“Ẹ Máa Rántí Àwọn ọjọ́ Tí Ó Ti Kọjá”—Èé ṣe?
“ẸMÁA rántí àwọn ọjọ́ tí ó ti kọjá.” A darí ìṣílétí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yìí, tí ó kọ ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Tiwa, sí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù, tí wọ́n ń gbé ní Jùdíà. (Hébérù 10:32, The New English Bible) Kí ni ó fa ọ̀rọ̀ yìí? Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn olùjọsìn Jèhófà ní ọ̀rúndún kìíní má ṣe gbàgbé àtijọ́? A ha lè jàǹfààní nípa kíkọbi ara sí ìránnilétí kan náà lónìí bí?
Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì ti kìlọ̀ léraléra nípa ṣíṣàìka àtijọ́ sí tàbí ṣíṣàìfiyèsí i. A ní láti máa fi ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́ sọ́kàn, kí a sì máa ronú lé e lórí. Àní Jèhófà pàápàá wí pé: “Ẹ rántí nǹkan ìṣáájú àtijọ́: nítorí èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn, èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹni tí ó dà bí èmi.” (Aísáyà 46:9) Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ìdí pàtàkì mẹ́ta fún kíkọbi ara sí ìṣílétí yìí.
Ìsúnniṣe àti Ìṣírí
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó lè jẹ́ orísun ńláǹlà fún ìsúnniṣe àti ìṣírí. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sí ìjọ Hébérù, ó ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí a ń dán ìgbàgbọ́ wọn wò lójoojúmọ́ nítorí àtakò láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù. Ní mímọ àìní wọn láti mú ìfaradà dàgbà, Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní rírántí àwọn ọjọ́ àtijọ́ nínú èyí tí, lẹ́yìn tí a ti là yín lóye, ẹ fara da ìjà ìdíje ńláǹlà lábẹ́ àwọn ìjìyà.” (Hébérù 10:32) Rírántí tí wọ́n ń rántí àwọn ìṣe àtijọ́ ti ìdúróṣinṣin nínú ogun nípa tẹ̀mí yóò fún wọn ní ìgboyà tí wọ́n nílò láti parí eré ìje náà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wòlíì Aísáyà kọ̀wé pé: “Ẹ rántí èyí, ẹ sì fi ara yín hàn bí ọkùnrin.” (Aísáyà 46:8) Pẹ̀lú irú agbára ìdarí fífani lọ́kàn mọ́ra bẹ́ẹ̀ lọ́kàn ni Jésù Kristi fi sọ fún ìjọ ní Éfésù pé: “Nítorí náà rántí inú ohun tí ìwọ́ ti ṣubú [ìfẹ́ tí o ní lákọ̀ọ́kọ́], kí o sì ronú pìwà dà kí o sì ṣe àwọn iṣẹ́ ti ìṣáájú.”—Ìṣípayá 2:4, 5.
Ìṣílétí náà láti “rántí ọjọ́ ìgbàanì, ronú ọdún ìrandíran” jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ àsọtúnsọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Mósè bá Ísírẹ́lì sọ, bí ó ṣe rọ orílẹ̀-èdè náà láti fi ìdúróṣinṣin aláìṣojo hàn fún Jèhófà. (Diutarónómì 32:7) Kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí a kọ sílẹ̀ nínú Diutarónómì 7:18 pé: “Kí ìwọ kí ó má ṣe bẹ̀rù wọn [àwọn ọmọ Kénáánì]: ṣùgbọ́n kì ìwọ kí ó rántí dáradára ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ṣe sí Fáráò, àti sí gbogbo Íjíbítì.” Rírántí ìṣe ìgbàlà Jèhófà nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ fún sísún wọn láti máa bá fífi ìṣòtítọ́ dìrọ̀ mọ́ àwọn òfin Ọlọ́run nìṣó.—Diutarónómì 5:15; 15:15.
Ó bani nínú jẹ́ pé, lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì juwọ́ sílẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ ìgbàgbé. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? “Wọ́n yí padà, wọ́n . . . dán Ọlọ́run wò, wọ́n sì ṣe àròpin Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì. Wọn kò rántí ọwọ́ rẹ̀, tàbí ọjọ́ nì tí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ ọ̀tá.” (Orin Dáfídì 78:41, 42) Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, gbígbàgbé tí wọ́n gbàgbé àṣẹ Jèhófà yọrí sí kíkọ̀ tí ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀.—Mátíù 21:42, 43.
Onísáàmù náà fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Èmi óò rántí iṣẹ́ Olúwa: ní tòótọ́ èmi óò rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ àtijọ́. Ṣùgbọ́n èmi óò máa ṣe àṣàrò gbogbo iṣẹ́ rẹ pẹ̀lú, èmi óò sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.” (Orin Dáfídì 77:11, 12) Irú ṣíṣàṣàrò tí ń múni rántí iṣẹ́ ìsìn àtijọ́ tí a fi ìdúróṣinṣin ṣe àti ìṣe onífẹ̀ẹ́ Jèhófà yóò pèsè ìsúnniṣe, ìṣírí, àti ìmọrírì tí a nílò fún wa. Bákan náà, “rírántí àwọn ọjọ́ àtijọ́” lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú àárẹ̀ kúrò, ó sì lè ru wá sókè láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe, kí a sì di ìfaradà àfòtítọ́ṣe mú.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Inú Àṣìṣe Àtijọ́
Èkejì ni pé, àìgbàgbé lè jẹ́ ọ̀nà kan láti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn ìṣìnà àtijọ́ àti àbájáde wọn. Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nímọ̀ràn pé: “Rántí, má ṣe gbàgbé, bí ìwọ ti mú OLÚWA Ọlọ́run rẹ bínú ní aginjù: láti ọjọ́ náà tí ìwọ ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, títí ẹ̀yín fi dé ìhín yìí, ẹ̀yin ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA.” (Diutarónómì 9:7) Ìyọrísí irú àìgbọràn bẹ́ẹ̀ níhà ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́, gẹ́gẹ́ bí Mósè ti sọ, pé ‘Jèhófà Ọlọ́run wọn sì mú wọn rìn ní aginjù fún ogójì ọdún.’ Èé ṣe tí a fi fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n rántí èyí? Ó jẹ́ láti mú wọn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti láti jẹ́ àtúnṣe fún ọ̀nà ọlọ̀tẹ̀ wọn, kí wọn baà lè “pa òfin OLÚWA Ọlọ́run [wọn] mọ́, láti máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti láti máa bẹ̀rù rẹ̀.” (Diutarónómì 8:2-6) Wọ́n ní láti kẹ́kọ̀ọ́ ní ti pé, kí wọn má ṣe ṣàṣìṣe tí wọ́n ti ṣe nígbà àtijọ́ mọ́.
Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Amòye máa ń jàǹfààní nínú ìrírí ara rẹ̀, àmọ́ ènìyàn ọlọ́gbọ́n ń jàǹfààní láti inú ìrírí àwọn ẹlòmíràn.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Mósè rọ àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì láti jàǹfààní nípa ríronú lórí ìṣìnà wọn àtijọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣí àwọn mìíràn létí—ìjọ Kọ́ríńtì ti ọ̀rúndún kìíní, tì a bá sì nasẹ̀ rẹ̀ díẹ̀ sí i, àwa—láti kẹ́kọ̀ọ́ kan láti inú àkọsílẹ̀ ìtàn kan náà. Ó kọ̀wé pé: “Wàyí o àwọn nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ láti máa ṣẹlẹ̀ sí wọn [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn láti jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa ẹni tí òpin àwọn ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan dé bá.” (Kọ́ríńtì Kìíní 10:11) Jésù Kristi ní ìṣẹ̀lẹ̀ míràn ti ìgbàanì kan tí ó wà nínú Bíbélì lọ́kàn àti ìjẹ́pàtàkì kíkẹ́kọ̀ọ́ láti inú rẹ̀, nígbà tí ó wí pé: “Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.” (Lúùkù 17:32; Jẹ́nẹ́sísì 19:1-26) Samuel Taylor Coleridge, akéwì àti ọlọ́gbọ́n èrò orí tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, kọ̀wé pé: “Bí àwọn ènìyàn bá lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìtàn, ẹ wo irú ẹ̀kọ́ tí ì bá kọ́ wa!”
Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti Ìmoore
Ẹ̀kẹta ni pé, rírántí lè gbin àwọn ànímọ́ tí ń dùn mọ́ Ọlọ́run nínú, ti ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ìmoore, sí wa lọ́kàn. Bí a ṣe ń hó ìhó ayọ̀ nínú ọ̀pọ̀ onírúurú ipò párádísè tẹ̀mí wa yíká ayé, ǹjẹ́ kí a má ṣe gbàgbé láé pé ó sinmi lórí àwọn ìpìlẹ̀ kan. Èyí ní nínú, ìdúróṣinṣin, ìfẹ́, ìfara-ẹni-rúbọ, ìgboyà lójú wàhálà, ìfaradà, ìpamọ́ra àti ìgbàgbọ́—àwọn ànímọ́ tí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà ní onírúurú ilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún sẹ́yìn fi hàn. Ní mímú ìròyìn rẹ̀ lórí ìtàn òde òní ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní Mexico wá sí ìparí, ìwé ọdọọdún 1995 Yearbook of Jehovah’s Witnesses wí pé: “Lójú àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àdánwò tí àwọn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà ní Mexico dojú kọ lè jẹ́ kàyéfì. Párádísè tẹ̀mí níbi tí ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí wà ti mọ́ wọn lára, níbi tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùbákẹ́gbẹ́ tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run wà, àti níbi tí a ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn sí Ọlọ́run lọ́nà tí a ṣètò dáradára.”
Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò náà sábà máa ń dá ṣiṣẹ́ tàbí kí wọ́n ṣiṣẹ́ ní àwùjọ àdádó. Wọ́n dojú kọ ìdánìkanwà, ìfi-nǹkan-duni, àti àwọn ìdánwò líle koko mìíràn tí ó jẹ́ ti ìwà títọ́ bí wọ́n ṣe ń forí tì í nínú pípòkìkí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ìgbà àtijọ́ wọ̀nyí ti kú, ẹ wo bí ó ti múni lọ́kàn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ tó pé Jèhófà ń rántí iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n fi tòótọ́tòótọ́ ṣe! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí sí èyí, nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 6:10) Bí Jèhófà bá fi tìmọrírìtìmọrírì rántí, kò ha yẹ kí a ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú nínú ẹ̀mí ìmoore?
Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ òtítọ́ lè ní òye ìtàn yìí nípasẹ̀ ìtẹ̀jáde náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom.a Síwájú sí i, bí a bá ní àǹfààní láti jẹ́ apá kan ìdílé kan tàbí kí a jẹ́ apá kan ìjọ Kristẹni tí ó ní àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà rẹ̀, tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún, a rọ̀ wá ní ìtumọ̀ gidi ti Diutarónómì 32:7 láti “rántí ọjọ́ ìgbàanì, ronú ọdún ìrandíran: bi bàbá rẹ léèrè yóò sì fi hàn ọ́; bi àwọn àgbà rẹ, wọn óò sì sọ fún ọ.”
Bẹ́ẹ̀ ni, rírántí àwọn ìṣe àtijọ́ ti ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run lè ru wá sókè láti máa bá a nìṣó láti fara dà tìdùnnútìdùnnú nínú iṣẹ́ ìsìn Kristẹni wa. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìtàn ní àwọn ẹ̀kọ́ tí a ní láti kọ́ nínú. Ṣíṣàṣàrò lórí párádísè tẹ̀mí wa tí Ọlọ́run ti bù kún sì ń mú àwọn ànímọ́ rere ti ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ìmoore jáde. Lóòótọ́, “ẹ máa rántí àwọn ọjọ́ tí ó ti kọjá.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.