Jóṣúà
13 Ní báyìí, Jóṣúà ti darúgbó, ó sì ti lọ́jọ́ lórí.+ Jèhófà sọ fún un pé: “O ti darúgbó, o sì ti lọ́jọ́ lórí; àmọ́ ẹ ò tíì gba* èyí tó pọ̀ jù nínú ilẹ̀ náà. 2 Àwọn ilẹ̀ tó ṣẹ́ kù nìyí:+ gbogbo ilẹ̀ àwọn Filísínì àti ti gbogbo àwọn ará Géṣúrì+ 3 (láti ẹ̀ka odò Náílì* tó wà ní ìlà oòrùn* Íjíbítì títí dé ààlà Ẹ́kírónì lọ sí àríwá, tí wọ́n máa ń pè ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì)+ pẹ̀lú ilẹ̀ àwọn alákòóso Filísínì márààrún,+ ìyẹn àwọn ará Gásà, àwọn ará Áṣídódì,+ àwọn ará Áṣíkẹ́lónì,+ àwọn ará Gátì+ àti àwọn ará Ẹ́kírónì;+ ilẹ̀ àwọn Áfímù+ 4 lọ sí apá gúúsù; gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì; Méárà, tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Sídónì,+ títí lọ dé Áfékì, dé ààlà àwọn Ámórì; 5 ilẹ̀ àwọn ará Gébálì+ àti gbogbo Lẹ́bánónì lápá ìlà oòrùn, láti Baali-gádì ní ìsàlẹ̀ Òkè Hámónì títí dé Lebo-hámátì;*+ 6 gbogbo àwọn tó ń gbé agbègbè olókè láti Lẹ́bánónì+ lọ dé Misirefoti-máímù;+ àti gbogbo àwọn ọmọ Sídónì.+ Mo máa lé wọn kúrò* níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Kí o ṣáà rí i pé o pín in fún Ísírẹ́lì pé kó jẹ́ ogún wọn, bí mo ṣe pa á láṣẹ fún ọ.+ 7 Kí o pín ilẹ̀ yìí fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè pé kó jẹ́ ogún wọn.”+
8 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà tó kù, wá gba ogún wọn tí Mósè fún wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe fún wọn:+ 9 láti Áróérì,+ tó wà létí Àfonífojì Áánónì+ àti ìlú tó wà láàárín àfonífojì náà àti gbogbo ilẹ̀ tó tẹ́jú* ní Médébà títí dé Díbónì; 10 àti gbogbo ìlú Síhónì ọba àwọn Ámórì, tó jọba ní Hẹ́ṣíbónì, títí dé ààlà àwọn ọmọ Ámónì;+ 11 pẹ̀lú Gílíádì àti ilẹ̀ àwọn ará Géṣúrì àti tàwọn ará Máákátì+ àti gbogbo Òkè Hámónì pẹ̀lú gbogbo Báṣánì+ títí lọ dé Sálékà;+ 12 gbogbo ilẹ̀ ọba Ógù ní Báṣánì, tó jọba ní Áṣítárótì àti Édíréì. (Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Réfáímù+ tó kẹ́yìn.) Mósè ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn kúrò.*+ 13 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lé+ àwọn ará Géṣúrì àti àwọn ará Máákátì kúrò,* torí àwọn Géṣúrì àti Máákátì ṣì wà láàárín Ísírẹ́lì títí di òní yìí.
14 Ẹ̀yà àwọn ọmọ Léfì nìkan ni kò pín ogún fún.+ Àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún wọn,+ bó ṣe ṣèlérí fún wọn.+
15 Mósè pín ogún fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní ìdílé-ìdílé, 16 ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Áróérì, tó wà létí Àfonífojì Áánónì àti ìlú tó wà láàárín àfonífojì náà pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ tó tẹ́jú lẹ́gbẹ̀ẹ́ Médébà; 17 Hẹ́ṣíbónì àti gbogbo ìlú rẹ̀+ tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú, Díbónì, Bamoti-báálì, Bẹti-baali-méónì,+ 18 Jáhásì,+ Kédémótì,+ Mẹ́fáátì,+ 19 Kiriátáímù, Síbúmà,+ Sereti-ṣáhà lórí òkè tó wà ní àfonífojì,* 20 Bẹti-péórì, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà,+ Bẹti-jẹ́ṣímótì,+ 21 gbogbo ìlú tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú àti gbogbo ilẹ̀ Síhónì ọba àwọn Ámórì, tó jọba ní Hẹ́ṣíbónì.+ Mósè ṣẹ́gun òun+ àtàwọn ìjòyè Mídíánì, ìyẹn Éfì, Rékémù, Súúrì, Húrì àti Rébà,+ àwọn ọba tó wà lábẹ́ Síhónì, tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà. 22 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa Báláámù+ ọmọ Béórì, tó jẹ́ woṣẹ́woṣẹ́+ pẹ̀lú àwọn yòókù tí wọ́n pa. 23 Jọ́dánì ni ààlà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì; ilẹ̀ yìí sì ni ogún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní ìdílé-ìdílé, pẹ̀lú àwọn ìlú náà àtàwọn ìgbèríko wọn.
24 Bákan náà, Mósè pín ogún fún ẹ̀yà Gádì, àwọn ọmọ Gádì ní ìdílé-ìdílé, 25 ara ilẹ̀ wọn sì ni Jásérì+ àti gbogbo ìlú tó wà ní Gílíádì pẹ̀lú ìdajì ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì+ títí dé Áróérì, èyí tó dojú kọ Rábà;+ 26 láti Hẹ́ṣíbónì+ dé Ramati-mísípè àti Bẹ́tónímù àti láti Máhánáímù+ títí dé ààlà Débírì; 27 àti ní àfonífojì,* Bẹti-hárámù, Bẹti-nímírà,+ Súkótù+ àti Sáfónì, èyí tó kù nínú ilẹ̀ Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì,+ tí Jọ́dánì jẹ́ ààlà rẹ̀ láti apá ìsàlẹ̀ Òkun Kínérétì*+ lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì. 28 Ogún àwọn ọmọ Gádì nìyí ní ìdílé-ìdílé, pẹ̀lú àwọn ìlú náà àtàwọn ìgbèríko wọn.
29 Yàtọ̀ síyẹn, Mósè pín ogún fún ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ìdajì nínú ẹ̀yà Mánásè ní ìdílé-ìdílé.+ 30 Ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Máhánáímù+ tó fi mọ́ gbogbo Báṣánì, gbogbo ilẹ̀ Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo abúlé Jáírì+ tí wọ́n pàgọ́ sí ní Báṣánì, ó jẹ́ ọgọ́ta (60) ìlú. 31 Ìdajì Gílíádì pẹ̀lú Áṣítárótì àti Édíréì,+ àwọn ìlú tó wà ní ilẹ̀ ọba Ógù ní Báṣánì, di ti àwọn ọmọ Mákírù,+ ọmọ Mánásè, ìyẹn ìdajì àwọn ọmọ Mákírù ní ìdílé-ìdílé.
32 Èyí ni ogún tí Mósè pín fún wọn ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù ní ìkọjá Jọ́dánì, lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò.+
33 Àmọ́ Mósè ò fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Léfì ní ogún kankan.+ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún wọn, bó ṣe ṣèlérí fún wọn.+