Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀ wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
• Ọ̀nà mẹ́rin wo ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ”?
Àkọ́kọ́, àwọn tí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì lo ọ̀rọ̀ náà ìjọ fún ní pàtàkì ni àpapọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn (àwọn ẹsẹ Bíbélì kan fi hàn pé Kristi náà wà lára wọn). Ìkejì, ó lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ Ọlọ́run” fún gbogbo àwọn Kristẹni tó wà lákòókò kan pàtó. Ìkẹta, ó lò ó fún gbogbo àwọn Kristẹni tó ń gbé lágbègbè ibì kan. Ìkẹrin, ọ̀rọ̀ náà ìjọ lè tọ́ka sáwọn Kristẹni tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ ìjọ kan.—4/15, ojú ìwé 21 sí 23.
• Ìgbà wo ni pípè tí Ọlọ́run ń pe àwọn Kristẹni sí ọ̀run yóò dópin?
Bíbélì ò fún wa ní ìdáhùn kan pàtó sí ìbéèrè yẹn. Ìpè yẹn bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ó sì ń bá a nìṣó títí di àkókò tá a wà yìí. Lẹ́yìn ọdún 1935, ìdí pàtàkì tá a fi ń ṣe iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn ni láti kó àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá jọ. Àwọn Kristẹni kan tó ṣèrìbọmi lẹ́yìn ọdún 1935 tún rí i pé ẹ̀mí mímọ́ bá àwọn jẹ́rìí pé ọ̀run làwọn ń lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, a ò lè sọ pé àkókò kan pàtó ni pípè tí Ọlọ́run ń pe àwọn Kristẹni sí ọ̀run yóò dópin. Àwọn ojúlówó Kristẹni ẹni àmì òróró kò gbà pé àwọn ní ẹ̀mí mímọ́ ju àwọn àgùntàn mìíràn lọ, wọn ò sì retí pé káwọn èèyàn inú ìjọ máa gbé àwọn gẹ̀gẹ̀. Yálà ìrètí àtilọ sọ́run ni Kristẹni kan ní tàbí ti wíwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé, a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́, ká sì máa bá a nìṣó ní ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—5/1, ojú ìwé 30 àti 31.
• Ṣé ohun tí Jẹ́fútà ní lọ́kàn nígbà tó ń jẹ́jẹ̀ẹ́ ni pé òún á fọmọbìnrin òun rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Ọlọ́run?
Rárá o. Ohun tí Jẹ́fútà ní lọ́kàn ni pé òun máa fi ẹni tó bá wá pàdé òun fún Ọlọ́run, kónítọ̀hún fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣiṣẹ́ Ọlọ́run, èyí sì wà níbàámu pẹ̀lú Òfin Mósè. (1 Sámúẹ́lì 2:22) Kí Jẹ́fútà lè mú ẹ̀jẹ́ yìí ṣẹ, ọmọbìnrin rẹ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ń bá a lọ láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà ní àgọ́ ìjọsìn. Nǹkan ńlá ni ọmọbìnrin yìí yááfì o, nítorí ohun tíyẹn gbà ni pé kò ní lọ́kọ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.—5/15, ojú ìwé 9 àti 10.
• Ipa wo ni ìwé àfọwọ́kọ alábala kó nínú ẹ̀sìn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní?
Ó dà bíi pé àkájọ ìwé nìkan làwọn Kristẹni lò, ó kéré tán títí di ìparí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni. Láàárín ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni, àwọn kan fara mọ́ lílo ìwé àfọwọ́kọ alábala, nígbà tó jẹ́ pé àkájọ ìwé làwọn kan fara mọ́. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n gbà pé lílò táwọn Kristẹni ń lo ìwé àfọwọ́kọ alábala kópa pàtàkì nínú bó ṣe wá dohun táwọn èèyàn fara mọ́ tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà káàkiri.—6/1, ojú ìwé 14 àti 15.
• Kí ni Kàlẹ́ńdà Gésérì?
Kàlẹ́ńdà Gésérì jẹ́ wàláà òkúta ẹfun kan tí wọ́n ṣàwárí lọ́dún 1908 ní ìlú Gésérì. Ọ̀pọ̀ awalẹ̀pìtàn gbà pé ọmọ iléèwé lẹni tó kọ ọ́ lọ́nà ewì gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àṣetiléwá. Ó jẹ́ àkópọ̀ ọ̀kan-ò-jọ̀kan iṣẹ́ táwọn àgbẹ̀ máa ń ṣe jálẹ̀ ọdún. Ẹni tó kọ kàlẹ́ńdà ìgbàanì yìí bẹ̀rẹ̀ látorí ìkórè gbogbo gbòò, èyí tó bọ́ sáàárín oṣù September àti October lórí kàlẹ́ńdà tiwa lónìí. Ó sì mẹ́nu kan oríṣiríṣi nǹkan ọ̀gbìn àti ìgbòkègbodò àwọn àgbẹ̀.—6/15, ojú ìwé 8.
• Kí ló túmọ̀ sí láti ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́?
Ó ṣeé ṣe kéèyàn ṣẹ̀ sí ẹ̀mí Jèhófà, èyí sì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. (Mátíù 12:31) Ọlọ́run ló ń pinnu bóyá ẹnì kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì, òun ló sì lè mú ẹ̀mí rẹ̀ kúrò lára ẹni. (Sáàmù 51:11) Tínú ẹnì kan bá bà jẹ́ gan-an nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, ó ṣeé ṣe kí ìyẹn jẹ́ ẹ̀rí pé onítọ̀hún ronú pìwà dà látọkànwá, àti pé kò tíì ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́.—7/15, ojú ìwé 16 àti 17.
• Nígbà tó jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù Ọba ti mọ Dáfídì dáadáa tẹ́lẹ̀, kí nìdí tó tún fi ń béèrè pé ọmọkùnrin ta ni Dáfídì? (1 Sámúẹ́lì 16:22; 17:58)
Kì í ṣe orúkọ bàbá Dáfídì nìkan ni Sọ́ọ̀lù fẹ́ mọ̀. Ojú tí Sọ́ọ̀lù fi ń wo Dáfídì ti yàtọ̀ pátápátá látìgbà tó ti ṣẹ́gun Gòláyátì tó sì fi hàn pé ọmọ tó nígbàgbọ́ gan-an tó sì tún nígboyà lòun. Nítorí ìdí yìí Sọ́ọ̀lù fẹ́ mọ ẹni tó tọ́ Dáfídì dàgbà. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí Sọ́ọ̀lù ní in lọ́kàn pé òun máa fi Jésè tàbí àwọn aráalé rẹ̀ mìíràn kún àwọn ọmọ ogun òun.—8/1, ojú ìwé 31.