Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
SEPTEMBER 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DIUTARÓNÓMÌ 33-34
“Jẹ́ Kí Jèhófà Fi ‘Ọwọ́ Ayérayé’ Rẹ̀ Dáàbò Bò Ẹ́”
it-2 51
Jéṣúrúnì
Orúkọ oyè tí wọ́n fún Ísírẹ́lì. Nínú Bíbélì Septuagint lédè Gíríìkì, wọ́n máa ń lo “Jéṣúrúnì” láti ṣàlàyé bí ìfẹ́ tẹ́nì kan ní sẹ́lòmíì ṣe jinlẹ̀ tó, torí náà wọ́n túmọ̀ ẹ̀ sí “ẹni ọ̀wọ́n.” Ó yẹ kí orúkọ oyè yìí máa rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí májẹ̀mú tó wà láàárín àwọn àti Jèhófà, kó sì máa rán wọn létí ìdí tó fi ṣe pàtàkì kí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. (Di 33:5, 26; Ais 44:2) Nínú Diutarónómì 32:15, Jèhófà sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ṣe ohun tó bá orúkọ yìí mu. Dípò tí wọ́n á fi jẹ́ kí orúkọ náà rò wọ́n, wọ́n ya alágídí, wọ́n sì fi Jèhófà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá àti Olùgbàlà wọn sílẹ̀.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-2 439 ¶3
Mósè
Ẹni ọgọ́fà (120) ọdún ni Mósè nígbà tó kú. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìlera ẹ̀, ó ní: “Ojú rẹ̀ ò di bàìbàì, agbára rẹ̀ ò sì dín kù.” Jèhófà sin ín síbi tẹ́nì kankan ò mọ̀ títí dòní. (Di 34:5-7) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí káwọn ọmọ Ísírẹ́lì má bàa sọ ibi tí wọ́n sin Mósè sí di ojúbọ òrìṣà ni Jèhófà ò fi jẹ́ kí wọ́n mọbẹ̀. Ẹ̀rí sì fi hàn pé ohun tí Sátánì fẹ́ nìyẹn, torí nígbà tó yá Júùdù tó jẹ́ àbúrò Jésù sọ pé: “Nígbà tí Máíkẹ́lì olú áńgẹ́lì ń bá Èṣù fa ọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń jiyàn nípa òkú Mósè, kò jẹ́ dá a lẹ́jọ́, kò sì sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí i, àmọ́ ó sọ fún un pé: ‘Kí Jèhófà bá ọ wí.’ ” (Júùdù 9) Kí Jóṣúà tó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ọgbọ̀n (30) ọjọ́ sunkún torí Mósè.—Di 34:8.
SEPTEMBER 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓṢÚÀ 3-5
“Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Nígbàgbọ́”
it-2 105
Jọ́dánì
Lọ́pọ̀ ìgbà, apá ibi tí Odò Jọ́dánì ti sún mọ́ Òkun Gálílì máa ń jìn tó mítà kan sí mẹ́ta, ó sì máa ń fẹ̀ tó mítà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n sí ọgbọ̀n (27 m sí 30 m). Àmọ́ lásìkò ìrúwé, Odò Jọ́dánì máa ń kún àkúnya, torí náà ó máa ń fẹ̀ sí i, á sì jìn sí i. (Joṣ 3:15) Ó dájú pé kò ní rọrùn fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti sọdá odò náà nírú àsìkò yẹn, pàápàá tó bá jẹ́ nítòsí Jẹ́ríkò, torí pé ọ̀gbàrá máa ń yára ṣàn lápá ibẹ̀, kódà lẹ́nu àìpẹ́ yìí ó ti gbé àwọn tó wá lúwẹ̀ẹ́ níbẹ̀ lọ. Àmọ́ Jèhófà sé odò náà lọ́nà ìyanu, ìyẹn sì jẹ́ kó rọrùn fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti gba orí ilẹ̀ gbígbẹ sọdá. (Joṣ 3:14-17) Lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà ṣe irú iṣẹ́ ìyanu yìí nígbà tí Èlíjà àti Èlíṣà ń sọdá Odò Jọ́dánì, ó tún ṣerú ẹ̀ nígbà tí Èlíṣà nìkan ń sọdá odò náà.—2Ọb 2:7, 8, 13, 14.
OCTOBER 4-10
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓṢÚÀ 8-9
“Ohun Tá A Rí Kọ́ Látinú Ìtàn Àwọn Ará Gíbíónì”
it-1 930-931
Gíbíónì
Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Láàárín Àwọn àti Jóṣúà. Nígbà ayé Jóṣúà, àwọn ọmọ Hífì ló ń gbé ìlú Gíbíónì, ó sì wà lára àwọn ìlú méje tí Jèhófà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa run nílẹ̀ Kénáánì. (Di 7:1, 2; Joṣ 9:3-7) Wọ́n tún máa ń pe àwọn ará Gíbíónì ní Ámórì, torí pé wọ́n máa ń lo orúkọ yìí fún àwọn tó ń gbé ilẹ̀ Kénáánì nígbà míì. (2Sa 21:2; fi wé Jẹ 10:15-18; 15:16.) Ohun táwọn ará Gíbíónì ṣe yàtọ̀ sí tàwọn ọmọ Kénáánì tó kù. Àwọn ará Gíbíónì gbà pé bí ìlú àwọn bá tiẹ̀ láàbò, táwọn ọmọ ogun wọn sì lágbára, wọn ò ní lè borí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí pé Jèhófà ló ń jà fún wọn. Torí náà, lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun Jẹ́ríkò àti Áì, àwọn àgbààgbà Gíbíónì rán àwọn aṣojú sí Jóṣúà ní Gílígálì, kí Ísírẹ́lì lè bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà. Ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn yẹn tún ṣojú fáwọn ìlú mẹ́ta míì táwọn ọmọ Hífì ń gbé, ìyẹn Kéfírà, Béérótì àti Kiriati-jéárímù. (Joṣ 9:17) Àwọn aṣojú yẹn wọ aṣọ àti bàtà tó ti gbó, wọ́n kó búrẹ́dì tó ti gbẹ tó sì ti rún dání sínú àpò tó ti gbó, wọ́n sì rọ wáìnì sínú awọ tó ti gbó, tó sì ti bẹ́. Wọ́n ṣe bíi pé ọ̀nà jíjìn làwọn ti wá káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gbà pé wọn ò sí lára àwọn tí Jèhófà ní kí wọ́n pa. Wọ́n gbà pé Jèhófà ló gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íjíbítì àti lọ́wọ́ àwọn ọba Ámórì méjèèjì, ìyẹn Síhónì àti Ógù. Àmọ́ wọn ò sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jẹ́ríkò àti Áì, torí wọ́n gbà pé táwọn bá sọ ọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á mọ̀ pé “ọ̀nà tó jìn” kọ́ ni wọ́n ti wá, ó ṣe tán ó máa pẹ́ kí ìròyìn yẹn tó lè débi tí wọ́n sọ pé àwọn ti wá. Àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, wọ́n sì gbà pé òótọ́ ni wọ́n sọ, wọ́n wá bá wọn dá májẹ̀mú pé àwọn ò ní pa wọ́n.—Joṣ 9:3-15.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 1030
Gbé kọ́
Nínú òfin tí Jèhófà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Jèhófà sọ pé wọ́n lè gbé ẹni tó bá jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn kan kọ́ sórí igi lẹ́yìn tí wọ́n bá pa á tán, torí pé ‘ẹni ègún nirú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ lójú Ọlọ́run,’ ìyẹn á sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún gbogbo àwọn tó bá rí i lórí òpó igi náà. Àmọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ gbé òkú yẹn sọ̀ kalẹ̀, kí wọ́n sì sin ín kílẹ̀ tó ṣú, torí tí wọ́n bá fi sílẹ̀ di àárọ̀ ọjọ́ kejì, ó máa sọ ilẹ̀ tí Ọlọ́run fún wọn di aláìmọ́. (Di 21:22, 23) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń tẹ̀ lé òfin yìí, kódà tó bá jẹ́ pé àjèjì ni ọ̀daràn náà.—Joṣ 8:29; 10:26, 27.
Máa Lo Ara Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
it-1 520
Májẹ̀mú
Àdéhùn táwọn méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ bára wọn ṣe láti ṣe ohun kan tàbí yẹra fún ohun kan. Wọ́n tún máa ń pe májẹ̀mú ní ohun tí wọ́n dì tàbí àdéhùn. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí májẹ̀mú ni berithʹ. A ò mọ ìtúmọ̀ ẹ̀ ní tààràtà, àmọ́ ó fara hàn ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún méjì àti ọgọ́rin (280) ìgbà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, inú ìwé márùn-ún tí Mósè kọ lèyí tó ju ọgọ́rin (80) lára ibi tó sì ti fara hàn wà. Àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí àwọn wàláà kan lọ́dún 1927 ní ọ̀kan lára àwọn ìlú Ísírẹ́lì àtijọ́ ìyẹn ìlú Qatna, tó wà lápá gúúsù ìlà oòrùn ìlú Hamath. Ohun tí wọ́n rí níbẹ̀ jẹ́rìí sí i pé ohun tí berithʹ túmọ̀ sí nípilẹ̀ṣẹ̀ ni “májẹ̀mú,” ohun kan náà ló sì túmọ̀ sí tá a bá fi wé “àdéhùn” táwọn èèyàn máa ń bára wọn ṣe lónìí. Àwọn awalẹ̀pìtàn yẹn rí wàláà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. nígbà tí wọ́n sì ń ṣàlàyé ohun tó wà nínú àwọn wàláà náà, wọ́n sọ pé: “Ohun tó wà nínú méjì lára àwọn wàláà náà ò lọ́jú pọ̀ rárá. Orúkọ àwọn èèyàn ló wà nínú wàláà tí wọ́n pè ní A . . . Bí wọ́n ṣe máa pín oúnjẹ ló wà nínú wàláà B . . . Torí náà, àwọn tórúkọ wọn wà nínú wàláà A ti wọnú àdéhùn láti ṣiṣẹ́ sin ẹnì kan tàbí láti ṣe ohun kan. Bó ṣe jẹ́ pé ẹnì kan náà ló kọ ohun tó wà nínú wàláà B, á jẹ́ pé ṣe lẹni náà ń ṣèlérí pé òun máa fún àwọn tórúkọ wọn wà nínú wàláà A ní nǹkan kan fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe. . . . ọ̀kan pàtàkì nínú ẹ̀kọ́ àwọn Júù (Yahwist theology) ni berit, tó túmọ̀ sí ‘májẹ̀mú.’ Yàtọ̀ sí Bíbélì, ìwé ẹ̀sìn yìí nìwé àkọ́kọ́ tí wọ́n ti lo ọ̀rọ̀ náà berit, ìyẹn sì jẹ́ ní nǹkan bí apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1400 Ṣ.S.K.”—Bulletin of the American Schools of Oriental Research, February 1951, p. 22.
it-1 525 ¶1
Májẹ̀mú
Àwọn Májẹ̀mú Míì. (a) Àdéhùn tí Jóṣúà àtàwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì ṣe pẹ̀lú àwọn ará Gíbíónì láti dá ẹ̀mí wọn sí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Gíbíónì wà lára àwọn ọmọ Kénáánì tí Jèhófà gégùn-ún fún, tó sì ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa run, síbẹ̀ májẹ̀mú tí wọ́n bá wọn dá lágbára débi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá ẹ̀mí wọn sí. Àmọ́ bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà ti gégùn-ún fún wọn ṣáájú ìgbà yẹn, ṣe làwọn ará Gíbíónì di aṣẹ́gi fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n sì ń pọnmi fún àpéjọ náà.—Joṣ 9:15, 16, 23-27
OCTOBER 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓṢÚÀ 10-11
“Jèhófà Jà Fáwọn Ọmọ Ísírẹ́lì”
it-1 50
Adoni-sédékì
Òun ni ọba Jerúsálẹ́mù nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun Ilẹ̀ Ìlérí. Adoni-sédékì àtàwọn ọba míì tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì gbìmọ̀ pọ̀ láti bá Jóṣúà jà, kó má bàa gba ilẹ̀ wọn. (Joṣ 9:1-3) Àmọ́, àwọn ọmọ Hífì tó ń gbé ilẹ̀ Gíbíónì ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Jóṣúà. Torí náà, Adoni-sédékì àtàwọn ọba mẹ́rin míì nílẹ̀ Ámórì gbìmọ̀ pọ̀ láti gbógun ti Gíbíónì. Àmọ́ Jóṣúà gba Gíbíónì sílẹ̀. Nígbà táwọn ọba márààrún rí bí agbára Jóṣúà ṣe pọ̀ tó, ẹ̀rù bà wọ́n, ni wọ́n bá sá lọ, tí wọ́n sì fara pa mọ́ sínú ihò àpáta kan ní Mákédà. Jóṣúà wá pa Adoni-sédékì àtàwọn ọba mẹ́rin tó kù níṣojú àwọn ọmọ ogun ẹ̀, ó sì gbé wọn kọ́ sórí òpó. Nígbà tó yá, inú ihò àpáta táwọn ọba náà sá sí ni wọ́n pa dà ju òkú wọn sí.—Joṣ 10:1-27.
it-1 1020
Yìnyín
Bí Jèhófà Ṣe Máa Ń Lò Ó. Yìnyín wà lára àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ń lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ àti láti fagbára ńlá rẹ̀ hàn. (Sm 148:1, 8; Ais 30:30) Ìgbà àkọ́kọ́ tí Jèhófà lo yìnyín ni ìgbà tó fi ìyọnu keje kọ lu àwọn ọmọ Íjíbítì nígbà àtijọ́. Yìnyín náà lágbára débi pé ó run gbogbo ewéko àti igi oko, ó sì pa gbogbo ohun tó wà nínú oko, títí kan èèyàn àti ẹranko. Àmọ́ kò ṣèpalára kankan fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní Góṣénì. (Ẹk 9:18-26; Sm 78:47, 48; 105:32, 33) Lẹ́yìn ìyẹn, nígbà tí Jóṣúà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n gba àwọn ará Gíbíónì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọba Ámórì márùn-ún tó wá gbógun jà wọ́n. Nígbà ogun yẹn, Jèhófà rọ̀jò òkúta yìnyín ńláńlá lé àwọn ọ̀tá náà lórí. Àwọn tí yìnyín náà pa pọ̀ ju àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa.—Joṣ 10:3-7, 11.
OCTOBER 18-24
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓṢÚÀ 12-14
“Máa Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ Tẹ̀ Lé Jèhófà”
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 902-903
Gébálì
“Ilẹ̀ àwọn ará Gébálì” wà lára àwọn ilẹ̀ tí Jèhófà sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò tíì gbà nígbà ayé Jóṣúà. (Joṣ 13:1-5) Àmọ́, àwọn alátakò sọ pé ẹsẹ yìí ò bá àwọn ẹsẹ Bíbélì míì mu, torí ibi tó jìnnà lápá àríwá Ísírẹ́lì nìlú Gébálì wà (ìyẹn nǹkan bí ọgọ́ta (60) máìlì sí àríwá ìlú Dánì) àti pé ó ṣeé ṣe kílùú yìí má sí lára àwọn ìlú táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti yí ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò nínú ẹsẹ yìí pa dà, wọ́n ní ohun tó yẹ kó wà níbẹ̀ ni “ilẹ̀ tó wà nítòsí Lẹ́bánónì” tàbí ‘títí lọ dé ààlà àwọn ará Gébálì.’ Àmọ́, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan kí ìlérí tí Jèhófà ṣe fún wọn nínú Jóṣúà 13:2-7 tó lè ṣẹ. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àìgbọràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ò jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀ Gébálì gbà.—Fi wé Joṣ 23:12, 13.
OCTOBER 25-31
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓṢÚÀ 15-17
“Dáàbò Bo Ogún Iyebíye Tí Jèhófà Fún Ẹ”
it-1 1083 ¶3
Hébúrónì
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣẹ́gun apá gúúsù ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n pa àwọn ará Hébúrónì run títí kan ọba wọn (ó ní láti jẹ́ ẹni tó jọba lẹ́yìn Hóhámù). (Joṣ 10:36, 37) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun ìlú tó pọ̀ nílẹ̀ Kénáánì, síbẹ̀ ó jọ pé wọn ò ṣètò àwọn ọmọ ogun tá máa ṣọ́ ilẹ̀ náà. Torí náà, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jagun níbòmíì, àwọn ọmọ Ánákímù tún kóra jọ sí Hébúrónì. Nígbà tó yá, ó di dandan fún Kélẹ́bù (tàbí àwọn ọmọ Júdà lábẹ́ ìdarí Kélẹ́bù) láti bá wọn jagun kó lè gba àwọn ìlú náà. (Joṣ 11:21-23; 14:12-15; 15:13, 14; Ond 1:10) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Kélẹ́bù tó wá látinú ẹ̀yà Júdà ló jogún Hébúrónì, nígbà tó yá wọ́n ya ìlú náà sọ́tọ̀, wọ́n sì sọ ọ́ di ìlú ààbò. Wọ́n tún sọ ọ́ di ìlú àwọn àlùfáà. Àmọ́, Kélẹ́bù ló ṣì ni àwọn “pápá tó wà ní ìlú [Hébúrónì]” àtàwọn ìgbèríko rẹ̀.—Joṣ 14:13, 14; 20:7; 21:9-13.
it-1 848
Fipá Múni Ṣiṣẹ́
Wọ́n sábà máa ń ‘fipá mú àwọn èèyàn ṣiṣẹ́’ (mas lédè Hébérù) láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Tí wọ́n bá ṣẹ́gun ìlú kan, wọ́n máa ń kó àwọn èèyàn ibẹ̀ lẹ́rú. (Di 20:11; Joṣ 16:10; 17:13; Ẹst 10:1; Ais 31:8; Ida 1:1) Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lóko ẹrú ní Íjíbítì, wọ́n fipá mú wọn ṣiṣẹ́, wọ́n ń fìyà jẹ wọ́n gan-an, wọ́n sì ní kí wọ́n máa kọ́ àwọn ibi tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí ní Pítómù àti Rámísésì. (Ẹk 1:11-14) Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, dípò kí wọ́n pa àwọn ọmọ Kénáánì run bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún wọn, ṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ wọ́n dẹrú, tí wọ́n sì ń fipá mú wọn ṣiṣẹ́. Ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe yẹn fa àjálù fún wọn, torí ó mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sin àwọn ọlọ́run èké. (Joṣ 16:10; Ond 1:28; 2:3, 11, 12) Nígbà tó yá, Ọba Sólómọ́nì túbọ̀ mú kí nǹkan nira fáwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọmọ Kénáánì, ìyẹn àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àtàwọn ará Jébúsì. Sólómọ́nì sọ wọ́n dẹrú, ó sì fipá mú wọn ṣiṣẹ́.—1Ọb 9:20, 21.
it-1 402 ¶3
Kénáánì
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ilẹ̀ Kénáánì kọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun nígbà tí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí, síbẹ̀ a ṣì lè sọ pé ‘Jèhófà fún wọn ní gbogbo ilẹ̀ tó búra pé òun máa fún àwọn baba ńlá wọn,’ Ó “fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo àyíká wọn” àti pé “kò sí ìlérí tí kò ṣẹ nínú gbogbo ìlérí dáadáa tí Jèhófà ṣe fún ilé Ísírẹ́lì; gbogbo rẹ̀ ló ṣẹ pátá.” (Joṣ 21:43-45) Kò sẹ́ni tó lè halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, torí gbogbo àwọn tó wà láyìíká wọn ló ń bẹ̀rù wọn. Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé “díẹ̀díẹ̀” lòun máa lé àwọn ọmọ Kénáánì kúrò ní ilẹ̀ náà, káwọn ẹranko búburú má bàa pọ̀ níbẹ̀ tí ò bá sẹ́ni tó ń gbébẹ̀. (Ẹk 23:29, 30; Di 7:22) Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ Kénáánì láwọn ọmọ ogun tó lágbára àtàwọn kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin, síbẹ̀ a ò lè sọ pé Jèhófà ò mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ṣe ṣẹ́gun àwọn ìlú kan nílẹ̀ náà. (Joṣ 17:16-18; Ond 4:13) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé àìṣòótọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló jẹ́ káwọn ọ̀tá ṣẹ́gun wọn láwọn ìgbà kan.—Nọ 14:44, 45; Joṣ 7:1-12.