi].” (Genesisi 33:1-5; 37:35) Bákan náà, Jesu súre fún gbogbo “awọn ọmọ kéékèèké” (tọkùnrin tobìnrin) tí a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Matteu 19:13-15) Ó lè dá wa lójú pé ó fi ojú ìwòye Jehofa lórí ọ̀ràn náà hàn.—Deuteronomi 16:14.
5. Ìgbéyẹ̀wò wo ni ó yẹ kí ó nípa lórí ìpinnu tọkọtaya kan lórí bí ìdílé wọ́n ṣe yẹ kí ó tóbi tó?
5 Ní àgbègbè yín, a ha retí pé kí obìnrin bí gbogbo ọmọ inú rẹ̀ tán bí? Lọ́nà tí ó bá a mu, iye ọmọ tí tọkọtaya kan bí jẹ́ ìpinnu wọn. Bí agbára àwọn òbí kò bá gbé bíbọ́, ríraṣọ sọ́rùn, àti rírán ọmọ rẹpẹtẹ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ńkọ́? Dájúdájú, tọkọtaya gbọ́dọ̀ gbé èyí yẹ̀ wò, nígbà tí wọ́n bá ń pinnu iye ọmọ tí wọn yóò bí. Àwọn tọkọtaya kan tí kò lè gbọ́ bùkátà lórí gbogbo ọmọ wọn fi àwọn kan sọ́dọ̀ àwọn ìbátan láti bá wọn tọ́ wọn. Àṣà yìí ha bọ́gbọ́n mu bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá. Kò sì mú kí àwọn òbí mórí bọ́ nínú ṣíṣe ojúṣe wọn sí àwọn ọmọ wọn. Bibeli wí pé: “Bí ẹni kan kò bá pèsè fún awọn wọnnì tí wọ̀n jẹ́ tirẹ̀, ati ní pàtàkì fún awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà agbo ilé rẹ̀, oun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́.” (1 Timoteu 5:8) Tọkọtaya tí ó mọṣẹ́níṣẹ́ máa ń gbìyànjú láti ṣètò bí “agbo ilé” wọn yóò ṣe tóbi tó, nítorí kí wọ́n baà lè ‘pèsè fún awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ tiwọn.’ Wọ́n ha lè fètò sọ́mọ bíbí kí wọ́n baà lè ṣe èyí bí? Ìyẹn pẹ̀lú jẹ́ ìpinnu ara ẹni, bí tọkọtaya bá sì pinnu láti gbé ìgbésẹ̀ yìí, irú ọ̀nà málòóyún tí wọ́n yàn jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni bákan náà. “Olúkúlùkù ni yoo ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Galatia 6:5) Àmọ́ ṣáá o, ọ̀nà ìfètò sọ́mọ bíbí tí ó wé mọ́ irú ìṣẹ́yún èyíkéyìí, ta ko ìlànà Bibeli. Jehofa Ọlọrun ni “orísun ìyè.” (Orin Dafidi 36:9) Nítorí náà, láti gba ẹ̀mí kan lẹ́yìn tí ó ti bẹ̀rẹ̀ yóò fi ìwà àìlọ́wọ̀ gbáà hàn sí Jehofa, ó sì já sí ìpànìyàn.—Eksodu 21:22, 23; Orin Dafidi 139:16; Jeremiah 1:5.
KÍKÁJÚ ÀÌNÍ ỌMỌ RẸ
6. Nígbà wo ni ó yẹ kí ẹ̀kọ́ ọmọ bẹ̀rẹ̀?
6 Owe 22:6 (NW) sọ pé: “Kọ́ ọmọdékùnrin ní ọ̀nà tí ó dára fún un.” Kíkọ́ àwọn ọmọ jẹ́ ojúṣe pàtàkì míràn fún àwọn òbí. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà wo ni ó yẹ kí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà bẹ̀rẹ̀? Ní kùtùkùtù ìgbésí ayé. Aposteli Paulu sọ pé a ti kọ́ Timoteu “lati ìgbà ọmọdé jòjòló.” (2 Timoteu 3:15) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a lò níhìn-ín lè tọ́ka sí ọmọ ọwọ́ jòjòló tàbí ọlẹ̀ inú pàápàá. (Luku 1:41, 44; Ìṣe 7:18-20) Nítorí náà, Timoteu gba ẹ̀kọ́ láti ìgbà tí ó ti wà ní kékeré—bí ó sì ti yẹ kí ó rí nìyẹn. Ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìgbà tí ó dára jù lọ láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọmọdé. Àní ọmọ ọwọ́ jòjòló pàápàá ń yán hànhàn fún ìmọ̀.
7. (a) Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí méjèèjì mú ipò ìbátan tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú ọmọ wọn jòjòló? (b) Irú ipò ìbátan wo ni ó wà láàárín Jehofa àti Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo?
7 Ìyá kan sọ pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ fojú gán-ánní ọmọ mi, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ púpọ̀.” Bí ọ̀pọ̀ ìyá ti ń nímọ̀lára nìyẹn. Ìsopọ̀ pẹ́kípẹ́kí dáradára yẹn láàárín ìyá àti ọmọ ń ga sí i bí wọ́n ti ń lo àkókò pa pọ̀, lẹ́yìn ìbí ọmọ náà. Fífún ọmọ lọ́mú ń fi kún ìsopọ̀ pẹ́kípẹ́kí náà. (Fi wé 1 Tessalonika 2:7.) Pípa tí ìyá ń fọwọ́ pa ọmọ rẹ̀ lára, tí ó sì ń bá a sọ̀rọ̀ ṣe kókó sí kíkúnjú àìní ọmọ náà nípa ti èrò ìmọ̀lára. (Fi wé Isaiah 66:12.) Ṣùgbọ́n, bàbá ńkọ́? Òun pẹ̀lú ní láti ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ọmọ jòjòló rẹ̀ yìí. Jehofa fúnra rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ èyí. Nínú ìwé Owe, a kọ́ nípa ipò ìbátan Jehofa pẹ̀lú Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, tí a wí nípa rẹ̀ pé ó sọ pé: “Oluwa pèsè mi ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ [ọ̀nà, NW] rẹ̀ . . . èmí sì jẹ́ dídùn inú rẹ̀ lójoojúmọ́.” (Owe 8:22, 30; Johannu 1:14) Lọ́nà kan náà, bàbá rere ń mú ipò ìbátan ọlọ́yàyà, onífẹ̀ẹ́ dàgbà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ọmọ náà. Òbí kan sọ pé: “Fi ìfẹ́ni púpọ̀ hàn. Kò sí ọmọ tí ń kú nítorí tí a gbá a mọ́ra tí a sì fẹnu kò ó lẹ́nu.”
8. Irú ìmọ́pọlọ jí pépé wo ni ó yẹ kí àwọn òbí fún àwọn ọmọ jòjòló, bí ó bá ti tètè ṣeé ṣe tó?
8 Ṣùgbọ́n ohun tí àwọn ọmọ ọwọ́ nílò ju ìyẹn lọ. Láti ìgbà ìbí wọn, ọpọlọ wọ́n ti ṣe tán láti gba ìsọfúnni àti láti fi wọ́n pa mọ́, àwọn òbí sì ni orísun pàtàkì ìsọfúnni. Wo èdè fún àpẹẹrẹ. Àwọn olùwádìí sọ pé, bí ọmọ kan ṣe kọ́ láti sọ̀rọ̀ àti láti kàwé dáradára tó “ni a ronú pé ó ní í ṣe pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú ìjùmọ̀ṣe ọmọ náà pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ ní kùtùkùtù ìgbésí ayé rẹ̀.” Bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀, kí o sì kàwé fún un, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ọmọdé jòjòló. Láìpẹ́ láìjìnnà, òun yóò fẹ́ láti ṣàfarawé rẹ, láìpẹ́, ìwọ yóò bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ láti kàwé. Ó ṣeé ṣe kí ó mọ bí a ti ń kàwé kí ó tó bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́. Èyí yóò ṣàǹfààní gidigidi, bí ẹ bá ń gbé ní orílẹ̀-èdè tí kò ti fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn olùkọ́, tí kíláàsì sì ń kún fọ́fọ́.
9. Góńgó pàtàkì jù lọ wo ni ó yẹ kí àwọn òbí máa rántí?
9 Títẹ́ àìní ọmọ wọn nípa tẹ̀mí lọ́rùn, ni ohun tí ó jẹ àwọn Kristian òbí lógún jù lọ. (Wo Deuteronomi 8:3.) Pẹ̀lú góńgó wo? Láti ran ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mú ìwà bíi ti Kristi dàgbà, ìyẹn ni pé, láti gbé “àkópọ̀ ìwà titun” wọ̀. (Efesu 4:24) Fún èyí, wọ́n ní láti gbé àwọn ohun èlò ìkọ́lé dídára àti àwọn ọ̀nà ìkọ́lé dídára yẹ̀ wò.
GBIN ÒTÍTỌ́ SÍNÚ ỌMỌ RẸ
10. Àwọn ànímọ́ wo ni àwọn ọmọdé ní láti mú dàgbà?
10 Bí ilé kan ti dára sí sinmi púpọ̀ lórí irú ohun èlò tí a lò láti fi kọ́ ọ. Aposteli Paulu sọ pé “wúrà, fàdákà, awọn òkúta ṣíṣeyebíye” ni àwọn ohun èlò ìkọ́lé tí ó dára jù lọ fún ìwà ànímọ́ Kristian. (1 Korinti 3:10-12) Àwọn wọ̀nyí dúró fún àwọn ànímọ́ bí ìgbàgbọ́, ọgbọ́n, ìfòyemọ̀, ìdúróṣinṣin, ọ̀wọ̀, àti ìmọrírì onífẹ̀ẹ́ fún Jehofa àti àwọn òfin rẹ̀. (Orin Dafidi 19:7-11; Owe 2:1-6; 3:13, 14) Báwo ni àwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló láti mú àwọn ànímọ́ wọ̀nyí dàgbà? Nípa títẹ̀ lé ìlànà kan tí a ti là sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́.
11. Báwo ni àwọn ọmọ Israeli tí ó jẹ́ òbí ṣe ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mú àwọn ànímọ́ oníwà-bí-Ọlọ́run dàgbà?
11 Kété ṣáájú kí orílẹ̀-èdè Israeli tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Jehofa sọ fún àwọn ọmọ Israeli tí ó jẹ́ òbí pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí mo pa láṣẹ fún ọ ní òní, kí ó máa wà ní àyà rẹ: Kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi, kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ìwọ́ bá jókòó nínú ilé rẹ, àti nígbà tí ìwọ́ bá ń rìn ní ọ̀nà, àti nígbà tí ìwọ́ bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí ìwọ́ bá dìde.” (Deuteronomi 6:6, 7) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn òbí ní láti jẹ́ àpẹẹrẹ, alábàákẹ́gbẹ́, olùbánisọ̀rọ̀pọ̀, àti olùkọ́ fún àwọn ọmọ wọn.
12. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí jẹ́ àpẹẹrẹ rere?
12 Jẹ́ àpẹẹrẹ. Lákọ̀ọ́kọ́, Jehofa wí pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí . . . kí ó máa wà ní àyà rẹ.” Lẹ́yìn náà, ó fi kún un pé: “Kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi.” Nítorí náà, àwọn ànímọ́ oníwà-bí-Ọlọ́run gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wà ní ọkàn-àyà òbí ná. Òbí gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, kí ó sì máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Kìkì nígbà náà ni ó tó lè dé inú ọkàn-àyà ọmọ rẹ̀. (Owe 20:7) Èé ṣe? Nítorí ohun tí àwọn ọmọ ń rí ń nípa lórí wọn ju ohun tí wọ́n ń gbọ́ lọ.—Luku 6:40; 1 Korinti 11:1.
13. Nínú fífún àwọn ọmọ wọn ní àfiyèsí, báwo ni àwọn Kristian òbí ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ Jesu?
13 Jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́. Jehofa sọ fún àwọn òbí ní Israeli pé: ‘Ẹ bá àwọn ọmọ yín sọ̀rọ̀ nígbà tí ẹ bá jókòó nínú ilé yín, àti nígbà tí ẹ bá ń rìn ní ọ̀nà.’ Èyí ń béèrè lílo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ láìka bí ọwọ́ àwọn òbí ti lè dí tó sí. Ó ṣe kedere pé Jesu ronú pé ó yẹ kí òun lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọdé. Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ti ń lọ sí òpin, “awọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mú awọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ rẹ̀ lati fọwọ́kan awọn wọnyi.” Kí ni ìṣarasíhùwà Jesu? “Ó sì gbé awọn ọmọ naa sí apá rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í súre fún wọn.” (Marku 10:13, 16) Rò ó wò ná, àwọn wákàtí ìkẹyìn ìgbésí ayé Jesu ti sún mọ́lé pẹ́kípẹ́kí. Síbẹ̀, ó lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọ̀nyí, ó sì fún wọn ní àfiyèsí. Ẹ wo ẹ̀kọ́ àtàtà tí èyí jẹ́!
14. Èé ṣe tí ó fi ṣàǹfààní fún àwọn òbí láti lo àkókò pẹ̀lú ọmọ wọn?
14 Jẹ́ olùbánisọ̀rọ̀pọ̀. Lílo àkókò pẹ̀lú ọmọ rẹ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bá a sọ̀rọ̀ pọ̀. Bí o bá ti ń bá a sọ̀rọ̀ pọ̀ tó ni ìwọ yóò ṣe máa fòye mọ bí ìwà ànímọ́ rẹ̀ ti ń dàgbà sí. Bí ó ti wù kí ó rí, rántí pé, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ré kọjá sísọ̀rọ̀. Ìyá kan ní Brazil sọ pé: “Mo ní láti mú ọnà ìfetísílẹ̀ dàgbà, fífetí sílẹ̀ pẹ̀lú ọkàn-àyà mi.” Sùúrù rẹ̀ méso jáde nígbà tí ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èrò ọkàn rẹ̀ jáde fún un.
15. Kí ni ó yẹ kí á ní lọ́kàn nígbà tí ó bá kan eré ìnàjú?
15 Àwọn ọmọdé nílò “ìgba rírẹ́rìn-ín . . . àti ìgba fífò kiri,” ìgbà eré ìnàjú. (Oniwasu 3:1, 4, NW; Sekariah 8:5) Eré ìnàjú máa ń méso rere jáde nígbà tí àwọn òbí àti àwọn ọmọ bá jọ gbádùn rẹ̀ pa pọ̀. Ó jẹ́ òtítọ́ kan tí kò múni láyọ̀ pé, ní ọ̀pọ̀ ilé, wíwo tẹlifíṣọ̀n ni eré ìnàjú wọn. Bí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n kan tilẹ̀ lè múni lára yá, ọ̀pọ̀ ń ba ìwà rere jẹ́, wíwo tẹlifíṣọ̀n sì máa ń ṣàkóbá fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nínú ìdílé. Nítorí náà, èé ṣe tí o kò fi ṣe ohun tí ó ń béèrè ọgbọ́n inú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ? Ẹ kọrin, ẹ tayò, ẹ kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ yín, ẹ ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibi tí ó gbádùn mọ́ni. Irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ ń ru ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ sókè.
16. Kí ni ó yẹ kí àwọn òbí fi kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Jehofa, báwo ni ó sì ṣe yẹ kí wọ́n ṣe èyí?
16 Jẹ́ olùkọ́. Jehofa sọ pé: “Kí ìwọ kí ó sì máa fi [ọ̀rọ̀ wọ̀nyí] kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi.” Àyíká ọ̀rọ̀ náà sọ ohun tí o ní láti fi kọ́ wọn àti bí o ṣe ní láti kọ́ wọn. Lákọ̀ọ́kọ́, “kí ìwọ kí ó sì fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ.” (Deuteronomi 6:5) Lẹ́yìn náà, “ọ̀rọ̀ wọ̀nyí . . . kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ.” Fúnni ní àwọn ìtọ́ni tí a pète láti mú ìfẹ́ àtọkànwá fún Jehofa àti àwọn òfin rẹ̀ dàgbà. (Fi wé Heberu 8:10.) Àpólà ọ̀rọ̀ náà, “fi wọ́n kọ́,” túmọ̀ sí kíkọ́ni nípa sísọ àsọtúnsọ. Nítorí náà, Jehofa, ní ti gidi, ń sọ fún ọ pé, ọ̀nà pàtàkì jù lọ tí o lè gbà ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti mú ànímọ́ oníwà-bí-Ọlọ́run dàgbà jẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lemọ́lemọ́. Èyí kan ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé pẹ̀lú wọn.
17. Kí ni àwọn òbí lè ní láti mú dàgbà nínú ọmọ wọn? Èé ṣe?
17 Ọ̀pọ̀ òbí mọ̀ pé kíkó ìsọfúnni sínú ọkàn ọmọdé kò rọrùn. Aposteli Peteru rọ àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Gẹ́gẹ́ bí awọn ọmọdé jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, ẹ ní ìyánhànhàn kan fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ naa.” (1 Peteru 2:2) Gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà, “ẹ ní ìyánhànhàn,” dọ́gbọ́n túmọ̀ sí pé, ọ̀pọ̀ kì í yán hànhàn fún oúnjẹ tẹ̀mí. Àwọn òbí lè ní láti wá àwọn ọ̀nà láti mú ìyánhànhàn yẹn dàgbà nínú ọmọ wọn.
18. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà ìkọ́ni Jesu tí a rọ àwọn òbí láti fara wé?
18 Jesu dé inú ọkàn àwọn ènìyàn nípa lílo àpèjúwe. (Marku 13:34; Luku 10:29-37) Ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí gbéṣẹ́ ní pàtàkì fún àwọn ọmọdé. Fi àwọn ìlànà Bibeli kọ́ni nípa lílo àwọn ìtàn tí ó lárinrin, tí ń runi lọ́kàn sókè, bóyá irú èyí tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde náà, Iwe Itan Bibeli Mi.a Jẹ́ kí àwọn ọmọ náà lọ́wọ́ sí i. Jẹ́ kí wọ́n lo ọgbọ́n inú wọn ní yíya àwòrán àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bibeli, kí wọ́n sì fi ṣeré. Jesu lo ìbéèrè pẹ̀lú. (Matteu 17:24-27) Lo àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín. Dípò wíwulẹ̀ sọ òfin Ọlọrun kan, béèrè ìbéèrè bí, Èé ṣe tí Jehofa fi fún wa ní òfin yìí? Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí a bá pa á mọ́? Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí a kò bá pa á mọ́? Irú àwọn ìbéèrè báwọ̀nyí ń ran ọmọdé lọ́wọ́ láti ronú àti láti rí i pé àwọn òfin Ọlọrun gbéṣẹ́, ó sì dára.—Deuteronomi 10:13.
19. Bí àwọn òbí bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bibeli nínú bíbá àwọn ọmọ wọn lò, àwọn àǹfààní ńlá wo ni àwọn ọmọ yóò gbádùn?
19 Nípa jíjẹ́ àpẹẹrẹ, alábàákẹ́gbẹ́, olùbánisọ̀rọ̀pọ̀, àti olùkọ́, ìwọ lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti kùtùkùtù ìgbésí ayé rẹ̀ láti mú ipò ìbátan tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú Jehofa Ọlọrun. Ipò ìbátan yìí yóò ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti láyọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristian kan. Òun yóò làkàkà láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ rẹ̀ àní nígbà tí ó bá dojú kọ ìkìmọ́lẹ̀ ojúgbà àti àdánwò pàápàá. Ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà láti mọrírì ipò ìbátan ṣíṣeyebíye yìí.—Owe 27:11.
ÀÌNÍ ṢÍṢE KÓKÓ FÚN ÌBÁWÍ
20. Kí ni ìbáwí, báwo ni ó sì ṣe yẹ kí á lò ó?
20 Ìbáwí jẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ń ṣàtúnṣe èrò inú àti ọkàn-àyà. Àwọn ọmọdé nílò rẹ̀ lemọ́lemọ́. Paulu fún àwọn bàbá nímọ̀ràn láti “máa bá a lọ ní títọ́ [àwọn ọmọ wọn] dàgbà ninu ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa.” (Efesu 6:4) Àwọn òbí gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ báni wí, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti ń ṣe. (Heberu 12:4-11) A lè fúnni ní ìbáwí tí a gbé karí ìfẹ́ nípa ríronú pọ̀ pẹ̀lú ẹni. Nítorí náà, a sọ fún wa láti “tẹ́tí sílẹ̀ sí ìbáwí.” (Owe 8:33, NW) Báwo ni ó ṣe yẹ kí á báni wí?
21. Àwọn ìlànà wo ni ó yẹ kí àwọn òbí ní lọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn ọmọ wọn wí?
21 Àwọn òbí kan ronú pé bíbá àwọn ọmọ wọn wí wulẹ̀ túmọ̀ sí híhalẹ̀ mọ́ wọn, nínà wọ́n, tàbí bíbú wọn pàápàá. Bí ó ti wù kí ó rí, lórí kókó kan náà, Paulu kìlọ̀ pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ máṣe máa sún awọn ọmọ yín bínú.” (Efesu 6:4) A rọ gbogbo Kristian láti jẹ́ “ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn . . . kí ó máa fún awọn wọnnì tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere ní ìtọ́ni pẹlu ìwàtútù.” (2 Timoteu 2:24, 25) Bí àwọn Kristian òbí tilẹ̀ mọ ìdí ṣíṣàìgba gbẹ̀rẹ́, wọ́n ń gbìyànjú láti fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn ọmọ wọn wí. Àmọ́ ṣáá o, ní àwọn ìgbà míràn, ríronú pọ̀ pẹ̀lú wọn kì í tó, irú ìjẹníyà kan sì lè yẹ.—Owe 22:15.
22. Bí a bá ní láti jẹ ọmọ kan níyà, kí ni ó yẹ kí a ràn án lọ́wọ́ láti lóye?
22 Ọmọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nílò ìbáwí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. “A kì í fi ọ̀rọ̀ kìlọ̀” fún àwọn kan. Fún wọn, ìyà tí a fi ń jẹ wọ́n lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí àìgbọràn wọn lè gba ẹ̀mí wọn là. (Owe 17:10; 23:13, 14; 29:19) Bí ó ti wù kí ó rí, ó yẹ kí ọmọ kan lóye ìdí tí a fi ń jẹ òun níyà. “Pàṣán àti ìbáwí fúnni ní ọgbọ́n.” (Owe 29:15, ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa; Jobu 6:24) Síwájú sí i, ìjẹniníyà níwọ̀n. Jehofa sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Èmi yóò bá ọ wí ní ìwọ̀n.” (Jeremiah 46:28b, ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Bibeli kò fọwọ́ sí fífìbínú nani lọ́rẹ́ tàbí líluni bolẹ̀, tí ń dápàá sára ọmọ, tí ó sì ń ṣe é léṣe pẹ̀lú.—Owe 16:32.
23. Kí ni ó yẹ kí ọmọ kan lè fòye mọ̀ nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ bá jẹ ẹ́ níyà?
23 Nígbà tí Jehofa kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé òun yóò bá wọn wí, ó kọ́kọ́ sọ pé: “Má bẹ̀rù . . . nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ.” (Jeremiah 46:28a) Bákan náà, ìbáwí òbí, ní ọ̀nà èyíkéyìí tí a bá gbà fi fúnni, kò gbọ́dọ̀ mú kí ọmọ ronú láé pé a ti kọ òun sílẹ̀. (Kolosse 3:21) Kàkà bẹ́ẹ̀, ọmọ náà gbọ́dọ̀ nímọ̀lára pé òbí òun bá òun wí nítorí ó ‘wà pẹ̀lú òun,’ ní ìhà ọ̀dọ̀ òun.
DÁÀBÒ BO ỌMỌ RẸ LỌ́WỌ́ ÌPALÁRA
24, 25. Kúrò lọ́wọ́ ewu burúkú wo ni a ní láti dáàbò bo àwọn ọmọdé, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí?
24 Ọ̀pọ̀ àgbàlagbà ń rántí ìgbà ọmọdé wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbà aláyọ̀. Wọ́n ń rántí níní ìmọ̀lára ìfọkànbalẹ̀, ìdánilójú pé àwọn òbí wọn yóò bójú tó wọn láìka ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí. Àwọn òbí ń fẹ́ kí àwọn ọmọ wọ́n nímọ̀lára lọ́nà yẹn, ṣùgbọ́n, lónìí, nínú ayé bíbàjẹ́ yìí, ó ṣòro gidigidi láti dáàbò bo àwọn ọmọ ju bí ó ti rí tẹ́lẹ̀ lọ.
25 Ìfìbálòpọ̀ fìtínà àwọn ọmọdé jẹ́ ewu burúkú kan tí ó ti gbilẹ̀ ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Ní Malaysia, ìròyìn ìfìbálòpọ̀ fìtínà ọmọdé ti di ìlọ́po mẹrin láàárín ọdún mẹ́wàá. Ní Germany, nǹkan bí 300,000 àwọn ọmọdé ni a ń bá ṣèṣekúṣe lọ́dọọdún, nígbà tí ó jẹ́ pé ní orílẹ̀-èdè kan ní Gúúsù America, ní ìbámu pẹ̀lú ìwádìí kan, iye tí a fojú díwọ̀n lọ́dọọdún tó 9,000,000! Lọ́nà tí ń bani nínú jẹ́, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọdé wọ̀nyí ni a ń fìtínà nínú ilé wọn gan-an, láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ̀, tí wọ́n sì fọkàn tẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó yẹ kí àwọn óbí jẹ́ ìgbèjà ńlá fún àwọn ọmọ wọn. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè jẹ́ adáàbòboni?
26. Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo ni àwọn ọmọdé lè gbà ní ìfọkànbalẹ̀, báwo sì ni ìmọ̀ ṣe lè dáàbò bo ọmọdé?
26 Níwọ̀n bí ìrírí ti fi hàn pé àwọn ọmọ tí kò mọ nǹkan kan nípa ìbálòpọ̀ ni ó sábà máa ń kó sọ́wọ́ àwọn tí ń fìbálòpọ̀ fìtínà ọmọdé, ọ̀nà pàtàkì kan láti ṣèdènà èyí jẹ́ láti kọ́ ọmọ náà, àní nígbà tí ó ṣì kéré gan-an pàápàá. Ìmọ̀ lè pèsè ààbò “lọ́wọ́ ẹni ibi, lọ́wọ́ ọkùnrin tí ń sọ̀rọ̀ àyídáyidà.” (Owe 2:10-12) Ìmọ̀ nípa kí ni? Ìmọ̀ nípa àwọn ìlànà Bibeli, nípa ìwà tí ó tọ̀nà àti èyí tí kò tọ̀nà. Àti ìmọ̀ pé àwọn àgbàlagbà kan máa ń ṣe àwọn ohun tí kò dára, àti pé ọmọdé kan kò ní láti ṣègbọràn nígbà tí àwọn ènìyàn bá dábàá àwọn ìwà tí kò bójú mu. (Fi wé Danieli 1:4, 8; 3:16-18.) Má ṣe fi irú ìtọ́ni báyìí mọ sí ìgbà kan ṣoṣo. A ní láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ní àsọtúnsọ kí ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọdé tó lè rántí wọn dáradára. Bí àwọn ọmọ ti ń dàgbà sí i, bàbá kan yóò fìfẹ́ bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní sí níní ibi ìkọ̀kọ̀, ìyá pẹ̀lú yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọmọkùnrin rẹ̀—ní títipa báyìí tẹ ohun tí ó bójú mu àti ohun tí kò bójú mu mọ́ ọmọ náà lọ́kàn. Dájúdájú, ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti ṣèdíwọ́ fún bíbá ọmọ ṣèṣekúṣe jẹ́ àbójútó tímọ́tímọ́ yín gẹ́gẹ́ bí òbí.
Ẹ WÁ ÌTỌ́SỌ́NÀ ỌLỌRUN
27, 28. Ta ni Orísun ìrànlọ́wọ́ títóbi jù lọ fún àwọn òbí, nígbà tí wọ́n bá dojú kọ ìpèníjà títọ́ ọmọ dàgbà?
27 Ní tòótọ́, kíkọ́ ọmọ láti ìgbà ọmọdé jòjòló jẹ́ ìpèníjà, ṣùgbọ́n àwọn òbí onígbàgbọ́ kò ní láti nìkan dojú kọ ìpèníjà náà. Tipẹ́tipẹ́ ní ọjọ́ àwọn Onídàájọ́, nígba tí ọ̀kùnrin kan tí ń jẹ́ Manoa gbọ́ pé òun yóò di bàbá, ó béèrè ìtọ́sọ́nà lọ́wọ́ Jehofa lórí bí yóò ṣe tọ́ ọmọ rẹ̀. Jehofa gbọ́ àdúrà rẹ̀.—Onidajọ 13:8, 12, 24.
28 Ní ọ̀nà kan náà, lónìí, bí àwọn òbí onígbàgbọ́ ti ń tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà, àwọn pẹ̀lú lè bá Jehofa sọ̀rọ̀ nínú àdúrà. Iṣẹ́ ribiribi ni jíjẹ́ òbí, ṣùgbọ́n èrè ńlá ń bẹ nínú rẹ̀. Kristian tọkọtaya kan ní Hawaii sọ pé: “O ní ọdún 12 láti fi ṣiṣẹ́ rẹ, kí àkókò ọ̀dọ́langba pípabambarì náà tó wọlé dé. Ṣùgbọ́n, bí o bá ti ṣiṣẹ́ kára láti lo àwọn ìlànà Bibeli, àkókò ti tó láti kórè ayọ̀ àti àlàáfíà, nígbà tí wọ́n bá pinnu pé àwọ́n fẹ́ sin Jehofa láti inú ọkàn wọ́n.” (Owe 23:15, 16) Nígbà tí ọmọ rẹ bá ṣe ìpinnu yẹn, a óò sún ìwọ pẹ̀lú láti sọ pé: “Àwọn ọmọ ni ìní Oluwa.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . ÀWỌN ÒBÍ LÁTI KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ WỌN?
Gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa.—Owe 3:5.
Jẹ́ amọṣẹ́ẹniníṣẹ́.—1 Timoteu 5:8.
Jehofa jẹ́ Bàbá onífẹ̀ẹ́.—Owe 8:22, 30.
Àwọn òbí ni ó ni ẹrù iṣẹ́ fífún àwọn ọmọ wọn nítọ̀ọ́ni.—Deuteronomi 6:6, 7.
A nílò ìbáwí.—Efesu 6:4.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 61]
ÌBÁWÍ GBÍGBÉṢẸ́
Ọ̀nà ìbáwí nínítumọ̀ kan jẹ́ láti mú kí àwọn ọmọdé tọ́ àbájáde aláìbáradé ìwà burúkú wọn wò. (Galatia 6:7; fi wé Eksodu 34:6, 7.) Fún àpẹẹrẹ, bí ọmọ rẹ bá ṣèdọ̀tí sílẹ̀, jíjẹ́ kí ó tú un ṣe fúnra rẹ̀ lè mú kí ó ní ìrírí tí kò ní gbàgbé láé. Ó ha ti hùwà sí ẹnì kan lọ́nà àìtọ́ bí? Bíbéèrè pé kí ó lọ tọrọ àforíjì lè mú kí ó ti ọwọ́ rẹ̀ bọlẹ̀. Ọ̀nà Ìbáwí mìíràn jẹ́ dídù ú ní àǹfààní kan fún ìgbà díẹ̀, kí ó lè kọ́ ọ lọ́gbọ́n. Ní ọ̀nà yìí, ọmọ ń kọ́ ọgbọ́n tí ń bẹ nídìí rírọ̀ mọ́ àwọn ìlànà títọ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 57]
Ẹ̀yin òbí, ẹ jẹ́ àpẹẹrẹ, alábàákẹ́gbẹ́, olùbánisọ̀rọ̀pọ̀, àti olùkọ́