ORÍ 11
“Ó Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo ní Gbogbo Ọ̀nà Rẹ̀”
1, 2. (a) Àwọn ìwà tó burú gan-an wo ni wọ́n hù sí Jósẹ́fù? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ tí wọ́n hù sí Jósẹ́fù?
ÌYÀ jẹ Jósẹ́fù gan-an láwọn àkókò tó ń dàgbà. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ni nígbà táwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ fẹ́ pa á. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n tà á fáwọn àjèjì, àwọn tó rà á wá mú un lọ sílẹ̀ òkèèrè, wọ́n sì sọ ọ́ di ẹrú. Lẹ́yìn náà, ìyàwó ọ̀gá ẹ̀ ní kó bá òun sùn. Àmọ́ Jósẹ́fù kọ̀, ni obìnrin náà bá bínú, tó sì parọ́ mọ́ Jósẹ́fù pé ó fẹ́ fipá bá òun lò pọ̀. Láìṣẹ̀ láìrò, bí Jósẹ́fù ṣe dèrò ẹ̀wọ̀n nìyẹn! Ńṣe ló dà bíi pé kò ní olùrànlọ́wọ́.
2 Àmọ́, Ọlọ́run tó “nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo” ń kíyè sí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù. (Sáàmù 33:5) Jèhófà wá gbé ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ tí wọ́n hù sí i. Ó mú kí wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Lẹ́yìn náà wọ́n dá a lọ́lá, wọ́n sì gbé e ga. (Jẹ́nẹ́sísì 40:15; 41:41-43; Sáàmù 105:17, 18) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó ṣe kedere sí gbogbo èèyàn pé ńṣe ni wọ́n parọ́ mọ́ Jósẹ́fù, ó sì lo ipò ńlá tó wà láti ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 45:5-8.
Láìṣẹ̀ láìrò, wọ́n fìyà jẹ Jósẹ́fù lẹ́wọ̀n
3. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo wa la fẹ́ káwọn èèyàn máa hùwà tó dáa sí wa, tá ò sì fẹ́ káwọn èèyàn máa fi ẹ̀tọ́ wa dù wá?
3 Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o rí bí Jèhófà ṣe dá sí ọ̀rọ̀ Jósẹ́fù? Ó dájú pé ó máa tù ẹ́ nínú, torí inú wa kì í dùn tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ tàbí tá a bá rí ẹnì kan tí wọ́n rẹ́ jẹ. Ká sòótọ́, gbogbo wa la fẹ́ káwọn èèyàn máa hùwà tó dáa sí wa, kò sì sẹ́ni táá fẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀tọ́ ẹ̀ dù ú. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè fìwà jọ ọ́, ìdájọ́ òdodo sì jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Ká tó lè mọ Jèhófà dáadáa, ó yẹ ká mọ ohun tí ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí. Èyí á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan, á sì wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn.
Kí Ni Ìdájọ́ Òdodo?
4. Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí?
4 Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ohun tó máa fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ onídàájọ́ òdodo kò ju pé kẹ́ni náà máa fọwọ́ pàtàkì mú òfin, kó sì máa pa òfin mọ́ nínú bó ṣe ń hùwà sáwọn èèyàn. Ìwé kan sọ pé, “ìdájọ́ òdodo sábà máa ń kan ọ̀rọ̀ òfin, ojúṣe àwọn èèyàn, ẹ̀tọ́ wọn àti iṣẹ́ wọn, tẹ́nì kan bá sì fẹ́ ṣèdájọ́ òdodo, ó gba pé kó fìyà jẹ ẹnì kan torí ìwà burúkú tẹ́ni náà hù tàbí kó san ẹnì kan lẹ́san torí pé ẹni náà hùwà tó dáa.” Àmọ́ ìdájọ́ òdodo Jèhófà jùyẹn lọ, Jèhófà kì í wulẹ̀ ṣe ohun tó bófin mu torí ó kàn gbà pé ohun tó yẹ kóun ṣe nìyẹn.
5, 6. (a) Kí nìtumọ̀ ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti ti Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìdájọ́ òdodo”? (b) Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà?
5 Tá a bá ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti ti Gíríìkì tí wọ́n tú sí ìdájọ́ òdodo nínú Bíbélì, á jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tí ìdájọ́ òdodo Jèhófà túmọ̀ sí. Ọ̀rọ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó jọra ni wọ́n lò fún ìdájọ́ òdodo nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Èyí tí wọ́n sábà máa ń tú sí “ìdájọ́ òdodo” nínú àwọn ọ̀rọ̀ náà tún lè túmọ̀ sí “ohun tó tọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:25) Wọ́n sì sábà máa ń tú ọ̀rọ̀ méjì tó kù sí “òdodo.” Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “òdodo” máa ń túmọ̀ sí pé “kéèyàn máa ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó bófin mu.” Torí náà, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ láàárín ọ̀rọ̀ náà òdodo àti ìdájọ́ òdodo.—Émọ́sì 5:24.
6 Tí Bíbélì bá wá sọ pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé Jèhófà máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo, kì í sì í ṣe ojúsàájú. (Róòmù 2:11) Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Élíhù fi sọ pé: “Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú, pé Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa!” (Jóòbù 34:10) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ò lè ṣe ohun tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu láé. Kí nìdí? Ìdí méjì pàtàkì ló mú ká gbà bẹ́ẹ̀.
7, 8. (a) Kí nìdí tí Jèhófà ò fi lè hùwà tí kò tọ́ láé? (b) Kí ló mú kí Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo tó máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo?
7 Ìdí àkọ́kọ́ ni pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́. Bá a ṣe sọ ní Orí 3 ìwé yìí, Jèhófà jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà, kò lábààwọ́n, ó sì jẹ́ olódodo. Torí náà, kò lè hùwà tí kò tọ́ láé. Ronú nípa ohun tíyẹn túmọ̀ sí ná. Torí pé Jèhófà Baba wa ọ̀run jẹ́ mímọ́, ọkàn wa balẹ̀ pé kò ní ṣe ohun tí kò dáa sáwa ọmọ rẹ̀. Bọ́rọ̀ ṣe rí lára Jésù náà nìyẹn. Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, ó gbàdúrà sí Jèhófà nípa àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀, ó ní: “Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn [àwọn ọmọ ẹ̀yìn] nítorí orúkọ rẹ.” (Jòhánù 17:11) Jèhófà nìkan ni wọ́n pè ní “Baba mímọ́” nínú Bíbélì. Èyí sì bá a mu, torí pé kò sí baba kankan tó jẹ́ èèyàn tó lè jẹ́ mímọ́ bíi ti Jèhófà. Jésù mọ̀ pé Bàbá òun mọ́ látòkè délẹ̀ láìní àbààwọ́n àti ẹ̀ṣẹ̀ kankan, torí náà ó dá Jésù lójú pé Bàbá òun máa dáàbò bo àwọn ọmọlẹ́yìn òun.—Mátíù 23:9.
8 Ìkejì, Jèhófà ò mọ tara ẹ̀ nìkan, ó sì jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ onídàájọ́ òdodo tó máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo. Àwọn tó máa ń ṣe ojúsàájú, tó sì máa ń hùwà tí kò dáa sáwọn ẹlòmíì sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí wọ́n jẹ́ olójúkòkòrò tó mọ tara wọn nìkan. Èyí sì fi hàn pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun kan nípa Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́. Ó sọ pé: “Olódodo ni Jèhófà; ó nífẹ̀ẹ́ àwọn iṣẹ́ òdodo.” (Sáàmù 11:7) Jèhófà tún sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Èmi Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Àìsáyà 61:8) Ó dájú pé ọkàn wa balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà Ọlọ́run wa máa ń dùn láti ṣe ohun tó tọ́!—Jeremáyà 9:24.
Aláàánú Ni Jèhófà, Ó sì Máa Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Lọ́nà Tó Pé
9-11. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń lo ìdájọ́ òdodo àti àánú pa pọ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé aláàánú àti onídàájọ́ òdodo lòun nínú bó ṣe ń bá àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lò?
9 Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń lo àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ lọ́nà tó tọ́, bó sì ṣe máa ń ṣe náà nìyẹn tó bá kan ìdájọ́ òdodo. Ìdí nìyẹn tí Mósè fi yin Jèhófà pé: “Àpáta náà, pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, torí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Ọlọ́run olóòótọ́, tí kì í ṣe ojúsàájú; olódodo àti adúróṣinṣin ni.” (Diutarónómì 32:3, 4) Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dájọ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, kì í le koko, kì í sì í gbàgbàkugbà.
10 Ṣe ni Jèhófà máa ń lo ìdájọ́ òdodo àti àánú pa pọ̀. Sáàmù 116:5 sọ pé: “Jèhófà jẹ́ agbatẹnirò àti olódodo [tàbí “onídàájọ́ òdodo,” The New American Bible]; Ọlọ́run wa jẹ́ aláàánú.” Lóòótọ́, Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo àti aláàánú. Èyí fi hàn pé ìwà àti ìṣe méjèèjì yìí kò ta kora. Tí Jèhófà bá ń fi àánú hàn lórí ọ̀rọ̀ kan, ìyẹn ò fi hàn pé kò ní dá ẹjọ́ náà lọ́nà tó tọ́, tó bá sì fẹ́ ṣe ìdájọ́ òdodo ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó máa ṣeé lọ́nà tó le koko. Ńṣe ni Jèhófà máa ń lo àwọn ìwà àti ìṣe méjèèjì yìí pa pọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.
11 Gbogbo wa la ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, torí náà ikú tọ́ sí wa. (Róòmù 5:12) Àmọ́ inú Jèhófà kì í dùn sí ikú ẹlẹ́ṣẹ̀. Ó jẹ́ ‘Ọlọ́run tó ṣe tán láti dárí jini, tó ń gba tẹni rò, tó sì jẹ́ aláàánú.’ (Nehemáyà 9:17) Síbẹ̀, torí pé ó jẹ́ mímọ́, kò lè fàyè gba àìṣòdodo. Báwo ni Jèhófà ṣe wá máa fàánú hàn sí àwa èèyàn tá a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀? Ńṣe ló fìfẹ́ pèsè ìràpadà fún wa ká lè rí ìgbàlà, ìràpadà yìí sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Bíbélì. A máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ẹ̀bùn pàtàkì yìí ní Orí 14. Ìràpadà yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti máa fàánú hàn sáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà láìsí pé ó ń ṣe ohun tó lòdì sí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ tó jẹ́ pípé. Ohun tí Jèhófà ṣe yìí jẹ́rìí sí i pé ìdájọ́ òdodo rẹ̀ kò lẹ́gbẹ́, àánú rẹ̀ sì pọ̀ gan-an.—Róòmù 3:21-26.
Ìdájọ́ Òdodo Jèhófà Ń Mú Kó Wù Wá Láti Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọn
12, 13. (a) Kí nìdí tí ìdájọ́ òdodo Jèhófà fi ń mú kó wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn? (b) Kí ni Ọba Dáfídì sọ nígbà tó kíyè sí bí Jèhófà ṣe jẹ́ onídàájọ́ òdodo, báwo lèyí sì ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀?
12 Dípò tí ìdájọ́ òdodo Jèhófà á fi mú ká jìnnà sí i, ńṣe ló ń mú kó wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn. Bíbélì jẹ́ ká ri í pé Jèhófà máa ń fìfẹ́ àti àánú hàn tó bá ń ṣèdájọ́. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun jẹ́ onídàájọ́ òdodo.
13 Jèhófà máa ń ṣèdájọ́ òdodo lọ́nà tó pé, ìdí nìyẹn tó fi máa ń jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Ọba Dáfídì kíyè sí bí Jèhófà ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, títí kan òun fúnra rẹ̀, èyí mú kó mọyì ìdájọ́ òdodo Jèhófà. Torí náà, ó sọ pé: “Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, kò sì ní kọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀. Ìgbà gbogbo ni yóò máa ṣọ́ wọn.” (Sáàmù 37:28) Ọ̀rọ̀ yìí mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Ó dá wa lójú pé Ọlọ́run wa ò ní kọ àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sílẹ̀ láé. Torí pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, ọkàn wa balẹ̀ pé kò ní pa wá tì láé, ó sì dá wa lójú pé á máa fìfẹ́ bójú tó wa!—Òwe 2:7, 8.
14. Báwo ni Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn aláìní jẹ ẹ́ lógún gan-an?
14 Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, ọ̀rọ̀ àwọn aláìní jẹ ẹ́ lógún gan-an. Èyí sì hàn nínú Òfin tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, Òfin yìí sọ àwọn nǹkan pàtó tó yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn ọmọ aláìníbaba àtàwọn opó. (Diutarónómì 24:17-21) Jèhófà mọ̀ pé nǹkan kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn ọmọ tí bàbá wọn ti kú àtàwọn obìnrin tí ọkọ wọn ti kú. Ìdí nìyẹn tó fi sọ ara ẹ̀ di Bàbá wọn àti ẹni tó ń dáàbò bò wọ́n, tó sì “ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún ọmọ aláìníbaba àti opó.”a (Diutarónómì 10:18; Sáàmù 68:5) Jèhófà kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ hùwà àìdáa sáwọn obìnrin àtàwọn ọmọ tí kò ní ẹni tó máa gbèjà wọn. Ó sọ pé tí wọ́n bá fìyà jẹ àwọn obìnrin yẹn àtàwọn ọmọ náà, tí wọ́n sì ké pe òun, òun máa gbọ́ igbe wọn. Ó tún sọ pé: Òun máa “bínú gidigidi.” (Ẹ́kísódù 22:22-24) Òótọ́ ni pé Jèhófà kì í tètè bínú, àmọ́ inú máa ń bí i tẹ́nì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ hùwà tí kò dáa sáwọn èèyàn. Kódà, ó máa ń ká a lára gan-an tẹ́ni tí wọ́n hùwà àìdáa sí náà bá jẹ́ aláìní.—Sáàmù 103:6.
15, 16. Kí ló jẹ́ kó hàn kedere pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú?
15 Jèhófà tún sọ fún wa pé òun ‘kì í ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni, òun kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.’ (Diutarónómì 10:17) Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sáwọn èèyàn tó wà nípò àṣẹ tó jẹ́ pé ipò tẹ́nì kan wà tàbí bó ṣe lówó tó ló máa ń pinnu ìwà tí wọ́n máa hù sí i. Jèhófà kì í ṣojúsàájú ní tiẹ̀. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan tó fi hàn kedere pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú. Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun, ó sì fẹ́ kí wọ́n láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Dípò tí Ọlọ́run á fi fún àwọn èèyàn díẹ̀ láǹfààní yìí, ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Ìṣe 10:34, 35) Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo èèyàn ni Ọlọ́run fún láǹfààní yìí, láìka ipò wọn, àwọ̀ wọn, tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé sí. Ká sòótọ́, kò sí ẹlòmíì tó jẹ́ onídàájọ́ òdodo bíi Jèhófà!
16 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà míì tí Jèhófà gbà ń ṣèdájọ́ òdodo lọ́nà tó pé, ìyẹn ni bó ṣe máa ń hùwà sáwọn tó bá ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà òdodo rẹ̀.
Jèhófà Ò Ní Ṣàìfi Ìyà Jẹ Ẹlẹ́ṣẹ̀
17. Ṣé báwọn nǹkan burúkú ṣe ń ṣẹlẹ̀ láyé yìí túmọ̀ sí pé Jèhófà kì í ṣe onídàájọ́ òdodo? Ṣàlàyé.
17 Àwọn kan lè máa rò ó pé: ‘Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni Jèhófà ò fara mọ́ àìṣòdodo, kí nìdí táwọn èèyàn fi ń hùwà ìrẹ́jẹ lónìí, tọ́pọ̀ èèyàn sì ń jìyà láìnídìí?’ Ti pé àwọn nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀ ò túmọ̀ sí pé Jèhófà kì í ṣe onídàájọ́ òdodo. Ìdí tí ìwà ìrẹ́jẹ fi pọ̀ láyé yìí ni pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn ló sì ń ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Àmọ́, ó dájú pé nǹkan máa yí pa dà láìpẹ́.—Diutarónómì 32:5.
18, 19. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ò ní gbà káwọn èèyàn mọ̀ọ́mọ̀ máa rú òfin òdodo rẹ̀ títí láé?
18 Òótọ́ ni pé Jèhófà máa ń fàánú hàn sáwọn tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti sún mọ́ ọn, síbẹ̀ kò ní gbà káwọn èèyàn máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ rẹ̀ títí láé. (Sáàmù 74:10, 22, 23) Onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, a ò sì lè tàn án jẹ, torí náà ó máa fìyà jẹ àwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin rẹ̀. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, . . . àmọ́ tí kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀.” (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, torí pé àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà rí i pé ó pọn dandan kóun fìyà jẹ àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin rẹ̀.
19 Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́. Lẹ́yìn tí Jèhófà mú wọn dé Ilẹ̀ Ìlérí, léraléra ni wọ́n ṣàìgbọràn sí i. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn ‘ba Jèhófà nínú jẹ́’ gan-an, síbẹ̀ ojú ẹsẹ̀ kọ́ ló pa wọ́n tì. (Sáàmù 78:38-41) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣàánú wọn, ó sì fún wọn láǹfààní láti yíwà pa dà. Ó sọ fún wọn pé: “Inú mi ò dùn sí ikú ẹni burúkú, bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí ìwà rẹ̀ pa dà, kó sì máa wà láàyè. Ẹ yí pa dà, ẹ yí ìwà búburú yín pa dà, ṣé ó wá yẹ kí ẹ kú ni, ilé Ísírẹ́lì?” (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Jèhófà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run, torí náà léraléra ló rán àwọn wòlíì rẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó lè fún wọn láǹfààní láti yí pa dà. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn ò fetí sí ọ̀rọ̀ Jèhófà, wọ́n sì kọ̀ láti yíwà pa dà. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Jèhófà gbà káwọn ọ̀tá ṣẹ́gun wọn kó lè gbèjà orúkọ mímọ́ rẹ̀, kó sì fi hàn pé onídàájọ́ òdodo lòun.—Nehemáyà 9:26-30.
20. (a) Kí la rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu bí Bíbélì ṣe máa ń lo kìnnìún láti ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe jẹ́ onígboyà àti onídàájọ́ òdodo?
20 Ọ̀nà tí Jèhófà gbà bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́. Ó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ń kíyè sí ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù lónìí, èyí sì máa ń bà á nínú jẹ́ gan-an. (Òwe 15:3) Ó tún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa ń fàánú hàn sáwọn tó bá ronú pìwà dà. Bákan náà, a rí i pé Jèhófà máa ń mú sùúrù fáwọn èèyàn kó lè wò ó bóyá wọ́n máa yíwà pa dà. Bí Jèhófà ṣe máa ń mú sùúrù yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kò ní fìyà jẹ àwọn ẹni burúkú. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá, torí àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún jẹ́ ká rí i pé títí láé kọ́ ni Ọlọ́run á máa mú sùúrù fáwọn ẹni ibi. Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣèdájọ́ òdodo, kò dà bí àwọn èèyàn tí wọ́n máa ń bẹ̀rù láti ṣe ohun tó tọ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi máa ń lo kìnnìún láti ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe jẹ́ onígboyà àti onídàájọ́ òdodo.b (Ìsíkíẹ́lì 1:10; Ìfihàn 4:7) Èyí jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa mú ìwà ìrẹ́jẹ kúrò láyé. Torí náà, a lè ṣàkópọ̀ ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣèdájọ́ báyìí pé: ó mọ ìgbà tó yẹ kóun fìyà jẹ ẹni tó bá ṣẹ̀, ó sì mọ ìgbà tó yẹ kóun fàánú hàn.—2 Pétérù 3:9.
Sún Mọ́ Ọlọ́run Tó Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo
21. Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ṣèdájọ́ òdodo, irú ẹni wo ló yẹ ká gbà pé ó jẹ́, kí sì nìdí?
21 Tá a bá ń ronú nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣèdájọ́ òdodo, kò yẹ ká máa rò pé Jèhófà kàn jẹ́ adájọ́ tí kò láàánú tó ń wá àwọn tó máa fìyà jẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká rí Jèhófà bíi Baba tí kì í gbàgbàkugbà, àmọ́ tó ń fìfẹ́ bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀ káyé wọn lè dáa. Torí pé onídàájọ́ òdodo ni Baba wa ọ̀run Jèhófà, ìgbà gbogbo ló máa ń ṣe ohun tó tọ́, ó sì máa ń fàánú hàn sáwa ọmọ rẹ̀ tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì wá.—Sáàmù 103:10, 13.
22. Ìrètí wo ni ìdájọ́ òdodo Jèhófà mú ká ní, kí sì nìdí tó fi fún wa ní ìrètí yìí?
22 Inú wa dùn gan-an bá a ṣe mọ̀ pé ìdájọ́ òdodo Jèhófà kọjá pé kó kàn máa fìyà jẹ àwọn aṣebi. Ìdájọ́ òdodo Jèhófà ló mú ká ní ìrètí àgbàyanu pé a máa wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun “níbi tí òdodo á máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Ìdí tó sì fi fún wa ní ìrètí yìí ni pé ńṣe ni ìdájọ́ òdodo rẹ̀ máa ń mú kó wá bó ṣe máa gbani là dípò táá fi máa wá bó ṣe máa fìyà jẹni. Ká sòótọ́, ìdájọ́ òdodo ṣe pàtàkì gan-an lára àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà, tá a bá sì lóye bí Jèhófà ṣe ń lò ó, ó máa wù wá pé ká túbọ̀ sún mọ́ ọn! Nínú àwọn orí tó tẹ̀ lé e, a máa túbọ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣèdájọ́ òdodo.
a Ọ̀rọ̀ náà “ọmọ aláìníbaba” jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe àwọn ọmọkùnrin tí kò ní baba nìkan ni Jèhófà ń bójú tó, ó tún máa ń bójú tó àwọn ọmọbìnrin tí kò ní baba. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe dá sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì lẹ́yìn tí bàbá wọn kú láìní ọmọkùnrin. Ńṣe ni Jèhófà ní kí wọ́n fún àwọn ọmọbìnrin náà ní ogún bàbá wọn. Jèhófà wá ní kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí di òfin ní Ísírẹ́lì káwọn èèyàn má bàa máa fi ẹ̀tọ́ àwọn ọmọbìnrin aláìníbaba dù wọ́n.—Nọ́ńbà 27:1-8.
b Ó jọni lójú pé nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa ṣèdájọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ Jèhófà fi ara ẹ̀ wé kìnnìún.—Jeremáyà 25:38; Hósíà 5:14.