ÌBÉÈRÈ LÁTI ỌWỌ́ ÀWỌN ÒǸKÀWÉ
Kí ló fi hàn pé kò pẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dó ti ìlú Jẹ́ríkò àtijọ́ tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀?
Bí Jóṣúà 6:10-15, 20 ṣe sọ, àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì yan yí ká ìlú Jẹ́ríkò lẹ́ẹ̀kan lóòjọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lọ́jọ́ keje, wọ́n lọ yí ká ìlú Jẹ́ríkò nígbà méje, Ọlọ́run sì mú kí ògiri gìrìwò tó yí ìlú náà ká wó lulẹ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọnú ìlú náà wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀. Ṣé ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn rí fi hàn pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé kò pẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dó ti ìlú Jẹ́ríkò àtijọ́ tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀?
Láyé àtijọ́, àwọn ọ̀tá sábà máa ń dó ti ìlú olódi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè pẹ́ gan-an táwọn ọ̀tá ti ń dó ti ìlú kan kí wọ́n tó wọnú ìlú náà, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí wọ́n bá wọnú rẹ̀ tán wọ́n máa ń kó àwọn ohun iyebíye tó wà nínú ìlú náà àtàwọn oúnjẹ tó ṣẹ́ kù níbẹ̀. Àmọ́, àwọn awalẹ̀pìtàn rí oúnjẹ rẹpẹtẹ nínú àwókù ìlú Jẹ́ríkò. Ìwé ìròyìn Biblical Archaeology Review sọ pé: “Yàtọ̀ sáwọn ohun èlò amọ̀, ọkà ló pọ̀ jù nínú ohun tí wọ́n rí nínú àwókù ìlú náà. . . . Ohun àrà ọ̀tọ̀ lèyí jẹ́ nínú ohun táwọn awalẹ̀pìtàn ilẹ̀ Palẹ́sìnì ṣàwárí. Ó ṣeé ṣe kí àwọn awalẹ̀pìtàn rí ìṣà kan tàbí méjì, àmọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ kí wọ́n rí ọkà tó pọ̀ tóyẹn.”
Bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ, ó nídìí pàtàkì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò fi kó ọkà tí wọ́n rí ní ìlú Jẹ́ríkò. Ìdí sì ni pé Jèhófà ti pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. (Jóṣ. 6:17, 18) Ìgbà ìrúwé làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbógun ti ìlú náà, ìyẹn sì jẹ́ lẹ́yìn ìgbà ìkórè tí ọkà máa ń pọ̀ rẹpẹtẹ. (Jóṣ. 3:15-17; 5:10) Ti pé ọkà rẹpẹtẹ ṣẹ́ kù ní ìlú Jẹ́ríkò fi hàn pé, bí Bíbélì ṣe sọ, kò pẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dó ti ìlú Jẹ́ríkò àtijọ́ tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀.